New International Version - UK

Genesis 35

Jacob returns to Bethel

1Then God said to Jacob, ‘Go up to Bethel and settle there, and build an altar there to God, who appeared to you when you were fleeing from your brother Esau.’

So Jacob said to his household and to all who were with him, ‘Get rid of the foreign gods you have with you, and purify yourselves and change your clothes. Then come, let us go up to Bethel, where I will build an altar to God, who answered me in the day of my distress and who has been with me wherever I have gone.’ So they gave Jacob all the foreign gods they had and the rings in their ears, and Jacob buried them under the oak at Shechem. Then they set out, and the terror of God fell on the towns all around them so that no one pursued them.

Jacob and all the people with him came to Luz (that is, Bethel) in the land of Canaan. There he built an altar, and he called the place El Bethel,[a] because it was there that God revealed himself to him when he was fleeing from his brother.

Now Deborah, Rebekah’s nurse, died and was buried under the oak outside Bethel. So it was named Allon Bakuth.[b]

After Jacob returned from Paddan Aram,[c] God appeared to him again and blessed him. 10 God said to him, ‘Your name is Jacob,[d] but you will no longer be called Jacob; your name will be Israel.[e]’ So he named him Israel.

11 And God said to him, ‘I am God Almighty;[f] be fruitful and increase in number. A nation and a community of nations will come from you, and kings will be among your descendants. 12 The land I gave to Abraham and Isaac I also give to you, and I will give this land to your descendants after you.’ 13 Then God went up from him at the place where he had talked with him.

14 Jacob set up a stone pillar at the place where God had talked with him, and he poured out a drink offering on it; he also poured oil on it. 15 Jacob called the place where God had talked with him Bethel.[g]

The deaths of Rachel and Isaac

16 Then they moved on from Bethel. While they were still some distance from Ephrath, Rachel began to give birth and had great difficulty. 17 And as she was having great difficulty in childbirth, the midwife said to her, ‘Don’t despair, for you have another son.’ 18 As she breathed her last – for she was dying – she named her son Ben-Oni.[h] But his father named him Benjamin.[i]

19 So Rachel died and was buried on the way to Ephrath (that is, Bethlehem). 20 Over her tomb Jacob set up a pillar, and to this day that pillar marks Rachel’s tomb.

21 Israel moved on again and pitched his tent beyond Migdal Eder. 22 While Israel was living in that region, Reuben went in and slept with his father’s concubine Bilhah, and Israel heard of it.

Jacob had twelve sons:

23 The sons of Leah:

Reuben the firstborn of Jacob,

Simeon, Levi, Judah, Issachar and Zebulun.

24 The sons of Rachel:

Joseph and Benjamin.

25 The sons of Rachel’s servant Bilhah:

Dan and Naphtali.

26 The sons of Leah’s servant Zilpah:

Gad and Asher.

These were the sons of Jacob, who were born to him in Paddan Aram.

27 Jacob came home to his father Isaac in Mamre, near Kiriath Arba (that is, Hebron), where Abraham and Isaac had stayed. 28 Isaac lived a hundred and eighty years. 29 Then he breathed his last and died and was gathered to his people, old and full of years. And his sons Esau and Jacob buried him.

Notas al pie

  1. Genesis 35:7 El Bethel means God of Bethel.
  2. Genesis 35:8 Allon Bakuth means oak of weeping.
  3. Genesis 35:9 That is, North-west Mesopotamia; also in verse 26
  4. Genesis 35:10 Jacob means he grasps the heel, a Hebrew idiom for he deceives.
  5. Genesis 35:10 Israel probably means he struggles with God.
  6. Genesis 35:11 Hebrew El-Shaddai
  7. Genesis 35:15 Bethel means house of God.
  8. Genesis 35:18 Ben-Oni means son of my trouble.
  9. Genesis 35:18 Benjamin means son of my right hand.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 35

Jakọbu padà sí Beteli

1Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Jakọbu pé, “Gòkè lọ sí Beteli kí o sì tẹ̀dó síbẹ̀, kí ó mọ pẹpẹ níbẹ̀ fún Ọlọ́run tó farahàn ọ́ nígbà tí o ń sálọ kúrò níwájú Esau arákùnrin rẹ.”

Nítorí náà, Jakọbu wí fún gbogbo ará ilé rẹ̀ pé, “Ẹ mú gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́dọ̀ yín kúrò, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín. Nígbà náà ni kí ẹ wá, kí ẹ jẹ́ kí a lọ sí Beteli, níbi tí n ó ti mọ pẹpẹ fún Ọlọ́run, tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú mi tí ó sì ti ń pẹ̀lú mi níbi gbogbo tí mo ń lọ.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fún Jakọbu ní gbogbo àjèjì òrìṣà tí ó wà lọ́wọ́ wọn, àti yẹtí etí wọn, Jakọbu sì bo gbogbo wọn mọ́lẹ̀ sábẹ́ igi óákù ní Ṣekemu. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run sì ń bẹ lára gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká, wọ́n kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu.

Jakọbu àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì dé sí Lusi (Beteli) tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani. Níbẹ̀ ni ó sì mọ pẹpẹ kan tí ó pè ní El-Beteli (Ọlọ́run Beteli), nítorí níbẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé fi ara hàn án nígbà tí ó ń sálọ fún arákùnrin rẹ̀.

Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni Debora, olùtọ́jú Rebeka kú, a sì sin ín sábẹ́ igi óákù ní ìsàlẹ̀ Beteli: Nítorí náà a sọ ọ́ ní Aloni-Bakuti (Óákù Ẹkún).

Lẹ́yìn tí Jakọbu padà dé láti Padani-Aramu, Ọlọ́run tún fi ara hàn án, ó sì súre fún un. 10 Ọlọ́run sì wí fun un pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ̀, a kì yóò pè ọ́ ní Jakọbu (alọ́nilọ́wọ́gbà) mọ́ bí kò ṣe Israẹli (ẹni tí ó bá Ọlọ́run jìjàkadì, tí ó sì ṣẹ́gun).” Nítorí náà, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Israẹli.

11 Ọlọ́run sì wí fún un pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai); máa bí sí i, kí o sì máa pọ̀ sí i. Orílẹ̀-èdè àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ni yóò ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, àwọn ọba yóò sì jáde wá láti ara rẹ̀. 12 Gbogbo ilẹ̀ tí mo fi fún Abrahamu àti Isaaki ni èmi yóò fún ọ pẹ̀lú, àti fún àwọn ìran rẹ tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn.” 13 Nígbà náà ni Ọlọ́run gòkè lọ kúrò ní ibi tí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀.

14 Jakọbu sì fi òkúta ṣe ọ̀wọ̀n kan sí ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ó sì ta ọrẹ ohun mímu (wáìnì) ní orí rẹ̀, ó sì da òróró olifi sí orí rẹ̀ pẹ̀lú. 15 Jakọbu sì pe orúkọ ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ní Beteli.

Ikú Rakeli àti Isaaki

16 Nígbà náà ni wọ́n ń tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn láti Beteli. Nígbà tí ó sì ku díẹ̀ kí wọn dé Efrata, Rakeli bẹ̀rẹ̀ sí ní rọbí, ó sì ní ìdààmú púpọ̀. 17 Bí ó sì ti ń rọbí pẹ̀lú ìrora yìí, agbẹ̀bí wí fún un pé “Má bẹ̀rù nítorí ọmọkùnrin mìíràn ni ó ń bọ̀ yìí.” 18 Bí o sì ti fẹ́ gbé ẹ̀mí mi (torí pé ó ń kú lọ), ó pe ọmọ rẹ̀ náà ní Bene-Oni (ọmọ ìpọ́njú mi). Ṣùgbọ́n Jakọbu sọ ọmọ náà ní Benjamini (ọmọ oókan àyà mi).

19 Báyìí ni Rakeli kú, a sì sin ín sí ọ̀nà Efrata (Bẹtilẹhẹmu). 20 Jakọbu sì mọ ọ̀wọ̀n (ọ̀wọ́n) kan sí ibojì rẹ̀, ọ̀wọ̀n náà sì tọ́ka sí ojú ibojì Rakeli títí di òní.

21 Israẹli sì ń bá ìrìnàjò rẹ̀ lọ, ó sì pa àgọ́ rẹ̀ sí Migida-Ederi (ilé ìṣọ́ Ederi). 22 Nígbà tí Israẹli sì ń gbé ní ibẹ̀, Reubeni wọlé tọ Biliha, àlè (ìyàwó tí a kò fi owó fẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀) baba rẹ̀ lọ, ó sì bá a lòpọ̀, Israẹli sì gbọ́ ọ̀rọ̀ náà.

Jakọbu sì bí ọmọkùnrin méjìlá:

23 Àwọn ọmọ Lea:

Reubeni tí í ṣe àkọ́bí Jakọbu,

Simeoni, Lefi, Juda, Isakari àti Sebuluni.

24 Àwọn ọmọ Rakeli:

Josẹfu àti Benjamini.

25 Àwọn ọmọ Biliha ìránṣẹ́bìnrin Rakeli:

Dani àti Naftali.

26 Àwọn ọmọ Silipa ìránṣẹ́bìnrin Lea:

Gadi àti Aṣeri.

Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ tí Jakọbu bí ní Padani-Aramu.

27 Jakọbu sì padà dé ilé lọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ni Mamre ní tòsí i Kiriati-Arba (Hebroni). Níbi tí Abrahamu àti Isaaki gbé. 28 Ẹni ọgọ́sàn-án (180) ọdún ni Isaaki. 29 Isaaki sì kú láìpẹ́ lẹ́yìn ìpadàbọ̀ Jakọbu, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Esau àti Jakọbu ọmọ rẹ̀ sì sin ín.