Éxodo 25 – NVI & YCB

Nueva Versión Internacional

Éxodo 25:1-40

Las ofrendas para el santuario

25:1-7Éx 35:4-9

1El Señor habló con Moisés y le dijo: 2«Ordénales a los israelitas que me traigan una ofrenda. La deben presentar todos los que sientan deseos de traérmela.

3»Como ofrenda se les aceptará lo siguiente:

»oro, plata, bronce,

4lana color azul, carmesí y escarlata, tela de lino fino,

pelo de cabra,

5pieles de carnero teñidas de rojo, pieles finas,

madera de acacia,

6aceite de oliva para las lámparas,

especias para el aceite de la unción y para el incienso aromático;

7también piedras de ónice y otras piedras preciosas para montarlas en el efod y en el pectoral del sacerdote.

8»Después me harán un santuario, para que yo habite entre ustedes. 9El santuario y todo su mobiliario deberán ser una réplica exacta del modelo que yo te mostraré.

El arca

25:10-20Éx 37:1-9

10»Haz25:10 Haz (LXX y Pentateuco Samaritano); Hagan ustedes (TM). un arca de madera de acacia, de dos codos y medio de largo, un codo y medio de ancho, y un codo y medio de alto.25:10 Es decir, aprox. 1 m de largo, 68 cm de ancho y 68 cm de alto; también en v. 17. 11Por dentro y por fuera recúbrela de oro puro y ponle en su derredor una moldura de oro. 12Funde cuatro anillos de oro para colocarlos en sus cuatro patas, colocando dos anillos en un lado y dos en el otro. 13Prepara luego unas varas de madera de acacia y recúbrelas de oro. 14Introduce las varas en los anillos que van a los costados del arca, para transportarla. 15Deja las varas en los anillos del arca y no las saques de allí, 16entonces pon dentro del arca las tablas del pacto que voy a entregarte.

17»Hazle al arca una tapa de oro puro, de dos codos y medio de largo por un codo y medio de ancho, 18y para los dos extremos de la tapa del arca harás dos querubines de oro trabajado a martillo. 19En cada uno de los extremos irá un querubín. Hazlos de modo que formen una sola pieza con la tapa del arca.

20»Los querubines deberán tener las alas extendidas por encima de la tapa del arca y cubrirla con ellas. Quedarán el uno frente al otro, mirando hacia la tapa del arca.

21»Coloca la tapa encima del arca y pon dentro de ella las tablas del pacto que voy a entregarte. 22Yo me reuniré allí contigo en medio de los dos querubines que están sobre el arca donde están las tablas del pacto. Desde la parte superior de la tapa del arca te daré todas las instrucciones que habrás de comunicarles a los israelitas.

La mesa

25:23-29Éx 37:10-16

23»Haz una mesa de madera de acacia de dos codos de largo por un codo de ancho y un codo y medio de alto.25:23 Es decir, aprox. 90 cm de largo, 45 cm de ancho y 68 cm de alto. 24Recúbrela de oro puro y ponle alrededor una moldura de oro. 25Haz también un reborde de un palmo25:25 Es decir, un palmo menor, aprox. 7.5 cm. de ancho, y una moldura de oro para ponerla alrededor del reborde.

26»Haz cuatro anillos de oro para la mesa y sujétalos a sus cuatro esquinas, donde van las cuatro patas. 27Los anillos deben quedar junto al reborde para pasar por ellos las varas empleadas para transportar la mesa.

28»Esas varas deben ser de madera de acacia y estar recubiertas de oro. 29También deben ser de oro puro sus platos y sus bandejas, así como sus jarras y tazones para verter las ofrendas líquidas. 30Sobre la mesa pondrás el pan de la Presencia, para que esté ante mí siempre.

El candelabro

25:31-39Éx 37:17-24

31»Haz un candelabro de oro puro trabajado a martillo. Su base, su tallo, y sus copas, cálices y flores, formarán una sola pieza. 32De los costados del candelabro saldrán seis brazos, tres de un lado y tres del otro. 33Cada uno de los seis brazos del candelabro tendrá tres copas en forma de flores de almendro, con cálices y pétalos. 34El candelabro mismo tendrá cuatro copas en forma de flor de almendro, con cálices y pétalos. 35Debajo del primer par de brazos que salen del candelabro habrá un cáliz; debajo del segundo par de brazos habrá un segundo cáliz y debajo del tercer par de brazos habrá un tercer cáliz —seis brazos en total. 36Los cálices y los brazos deben formar una sola pieza con el candelabro y ser de oro puro trabajado a martillo.

37»Hazle también sus siete lámparas y colócalas de tal modo que alumbren hacia el frente. 38Sus cortapabilos y braseros deben ser de oro puro. 39Para hacer el candelabro y todos estos accesorios se usará un talento25:39 Es decir, aprox. 34 kg. de oro puro.

40»Asegúrate de hacerlo todo según el modelo que se te mostró en el monte.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 25:1-40

Ọrẹ ẹbọ fún àgọ́

125.1: Ek 35–40.Olúwa sì wí fún Mose pé, 225.2-8: Ek 35.4-9.“Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọn mú ọrẹ wá fún mi, ìwọ yóò gba ọrẹ náà fún mi ni ọwọ́ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan ti ọkàn rẹ bá fẹ́ láti fi fún mi.

3“Wọ̀nyí ni ọrẹ ti ìwọ yóò gbà ni ọwọ́ wọn:

“wúrà, fàdákà àti idẹ;

4aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó, ọ̀gbọ̀;

irun ewúrẹ́.

5Awọ àgbò tí a rẹ ní pupa àti awọ ewúrẹ́ igbó;

igi kasia;

6Òróró olifi fún iná títàn;

òróró olóòórùn dídùn fún ìtasórí àti fún tùràrí olóòórùn dídùn;

7àti òkúta óníkìsì àti òkúta olówó iyebíye ti a fi ṣe ọ̀ṣọ́ sí ara ẹ̀wù efodu àti ẹ̀wù ìgbàyà.

8“Nígbà náà ni ìwọ yóò jẹ́ kí wọn kọ́ ibi mímọ́ fún mi. Èmi yóò sì máa gbé ní àárín wọn. 9Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí ti mo fihàn ọ́, nípa àpẹẹrẹ àgọ́, àti àpẹẹrẹ gbogbo ohun èlò inú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe é.

Àpótí ẹ̀rí

1025.10-22: Ek 37.1-9.“Wọn yóò sì fi igi ṣittimu ṣe àpótí, ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni gíga rẹ̀. 11Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà, bò ó ní inú àti ní òde, ìwọ ó sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká. 12Ìwọ ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún. Ìwọ ó sì fi wọ́n sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ẹsẹ̀ rẹ̀, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹgbẹ́ kejì. 13Ìwọ ó sì fi igi kasia ṣe ọ̀pá mẹ́rin, ìwọ ó sì fi wúrà bò wọ́n. 14ìwọ ó sì fi ọ̀pá náà bọ òrùka ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà láti fi gbé e. 15Òpó náà yóò wá nínú òrùka lára àpótí ẹ̀rí; a kò ní yọ wọ́n kúrò. 16Nígbà náà ni ìwọ yóò fi ẹ̀rí ti èmi yóò fi fún ọ sínú àpótí náà.

17“Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú; ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní fífẹ̀. 18Ìwọ ó sì ṣe kérúbù méjì láti inú wúrà tí a fi òòlù sí igun ìtẹ́ àánú náà. 19Ìwọ ó ṣe kérúbù kan sí igun kìn-ín-ní àti kérúbù kejì sí igun kejì, kí kérúbù náà jẹ́ irú kan náà ní igun méjèèjì pẹ̀lú ìbòrí wọn. 20Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè, tí wọn yóò sì fi ìyẹ́ apá wọn ṣe ibòòji sí orí ìtẹ́ àánú. Àwọn kérúbù náà yóò kọ ojú sí ara wọn, wọn yóò máa wo ọ̀kánkán ìtẹ́. 21Gbé ọmọrí orí àpótí ẹ̀rí kí o sì fi ẹ̀rí èyí tí èmí yóò fi fún ọ sínú àpótí ẹ̀rí. 22Níbẹ̀, ni òkè ìtẹ́, ní àárín kérúbù méjèèjì ti ó wà ni orí àpótí ẹ̀rí ni èmi yóò ti pàdé rẹ, ti èmi yóò sì fún ọ ní àwọn òfin mi fún àwọn ọmọ Israẹli.

Tábìlì

2325.23-30: Ek 37.10-15.“Fi igi kasia kan tábìlì: ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní gíga. 24Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó, ìwọ ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí i ká. 25Ìwọ sì ṣe etí kan ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ sí i yíká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká. 26Ìwọ ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, ìwọ ó sì fi òrùka kọ̀ọ̀kan sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. 27Ní abẹ́ ìgbátí náà ni àwọn òrùka náà yóò wà fún ibi ọ̀pá láti máa fi gbé tábìlì náà. 28Ìwọ ó sì fi igi kasia ṣe àwọn ọ̀pá, ìwọ ó sì fi wúrà bò wọ́n, láti máa fi wọ́n gbé tábìlì náà. 29Ìwọ ó sì fi ojúlówó wúrà ṣe àwo àti ṣíbí rẹ̀, kí o sì ṣe àwokòtò àti ago pẹ̀lú fún dída ọrẹ jáde. 3025.30: Ek 39.36; 40.23; Le 24.5-9.Gbé àkàrà ìfihàn sí orí tábìlì yìí, kí ó le wà ní iwájú mi ni gbogbo ìgbà.

Ọ̀pá fìtílà

3125.31-40: Ek 37.17-24.“Ìwọ ó sì ojúlówó wúrà, lù ú dáradára, ṣe ọ̀pá fìtílà kan, ìsàlẹ̀ àti apá rẹ̀, kọ́ọ̀bù rẹ̀ ti ó dàbí òdòdó, ìṣọ àti ìtànná rẹ̀ yóò jẹ́ ara kan náà pẹ̀lú rẹ̀. 32Ẹ̀ka mẹ́fà ni yóò yọ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pá fìtílà: mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kejì. 33Àwo mẹ́ta ni kí a ṣe bí ìtànná almondi, tí ó ṣọ tí ó sì tanná ni yóò wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta yóò sì wà ní ẹ̀ka kejì, àti bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó jáde lára ọ̀pá fìtílà. 34Ní ara ọ̀pá fìtílà ni àwo mẹ́rin ti a ṣe gẹ́gẹ́ bí òdòdó almondi ti ó ni ìṣọ àti ìtànná yóò wà. 35Irúdì kan yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, irúdì kejì ó sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kejì, irúdì kẹta yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kẹta: ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀. 36Irúdì wọn àti ẹ̀ka wọn kí ó rí bákan náà, kí gbogbo rẹ̀ kí ó jẹ́ lílù ojúlówó wúrà.

37“Nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe fìtílà méje. Ìwọ yóò sì gbe ka orí rẹ̀, kí wọn kí ó lè máa ṣe ìmọ́lẹ̀ sí iwájú rẹ̀. 38Àti alumagaji rẹ̀, àti àwo alimagaji rẹ̀, kí ó jẹ́ kìkì wúrà. 39Tálẹ́ǹtì kìkì wúrà ni ó fi ṣe é, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò wọ̀nyí. 4025.40: Ap 7.44; Hb 8.5.Kíyèsí i, kí ìwọ kí ó ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ wọn, ti a fi hàn ọ́ ni orí òkè.