Exodus 4 – NIVUK & YCB

New International Version – UK

Exodus 4:1-31

Signs for Moses

1Moses answered, ‘What if they do not believe me or listen to me and say, “The Lord did not appear to you”?’

2Then the Lord said to him, ‘What is that in your hand?’

‘A staff,’ he replied.

3The Lord said, ‘Throw it on the ground.’

Moses threw it on the ground and it became a snake, and he ran from it. 4Then the Lord said to him, ‘Reach out your hand and take it by the tail.’ So Moses reached out and took hold of the snake and it turned back into a staff in his hand. 5‘This,’ said the Lord, ‘is so that they may believe that the Lord, the God of their fathers – the God of Abraham, the God of Isaac and the God of Jacob – has appeared to you.’

6Then the Lord said, ‘Put your hand inside your cloak.’ So Moses put his hand into his cloak, and when he took it out, the skin was leprous4:6 The Hebrew word for leprous was used for various diseases affecting the skin. – it had become as white as snow.

7‘Now put it back into your cloak,’ he said. So Moses put his hand back into his cloak, and when he took it out, it was restored, like the rest of his flesh.

8Then the Lord said, ‘If they do not believe you or pay attention to the first sign, they may believe the second. 9But if they do not believe these two signs or listen to you, take some water from the Nile and pour it on the dry ground. The water you take from the river will become blood on the ground.’

10Moses said to the Lord, ‘Pardon your servant, Lord. I have never been eloquent, neither in the past nor since you have spoken to your servant. I am slow of speech and tongue.’

11The Lord said to him, ‘Who gave human beings their mouths? Who makes them deaf or mute? Who gives them sight or makes them blind? Is it not I, the Lord? 12Now go; I will help you speak and will teach you what to say.’

13But Moses said, ‘Pardon your servant, Lord. Please send someone else.’

14Then the Lord’s anger burned against Moses and he said, ‘What about your brother, Aaron the Levite? I know he can speak well. He is already on his way to meet you, and he will be glad to see you. 15You shall speak to him and put words in his mouth; I will help both of you speak and will teach you what to do. 16He will speak to the people for you, and it will be as if he were your mouth and as if you were God to him. 17But take this staff in your hand so that you can perform the signs with it.’

Moses returns to Egypt

18Then Moses went back to Jethro his father-in-law and said to him, ‘Let me return to my own people in Egypt to see if any of them are still alive.’

Jethro said, ‘Go, and I wish you well.’

19Now the Lord had said to Moses in Midian, ‘Go back to Egypt, for all those who wanted to kill you are dead.’ 20So Moses took his wife and sons, put them on a donkey and started back to Egypt. And he took the staff of God in his hand.

21The Lord said to Moses, ‘When you return to Egypt, see that you perform before Pharaoh all the wonders I have given you the power to do. But I will harden his heart so that he will not let the people go. 22Then say to Pharaoh, “This is what the Lord says: Israel is my firstborn son, 23and I told you, ‘Let my son go, so that he may worship me.’ But you refused to let him go; so I will kill your firstborn son.” ’

24At a lodging place on the way, the Lord met Moses4:24 Hebrew him and was about to kill him. 25But Zipporah took a flint knife, cut off her son’s foreskin and touched Moses’ feet with it.4:25 The meaning of the Hebrew for this clause is uncertain. ‘Surely you are a bridegroom of blood to me,’ she said. 26So the Lord let him alone. (At that time she said ‘bridegroom of blood’, referring to circumcision.)

27The Lord said to Aaron, ‘Go into the wilderness to meet Moses.’ So he met Moses at the mountain of God and kissed him. 28Then Moses told Aaron everything the Lord had sent him to say, and also about all the signs he had commanded him to perform.

29Moses and Aaron brought together all the elders of the Israelites, 30and Aaron told them everything the Lord had said to Moses. He also performed the signs before the people, 31and they believed. And when they heard that the Lord was concerned about them and had seen their misery, they bowed down and worshipped.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 4:1-31

Àwọn ààmì fún Mose

1Mose dáhùn ó sì wí pé; “Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gbà mí gbọ́ ńkọ́? Tàbí tí wọn kò fi etí sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, tí wọn sì wí pé, ‘Olúwa kò farahàn ọ́’?”

2Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún un pé, “Kí ni ó wà ní ọwọ́ rẹ n nì?”

Ó sì dáhùn pé, “ọ̀pá ni.”

3Olúwa sì sọ pé, “Sọ ọ̀pá náà sílẹ̀.”

Mose sì sọ ọ̀pá náà sílẹ̀, lọ́gán ni ọ̀pá náà di ejò, ó sì sá fún un. 4Nígbà náà ni Ọlọ́run wá sọ fún un pé, “na ọwọ́ rẹ, kí o sì mú un ni ìrù.” Mose sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mu ejò náà, ejò náà sì padà di ọ̀pá tí ó wà ni ọwọ́ rẹ̀. 5Olúwa sì wí pé, “Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí wọn bá à le è gbàgbọ́ pé, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn: Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu; tí farahàn ọ́.”

6Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀.” Mose sì ti ọwọ́ rẹ̀ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀, ní ìgbà ti ó sì yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ ti dẹ́tẹ̀, ó sì ti funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

7Ó sì wí pé, “Nísinsin yìí, fi ọwọ́ náà padà sí abẹ́ aṣọ ní igbá àyà rẹ.” Mose sì ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ́ sípò bí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ tókù.

8Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé; “Bí wọn kò bá gbà ọ́ gbọ́ tàbí kọ ibi ara sí iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́, wọ́n le è ti ipasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu kejì gbàgbọ́. 9Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gba ààmì méjèèjì wọ̀nyí gbọ́, tí wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ, bu omi díẹ̀ láti inú odò Naili kí o si dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀, omi tí ìwọ bù láti inú odò yìí yóò sì di ẹ̀jẹ̀.”

10Mose sì sọ fún Olúwa pé, “Èmi jẹ́ akólòlò, èmi kì í ṣe ẹni tó lè sọ̀rọ̀ já gaara láti ìgbà àtijọ́ wá tàbí láti ìgbà ti o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, mo jẹ́ ẹni ti ahọ́n rẹ̀ lọ́, tí ó sì ń lọ́ra àti sọ̀rọ̀.”

11Olúwa sì sọ fún un pé, “Ta ni ó fún ènìyàn ni ẹnu? Ta ni ó mú un ya odi tàbí adití? Ta ni ó mú un ríran, tàbí mú un fọ́jú? Ǹjẹ́ kì í ṣe Èmi Olúwa? 12Lọ nísinsin yìí, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀. Èmi yóò sì kọ́ ọ ni ohun ti ìwọ yóò sọ.”

13Mose dáhùn ó wí pé, “Olúwa jọ̀wọ́ rán ẹlòmíràn láti lọ ṣe iṣẹ́ yìí.”

14Ìbínú Ọlọ́run ru sókè sí Mose, ó sì sọ pé, “Aaroni ará Lefi arákùnrin rẹ ńkọ́? Mo mọ̀ pé ó lè sọ̀rọ̀ já gaara, ó ti wà ní ọ̀nà rẹ̀ báyìí láti pàdé e rẹ. Inú rẹ̀ yóò sì dùn ti ó bá rí ọ. 15Ìwọ yóò sọ̀rọ̀ fún un, ìwọ yóò sì fi ọ̀rọ̀ sí i lẹ́nu: Èmi yóò ràn yín lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀. Èmi yóò kọ́ ọ yín ni ohun ti ẹ ó ṣe. 16Òun yóò bá ọ sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn, yóò sì dàbí i pé ẹnu un rẹ ni a gbà sọ ọ̀rọ̀ náà, ìwọ yóò sì dàbí Ọlọ́run ní iwájú rẹ̀. 17Ṣùgbọ́n mú ọ̀pá yìí ni ọwọ́ rẹ kí ìwọ bá à lè fi ṣe àwọn iṣẹ́ ààmì ìyanu pẹ̀lú rẹ̀.”

Mose padà sí Ejibiti

18Mose padà sí ọ̀dọ̀ Jetro baba ìyàwó rẹ̀, ó sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí n padà tọ àwọn ènìyàn mi lọ ni ilẹ̀ Ejibiti láti wò bóyá wọ́n ṣì wà láààyè síbẹ̀.”

Jetro sì dáhùn, ó wí pé, “Máa lọ ni àlàáfíà.”

194.19: Ap 7.34.Nísinsin yìí, Olúwa ti sọ fún Mose ni ilẹ̀ Midiani pé, “Máa padà lọ sí Ejibiti, nítorí àwọn ti ó fẹ́ pa ọ ti kú.” 20Mose mú ìyàwó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó kó wọn lé orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ padà sí Ejibiti. Ó sì mú ọ̀pá Ọlọ́run sí ọwọ́ rẹ̀.

21Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Ní ìgbà tí ìwọ bá padà sí Ejibiti rí i pé ìwọ ṣe iṣẹ́ ìyanu ni iwájú Farao. Èmi ti fún ọ lágbára láti ṣe é. Èmi yóò sì sé àyà rẹ̀ le, òun kì yóò jẹ́ kí àwọn ènìyàn náà kí ó lọ. 22Lẹ́yìn náà, kí o sọ fún Farao pé, ‘Èyí ni Olúwa sọ: Israẹli ní àkọ́bí ọmọ mi ọkùnrin, 234.23: Ek 12.29.mo sọ fún ọ, “Jẹ́ kí ọmọ mi lọ, ki òun kí ó lè máa sìn mí.” Ṣùgbọ́n ìwọ kọ̀ láti jẹ́ kí ó lọ; nítorí náà, èmi yóò pa àkọ́bí ọmọ rẹ ọkùnrin.’ ”

24Ní ọ̀nà ìrìnàjò rẹ, ni ibi tí wọ́n gbé sùn ní ilé èrò ní alẹ́, Olúwa pàdé Mose, ó sì fẹ́ láti pa á. 25Ṣùgbọ́n Sippora mú ọ̀bẹ òkúta mímú, ó sì kọ ọmọ rẹ̀ ní ilà abẹ́, ó sì fi awọ rẹ̀ kan ẹsẹ̀ Mose. Sippora sì wí pé, “Ọkọ ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ jẹ́ sí mi.” 26Nítorí náà Olúwa yọ̀ǹda rẹ láti ìgbà tí ó ti wí pé, “Ẹlẹ́jẹ̀ ni ìwọ í ṣe.” Èyí tó túmọ̀ sí ìkọlà abẹ́.

27Olúwa sì sọ fún Aaroni pé, “Lọ sínú aginjù láti lọ pàdé Mose.” Ní ìgbà náà ni ó lọ pàdé Mose ní orí òkè Ọlọ́run, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu. 28Ní ìgbà náà ni Mose sì sọ ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti rán fún Aaroni àti nípa gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un láti ṣe ní iwájú Farao.

29Mose àti Aaroni pe gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli jọ. 30Aaroni sọ ohun gbogbo tí Olúwa sọ fún Mose fún wọn, ó sì ṣe iṣẹ́ ààmì náà ní ojú àwọn ènìyàn náà. 31Wọ́n sì gbàgbọ́. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Olúwa ti bẹ àwọn ọmọ Israẹli wò àti pé Olúwa ti gbọ́ nípa ìpọ́njú wọn, wọ́n tẹríba, wọ́n sì sìn Ín. Ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ààmì náà níwájú àwọn ènìyàn náà.