New International Version - UK

Genesis 28

1So Isaac called for Jacob and blessed him. Then he commanded him: ‘Do not marry a Canaanite woman. Go at once to Paddan Aram,[a] to the house of your mother’s father Bethuel. Take a wife for yourself there, from among the daughters of Laban, your mother’s brother. May God Almighty[b] bless you and make you fruitful and increase your numbers until you become a community of peoples. May he give you and your descendants the blessing given to Abraham, so that you may take possession of the land where you now reside as a foreigner, the land God gave to Abraham.’ Then Isaac sent Jacob on his way, and he went to Paddan Aram, to Laban son of Bethuel the Aramean, the brother of Rebekah, who was the mother of Jacob and Esau.

Now Esau learned that Isaac had blessed Jacob and had sent him to Paddan Aram to take a wife from there, and that when he blessed him he commanded him, ‘Do not marry a Canaanite woman,’ and that Jacob had obeyed his father and mother and had gone to Paddan Aram. Esau then realised how displeasing the Canaanite women were to his father Isaac; so he went to Ishmael and married Mahalath, the sister of Nebaioth and daughter of Ishmael son of Abraham, in addition to the wives he already had.

Jacob’s dream at Bethel

10 Jacob left Beersheba and set out for Harran. 11 When he reached a certain place, he stopped for the night because the sun had set. Taking one of the stones there, he put it under his head and lay down to sleep. 12 He had a dream in which he saw a stairway resting on the earth, with its top reaching to heaven, and the angels of God were ascending and descending on it. 13 There above it[c] stood the Lord, and he said: ‘I am the Lord, the God of your father Abraham and the God of Isaac. I will give you and your descendants the land on which you are lying. 14 Your descendants will be like the dust of the earth, and you will spread out to the west and to the east, to the north and to the south. All peoples on earth will be blessed through you and your offspring.[d] 15 I am with you and will watch over you wherever you go, and I will bring you back to this land. I will not leave you until I have done what I have promised you.’

16 When Jacob awoke from his sleep, he thought, ‘Surely the Lord is in this place, and I was not aware of it.’ 17 He was afraid and said, ‘How awesome is this place! This is none other than the house of God; this is the gate of heaven.’

18 Early the next morning Jacob took the stone he had placed under his head and set it up as a pillar and poured oil on top of it. 19 He called that place Bethel,[e] though the city used to be called Luz.

20 Then Jacob made a vow, saying, ‘If God will be with me and will watch over me on this journey I am taking and will give me food to eat and clothes to wear 21 so that I return safely to my father’s household, then the Lord[f] will be my God 22 and[g] this stone that I have set up as a pillar will be God’s house, and of all that you give me I will give you a tenth.’

Notas al pie

  1. Genesis 28:2 That is, North-west Mesopotamia; also in verses 5, 6 and 7
  2. Genesis 28:3 Hebrew El-Shaddai
  3. Genesis 28:13 Or There beside him
  4. Genesis 28:14 Or will use your name and the name of your offspring in blessings (see 48:20)
  5. Genesis 28:19 Bethel means house of God.
  6. Genesis 28:21 Or Since God . . . father’s household, the Lord
  7. Genesis 28:22 Or household, and the Lord will be my God, 22 then

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 28

1Nítorí náà Isaaki pe Jakọbu, ó sì súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé; “Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrín àwọn ọmọbìnrin Kenaani. Dípò bẹ́ẹ̀ lọ sí Padani-Aramu, sí ilé Betueli, baba ìyá rẹ, kí ìwọ kí ó sì fẹ́ aya fún ara rẹ nínú àwọn ọmọbìnrin Labani arákùnrin ìyá rẹ. Kí Ọlọ́run Olódùmarè (Eli-Ṣaddai) kí ó bùkún fún ọ, kí ó sì mú ọ bí sí i, kí ó sì mú ọ pọ̀ sí i ní iye títí tí ìwọ yóò di àgbájọ àwọn ènìyàn. Kí Ọlọ́run kí ó fún ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ní ìre tí ó sú fún Abrahamu, kí ìwọ kí ó le gba ilẹ̀ níbi tí a ti ń ṣe àtìpó yìí, ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún Abrahamu.” Bẹ́ẹ̀ ni Isaaki sì rán Jakọbu lọ. Ó sì lọ sí Padani-Aramu, lọ́dọ̀ Labani ọmọ Betueli, ará Aramu, tí í ṣe arákùnrin Rebeka ìyá Jakọbu àti Esau.

Nígbà tí Esau gbọ́ pé, Isaaki ti súre fún Jakọbu, ó sì ti rán Jakọbu lọ sí Padani-Aramu láti fẹ́ aya níbẹ̀ àti pé nígbà tí ó súre fún un, ó kìlọ̀ fun un pé, kò gbọdọ̀ fẹ́ nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani àti pé, Jakọbu ti gbọ́rọ̀ sí ìyá àti baba rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ti lọ sí Padani-Aramu. Nígbà náà ni Esau mọ bí Isaaki baba rẹ ti kórìíra àwọn ọmọbìnrin Kenaani tó. Nítorí náà Esau tọ Iṣmaeli lọ, ó sì fẹ́ Mahalati, arábìnrin Nebaioti, ọmọbìnrin Iṣmaeli tí í ṣe ọmọ Abrahamu. Ó fẹ́ ẹ, kún àwọn ìyàwó tí ó ti ní tẹ́lẹ̀.

Àlá Jakọbu ní Beteli

10 Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, ó sì kọrí sí ìlú Harani. 11 Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń ṣú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn. 12 Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn angẹli Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀. 13 Olúwa sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, “Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún. 14 Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, àti dé gúúsù àti àríwá. A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nípasẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ. 15 Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.”

16 Nígbà tí Jakọbu jí lójú oorun rẹ̀, ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú Olúwa ń bẹ ní ìhín yìí, èmi kò sì mọ̀.” 17 Ẹ̀rù sì bà á, ó sì wí pé, “Ìhín yìí ní ẹ̀rù gidigidi; ibí kì í ṣe ibòmíràn bí kò ṣe ilé Ọlọ́run, àní ẹnu ibodè ọ̀run nìyìí.”

18 Jakọbu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí lélẹ̀ bí ọ̀wọ́n, ó sì da òróró si lórí. 19 Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Beteli (Ilé Ọlọ́run) bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú náà ń jẹ́ Lusi tẹ́lẹ̀ rí.

20 Jakọbu sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ níbẹ̀ pé, “Bí Ọlọ́run yóò bá wà pẹ̀lú mi, tí yóò sì pa mí mọ́ ní ìrìnàjò mi tí mo ń lọ, tí yóò sì fún mi ní oúnjẹ láti jẹ àti aṣọ láti wọ̀, 21 tí mo sì padà sílé baba mi ní àlàáfíà, nígbà náà Olúwa ni yóò jẹ́ Ọlọ́run mi, 22 Òkúta yìí tí mo gbé kalẹ̀ bí ọ̀wọ́n yóò jẹ́ ilé Ọlọ́run, nínú gbogbo ohun tí ìwọ ó fi fún mi, èmi yóò sì fi ìdámẹ́wàá rẹ̀ fún ọ.”