Deuteronômio 27 – NVI-PT & YCB

Nova Versão Internacional

Deuteronômio 27:1-26

O Altar no Monte Ebal

1Moisés, acompanhado das autoridades de Israel, ordenou ao povo: “Obedeçam a toda esta lei que hoje dou a vocês. 2Quando vocês atravessarem o Jordão e entrarem na terra que o Senhor, o seu Deus, dá a vocês, levantem algumas pedras grandes e pintem-nas com cal. 3Escrevam nelas todas as palavras desta lei, assim que tiverem atravessado para entrar na terra que o Senhor, o seu Deus, dá a vocês, terra onde há leite e mel com fartura, como o Senhor, o Deus dos seus antepassados, prometeu a vocês. 4E, quando tiverem atravessado o Jordão, levantem essas pedras no monte Ebal, como hoje ordeno a vocês e pintem-nas com cal. 5Construam ali um altar ao Senhor, o seu Deus, um altar de pedras. Não utilizem ferramenta de ferro nas pedras. 6Façam o altar do Senhor, o seu Deus, com pedras brutas, e sobre ele ofereçam holocaustos27.6 Isto é, sacrifícios totalmente queimados. ao Senhor, o seu Deus. 7Ofereçam também sacrifícios de comunhão27.7 Ou de paz e comam e alegrem-se na presença do Senhor, o seu Deus. 8E nessas pedras que levantarem, vocês escreverão com bastante clareza todas as palavras desta lei”.

As Maldições Proferidas do Monte Ebal

9Então Moisés, tendo ao seu lado os sacerdotes levitas, disse a todo o Israel: “Faça silêncio e escute, ó Israel! Agora você se tornou o povo do Senhor, o seu Deus. 10Obedeça ao Senhor, o seu Deus, e siga os seus mandamentos e decretos que hoje dou a você”.

11No mesmo dia Moisés ordenou ao povo:

12“Quando vocês tiverem atravessado o Jordão, as tribos que estarão no monte Gerizim para abençoar o povo serão: Simeão, Levi, Judá, Issacar, José e Benjamim. 13E as tribos que estarão no monte Ebal para declararem maldições serão: Rúben, Gade, Aser, Zebulom, Dã e Naftali.

14“E os levitas recitarão a todo o povo de Israel em alta voz:

15“ ‘Maldito quem esculpir uma imagem ou fizer um ídolo fundido, obra de artesãos, detestável ao Senhor, e levantá-lo secretamente’.

Todo o povo dirá: ‘Amém!’

16‘Maldito quem desonrar o seu pai ou a sua mãe’.

Todo o povo dirá: ‘Amém!’

17‘Maldito quem mudar o marco de divisa da propriedade do seu próximo’.

Todo o povo dirá: ‘Amém!’

18‘Maldito quem fizer o cego errar o caminho’.

Todo o povo dirá: ‘Amém!’

19‘Maldito quem negar justiça ao estrangeiro, ao órfão ou à viúva’.

Todo o povo dirá: ‘Amém!’

20‘Maldito quem se deitar com a mulher do seu pai, desonrando a cama do seu pai’.

Todo o povo dirá: ‘Amém!’

21‘Maldito quem tiver relações sexuais com algum animal’.

Todo o povo dirá: ‘Amém!’

22‘Maldito quem se deitar com a sua irmã, filha do seu pai ou da sua mãe’.

Todo o povo dirá: ‘Amém!’

23‘Maldito quem se deitar com a sua sogra’.

Todo o povo dirá: ‘Amém!’

24‘Maldito quem matar secretamente o seu próximo’.

Todo o povo dirá: ‘Amém!’

25‘Maldito quem aceitar pagamento para matar um inocente’.

Todo o povo dirá: ‘Amém!’

26‘Maldito quem não puser em prática as palavras desta lei’.

Todo o povo dirá: ‘Amém!’

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 27:1-26

Pẹpẹ ní orí òkè Ebali

1Mose àti àwọn àgbàgbà Israẹli pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé: “Pa gbogbo àṣẹ tí mo fún ọ lónìí mọ́. 2Nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani sí inú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, gbé kalẹ̀ lára àwọn òkúta ńlá àti aṣọ ìlekè rẹ pẹ̀lú ẹfun. 3Kí ìwọ kí ó kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí sára wọn nígbà tí ìwọ bá ti ń rékọjá láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti ṣèlérí fún ọ. 4Àti nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani, kí o gbé òkúta yìí kalẹ̀ sórí i Ebali, bí mo ti pa à láṣẹ fún ọ lónìí, kí o sì wọ̀ wọ́n pẹ̀lú ẹfun. 5Kọ́ pẹpẹ síbẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ òkúta. Má ṣe lo ohun èlò irin lórí wọn. 6Kí ìwọ kí ó mọ pẹpẹ pẹ̀lú òkúta àìgbẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí ìwọ kí ó sì máa rú ẹbọ sísun ni orí rẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. 7Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ. 8Kí o sì kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí ketekete sórí òkúta tí ó ti gbé kalẹ̀.”

Ègún ní orí òkè Ebali

9Nígbà náà ni Mose àti àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, sọ fún Israẹli pé, “Ẹ dákẹ́ ẹ̀yin Israẹli, kí ẹ sì fetísílẹ̀! O ti wá di ènìyàn Olúwa Ọlọ́run rẹ báyìí. 10Gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì tẹ̀lé àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mo ń fi fún ọ lónìí.”

11Ní ọjọ́ kan náà Mose pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé.

12Nígbà tí ìwọ bá ti kọjá a Jordani, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gerisimu láti súre fún àwọn ènìyàn: Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Josẹfu àti Benjamini. 13Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ebali láti gé ègún: Reubeni, Gadi, àti Aṣeri, àti Sebuluni, Dani, àti Naftali.

14Àwọn ẹ̀yà Lefi yóò ké sí gbogbo ènìyàn Israẹli ní ohùn òkè:

1527.15: Ek 20.4,23; 34.17; Le 19.4; 26.1; De 4.16,23,25; 5.8; 7.25.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú Olúwa, iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

1627.16: Ek 20.12; 21.15,17; Le 20.9; De 5.16; 21.18-21.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dójútì baba tàbí ìyá rẹ̀”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

17“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládùúgbò o rẹ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

1827.18: Le 19.14.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣi afọ́jú lọ́nà ní ojú ọ̀nà.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

1927.19: Ek 22.21-24; 23.9; Le 19.33,34; De 24.17,18.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí ìdájọ́ po fún àlejò, aláìní baba tàbí opó”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

2027.20: Le 18.8; 20.11; De 22.30.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó baba rẹ̀, nítorí ó ti dójúti ibùsùn baba rẹ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

2127.21: Ek 22.19; Le 18.23; 20.15.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹranko.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

22“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

2327.23: Le 18.17; 20.14.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyá ìyàwó o rẹ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

24“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó pa aládùúgbò rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

25“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ènìyàn láìjẹ̀bi.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

2627.26: Ga 3.10.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí kò gbé ọ̀rọ̀ òfin yìí ró nípa ṣíṣe wọ́n.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”