Isaías 25 – NVI-PT & YCB

Nova Versão Internacional

Isaías 25:1-12

Louvem o Senhor

1Senhor, tu és o meu Deus;

eu te exaltarei e louvarei o teu nome,

pois com grande perfeição

tens feito maravilhas,

coisas há muito planejadas.

2Fizeste da cidade um monte de entulho,

da cidade fortificada uma ruína,

da cidadela dos estrangeiros

uma cidade inexistente

que jamais será reconstruída.

3Por isso um povo forte te honrará;

a cidade das nações cruéis te temerá.

4Tens sido refúgio para os pobres,

refúgio para o necessitado em sua aflição,

abrigo contra a tempestade

e sombra contra o calor

quando o sopro dos cruéis

é como tempestade contra um muro

5e como o calor do deserto.

Tu silencias o bramido dos estrangeiros;

assim como diminui o calor com a sombra de uma nuvem,

assim a canção dos temíveis é emudecida.

6Neste monte o Senhor dos Exércitos

preparará um farto banquete para todos os povos,

um banquete de vinho envelhecido,

com carnes suculentas e o melhor vinho.

7Neste monte ele destruirá o véu

que envolve todos os povos,

a cortina que cobre todas as nações;

8destruirá a morte para sempre.

O Soberano, o Senhor, enxugará as lágrimas de todo rosto

e retirará de toda a terra a zombaria do seu povo.

Foi o Senhor quem o disse!

9Naquele dia, dirão:

“Este é o nosso Deus;

nós confiamos nele, e ele nos salvou.

Este é o Senhor, nós confiamos nele;

exultemos e alegremo-nos, pois ele nos salvou”.

10Pois a mão do Senhor repousará sobre este monte;

mas Moabe será pisoteado em seu próprio lugar,

como a palha é pisoteada na esterqueira.

11Ali Moabe estenderá as mãos

como faz o nadador para nadar,

mas o Senhor abaterá o seu orgulho,

apesar da habilidade das suas mãos.

12Abaterá as torres altas dos seus altos muros e os derrubará;

ele os lançará ao pó da terra.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 25:1-12

Ẹ yin Olúwa

1Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run mi;

Èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sì

fi ìyìn fún orúkọ rẹ

nítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́

o ti ṣe ohun ńlá,

àwọn ohun tí o ti gbèrò o rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́.

2Ìwọ ti sọ ìlú di àkójọ àlàpà,

ìlú olódi ti di ààtàn,

ìlú olódi fún àwọn àjèjì ni kò sí mọ́;

a kì yóò tún un kọ́ mọ́.

3Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóò

bọ̀wọ̀ fún ọ;

àwọn ìlú orílẹ̀-èdè aláìláàánú

yóò bu ọlá fún ọ.

4Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòṣì

ààbò fún aláìní nínú ìpọ́njú rẹ̀

ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì

bòòji kúrò lọ́wọ́ ooru.

Nítorí pé èémí àwọn ìkà

dàbí ìjì tí ó bì lu ògiri

5àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní aginjù.

O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì,

gẹ́gẹ́ bí òjìji kurukuru ṣe ń dín ooru kù,

bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́.

6Ní orí òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun

yóò ti pèsè

àsè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn

àpèjẹ ti ọtí wáìnì àtijọ́

ti ẹran tí ó dára jù àti ti ọtí wáìnì

tí ó gbámúṣé.

7Ní orí òkè yìí ni yóò pa

aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn,

abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀;

825.8: 1Kọ 15.54; If 7.17; 21.4.Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé.

Olúwa Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù,

kúrò ní ojú gbogbo wọn;

Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò

ní gbogbo ilẹ̀ ayé.

Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

9Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé,

“Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa;

àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là.

Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e,

ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”

1025.10-12: Isa 15–16; Jr 48; El 25.8-11; Am 2.1-3; Sf 2.8-11.Ọwọ́ Olúwa yóò sinmi lé orí òkè yìí

ṣùgbọ́n a ó tẹ Moabu mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀;

gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀.

11Wọn yóò na ọwọ́ wọn jáde nínú rẹ̀,

gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ rẹ̀

jáde láti lúwẹ̀ẹ́.

Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀

bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ní ọwọ́ wọn.

12Òun yóò sì bi gbogbo ògiri gíga alágbára yín lulẹ̀

wọn yóò sì wà nílẹ̀

Òun yóò sì mú wọn wá si ilẹ̀,

àní sí erùpẹ̀ lásán.