Jeremias 18 – NVI-PT & YCB

Nova Versão Internacional

Jeremias 18:1-23

Na Casa do Oleiro

1Esta é a palavra que veio a Jeremias da parte do Senhor: 2“Vá à casa do oleiro, e ali você ouvirá a minha mensagem”. 3Então fui à casa do oleiro, e o vi trabalhando com a roda. 4Mas o vaso de barro que ele estava formando estragou-se em suas mãos; e ele o refez, moldando outro vaso de acordo com a sua vontade.

5Então o Senhor dirigiu-me a palavra: 6“Ó comunidade de Israel, será que eu não posso agir com vocês como fez o oleiro?”, pergunta o Senhor. “Como barro nas mãos do oleiro, assim são vocês nas minhas mãos, ó comunidade de Israel. 7Se em algum momento eu decretar que uma nação ou um reino seja arrancado, despedaçado e arruinado, 8e se essa nação que eu adverti converter-se da sua perversidade, então eu me arrependerei e não trarei sobre ela a desgraça que eu tinha planejado. 9E, se noutra ocasião eu decretar que uma nação ou um reino seja edificado e plantado, 10e se ele fizer o que eu reprovo e não me obedecer, então me arrependerei do bem que eu pretendia fazer em favor dele.

11“Agora, portanto, diga ao povo de Judá e aos habitantes de Jerusalém: Assim diz o Senhor: Estou preparando uma desgraça e fazendo um plano contra vocês. Por isso, converta-se cada um de seu mau procedimento e corrija a sua conduta e as suas ações. 12Mas eles responderão: ‘Não adianta. Continuaremos com os nossos próprios planos; cada um de nós seguirá a rebeldia do seu coração mau’.”

13Portanto, assim diz o Senhor:

“Perguntem entre as nações

se alguém já ouviu uma coisa dessas;

coisa tremendamente horrível fez a virgem, Israel!

14Poderá desaparecer a neve do Líbano

de suas encostas rochosas?

Poderão parar de fluir suas águas frias,

vindas de lugares distantes?

15Contudo, o meu povo esqueceu-se de mim:

queimam incenso a ídolos inúteis,

que os fazem tropeçar em seus caminhos

e nas antigas veredas,

para que andem em desvios,

em estradas não aterradas.

16A terra deles ficará deserta

e será tema de permanente zombaria.

Todos os que por ela passarem

ficarão chocados e balançarão a cabeça.

17Como o vento leste,

eu os dispersarei diante dos inimigos;

eu lhes mostrarei as costas e não o rosto,

no dia da sua derrota”.

18Então disseram: “Venham! Façamos planos contra Jeremias, pois não cessará o ensino da lei pelo sacerdote nem o conselho do sábio nem a mensagem do profeta. Venham! Façamos acusações contra ele e não ouçamos nada do que ele disser”.

19Atende-me, ó Senhor;

ouve o que os meus acusadores estão dizendo!

20Acaso se paga o bem com o mal?

Mas eles cavaram uma cova para mim.

Lembra-te de que eu compareci diante de ti

para interceder em favor deles,

para que desviasses deles a tua ira.

21Por isso entrega os filhos deles à fome

e ao poder da espada.

Que as suas mulheres fiquem viúvas e sem filhos;

que os seus homens sejam mortos,

e os seus rapazes sejam mortos à espada na batalha.

22Seja ouvido o grito que vem de suas casas,

quando repentinamente trouxeres invasores contra eles;

pois cavaram uma cova para me capturarem

e esconderam armadilhas para os meus pés.

23Mas tu conheces, ó Senhor,

todas as suas conspirações para me matarem.

Não perdoes os seus crimes

nem apagues de diante da tua vista os seus pecados.

Sejam eles derrubados diante de ti;

age contra eles na hora da tua ira!

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jeremiah 18:1-23

Ní ilé amọ̀kòkò

1Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wá wí pe: 2“Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni èmi yóò ti bá ọ sọ̀rọ̀.” 3Nígbà náà ni mo lọ sí ilé amọ̀kòkò mo sì rí i tí ó ń ṣiṣẹ́ kan lórí kẹ̀kẹ́. 4Ṣùgbọ́n ìkòkò tí ó ń mọ láti ara amọ̀ bàjẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí náà ni amọ̀kòkò fi ṣe ìkòkò mìíràn, ó mọ ọ́n bí èyí tí ó dára jù ní ojú rẹ̀.

5Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé: 618.6: Ro 9.21.“Ẹyin ilé Israẹli, èmi kò ha lè ṣe fún un yín gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe?” ni Olúwa wí. “Gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli. 7Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun. 8Tí orílẹ̀-èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà nínú àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn. 9Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan. 10Bí ó bá sì ṣe búburú níwájú mi, tí kò sì gba ohùn mi gbọ́, nígbà náà ni èmi yóò yí ọkàn mi padà ní ti rere, èyí tí mo wí pé, èmi ó ṣe fún wọn.

11“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, sọ fún àwọn ènìyàn Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbèrò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlùkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rẹ̀ ṣe.’ 12Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò ṣe nǹkan kan, àwa yóò tẹ̀síwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, yóò hùwà agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ”

13Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:

“Ẹ béèrè nínú orílẹ̀-èdè,

ẹni tí ó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri?

Ohun tí ó burú gidi ni wúńdíá Israẹli ti ṣe.

14Ǹjẹ́ omi ojo dídì Lebanoni

yóò ha dá láti máa sàn láti ibi àpáta?

Tàbí odò tí ó jìnnà, tí ó tútù,

tí ó ń sàn, yóò ha gbẹ bí?

15Nítorí àwọn ènìyàn mi gbàgbé mi,

wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà asán,

tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn,

àti ọ̀nà wọn àtijọ́.

Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́,

àti ní ojú ọ̀nà ti a kò ṣe

16Ilẹ̀ wọn yóò wà lásán yóò sì di

nǹkan ẹ̀gàn títí láé;

Gbogbo àwọn tí ó ń kọjá yóò bẹ̀rù,

wọn yóò sì mi orí wọn.

17Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn,

Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn.

Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọn

ní ọjọ́ àjálù wọn.”

18Wọ́n sọ wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ ṣọ̀tẹ̀ sí Jeremiah, nítorí òfin ìkọ́ni láti ẹnu àwọn àlùfáà kì yóò jásí asán, tàbí ìmọ̀ràn fún àwọn ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì. Nítorí náà wá, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú pẹ̀lú ahọ́n wa, kí a má sì ṣe tẹ́tí sí ohunkóhun tí ó bá sọ.”

19Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi Olúwa, gbọ́ ohun

tí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ.

20Ṣe kí a fi rere san búburú?

Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi,

rántí pé mo dúró níwájú rẹ,

mo sì sọ̀rọ̀ nítorí wọn, láti

yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.

21Nítorí náà, jẹ́ kí ìyàn mú ọmọ wọn

jọ̀wọ́ wọn fún ọwọ́ idà

jẹ́ kí ìyàwó wọn kí ó di aláìlọ́mọ àti opó

jẹ́ kí a pa àwọn ọkùnrin wọn

kí a sì fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin

wọn lójú ogun.

22Jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ẹkún láti ilé wọn

nígbà tí ó bá mu àwọn jagunjagun

kọlù wọ́n lójijì nítorí wọ́n ti gbẹ́

kòtò láti mú mi. Wọ́n ti dẹ okùn fún ẹsẹ̀ mi

23Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa mọ

gbogbo ète wọn láti pa mí,

má ṣe dárí ẹ̀bi wọn jì wọ́n

bẹ́ẹ̀ ni má ṣe pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò lójú rẹ.

Jẹ́ kí wọn kí ó ṣubú níwájú rẹ,

bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì ṣe sí wọn nígbà ìbínú rẹ.