Éxodo 31 – NVI & YCB

Nueva Versión Internacional

Éxodo 31:1-18

Bezalel y Aholiab

31:2-6Éx 35:30-35

1El Señor habló con Moisés y le dijo: 2«Toma en cuenta que he escogido a Bezalel, hijo de Uri y nieto de Hur, de la tribu de Judá, 3y lo he llenado del Espíritu de Dios, de sabiduría, inteligencia y capacidad creativa 4para hacer trabajos artísticos en oro, plata y bronce, 5para cortar y engastar piedras preciosas, para hacer tallados en madera y realizar toda clase de artesanías. 6Además, he designado como su ayudante a Aholiab, hijo de Ajisamac, de la tribu de Dan.

»Y he dotado de habilidad a todos los artesanos para que hagan todo lo que te he mandado hacer, es decir:

7»la Tienda de reunión,

el arca con las tablas del pacto,

la tapa que va encima de ella,

el resto del mobiliario de la Tienda,

8la mesa y sus utensilios,

el candelabro de oro puro y todos sus accesorios,

el altar del incienso,

9el altar de los holocaustos y todos sus utensilios,

el recipiente de bronce con su pedestal,

10las vestiduras tejidas,

tanto las vestiduras sagradas para Aarón el sacerdote

como las vestiduras sacerdotales de sus hijos,

11el aceite de la unción y el incienso aromático para el Lugar Santo.

»Todo deberán hacerlo tal como te he mandado que lo hagas».

El sábado

12El Señor ordenó a Moisés:

13«Diles lo siguiente a los israelitas: Ustedes deberán observar mis sábados. En todas las generaciones venideras, el sábado será una señal entre ustedes y yo, para que sepan que yo, el Señor, los he consagrado.31:13 los he consagrado. Alt. los he separado como santos.

14»El sábado será para ustedes un día sagrado. Obsérvenlo.

»Quien no lo observe será condenado a muerte.

»Quien haga algún trabajo en sábado será eliminado de su pueblo.

15»Durante seis días se podrá trabajar, pero el día séptimo, el sábado, será de completo reposo consagrado al Señor.

»Quien haga algún trabajo en sábado será condenado a muerte.

16»Los israelitas deberán observar el sábado. En todas las generaciones futuras será para ellos un pacto perpetuo, 17una señal eterna entre ellos y yo.

»En efecto, en seis días hizo el Señor los cielos y la tierra, el séptimo día descansó».

18Y cuando terminó de hablar con Moisés en el monte Sinaí, le dio las dos tablas del pacto, que eran dos lajas escritas por el dedo mismo de Dios.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 31:1-18

Besaleli àti Oholiabu

131.1-6: Ek 35.30–36.1.Olúwa wí fún Mose pé, 2“Wò ó, èmi ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, 3Èmi sì ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún un pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 4Láti ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní wúrà, fàdákà àti idẹ, 5láti gbẹ́ òkúta àti láti tò wọ́n, láti ṣiṣẹ́ ní igi, àti láti ṣiṣẹ́ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 6Síwájú sí i, èmi ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, láti ràn án lọ́wọ́.

“Bákan náà, èmi ti fi ọgbọ́n fún gbogbo àwọn oníṣẹ́-ọnà láti ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún ọ:

7“àgọ́ àjọ náà,

àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀,

àti gbogbo ohun èlò àgọ́ náà,

8tábìlì àti ohun èlò rẹ̀,

ọ̀pá fìtílà tí ó jẹ́ kìkì wúrà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,

pẹpẹ tùràrí,

9pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,

agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀,

10àti aṣọ híhun pẹ̀lú,

papọ̀ pẹ̀lú aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà

àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ bí àlùfáà,

11òróró ìtasórí àti tùràrí olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́.

“Kí wọ́n ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ.”

Ọjọ́ ìsinmi

1231.12-17: Ek 20.8; 23.12; 35.2; De 5.12-15.Olúwa wí fún Mose pé, 13“Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ ààmì láàrín èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́.

14“ ‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a yóò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a yóò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ. 15Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ní ọjọ́ ìsinmi tí ẹ̀yin yóò fi sinmi, mímọ́ ni fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ni a ó pa nítòótọ́. 16Nítorí náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóò ṣe máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, ẹ máa ṣe àkíyèsí rẹ̀ dé ìrandíran tó ń bọ̀ bí i májẹ̀mú títí láé. 17Yóò jẹ́ ààmì láàrín èmi àti àwọn ọmọ Israẹli títí láé, nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, àti ní ọjọ́ keje ni ó fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó sì sinmi.’ ”

18Nígbà tí Olúwa parí ọ̀rọ̀ sísọ fún Mose lórí òkè Sinai, ó fún un ní òkúta wàláà ẹ̀rí méjì, òkúta wàláà òkúta tí a fi ìka Ọlọ́run kọ.