Isaías 60 – NVI-PT & YCB

Nova Versão Internacional

Isaías 60:1-22

A Glória de Sião

1“Levante-se, refulja! Porque chegou a sua luz,

e a glória do Senhor raia sobre você.

2Olhe! A escuridão cobre a terra,

densas trevas envolvem os povos,

mas sobre você raia o Senhor,

e sobre você se vê a sua glória.

3As nações virão à sua luz

e os reis ao fulgor do seu alvorecer.

4“Olhe ao redor e veja:

todos se reúnem e vêm a você;

de longe vêm os seus filhos,

e as suas filhas vêm carregadas nos braços.

5Então você o verá e ficará radiante;

o seu coração pulsará forte e se encherá de alegria,

porque a riqueza dos mares será trazida a você,

e a você virão as riquezas das nações.

6Manadas de camelos cobrirão a sua terra,

camelos novos de Midiã e de Efá.

Virão todos os de Sabá

carregando ouro e incenso

e proclamando o louvor do Senhor.

7Todos os rebanhos de Quedar se reunirão junto de você,

e os carneiros de Nebaiote a servirão;

serão aceitos como ofertas em meu altar,

e adornarei o meu glorioso templo.

8“Quem são estes que voam como nuvens,

que voam como pombas para os seus ninhos?

9Pois as ilhas esperam em mim;

à frente vêm os navios de Társis60.9 Ou navios mercantes,

trazendo de longe os seus filhos,

com prata e ouro,

em honra ao Senhor, o seu Deus,

o Santo de Israel,

porque ele se revestiu de esplendor.

10“Estrangeiros reconstruirão os seus muros,

e seus reis a servirão.

Com ira eu a feri, mas com amor

mostrarei a você compaixão.

11As suas portas permanecerão abertas;

jamais serão fechadas, dia e noite,

para que tragam a você as riquezas das nações,

com seus reis e sua comitiva.

12Pois a nação e o reino que não a servirem perecerão;

serão totalmente exterminados.

13“A glória do Líbano virá a você;

juntos virão o pinheiro, o abeto e o cipreste,

para adornarem o lugar do meu santuário;

e eu glorificarei o local em que pisam os meus pés.

14Os filhos dos seus opressores virão e se inclinarão diante de você;

todos os que a desprezam se curvarão aos seus pés

e a chamarão Cidade do Senhor,

Sião do Santo de Israel.

15“Em vez de abandonada e odiada,

sem que ninguém quisesse percorrê-la,

farei de você um orgulho,

uma alegria para todas as gerações.

16Você beberá o leite das nações

e será amamentada por mulheres nobres.

Então você saberá que eu, o Senhor,

sou o seu Salvador,

o seu Redentor, o Poderoso de Jacó.

17Em vez de bronze eu trarei a você ouro,

e em vez de ferro, prata.

Em vez de madeira eu trarei a você bronze,

e em vez de pedras, ferro.

Farei da paz o seu dominador,

da justiça, o seu governador.

18Não se ouvirá mais falar de violência em sua terra,

nem de ruína e destruição dentro de suas fronteiras.

Os seus muros você chamará salvação,

e as suas portas, louvor.

19O sol não será mais a sua luz de dia,

e você não terá mais o brilho do luar,

pois o Senhor será a sua luz para sempre;

o seu Deus será a sua glória.

20O seu sol nunca se porá,

e a sua lua nunca desaparecerá,

porque o Senhor será a sua luz para sempre,

e os seus dias de tristeza terão fim.

21Então todo o seu povo será justo,

e possuirá a terra para sempre.

Ele é o renovo que plantei,

obra das minhas mãos,

para manifestação da minha glória.

22O mais pequenino se tornará mil,

o menor será uma nação poderosa.

Eu sou o Senhor;

na hora certa farei que isso aconteça depressa.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 60:1-22

Ògo Sioni

1“Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,

ògo Olúwa sì ràdàbò ọ́.

2Kíyèsi i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayé

òkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn,

ṣùgbọ́n Olúwa ràn bò ọ́

ògo rẹ̀ sì farahàn lórí i rẹ.

3Àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ,

àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ.

4“Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò:

Gbogbo wọn ṣa ara jọ pọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ;

àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò wá láti ọ̀nà jíjìn,

àwọn ọmọ rẹ obìnrin ni a ó tọ́jú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ.

5Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán,

ọkàn rẹ yó fò, yó sì kún fún ayọ̀;

ọrọ̀ inú Òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ,

sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá.

660.6: Mt 2.11.Ọ̀wọ́ ìbákasẹ yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ,

àwọn ọ̀dọ́ ìbákasẹ Midiani àti Efani.

Àti gbogbo wọn láti Ṣeba yóò wá,

wọn yóò mú wúrà àti tùràrí lọ́wọ́

tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn Olúwa.

7Gbogbo agbo ẹran Kedari ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ,

àwọn àgbò ti Nebaioti yóò sìn ọ́;

wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi,

bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹmpili ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́.

8“Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kurukuru,

gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn?

9Lóòtítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí;

ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;

mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn,

pẹ̀lú fàdákà àti wúrà wọn,

fún ti ọlá Olúwa Ọlọ́run rẹ,

Ẹni Mímọ́ Israẹli,

nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́.

10“Àwọn àjèjì yóò tún ògiri rẹ mọ

àwọn ọba wọn yóò sì sìn ọ́.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ìbínú ni mo lù ọ́,

ní àánú èmi yóò ṣe inú rere sí ọ.

1160.11: If 21.25-26.Gbogbo ẹnu-bodè rẹ ni yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀,

a kì yóò tì wọ́n ní ọ̀sán àti ní òru,

tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yóò le è kó

ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá

tí àwọn ọba wọn yóò ṣáájú ní

ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ìṣẹ́gun.

12Nítorí pé orílẹ̀-èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun;

pátápátá ni yóò sì dahoro.

13“Ògo Lebanoni yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,

igi junifa, firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀,

láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi;

àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo.

1460.14: If 3.9.Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóò

wá foríbalẹ̀ fún ọ;

gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹ

wọn yóò sì pè ọ́ ní ìlú Olúwa,

Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.

15“Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kórìíra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,

láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá,

Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayé

àti ayọ̀ àtìrandíran.

16Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀-èdè

a ó sì fun ọ́ ni ọmú àwọn ọba.

Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi Olúwa,

èmi ni Olùgbàlà rẹ,

Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jakọbu.

17Dípò idẹ, èmi ó mú wúrà wá fún ọ,

dípò fàdákà èmi ó mú irin wá. Dípò igi yóò mú idẹ wá fún ọ,

àti irin dípò òkúta.

Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe àwọn ìjòyè rẹ

àti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ.

18A kì yóò gbọ́ nípa rògbòdìyàn ní ilẹ̀ rẹ mọ́,

tàbí ìdahoro àti ìparun nínú agbègbè rẹ,

ṣùgbọ́n ìwọ yóò pe ògiri rẹ ní ìgbàlà

àti àwọn ẹnu-bodè rẹ ní ìyìn.

19Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́,

tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́,

nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé,

àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ.

20Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́,

àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́;

Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ,

àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin.

21Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodo

àwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé.

Àwọn ni irúgbìn tí mo ti gbìn,

iṣẹ́ ọwọ́ mi,

láti fi ọláńlá mi hàn.

22Èyí tí ó kéré jù nínú yín yóò di ẹgbẹ̀rún kan,

èyí tí ó kéré yóò di orílẹ̀-èdè ńlá.

Èmi ni Olúwa;

ní àkókò rẹ̀ Èmi yóò ṣe èyí kánkán.”