Levítico 9 – NVI-PT & YCB

Nova Versão Internacional

Levítico 9:1-24

Os Sacerdotes Começam o seu Ministério

1Oito dias depois, Moisés convocou Arão, seus filhos e as autoridades de Israel. 2E disse a Arão: “Traga um bezerro para a oferta pelo pecado e um carneiro para o holocausto, ambos sem defeito, e apresente-os ao Senhor. 3Depois diga aos israelitas: Tragam um bode para oferta pelo pecado; um bezerro e um cordeiro, ambos de um ano de idade e sem defeito, para holocausto; 4e um boi9.4 A palavra hebraica pode significar boi ou vaca. e um carneiro para oferta de comunhão, para os sacrificar perante o Senhor, com a oferta de cereal amassada com óleo; pois hoje o Senhor aparecerá a vocês”.

5Levaram então tudo o que Moisés tinha determinado para a frente da Tenda do Encontro, e a comunidade inteira aproximou-se e ficou em pé perante o Senhor. 6Disse-lhes Moisés: “Foi isso que o Senhor ordenou que façam, para que a glória do Senhor apareça a vocês”.

7Disse Moisés a Arão: “Venha até o altar e ofereça o seu sacrifício pelo pecado e o seu holocausto, e faça propiciação por você mesmo e pelo povo; ofereça o sacrifício pelo povo e faça propiciação por ele, conforme o Senhor ordenou”.

8Arão foi até o altar e ofereceu o bezerro como sacrifício pelo pecado por si mesmo. 9Seus filhos levaram-lhe o sangue, e ele molhou o dedo no sangue e o pôs nas pontas do altar; depois derramou o restante do sangue na base do altar, 10onde queimou a gordura, os rins e o lóbulo do fígado da oferta pelo pecado, conforme o Senhor tinha ordenado a Moisés; 11a carne e o couro, porém, queimou fora do acampamento.

12Depois sacrificou o holocausto. Seus filhos lhe entregaram o sangue, e ele o derramou nos lados do altar. 13Entregaram-lhe, em seguida, o holocausto pedaço por pedaço, inclusive a cabeça, e ele os queimou no altar. 14Lavou as vísceras e as pernas e as queimou em cima do holocausto sobre o altar.

15Depois Arão apresentou a oferta pelo povo. Pegou o bode para a oferta pelo pecado do povo e o ofereceu como sacrifício pelo pecado, como fizera com o primeiro.

16Apresentou o holocausto e ofereceu-o conforme fora prescrito. 17Também apresentou a oferta de cereal, pegou um punhado dela e a queimou no altar, além do holocausto da manhã.

18Matou o boi e o carneiro como sacrifício de comunhão pelo povo. Seus filhos levaram-lhe o sangue, e ele o derramou nos lados do altar. 19Mas as porções de gordura do boi e do carneiro, a cauda gorda, a gordura que cobre as vísceras, os rins e o lóbulo do fígado, 20puseram em cima do peito; e Arão queimou essas porções no altar. 21Em seguida, Arão moveu o peito e a coxa direita do animal perante o Senhor como gesto ritual de apresentação, conforme Moisés tinha ordenado.

22Depois Arão ergueu as mãos em direção ao povo e o abençoou. E, tendo oferecido o sacrifício pelo pecado, o holocausto e o sacrifício de comunhão, desceu.

23Assim Moisés e Arão entraram na Tenda do Encontro. Quando saíram, abençoaram o povo; e a glória do Senhor apareceu a todos eles. 24Saiu fogo da presença do Senhor e consumiu o holocausto e as porções de gordura sobre o altar. E, quando todo o povo viu isso, gritou de alegria e prostrou-se com o rosto em terra.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 9:1-24

Àwọn àlùfáà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́

1Ní ọjọ́ kẹjọ, Mose pe Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àgbàgbà Israẹli. 2Ó sọ fún Aaroni pé, “Mú akọ ọmọ màlúù kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò kan fún ẹbọ sísun, kí méjèèjì jẹ́ aláìlábùkù, kí o sì mú wọn wá sí iwájú Olúwa. 3Kí o sì sọ fún àwọn ará Israẹli pé, ‘Ẹ mú òbúkọ kan wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọmọ màlúù àti ọ̀dọ́-àgùntàn kan, kí méjèèjì jẹ́ ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun, 4àti akọ màlúù kan àti àgbò kan fún ẹbọ àlàáfíà àti ẹbọ ohun jíjẹ tí a fi òróró pò láti fi rú ẹbọ ní iwájú Olúwa. Nítorí pé Olúwa yóò farahàn yín ní òní.’ ”

5Wọ́n kó gbogbo àwọn nǹkan tí Mose pàṣẹ wá sí iwájú àgọ́ ìpàdé, gbogbo ìjọ ènìyàn sì súnmọ́ tòsí, wọ́n sì dúró níwájú Olúwa. 6Nígbà náà ni Mose wí pé, “Ohun tí Olúwa pàṣẹ fún yín láti ṣe nìyìí, kí ògo Olúwa bá à lè farahàn yín.”

7Mose sọ fún Aaroni pé, “Wá sí ibi pẹpẹ kí o sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù fún ara rẹ àti fún àwọn ènìyàn; rú ẹbọ ti àwọn ènìyàn náà, kí o sì ṣe ètùtù fún wọn gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ.”

8Aaroni sì wá sí ibi pẹpẹ, ó pa akọ ọmọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀. 9Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì ti ìka ọwọ́ rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí ìwo pẹpẹ, ó sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. 10Ó sun ọ̀rá, kíndìnrín àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, èyí tó mú láti inú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, lórí pẹpẹ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose. 11Ó sì sun ara ẹran àti awọ rẹ̀ ní ẹ̀yìn ibùdó.

12Lẹ́yìn èyí ó pa ẹran tó wà fún ẹbọ sísun. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká. 13Wọ́n sì ń mú ẹbọ sísun náà fún un ní ègé kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú orí rẹ̀, ó sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ. 14Ó fọ nǹkan inú rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sun wọ́n lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ.

15Aaroni mú ẹbọ tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn wá. Ó mú òbúkọ èyí tó dúró fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn ó sì pa á, ó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ti àkọ́kọ́.

16Ó mú ẹbọ sísun wá, ó sì rú u gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a fi lélẹ̀. 17Ó tún mu ẹbọ ohun jíjẹ wá, ó bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú rẹ̀, ó sì sun ún lórí pẹpẹ ní àfikún ẹbọ sísun tí àárọ̀.

189.18-21: Le 3.1-11.Ó pa akọ màlúù àti àgbò bí ẹbọ àlàáfíà fún àwọn ènìyàn. Àwọn ọmọ Aaroni sì mú ẹ̀jẹ̀ ẹran náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì wọn yí pẹpẹ náà ká. 19Ṣùgbọ́n ọ̀rá akọ màlúù àti àgbò náà: ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, básí ọ̀rá, ọ̀rá kíndìnrín, àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀: 20gbogbo rẹ̀ ni wọ́n kó lórí igẹ̀ ẹran náà. Aaroni sì sun ọ̀rá náà lórí pẹpẹ. 21Aaroni fi igẹ̀ àti itan ọ̀tún ẹran náà níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì bí Mose ṣe pa á láṣẹ.

229.22: Nu 6.22-26.Aaroni sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn ènìyàn, ó sì súre fún wọn. Lẹ́yìn tó sì ti rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà, ó sọ̀kalẹ̀.

23Mose àti Aaroni sì wọ inú àgọ́ ìpàdé. Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn ènìyàn, ògo Olúwa sì farahàn sí gbogbo ènìyàn, 24Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì jó ẹbọ sísun àti ọ̀rá orí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì rí èyí wọ́n hó ìhó ayọ̀, wọ́n sì dojúbolẹ̀.