2 Cronici 34 – NTLR & YCB

Nouă Traducere În Limba Română

2 Cronici 34:1-33

Domnia lui Iosia peste Iuda

(2 Regi 22:1-2; 23:4-20)

1Iosia era în vârstă de opt ani când a devenit rege și a domnit la Ierusalim timp de treizeci și unu de ani. 2El a făcut ce este drept în ochii Domnului și a umblat pe căile tatălui său David, fără a se abate nici la dreapta, nici la stânga.

3În al optulea an al domniei sale, pe când era încă tânăr, a început să‑L caute pe Dumnezeul tatălui său David. Iar în al doisprezecelea an al domniei sale, a început să curățească Iuda și Ierusalimul de înălțimi, de așere, de chipuri cioplite și de idoli turnați. 4Au dărâmat înaintea lui altarele baalilor și au tăiat în bucăți altarele pentru tămâiere care erau deasupra acestora; a sfărâmat așerele, chipurile cioplite și idolii turnați, i‑a făcut pulbere și a presărat‑o pe mormintele celor ce le aduseseră jertfe, 5iar oasele preoților lor le‑a ars pe altarele lor. Astfel, Iosia a curățit ținutul lui Iuda și Ierusalimul. 6În cetățile lui Manase, Efraim, Simeon și până în Neftali, precum și în ruinele dimprejurul lor, 7a dărâmat altarele și așerele, a făcut pulbere chipurile cioplite și a tăiat în bucăți toate altarele pentru tămâiere din tot ținutul lui Israel. Apoi s‑a întors la Ierusalim.

Restaurarea Casei Domnului

(2 Regi 22:3-7)

8În al optsprezecelea an al domniei lui, ca să curățească țara și Casa, Iosia l‑a trimis pe Șafan, fiul lui Ațalia, pe Maaseia, conducătorul cetății, și pe Ioah, fiul cronicarului Iehoahaz, ca să restaureze Casa Domnului, Dumnezeul lui.

9Aceștia s‑au dus la marele preot Hilchia și i‑au dat argintul care a fost adus la Casa lui Dumnezeu, cel care fusese adunat de leviți, adică de paznicii porții, de la cei din Manase și Efraim, de la toată rămășița lui Israel, de la toți cei din Iuda și Beniamin și de la locuitorii Ierusalimului. 10Ei au dat argintul celor ce supravegheau lucrarea la Casa Domnului, iar aceștia l‑au dat lucrătorilor care lucrau în Casa Domnului, pentru repararea și restaurarea Casei; 11l‑au dat tâmplarilor și constructorilor ca să cumpere pietre cioplite, lemne pentru grinzi, precum și pentru placarea clădirilor pe care le distruseseră regii lui Iuda.

12Oamenii își făceau cu credincioșie lucrarea. Peste ei au fost numiți ca responsabili Iahat și Obadia, leviți dintre urmașii lui Merari, precum și Zaharia și Meșulam, dintre chehatiți. Toți leviții care erau pricepuți să cânte la instrumente muzicale 13vegheau asupra cărăușilor și îi supravegheau pe toți cei ce făceau lucrarea, potrivit slujbelor lor, în timp ce alți leviți erau scribi, supraveghetori și portari.

Cartea Legii și reforma religioasă

(2 Regi 22:8-20; 23:1-3)

14În timp ce scoteau argintul care fusese adus în Casa Domnului, preotul Hilchia a găsit Cartea Legii Domnului, care fusese dată prin Moise. 15Hilchia a luat cuvântul și i‑a zis scribului Șafan: „Am găsit Cartea Legii în Casa Domnului!“ Hilchia i‑a dat Cartea lui Șafan.

16Șafan a adus Cartea la rege și i‑a adus totodată și următorul mesaj: „Slujitorii tăi fac tot ceea ce le‑ai dat să facă. 17Ei au strâns argintul care se afla în Casa Domnului și l‑au dat celor ce supraveghează și celor ce fac lucrarea.“ 18Apoi scribul Șafan l‑a înștiințat pe rege, zicând: „Preotul Hilchia mi‑a dat o Carte!“ Apoi Șafan a citit din ea înaintea regelui.

19Când a auzit regele cuvintele Legii, și‑a sfâșiat hainele. 20Și regele le‑a poruncit lui Hilchia, lui Ahikam, fiul lui Șafan, lui Abdon, fiul lui Mica20 Numit și Acbor, fiul lui Micaia., scribului Șafan și lui Asaia, slujitorul regelui, zicând: 21„Duceți‑vă și întrebați‑L pe Domnul pentru mine și pentru rămășița lui Israel și a lui Iuda, cu privire la cuvintele Cărții care a fost găsită. Căci mare este mânia Domnului care s‑a revărsat asupra noastră, pentru că părinții noștri n‑au păzit Cuvântul Domnului și n‑au împlinit tot ce este scris în Cartea aceasta.“

22Hilchia și oamenii regelui s‑au dus la profetesa Hulda, soția lui Șalum, fiul lui Tokhat22 Numit și Tikva., fiul lui Hasrah22 Numit și Harhas; compară cu 2 Regi 22:14., păzitorul veșmintelor, care locuia în Ierusalim, în cartierul cel nou22 Sau: al doilea cartier, posibil o zonă a orașului unde locuiau cei mai înstăriți. și i‑au spus toate acestea. 23Ea le‑a răspuns: „Așa vorbește Domnul, Dumnezeul lui Israel; să spuneți omului care v‑a trimis la mine că 24așa vorbește Domnul: «Iată că voi aduce nenorocirea asupra acestui loc și asupra locuitorilor lui, potrivit cu toate blestemele care sunt scrise în Cartea citită înaintea regelui lui Iuda. 25Pentru că M‑au părăsit și au adus tămâie altor dumnezei, mâniindu‑Mă prin toate lucrările mâinilor lor, mânia Mea se va revărsa împotriva acestui loc și nu se va stinge!» 26Totodată spuneți‑i regelui lui Iuda, care v‑a trimis să‑L întrebați pe Domnul, următoarele: «Așa vorbește Domnul, Dumnezeul lui Israel, cu privire la cuvintele pe care le‑ai auzit: 27‘Pentru că ți s‑a înmuiat inima și te‑ai smerit înaintea lui Dumnezeu când ai auzit cuvintele Sale împotriva acestui loc și împotriva locuitorilor lui, pentru că te‑ai smerit înaintea Mea, ți‑ai sfâșiat hainele și ai plâns înaintea Mea, iată că și Eu am auzit, zice Domnul! 28De aceea, iată că te voi adăuga la părinții tăi și vei fi așezat în pace în mormântul tău, astfel că nu vei vedea toată nenorocirea pe care o voi aduce asupra acestui loc și asupra locuitorilor lui!’»“

Ei i‑au adus regelui răspunsul acesta.

29Atunci regele a trimis și i‑a strâns pe toți bătrânii lui Iuda și ai Ierusalimului. 30Regele s‑a suit la Casa Domnului împreună cu toți bărbații lui Iuda, cu locuitorii Ierusalimului, cu preoții și cu leviții, cu întreg poporul, de la cel mai mare până la cel mai mic, și a citit în auzul lor toate cuvintele Cărții Legământului, care a fost găsită în Casa Domnului. 31Regele a stat în picioare lângă locul său și a încheiat un legământ înaintea Domnului, hotărându‑se să‑L urmeze pe Domnul și să păzească poruncile, mărturiile și hotărârile Lui din toată inima și din tot sufletul lui, împlinind astfel cuvintele legământului, scrise în Cartea aceasta.

32Apoi el i‑a făcut să intre în legământ pe toți cei ce se aflau la Ierusalim și în Beniamin. Și astfel locuitorii Ierusalimului au urmat legământul lui Dumnezeu, Dumnezeul părinților lor.

33Iosia a îndepărtat toate urâciunile din toate teritoriile unde erau fiii lui Israel și i‑a făcut pe toți cei ce se aflau în Israel să slujească Domnului, Dumnezeul lor. În toate zilele lui, ei nu s‑au îndepărtat de Domnul, Dumnezeul părinților lor.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 34:1-33

Josiah gbógun ti ìwà ìbọ̀rìṣà

134.1,2: 2Ọb 22.1,2.Josiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì dí ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n. 2Ó sì ṣe ohun tí ó dára ní ojú Olúwa, ó sì rìn ọ̀nà baba rẹ̀ Dafidi, kò sì yà sí ọwọ́ ọ̀tún tàbí òsì.

334.3-7: 2Ọb 23.4-20.Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀, nígbà tí ó sì wà ní ọ̀dọ́mọdé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá ojú Ọlọ́run baba Dafidi. Ní ọdún kejìlá. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ Juda àti Jerusalẹmu mọ́ kúrò ní ibi gíga rẹ̀, ère òrìṣà Aṣerah, àti ère yíyá àti ère dídà. 4Lábẹ́ àpẹẹrẹ àwọn pẹpẹ Baali ni a yí lulẹ̀, ó sì fọ́ àwọn ère sí wẹ́wẹ́, ó run àwọn pẹpẹ tí ó wà lórí rẹ̀, wọ́n sì fọ́ túútúú, àwọn ère Aṣerah àti àwọn òrìṣà. Èyí tí ó fọ́ wọn sì lúúlúú, ó sì gbọ̀n wọ́n sí orí isà òkú àti àwọn tí ó ń rú ẹbọ sí wọn. 5Ó sì sun àwọn egungun àwọn àlùfáà lórí pẹpẹ wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ó sì wẹ Juda àti Jerusalẹmu mọ́. 6Ní ìlú Manase, Efraimu àti Simeoni, àní títí ó fi dé Naftali, àti nínú àwọn, ó tú ilé wọn yíkákiri. 7Ó sì wó pẹpẹ àti ère Aṣerah lulẹ̀ àti àwọn ère yíyá àti àwọn òrìṣà, ó sì gùn ó sì ti ké gbogbo àwọn ère orí pẹpẹ lulẹ̀ ní gbogbo àyíká Israẹli. Lẹ́yìn náà ó padà sí Jerusalẹmu.

834.8-12: 2Ọb 22.3-7.Ní ọdún kejì-dínlógún ìjọba Josiah ni a ti wẹ ilẹ̀ náà mọ́ àti ilé Olúwa, ó sì rán Ṣafani ọmọ Asalia àti Maaseiah olórí ìlú náà, pẹ̀lú Joah, ọmọ Joahasi, akọ̀wé, láti tún ilé Olúwa Ọlọ́run ṣe.

9Wọ́n sì lọ sí ọ̀dọ̀ Hilkiah olórí àlùfáà, ó sì fún un ní owó náà tí ó mú wá sí inú ilé Ọlọ́run, ti àwọn ọmọ Lefi ẹni tí ó jẹ́ aṣọ́bodè ti gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn Manase Efraimu àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ìyókù Israẹli àti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn Juda àti Benjamini wọ́n sì padà sí Jerusalẹmu. 10Nígbà náà ni wọn sì fi le àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ilé lọ́wọ́, àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ ilé Olúwa. Àwọn ọkùnrin yìí sì san owó fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń túnṣe, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ní ilé Olúwa. 11Wọ́n sì tún fi owó fún àwọn oníṣọ̀nà àti àwọn olùkọ́lé láti ra òkúta gbígbẹ́ àti ìtì igi fún ìsopọ̀ àti igi rírẹ́ fún ìkọ́lé tí ọba Juda ti gbà láti túnṣe.

12Àwọn ọkùnrin náà ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú òtítọ́, láti darí wọn ní Jahati àti Ọbadiah, àwọn ọmọ Lefi láti Merari, àti Sekariah àti Meṣullamu, sọ̀kalẹ̀ láti Kohati àwọn ọmọ Lefi gbogbo tí ó ní ọgbọ̀n ohun èlò orin. 13Wọ́n sì ní olórí àwọn aláàárù àti àwọn alábojútó gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ láti ibi iṣẹ́ sí ibi iṣẹ́, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Lefi sì ní akọ̀wé, olùtọ́jú àti olùṣọ́nà.

A rí ìwé òfin

14Nígbà tí wọ́n mú owó náà tí wọ́n mú wá sí ilé Olúwa, Hilkiah àlùfáà sì rí ìwé òfin Olúwa tí a ti fi fún un láti ọwọ́ Mose. 15Hilkiah sì wí fún Ṣafani akọ̀wé pé, “Èmi ti rí ìwé òfin nínú ilé Olúwa.” Ó sì fi fún Ṣafani.

16Nígbà náà Ṣafani sì mú ìwé náà lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ó sì ròyìn fún un. “Àwọn ìjòyè rẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan tí a ti fi lé wọn lọ́wọ́. 17Wọ́n ti san owó náà tí ó wà nínú ilé Olúwa wọ́n sì ti fi lé àwọn alábojútó lọ́wọ́ àti àwọn òṣìṣẹ́.” 18Nígbà náà Ṣafani akọ̀wé sì sọ fún ọba, “Hilkiah àlùfáà ti fún mi ní ìwé.” Ṣafani sì kà níwájú ọba.

19Nígbà tí ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya. 20Ó sì pa àṣẹ yìí fún Hilkiah, Ahikamu ọmọ Ṣafani, Abdoni ọmọ Mika, Ṣafani akọ̀wé àti Asaiah ìránṣẹ́ ọba. 21“Ẹ lọ kí ẹ lọ béèrè lọ́wọ́ Olúwa fún mi nípa àwọn ìyókù Israẹli àti Juda nípa ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú Olúwa tí ó ti jáde sí orí wa nítorí àwọn baba wa kò ti pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́, wọn kò sì tí ì ṣe gẹ́gẹ́ bí i gbogbo èyí tí a kọ sínú ìwé yìí.”

22Hilkiah àti àwọn ènìyàn tí ọba yàn tọ Hulda wòlíì obìnrin láti ba sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ aya Ṣallumu ọmọ Tokhati tí a tún ń pè ní Tikfa, ọmọ Harhasi, olùtọ́jú ibi ìkáṣọsí. Ó sì ń gbé ní Jerusalẹmu, ní ìhà kejì.

23Ó sì wí fún wọn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli ti sọ: Sọ fún àwọn ọkùnrin tí ó rán ọ sí mi pé, 24‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò sì mú ibi wá sí ìhín yìí àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gbogbo àní ègún tí a kọ sínú ìwé tí wọ́n ti kà níwájú ọba Juda. 25Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀ wọ́n sì ti sun tùràrí sí ọlọ́run mìíràn wọ́n sì ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn ṣe, ìbínú yóò tú jáde wá sórí ibí yìí, a kì yóò sì paná rẹ̀.’ 26Sọ fún ọba Juda, ẹni tí ó rán yín láti béèrè lọ́wọ́ Olúwa, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa ti sọ, Ọlọ́run Israẹli, sọ nípa ọ̀rọ̀ wọ́n nì tí ìwọ gbọ́: 27Nítorí ọkàn rẹ̀ dúró, ìwọ sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Olúwa nígbà tí ó gbọ́ ohun tí ó sọ lórí ibí yìí àti ènìyàn rẹ, nítorí ìwọ rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi tí o sì fa aṣọ rẹ ya, tí o sì lọ níwájú mi. Èmi ti gbọ́ tìrẹ ni Olúwa wí. 28Nísinsin yìí, Èmi ó kó ọ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ àwọn baba rẹ, a ó sì sin ọ́ ní àlàáfíà. Ojú rẹ kò sì ní rí gbogbo ibi tí èmi ó mú wá sórí ibí yìí àti lórí àwọn tí ń gbé ibẹ̀.’ ”

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mún ìdáhùn rẹ̀ padà sí ọ̀dọ̀ ọba.

29Nígbà náà ni ọba sì pe gbogbo àwọn àgbàgbà Juda jọ àti Jerusalẹmu. 30Ó gòkè lọ sí ilé Olúwa pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu, àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi—gbogbo àwọn ènìyàn láti ibi kéékèèkéé sí ńlá. Ó kà á sí etí ìgbọ́ ọ wọn, gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé májẹ̀mú, tí a ti rí nínú ilé Olúwa. 31Ọba sì dúró ní ipò rẹ̀ ó sì tún májẹ̀mú dá níwájú Olúwa láti tẹ̀lé Olúwa àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti ẹ̀rí rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo àyà rẹ̀ àti láti pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sí inú ìwé yìí.

32Nígbà náà, ó sì mú kí gbogbo ènìyàn ní Jerusalẹmu àti Benjamini dúró nínú ẹ̀rí fún ara wọn, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ṣe èyí gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú Ọlọ́run, Ọlọ́run Baba wọn.

33Josiah sì kó gbogbo ohun ìríra kúrò nínú gbogbo ìlú tí ń ṣe ti àwọn tí ó wà ní Israẹli, ó sì mú kí gbogbo àwọn tí ó wà ní Israẹli sin Olúwa Ọlọ́run wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà láyè wọn, kò yà kúrò láti máa tọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn lẹ́yìn.