Jeremias 29 – NVI-PT & YCB

Nova Versão Internacional

Jeremias 29:1-32

A Carta aos Exilados

1Este é o conteúdo da carta que o profeta Jeremias enviou de Jerusalém aos líderes, que ainda restavam entre os exilados, aos sacerdotes, aos profetas e a todo o povo que Nabucodonosor deportara de Jerusalém para a Babilônia. 2Isso aconteceu depois que o rei Joaquim e a rainha-mãe, os oficiais do palácio real, os líderes de Judá e Jerusalém, os artesãos e os artífices foram deportados de Jerusalém para a Babilônia. 3Ele enviou a carta por intermédio de Eleasa, filho de Safã, e Gemarias, filho de Hilquias, os quais Zedequias, rei de Judá, mandou a Nabucodonosor, rei da Babilônia. A carta dizia o seguinte:

4“Assim diz o Senhor dos Exércitos, o Deus de Israel, a todos os exilados, que deportei de Jerusalém para a Babilônia: 5‘Construam casas e habitem nelas; plantem jardins e comam de seus frutos. 6Casem-se e tenham filhos e filhas; escolham mulheres para casar-se com seus filhos e deem as suas filhas em casamento, para que também tenham filhos e filhas. Multipliquem-se e não diminuam. 7Busquem a prosperidade da cidade para a qual eu os deportei e orem ao Senhor em favor dela, porque a prosperidade de vocês depende da prosperidade dela’. 8Porque assim diz o Senhor dos Exércitos, o Deus de Israel: ‘Não deixem que os profetas e adivinhos que há no meio de vocês os enganem. Não deem atenção aos sonhos que vocês os encorajam a terem. 9Eles estão profetizando mentiras em meu nome. Eu não os enviei’, declara o Senhor.

10“Assim diz o Senhor: ‘Quando se completarem os setenta anos da Babilônia, eu cumprirei a minha promessa em favor de vocês, de trazê-los de volta para este lugar. 11Porque sou eu que conheço os planos que tenho para vocês’, diz o Senhor, ‘planos de fazê-los prosperar e não de causar dano, planos de dar a vocês esperança e um futuro. 12Então vocês clamarão a mim, virão orar a mim, e eu os ouvirei. 13Vocês me procurarão e me acharão quando me procurarem de todo o coração. 14Eu me deixarei ser encontrado por vocês’, declara o Senhor, ‘e os trarei de volta do cativeiro.29.14 Ou e restaurarei a sorte de vocês. Eu os reunirei de todas as nações e de todos os lugares para onde eu os dispersei e os trarei de volta para o lugar de onde os deportei’, diz o Senhor.

15“Vocês podem dizer: ‘O Senhor levantou profetas para nós na Babilônia’, 16mas assim diz o Senhor sobre o rei que se assenta no trono de Davi e sobre todo o povo que permanece nesta cidade, seus compatriotas que não foram com vocês para o exílio; 17assim diz o Senhor dos Exércitos: ‘Enviarei a guerra, a fome e a peste contra eles; lidarei com eles como se lida com figos ruins, que são intragáveis. 18Eu os perseguirei com a guerra, a fome e a peste; farei deles objeto de terror para todos os reinos da terra, maldição e exemplo, zombaria e afronta entre todas as nações para onde eu os dispersei. 19Porque eles não deram atenção às minhas palavras’, declara o Senhor, ‘palavras que lhes enviei pelos meus servos, os profetas. E vocês também não deram atenção!’, diz o Senhor.

20“Ouçam, agora, a palavra do Senhor, todos vocês exilados, que deportei de Jerusalém para a Babilônia! 21Assim diz o Senhor dos Exércitos, o Deus de Israel, a respeito de Acabe, filho de Colaías, e a respeito de Zedequias, filho de Maaseias, que estão profetizando mentiras a vocês em meu nome: ‘Eu os entregarei nas mãos de Nabucodonosor, rei da Babilônia, e ele os matará diante de vocês. 22Em razão disso, os exilados de Judá que estão na Babilônia usarão esta maldição: “Que o Senhor o trate como tratou Zedequias e Acabe, os quais o rei da Babilônia queimou vivos”. 23Porque cometeram loucura em Israel: adulteraram com as mulheres de seus amigos e em meu nome falaram mentiras, que eu não ordenei que falassem. Mas eu estou sabendo; sou testemunha disso’, declara o Senhor.

Mensagem a Semaías

24“Diga a Semaías, de Neelam: 25Diz o Senhor dos Exércitos, o Deus de Israel, que você enviou cartas em seu próprio nome a todo o povo de Jerusalém, a Sofonias, filho do sacerdote Maaseias, e a todos os sacerdotes. Você disse a Sofonias: 26‘O Senhor o designou sacerdote em lugar de Joiada como encarregado do templo do Senhor; você deveria prender no tronco, com correntes de ferro, qualquer doido que agisse como profeta. 27E por que você não repreendeu Jeremias de Anatote, que se apresenta como profeta entre vocês? 28Ele até mandou esta mensagem para nós que estamos na Babilônia, dizendo que o exílio será longo, que construam casas e habitem nelas, plantem jardins e comam de seus frutos’ ”.

29O sacerdote Sofonias leu a carta para o profeta Jeremias. 30Então o Senhor dirigiu a palavra a Jeremias: 31“Envie esta mensagem a todos os exilados: Assim diz o Senhor sobre Semaías, de Neelam: Embora eu não o tenha enviado, Semaías profetizou a vocês e fez com que vocês cressem numa mentira, 32por isso, assim diz o Senhor: Castigarei Semaías, de Neelam, e os seus descendentes. Não lhe restará ninguém entre este povo, e ele não verá as coisas boas que farei em favor de meu povo”, declara o Senhor, “porque ele pregou rebelião contra o Senhor”.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jeremiah 29:1-32

Lẹ́tà si àwọn ìgbèkùn

1Èyí ni ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí wòlíì Jeremiah rán láti Jerusalẹmu sí ìyókù nínú àwọn àgbàgbà tí ó wà ní ìgbèkùn àti sí àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn tí Nebukadnessari tí kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli. 2Lẹ́yìn ìgbà tí Jekoniah, ọba, àti ayaba, àti àwọn ìwẹ̀fà, àti àwọn ìjòyè Juda àti Jerusalẹmu, àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà àti àwọn olùyàwòrán tí wọ́n lọ ṣe àtìpó láti Jerusalẹmu. 3Ó fi lẹ́tà náà rán Eleasa ọmọ Ṣafani àti Gemariah ọmọ Hilkiah, ẹni tí Sedekiah ọba Juda rán sí Nebukadnessari ọba Babeli. Wí pé.

4Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí mo kó lọ ṣe àtìpó láti Jerusalẹmu ní Babeli: 5“Ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èso ohun ọ̀gbìn oko yín. 6Ẹ ṣe ìgbéyàwó, kí ẹ sì bí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, ẹ gbé ìyàwó fún àwọn ọmọkùnrin yín, kí ẹ sì fi àwọn ọmọbìnrin yín fún ọkọ. Kí àwọn náà lè ní ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin. Ẹ máa pọ̀ sí i ní iye, ẹ kò gbọdọ̀ dínkù ní iye níbẹ̀ rárá. 7Bákan náà, ẹ máa wá àlàáfíà àti ìre ìlú, èyí tí mo kó yín lọ láti ṣe àtìpó. Ẹ gbàdúrà sí Olúwa fún ìre ilẹ̀ náà; nítorí pé bí ó bá dára fún ilẹ̀ náà, yóò dára fún ẹ̀yin pẹ̀lú.” 8Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: “Ẹ má ṣe gbà kí àwọn wòlíì èké àti àwọn aláfọ̀ṣẹ àárín yín tàn yín jẹ. Ẹ má ṣe fetísílẹ̀ sí àlá, èyí tí ẹ gbà wọ́n níyànjú láti lá. 9Wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún yín lórúkọ mi; Èmi kò rán wọn níṣẹ́,” ni Olúwa wí.

10Báyìí ni Olúwa wí: “Nígbà tí ẹ bá lo àádọ́rin ọdún pé ní Babeli, èmi yóò tọ̀ yín wá láti ṣe àmúṣẹ ìlérí ńlá mi fún un yín, àní láti kó o yín padà sí Jerusalẹmu. 11Nítorí mo mọ èrò tí mo rò sí yín,” ni Olúwa wí, “àní èrò àlàáfíà, kì í sì ṣe fún ibi, èrò láti fún un yín ní ìgbà ìkẹyìn àti ìrètí ọjọ́ iwájú. 12Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò ké pè mí, tí ẹ̀yin yóò sì gbàdúrà sí mi, tí èmi yóò sì gbọ́ àdúrà yín. 13Ẹ̀yin yóò wá mi, bí ẹ̀yin bá sì fi gbogbo ọkàn yín wá mi: ẹ̀yin yóò rí mi ni Olúwa Ọlọ́run wí. 14Èmi yóò di rí rí fún yín ni Olúwa wí, Èmi yóò sì mú yín padà kúrò ní ìgbèkùn. Èmi yóò ṣà yín jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè àti ibi gbogbo tí Èmi ti lé yín jáde, ni Olúwa wí. Èmi yóò sì kó yín padà sí ibi tí mo ti mú kí a kó yín ní ìgbèkùn lọ.”

15Ẹ̀yin lè wí pé, “Olúwa ti gbé àwọn wòlíì dìde fún wa ní Babeli.” 16Ṣùgbọ́n èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa ní ti ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi àti ní ti gbogbo ènìyàn tó ṣẹ́kù ní ìlú yìí; àní ní ti àwọn ènìyàn yín tí kò bá yín lọ sí ìgbèkùn, 17bẹ́ẹ̀ ni, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín wọn; Èmi yóò ṣe wọ́n bí èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú tí kò ṣe é jẹ. 18Èmi yóò fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn lépa wọn; Èmi yóò sì sọ wọ́n di ìríra lójú gbogbo ìjọba ayé, fún ègún, àti ìyanu, àti ẹ̀sín, àti ẹ̀gàn láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, ní ibi tí Èmi yóò lé wọn sí. 19Nítorí wọ́n kọ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,” ni Olúwa Ọlọ́run wí. Ọ̀rọ̀ tí mo tún ti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sọ ní ẹ̀yin tí ń ṣe àtìpó kò gbọ́ ni Olúwa Ọlọ́run wí.

20Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yin ìgbèkùn, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin tí mo rán lọ kúrò ní Jerusalẹmu lọ sí Babeli. 21Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli sọ nípa Ahabu ọmọ Kolaiah àti nípa Sedekiah ọmọ Maaseiah tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún un yín lórúkọ mi: “Èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́. Òun yóò sì gba ẹ̀mí wọn ní ìṣẹ́jú yìí gan an. 22Nítorí tiwọn, ègún yìí yóò ran gbogbo àwọn àtìpó tó wà ní ilẹ̀ Babeli láti Juda: ‘Ọlọ́run yóò ṣe yín bí i Sedekiah àti Ahabu tí ọba Babeli dáná sun.’ 23Nítorí wọ́n ti ṣe ibi ní ilé Israẹli, wọ́n ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ìyàwó aládùúgbò wọn, àti ní orúkọ mi ni wọ́n ti ṣe èké, èyí tí èmi kò rán wọn láti ṣe. Ṣùgbọ́n, Èmi mọ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo sì jẹ́ ẹlẹ́rìí sí i,” ni Olúwa wí.

Iṣẹ́ pàtàkì tí a rán sí Ṣemaiah

24Wí fún Ṣemaiah tí í ṣe Nehalami pé, 25“Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli wí: Ìwọ fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ènìyàn ní Jerusalẹmu sí Sefaniah ọmọ Maaseiah tí í ṣe àlùfáà ní orúkọ mi; ó sì sọ fún Sefaniah wí pé, 26Olúwa ti yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà rọ́pò Jehoiada láti máa jẹ́ alákòóso ilé Olúwa, kí o máa fi èyíkéyìí nínú àwọn aṣiwèrè tó bá ṣe bí i wòlíì si inú àgò irin. 27Nítorí náà, èéṣe tí o kò fi bá Jeremiah ará Anatoti wí. Ẹni tí ó ń dúró bí i wòlíì láàrín yín? 28Ó ti rán iṣẹ́ yìí sí wa ni Babeli wí pé, àtìpó náà yóò pẹ́ kí ó tó parí, nítorí náà, ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èso ohun ọ̀gbìn oko yín.’ ”

29Sefaniah àlùfáà ka lẹ́tà náà sí etí ìgbọ́ Jeremiah tí í ṣe wòlíì. 30Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé, 31“Rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo àwọn ìgbèkùn wí pé: ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí ní ti Ṣemaiah, ará Nehalami: Nítorí pé Ṣemaiah ti sọtẹ́lẹ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n èmi kò ran an, tí òun sì ń mú u yín gbẹ́kẹ̀lé èké. 32Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: Wò ó, èmi yóò bẹ Ṣemaiah, ará Nehalami wò, àti irú-ọmọ rẹ̀; òun kì yóò ní ọkùnrin kan láti máa gbé àárín ènìyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò rí rere náà tí èmi yóò ṣe fún àwọn ènìyàn mi ni Olúwa wí, nítorí ó ti ti kéde ìṣọ̀tẹ̀ sí mi.’ ”