New International Version - UK

Genesis 25

The death of Abraham

1Abraham had taken another wife, whose name was Keturah. She bore him Zimran, Jokshan, Medan, Midian, Ishbak and Shuah. Jokshan was the father of Sheba and Dedan; the descendants of Dedan were the Ashurites, the Letushites and the Leummites. The sons of Midian were Ephah, Epher, Hanok, Abida and Eldaah. All these were descendants of Keturah.

Abraham left everything he owned to Isaac. But while he was still living, he gave gifts to the sons of his concubines and sent them away from his son Isaac to the land of the east.

Abraham lived a hundred and seventy-five years. Then Abraham breathed his last and died at a good old age, an old man and full of years; and he was gathered to his people. His sons Isaac and Ishmael buried him in the cave of Machpelah near Mamre, in the field of Ephron son of Zohar the Hittite, 10 the field Abraham had bought from the Hittites.[a] There Abraham was buried with his wife Sarah. 11 After Abraham’s death, God blessed his son Isaac, who then lived near Beer Lahai Roi.

Ishmael’s sons

12 This is the account of the family line of Abraham’s son Ishmael, whom Sarah’s slave, Hagar the Egyptian, bore to Abraham.

13 These are the names of the sons of Ishmael, listed in the order of their birth: Nebaioth the firstborn of Ishmael, Kedar, Adbeel, Mibsam, 14 Mishma, Dumah, Massa, 15 Hadad, Tema, Jetur, Naphish and Kedemah. 16 These were the sons of Ishmael, and these are the names of the twelve tribal rulers according to their settlements and camps. 17 Ishmael lived a hundred and thirty-seven years. He breathed his last and died, and he was gathered to his people. 18 His descendants settled in the area from Havilah to Shur, near the eastern border of Egypt, as you go towards Ashur. And they lived in hostility towards[b] all the tribes related to them.

Jacob and Esau

19 This is the account of the family line of Abraham’s son Isaac.

Abraham became the father of Isaac, 20 and Isaac was forty years old when he married Rebekah daughter of Bethuel the Aramean from Paddan Aram[c] and sister of Laban the Aramean.

21 Isaac prayed to the Lord on behalf of his wife, because she was childless. The Lord answered his prayer, and his wife Rebekah became pregnant. 22 The babies jostled each other within her, and she said, ‘Why is this happening to me?’ So she went to enquire of the Lord.

23 The Lord said to her,

‘Two nations are in your womb,
    and two peoples from within you will be separated;
one people will be stronger than the other,
    and the elder will serve the younger.’

24 When the time came for her to give birth, there were twin boys in her womb. 25 The first to come out was red, and his whole body was like a hairy garment; so they named him Esau.[d] 26 After this, his brother came out, with his hand grasping Esau’s heel; so he was named Jacob.[e] Isaac was sixty years old when Rebekah gave birth to them.

27 The boys grew up, and Esau became a skilful hunter, a man of the open country, while Jacob was content to stay at home among the tents. 28 Isaac, who had a taste for wild game, loved Esau, but Rebekah loved Jacob.

29 Once when Jacob was cooking some stew, Esau came in from the open country, famished. 30 He said to Jacob, ‘Quick, let me have some of that red stew! I’m famished!’ (That is why he was also called Edom.[f])

31 Jacob replied, ‘First sell me your birthright.’

32 ‘Look, I am about to die,’ Esau said. ‘What good is the birthright to me?’

33 But Jacob said, ‘Swear to me first.’ So he swore an oath to him, selling his birthright to Jacob.

34 Then Jacob gave Esau some bread and some lentil stew. He ate and drank, and then got up and left.

So Esau despised his birthright.

Notas al pie

  1. Genesis 25:10 Or the descendants of Heth
  2. Genesis 25:18 Or lived to the east of
  3. Genesis 25:20 That is, North-west Mesopotamia
  4. Genesis 25:25 Esau may mean hairy.
  5. Genesis 25:26 Jacob means he grasps the heel, a Hebrew idiom for he deceives.
  6. Genesis 25:30 Edom means red.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 25

Ikú Abrahamu

1Abrahamu sì tún fẹ́ aya mìíràn, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ketura. Ó sì bí Simrani, Jokṣani, Medani, Midiani, Iṣbaki, àti Ṣua Jokṣani ni baba Ṣeba àti Dedani, àwọn ìran Dedani ni àwọn ara Asṣuri, Letusi àti Leumiti. Àwọn ọmọ Midiani ni Efani, Eferi, Hanoku, Abida àti Eldaa. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ìran Ketura.

Abrahamu sì fi ohun gbogbo tí ó ní fún Isaaki. Ṣùgbọ́n kí Abrahamu tó kú, Abrahamu fún àwọn ọmọ tí àwọn àlè rẹ̀ bí fún un ní ẹ̀bùn, ó sì lé wọn jáde lọ fún Isaaki ọmọ rẹ sí ilẹ̀ ìlà-oòrùn.

Gbogbo àpapọ̀ ọdún tí Abrahamu lò láyé jẹ́ igba kan ó-dínmẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (175). Abrahamu sì kú ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ó dàgbà, ó darúgbó kí ó tó kú. A sì sin ín sí ibojì àwọn ènìyàn rẹ̀. Àwọn ọmọ rẹ̀, Isaaki àti Iṣmaeli sì sin ín sínú ihò àpáta ni Makpela ní ẹ̀gbẹ́ Mamre, ní oko Efroni ọmọ Sohari ará Hiti 10 Inú oko tí Abrahamu rà lọ́wọ́ ara Hiti yìí ni a sin Abrahamu àti Sara aya rẹ̀ sí. 11 Lẹ́yìn ikú Abrahamu, Ọlọ́run sì bùkún fún Isaaki ọmọ rẹ̀, tí ó ń gbé nítòsí kànga Lahai-Roi ní ìgbà náà.

Àwọn ìran Iṣmaeli

12 Wọ̀nyí ni ìran Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu ẹni tí Hagari ará Ejibiti, ọmọ ọ̀dọ̀ Sara bí fún un.

13 Wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Iṣmaeli bí a ṣe bí wọn, bẹ̀rẹ̀ láti orí:

Nebaioti àkọ́bí,

Kedari, Adbeeli, Mibsamu,

14 Miṣima, Duma, Massa,

15 Hadadi, Tema, Jeturi,

Nafiṣi, àti Kedema.

16 Wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ọmọ Iṣmaeli, wọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọba méjìlá gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn.

17 Àpapọ̀ ọdún tí Iṣmaeli lò láyé jẹ́ ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún, a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀. 18 Àwọn ìran rẹ̀ sì tẹ̀dó sí agbègbè Hafila títí tí ó fi dé Ṣuri, ní ẹ̀bá ààlà Ejibiti, bí ìwọ ti ń lọ sí ìhà Asiria. Ó sì kú níwájú àwọn arákùnrin rẹ̀ gbogbo.

Jakọbu[a] àti Esau

19 Wọ̀nyí ni ìtàn ìran Isaaki ọmọ Abrahamu.

Abrahamu bí Isaaki. 20 Nígbà tí Isaaki di ọmọ ogójì (40) ọdún ni ó gbé Rebeka ọmọ Betueli ará Aramu ti Padani-Aramu tí í ṣe arábìnrin Labani ará Aramu ní ìyàwó.

21 Isaaki sì gbàdúrà sì Olúwa, nítorí aya rẹ̀ tí ó yàgàn, Olúwa sì gbọ́ àdúrà rẹ̀, Rebeka sì lóyún. 22 Àwọn ọmọ náà ń gbún ara wọn nínú rẹ̀, ó sì wí pé, “Èéṣe tí èyí ń ṣẹlẹ̀ sí mi,” ó sì lọ béèrè lọ́dọ̀ Olúwa.

23 Olúwa sì wí fún un pé,

“Orílẹ̀-èdè méjì ni ń bẹ nínú rẹ,
    irú ènìyàn méjì ni yóò yà láti inú rẹ;
àwọn ènìyàn kan yóò jẹ́ alágbára ju èkejì lọ,
    ẹ̀gbọ́n ni yóò máa sin àbúrò.”

24 Nígbà tí ó tó àkókò fún un láti bímọ, ìbejì ni ó wà nínú rẹ̀, ọkùnrin sì ni wọ́n. 25 Èyí tí ó kọ jáde jẹ́ ọmọ pupa, irun sì bo gbogbo ara rẹ̀ bí aṣọ onírun, nítorí náà, wọ́n pè é ní Esau. 26 Lẹ́yìn èyí ni arákùnrin èkejì jáde wá, ọwọ́ rẹ̀ sì di Esau ni gìgísẹ̀ mú, nítorí náà ni wọn ṣe pe orúkọ rẹ ni Jakọbu. Ọmọ ọgọ́ta ọdún ni Isaaki, nígbà tí Rebeka bí wọn.

27 Àwọn ọmọkùnrin náà sì dàgbà. Esau sì di ọlọ́gbọ́n ọdẹ, ẹni tí ó fẹ́ràn àti máa dúró ní oko. Jakọbu sì jẹ́ ènìyàn jẹ́ẹ́jẹ́ tí ó ń gbé láàrín ìlú. 28 Isaaki, ẹni tí ó fẹ́ràn ẹran igbó fẹ́ràn Esau nítorí ẹran igbó tí Esau máa ń pa, ṣùgbọ́n Rebeka fẹ́ràn Jakọbu.

29 Ní ọjọ́ kan, Jakọbu sì pa ìpẹ̀tẹ̀, Esau sì ti igbó ọdẹ dé, ó sì ti rẹ̀ ẹ́. 30 Esau wí fún Jakọbu pé, “Èmí bẹ̀ ọ, fi ìpẹ̀tẹ̀ rẹ pupa n nì bọ́ mi, nítorí tí ó rẹ̀ mí gidigidi.” (Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ rẹ̀ ní Edomu).

31 Jakọbu dáhùn pé, “Kò burú, ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ta ogún ìbí rẹ fún mi ná.”

32 Esau sì dáhùn pé, “Wò ó mo ti fẹ́rẹ kú, àǹfààní kín sì ni ogún ìbí jẹ́ fún mi?”

33 Ṣùgbọ́n, Jakọbu dáhùn pé, “Kọ́kọ́ búra fún mi pé tèmi ni ogún ìbí náà yóò jẹ́.” Báyìí ni Esau búra tí ó sì gbé ogún ìbí rẹ̀ tà fún Jakọbu.

34 Nígbà náà ni Jakọbu fi àkàrà àti ìpẹ̀tẹ̀ lẹntili fún Esau. Ó sì jẹ, ó sì mu, ó sì bá tirẹ̀ lọ.

Báyìí ni Esau gan ogún ìbí rẹ̀.

Notas al pie

  1. 25.19 Jakọbu yí ni a mọ̀ sí Israẹli.