Exodus 38 – NIVUK & YCB

New International Version – UK

Exodus 38:1-31

The altar of burnt offering

1They38:1 Or He; also in verses 2-9 built the altar of burnt offering of acacia wood, three cubits38:1 That is, about 1.4 metres high; it was square, five cubits long and five cubits wide.38:1 That is, about 2.3 metres long and wide 2They made a horn at each of the four corners, so that the horns and the altar were of one piece, and they overlaid the altar with bronze. 3They made all its utensils of bronze – its pots, shovels, sprinkling bowls, meat forks and firepans. 4They made a grating for the altar, a bronze network, to be under its ledge, halfway up the altar. 5They cast bronze rings to hold the poles for the four corners of the bronze grating. 6They made the poles of acacia wood and overlaid them with bronze. 7They inserted the poles into the rings so they would be on the sides of the altar for carrying it. They made it hollow, out of boards.

The basin for washing

8They made the bronze basin and its bronze stand from the mirrors of the women who served at the entrance to the tent of meeting.

The courtyard

9Next they made the courtyard. The south side was a hundred cubits38:9 That is, about 45 metres long and had curtains of finely twisted linen, 10with twenty posts and twenty bronze bases, and with silver hooks and bands on the posts. 11The north side was also a hundred cubits long and had twenty posts and twenty bronze bases, with silver hooks and bands on the posts.

12The west end was fifty cubits38:12 That is, about 23 metres wide and had curtains, with ten posts and ten bases, with silver hooks and bands on the posts. 13The east end, towards the sunrise, was also fifty cubits wide. 14Curtains fifteen cubits38:14 That is, about 6.8 metres long were on one side of the entrance, with three posts and three bases, 15and curtains fifteen cubits long were on the other side of the entrance to the courtyard, with three posts and three bases. 16All the curtains around the courtyard were of finely twisted linen. 17The bases for the posts were bronze. The hooks and bands on the posts were silver, and their tops were overlaid with silver; so all the posts of the courtyard had silver bands.

18The curtain for the entrance to the courtyard was made of blue, purple and scarlet yarn and finely twisted linen – the work of an embroiderer. It was twenty cubits38:18 That is, about 9 metres long and, like the curtains of the courtyard, five cubits38:18 That is, about 2.3 metres high, 19with four posts and four bronze bases. Their hooks and bands were silver, and their tops were overlaid with silver. 20All the tent pegs of the tabernacle and of the surrounding courtyard were bronze.

The materials used

21These are the amounts of the materials used for the tabernacle, the tabernacle of the covenant law, which were recorded at Moses’ command by the Levites under the direction of Ithamar son of Aaron, the priest. 22(Bezalel son of Uri, the son of Hur, of the tribe of Judah, made everything the Lord commanded Moses; 23with him was Oholiab son of Ahisamak, of the tribe of Dan – an engraver and designer, and an embroiderer in blue, purple and scarlet yarn and fine linen.) 24The total amount of the gold from the wave offering used for all the work on the sanctuary was 29 talents and 730 shekels,38:24 The weight of the gold was about 1 metric ton. according to the sanctuary shekel.

25The silver obtained from those of the community who were counted in the census was 100 talents38:25 That is, about 3.4 metric tons; also in verse 27 and 1,775 shekels,38:25 That is, about 20 kilograms; also in verse 28 according to the sanctuary shekel – 26one beka per person, that is, half a shekel,38:26 That is, about 5.7 grams according to the sanctuary shekel, from everyone who had crossed over to those counted, twenty years old or more, a total of 603,550 men. 27The 100 talents of silver were used to cast the bases for the sanctuary and for the curtain – 100 bases from the 100 talents, one talent for each base. 28They used the 1,775 shekels to make the hooks for the posts, to overlay the tops of the posts, and to make their bands.

29The bronze from the wave offering was 70 talents and 2,400 shekels.38:29 The weight of the bronze was about 2.4 metric tons. 30They used it to make the bases for the entrance to the tent of meeting, the bronze altar with its bronze grating and all its utensils, 31the bases for the surrounding courtyard and those for its entrance and all the tent pegs for the tabernacle and those for the surrounding courtyard.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 38:1-31

Pẹpẹ ẹbọ sísun

138.1-7: Ek 27.1-8.Ó sì fi igi kasia kọ́ pẹpẹ ẹbọ sísun, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ni gíga rẹ̀: ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, igun rẹ̀ ṣe déédé. 2Ó ṣe ìwo sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, nítorí kí ìwo àti pẹpẹ náà lè jẹ́ ọ̀kan, ó sì bo pẹpẹ náà pẹ̀lú idẹ. 3Idẹ ni ó ṣe gbogbo ohun èlò pẹpẹ, ìkòkò rẹ̀, ọkọ, àwokòtò rẹ̀, fọ́ọ̀kì tí a fi n mú ẹran àti àwo iná rẹ̀. 4Ó ṣe ààrò fún pẹpẹ náà, àwọ̀n onídẹ, kí ó wà níṣàlẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, dé ìdajì òkè pẹpẹ náà. 5Ó dá òrùka idẹ láti mú kí ó di òpó igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin idẹ ààrò náà mú. 6Ó sì fi igi kasia ṣe àwọn òpó náà, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú idẹ. 7Ó sì fi òpó náà bọ inú òrùka, nítorí kí ó lè wà ní ìhà pẹpẹ náà láti máa fi gbé e. Ó sì fi pákó ṣé pẹpẹ náà ní oníhò nínú.

Agbada fún fífọ̀

838.8: Ek 30.18.Ó ṣe agbada idẹ, o sì fi idẹ ṣe ẹsẹ̀ rẹ̀ ti àwòjìji àwọn obìnrin tí ó ń sìn ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ.

Àgbàlá inú

938.9-20: Ek 27.9-19.Ó sì ṣe àgbàlá inú náà. Ní ìhà gúúsù ni aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára wà, ó jẹ́ mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ní gígùn, 10pẹ̀lú ogún òpó àti ogún (20) ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, àti pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà. 11Ní ìhà àríwá náà tún jẹ mítà mẹ́rìn-dínláàádọ́ta ní gígùn, ó sì ní ogún òpó àti ogun ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà.

12Ìhà ìwọ̀-oòrùn jẹ́ mítà mẹ́tàlélógún ní fífẹ̀, ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà pọ̀. 13Fún ìhà ìlà-oòrùn, sí ibi tí oòrùn ti ń yọ náà jẹ́ mítà mẹ́tàlélógún ni fífẹ̀ 14Aṣọ títa ìhà ẹnu-ọ̀nà kan jẹ́ mítà mẹ́fà ààbọ̀, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta, 15àti aṣọ títa ní ìhà kejì tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ mítà mẹ́fà ààbọ̀ pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́fà. 16Gbogbo aṣọ tí ó yí àgbàlá náà jẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára. 17Ihò ìtẹ̀bọ̀ fún òpó náà idẹ ni. Ìkọ́ òpó náà àti ìgbànú tí ó wà lára òpó náà jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà; gbogbo àwọn òpó àgbàlá náà ní ìgbànú fàdákà.

18Aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe; ogún ìgbọ̀nwọ́ sì ni gígùn rẹ̀, àti gíga rẹ̀ ní ìbò rẹ̀ jẹ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, ó bá aṣọ títa àgbàlá wọ̀n-ọn-nì ṣe déédé, 19pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ mẹ́rin. Ìkọ́ àti ìgbànú wọn jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà. 20Gbogbo èèkàn àgọ́ tabanaku náà àti ti àyíká àgbàlá náà jẹ́ idẹ.

Àwọn ohun èlò tí a lò

21Wọ̀nyí ni iye ohun èlò tí a lò fún tabanaku náà, tabanaku ẹ̀rí, èyí ti a kọ bí òfin Mose nípa àwọn ọmọ Lefi ní abẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni àlùfáà. 22(Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, ṣe ohun gbogbo ti Olúwa pàṣẹ fún Mose; 23Pẹ̀lú rẹ̀ ni Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani: alágbẹ̀dẹ, àti oníṣẹ́-ọnà àti oníṣọ̀nà tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe ní aṣọ aláró àti elése àlùkò àti òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára.) 24Àròpọ̀ iye wúrà lára wúrà ọrẹ tí a lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà jẹ́ tálẹ́ǹtì mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n àti ẹgbẹ̀rin ṣékélì gẹ́gẹ́ bí i ṣékélì ibi mímọ́.

2538.25,26: Ek 30.11-16.Fàdákà tí a rí nínú ìjọ, ẹni tí a kà nínú ìkànìyàn jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) tálẹ́ǹtì àti òjìlélẹ́gbẹ̀sán ó-lé-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣékélì gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, 26ààbọ̀ ṣékélì kan ní orí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́, lórí olúkúlùkù ẹni tí ó ti kọjá tí a ti kà, láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àròpọ̀ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n-ọ̀kẹ́-lé-ẹgbẹ̀ta-dínlógún ó-lé-àádọ́jọ ọkùnrin (603,550). 27Ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà ní a lò láti fi dá ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ibi mímọ́ àti fún aṣọ títa ọgọ́rùn-ún ihò ìtẹ̀bọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì náà tálẹ́ǹtì kan fún ihò ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan. 28Ó lo òjì-dínlẹ́gbẹ̀san ó-lé-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣékélì (1,775 shekels) ni ó fi ṣe ìkọ́ fún òpó náà, láti fi bo orí òpó náà àti láti fi ṣe ọ̀já wọn.

29Idẹ ara ọrẹ náà jẹ́ àádọ́rin tálẹ́ǹtì àti egbèjìlá ṣékélì. 30Ó lò ó láti fi ṣe ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, pẹpẹ idẹ náà pẹ̀lú ààrò idẹ rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, 31ihò ìtẹ̀bọ̀ àgbàlá náà àyíká àti ihò ìtẹ̀bọ̀ ẹnu-ọ̀nà àgbàlá àti gbogbo èèkàn àgọ́ náà, àti gbogbo èèkàn àgbàlá náà yíká.