New International Version - UK

Exodus 26

The tabernacle

1‘Make the tabernacle with ten curtains of finely twisted linen and blue, purple and scarlet yarn, with cherubim woven into them by a skilled worker. All the curtains are to be the same size – twenty-eight cubits long and four cubits wide.[a] Join five of the curtains together, and do the same with the other five. Make loops of blue material along the edge of the end curtain in one set, and do the same with the end curtain in the other set. Make fifty loops on one curtain and fifty loops on the end curtain of the other set, with the loops opposite each other. Then make fifty gold clasps and use them to fasten the curtains together so that the tabernacle is a unit.

‘Make curtains of goat hair for the tent over the tabernacle – eleven altogether. All eleven curtains are to be the same size – thirty cubits long and four cubits wide.[b] Join five of the curtains together into one set and the other six into another set. Fold the sixth curtain double at the front of the tent. 10 Make fifty loops along the edge of the end curtain in one set and also along the edge of the end curtain in the other set. 11 Then make fifty bronze clasps and put them in the loops to fasten the tent together as a unit. 12 As for the additional length of the tent curtains, the half curtain that is left over is to hang down at the rear of the tabernacle. 13 The tent curtains will be a cubit[c] longer on both sides; what is left will hang over the sides of the tabernacle so as to cover it. 14 Make for the tent a covering of ram skins dyed red, and over that a covering of other durable leather.[d]

15 ‘Make upright frames of acacia wood for the tabernacle. 16 Each frame is to be ten cubits long and a cubit and a half wide,[e] 17 with two projections set parallel to each other. Make all the frames of the tabernacle in this way. 18 Make twenty frames for the south side of the tabernacle 19 and make forty silver bases to go under them – two bases for each frame, one under each projection. 20 For the other side, the north side of the tabernacle, make twenty frames 21 and forty silver bases – two under each frame. 22 Make six frames for the far end, that is, the west end of the tabernacle, 23 and make two frames for the corners at the far end. 24 At these two corners they must be double from the bottom all the way to the top and fitted into a single ring; both shall be like that. 25 So there will be eight frames and sixteen silver bases – two under each frame.

26 ‘Also make crossbars of acacia wood: five for the frames on one side of the tabernacle, 27 five for those on the other side, and five for the frames on the west, at the far end of the tabernacle. 28 The centre crossbar is to extend from end to end at the middle of the frames. 29 Overlay the frames with gold and make gold rings to hold the crossbars. Also overlay the crossbars with gold.

30 ‘Set up the tabernacle according to the plan shown you on the mountain.

31 ‘Make a curtain of blue, purple and scarlet yarn and finely twisted linen, with cherubim woven into it by a skilled worker. 32 Hang it with gold hooks on four posts of acacia wood overlaid with gold and standing on four silver bases. 33 Hang the curtain from the clasps and place the ark of the covenant law behind the curtain. The curtain will separate the Holy Place from the Most Holy Place. 34 Put the atonement cover on the ark of the covenant law in the Most Holy Place. 35 Place the table outside the curtain on the north side of the tabernacle and put the lampstand opposite it on the south side.

36 ‘For the entrance to the tent make a curtain of blue, purple and scarlet yarn and finely twisted linen – the work of an embroiderer. 37 Make gold hooks for this curtain and five posts of acacia wood overlaid with gold. And cast five bronze bases for them.

Notas al pie

  1. Exodus 26:2 That is, about 13 metres long and 1.8 metres wide
  2. Exodus 26:8 That is, about 13.5 metres long and 1.8 metres wide
  3. Exodus 26:13 That is, about 45 centimetres
  4. Exodus 26:14 Possibly the hides of large aquatic mammals (see 25:5)
  5. Exodus 26:16 That is, about 4.5 metres long and 68 centimetres wide

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 26

Àgọ́ náà

1“Ṣe àgọ́ náà pẹ̀lú aṣọ títa mẹ́wàá, aṣọ ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ àti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, pẹ̀lú àwọn kérúbù ni kí ó ṣe iṣẹ́ ọlọ́nà sí wọn. Gbogbo aṣọ títa náà ni kí ó jẹ́ ìwọ̀n kan náà: ìgbọ̀nwọ́ méjì-dínlọ́gbọ̀n ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ni fífẹ̀. Aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn, àti aṣọ títa márùn-ún ni kí a so papọ̀ mọ́ ara wọn. Ìwọ yóò ṣì ṣe ajábó aṣọ aláró sí aṣọ títa kan láti ìṣẹ́tí rẹ̀ wá níbi ìsopọ̀, àti bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìwọ yóò ṣe ni etí ìkangun aṣọ títa kejì, ni ibi ìsopọ̀ kejì. Àádọ́ta ajábó ní ó pa lára aṣọ títa kan, àti àádọ́ta ajábó ni ó sì lò pa ní etí aṣọ títa tí ó wà ní ìsolù kejì, ajábó náà sì wà ní ọ̀kánkán ara wọn. Ó sì ṣe àádọ́ta ìkọ́ wúrà, ó sì lò ìkọ́ wọ̀n-ọn-nì láti fi aṣọ títa kan kọ́ èkejì, bẹ́ẹ̀ ó sì di odidi àgọ́ kan.

“Ìwọ ó sì ṣe aṣọ títa irun ewúrẹ́ láti fi ṣe ìbò sórí àgọ́ náà—aṣọ títa mọ́kànlá ni ìwọ ó ṣe é. Gbogbo aṣọ títa mọ́kọ̀ọ̀kànlá náà jẹ́ ìwọ̀n kan náà, ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀. Ìwọ ó so aṣọ títa márùn-ún pọ̀ mọ́ ara wọn se ọ̀kan, ó sì tún so mẹ́fà tókù mọ́ ara wọn se ọ̀kan. Ìwọ ó sì ṣẹ́ aṣọ títa kẹfà po sí méjì níwájú àgọ́ náà. 10 Ìwọ ó sì pa àádọ́ta ajábó sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kan, wọ́n sì tún pa ajábó mìíràn sí ìṣẹ́tí ìkangun aṣọ títa ní apá kejì. 11 Nígbà náà ṣe àádọ́ta ìkọ́ idẹ kí o sì kó wọn sínú ọ̀jábó láti fi so àgọ́ náà pọ̀ kí ó lè jẹ́ ọ̀kan. 12 Àti ìyókù tí ó kù nínú aṣọ títa àgọ́ náà, ìdajì aṣọ títa tí ó kù, yóò rọ̀ sórí ẹ̀yìn àgọ́ náà. 13 Aṣọ títa àgọ́ náà yóò jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan gígùn ní ìhà méjèèjì; Èyí tí ó kù yóò rọ̀ sórí ìhà àgọ́ náà láti fi bò ó. 14 Ìwọ ó sì ṣe ìbòrí awọ àgbò tí a rì ní pupa fún àgọ́ náà, kí ó sì ṣe ìbòrí awọ seali sórí rẹ̀.

15 “Ìwọ ó sì ṣe pákó igi kasia tí ó dúró òró fún àgọ́ náà. 16 Kí pákó kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀. 17 Pẹ̀lú ìtẹ̀bọ̀ méjì ni kí ó kọjú sí ara wọn. Ṣe gbogbo àwọn pákó àgọ́ náà bí èyí. 18 Ìwọ ó sì ṣe ogún (20) pákó sí ìhà gúúsù àgọ́ náà, 19 Ìwọ ó sì ṣe ogójì (40) ìhà ìtẹ̀bọ̀ fàdákà kí ó lọ sí ìsàlẹ̀ wọn, méjì fún pákó kọ̀ọ̀kan, ọ̀kan ní ìsàlẹ̀ ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan. 20 Àti ìhà kejì, ni ìhà àríwá àgọ́ náà, ṣe ogún pákó síbẹ̀ 21 àti ogójì ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà méjì ní abẹ́ pákó kọ̀ọ̀kan. 22 kí ìwọ kí ó ṣe pákó mẹ́fà sì ìkangun, ní ìkangun ìhà ìwọ̀-oòrùn àgọ́ náà, 23 kí o sì ṣe pákó méjì fún igun ní ìhà ẹ̀yìn. 24 Ní igun méjèèjì yìí, wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ méjì láti ìdí dé orí rẹ̀, a ó sì so wọ́n pọ̀ sí òrùka kan: méjèèjì yóò sì rí bákan náà. 25 Wọn ó sì jẹ́ pákó mẹ́jọ, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rìnlélógún, méjì wà ní ìsàlẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan.

26 “Ìwọ ó sì ṣe ọ̀pá ìdábùú igi kasia; márùn-ún fún pákó ìhà kan àgọ́ náà, 27 Márùn-ún fún àwọn ìhà kejì, àti márùn-ún fún pákó ni ìhà ìwọ̀-oòrùn ní ìhà ẹ̀yìn àgọ́ náà. 28 Ọ̀pá ìdábùú àárín ni agbede-méjì gbọdọ̀ tàn láti ìkangun dé ìkangun pákó náà. 29 Ìwọ́ ó sì bo àwọn pákó náà pẹ̀lú wúrà, kí o sì ṣe òrùka wúrà kí ó lè di ọ̀pá ìdábùú mu. Kí o sì tún bo ọ̀pá ìdábùú náà pẹ̀lú wúrà.

30 “Gbé àgọ́ náà ró gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a fihàn ọ́ lórí òkè.

31 “Ìwọ ó sì ṣe aṣọ ìgélé aláró, àti elése àlùkò, àti òdòdó, àti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí í ṣe ọlọ́nà, tí òun ti àwọn kérúbù ni kí á ṣe é. 32 Ìwọ yóò sì fi rọ̀ sára òpó tí ó di igi kasia mẹ́rin ró tí a fi wúrà bò, tí ó dúró lórí ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin mẹ́rin. 33 Ṣo aṣọ títa náà sí ìsàlẹ̀ àwọn ìkọ́, kí o sì gbé àpótí ẹ̀rí sí ẹ̀gbẹ́ aṣọ títa náà. Aṣọ títa náà yóò pínyà ibi mímọ́ kúrò ní ibi mímọ́ tí ó ga jùlọ. 34 Fi ìtẹ́ àánú bo àpótí ẹ̀rí náà ni ibi mímọ́ tí ó ga jùlọ. 35 Gbé tábìlì náà sí ìta aṣọ títa náà sí ìhà gúúsù àgọ́ náà, kí o sì gbé ọ̀pá fìtílà sí òdìkejì rẹ̀ ní ìhà àríwá.

36 “Fún ti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà, ìwọ yóò ṣe aṣọ títa aláró, elése àlùkò, ti òdódó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe. 37 Ìwọ ó sì ṣe ìkọ́ wúrà fún aṣọ títa yìí, àti òpó igi ṣittimu márùn-ún tí a sì fi wúrà bò. Kí o sì dà ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ márùn-ún fún wọn.