New International Version

Micah 7:1-20

Israel’s Misery

1What misery is mine!

I am like one who gathers summer fruit

at the gleaning of the vineyard;

there is no cluster of grapes to eat,

none of the early figs that I crave.

2The faithful have been swept from the land;

not one upright person remains.

Everyone lies in wait to shed blood;

they hunt each other with nets.

3Both hands are skilled in doing evil;

the ruler demands gifts,

the judge accepts bribes,

the powerful dictate what they desire—

they all conspire together.

4The best of them is like a brier,

the most upright worse than a thorn hedge.

The day God visits you has come,

the day your watchmen sound the alarm.

Now is the time of your confusion.

5Do not trust a neighbor;

put no confidence in a friend.

Even with the woman who lies in your embrace

guard the words of your lips.

6For a son dishonors his father,

a daughter rises up against her mother,

a daughter-in-law against her mother-in-law—

a man’s enemies are the members of his own household.

7But as for me, I watch in hope for the Lord,

I wait for God my Savior;

my God will hear me.

Israel Will Rise

8Do not gloat over me, my enemy!

Though I have fallen, I will rise.

Though I sit in darkness,

the Lord will be my light.

9Because I have sinned against him,

I will bear the Lord’s wrath,

until he pleads my case

and upholds my cause.

He will bring me out into the light;

I will see his righteousness.

10Then my enemy will see it

and will be covered with shame,

she who said to me,

“Where is the Lord your God?”

My eyes will see her downfall;

even now she will be trampled underfoot

like mire in the streets.

11The day for building your walls will come,

the day for extending your boundaries.

12In that day people will come to you

from Assyria and the cities of Egypt,

even from Egypt to the Euphrates

and from sea to sea

and from mountain to mountain.

13The earth will become desolate because of its inhabitants,

as the result of their deeds.

Prayer and Praise

14Shepherd your people with your staff,

the flock of your inheritance,

which lives by itself in a forest,

in fertile pasturelands.7:14 Or in the middle of Carmel

Let them feed in Bashan and Gilead

as in days long ago.

15“As in the days when you came out of Egypt,

I will show them my wonders.”

16Nations will see and be ashamed,

deprived of all their power.

They will put their hands over their mouths

and their ears will become deaf.

17They will lick dust like a snake,

like creatures that crawl on the ground.

They will come trembling out of their dens;

they will turn in fear to the Lord our God

and will be afraid of you.

18Who is a God like you,

who pardons sin and forgives the transgression

of the remnant of his inheritance?

You do not stay angry forever

but delight to show mercy.

19You will again have compassion on us;

you will tread our sins underfoot

and hurl all our iniquities into the depths of the sea.

20You will be faithful to Jacob,

and show love to Abraham,

as you pledged on oath to our ancestors

in days long ago.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Mika 7:1-20

Ìrora Israẹli

1Ègbé ni fún mi!

Nítorí èmi sì dàbí ẹni tí ń kó èso ẹ̀ẹ̀rùn jọ,

ìpèsè ọgbà àjàrà;

kò sì ṣí odidi àjàrà kankan láti jẹ,

kò sì ṣí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ nítorí tí ebi ń pa mí.

2Àwọn olódodo sì ti kúrò ní ilẹ̀ náà,

kò sì ṣí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù tí ó jọ olóòtítọ́;

gbogbo wọn sì ń purọ́ ní dídúró nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀,

olúkúlùkù wọ́n sì ń fi àwọ̀n de arákùnrin rẹ̀.

3Ọwọ́ wọn méjèèjì ti múra tán láti ṣe búburú;

àwọn alákòóso ń béèrè fún ẹ̀bùn,

àwọn onídàájọ́ sì ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀

alágbára sì ń pàṣẹ ohun tí wọ́n fẹ́,

gbogbo wọn sì jùmọ̀ ń dìtẹ̀.

4Ẹni tí ó sàn jùlọ nínú wọn sì dàbí ẹ̀gún,

ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ burú ju ẹ̀gún ọgbà lọ.

Ọjọ́ àwọn olùṣọ́ rẹ̀ ti dé,

àti ọjọ́ tí Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ wò.

Nísinsin yìí ní àkókò ìdààmú wọn.

5Ẹ má ṣe gba ọ̀rẹ́ kan gbọ́;

ẹ má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé amọ̀nà kankan.

Pa ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ fún ẹni

tí ó sùn ní oókan àyà rẹ.

67.6: Mt 10.21,35,36; Mk 13.12; Lk 12.53.Nítorí tí ọmọkùnrin kò bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀,

ọmọbìnrin sì dìde sí ìyá rẹ̀,

aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀,

ọ̀tá olúkúlùkù ni àwọn ará ilé rẹ̀.

7Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi ní ìwòye ní ìrètí sí Olúwa,

Èmi dúró de Ọlọ́run olùgbàlà mi;

Ọlọ́run mi yóò sì tẹ́tí sí mi.

Israẹli yóò dìde

8Má ṣe yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi;

Bí mó bá ṣubú, èmi yóò dìde.

Nígbà tí mo bá jókòó sínú òkùnkùn

Olúwa yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún mi.

9Nítorí èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí i,

Èmi yóò faradà ìbínú Olúwa,

títí òun yóò ṣe gba ẹjọ́ mi rò,

tí yóò sì ṣe ìdájọ́ mi.

Òun yóò sì mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀;

èmi yóò sì rí òdodo rẹ̀.

10Nígbà náà ni ọ̀tá mi yóò rí i

ìtìjú yóò sì bo ẹni tí ó wí fún mi pé,

“Níbo ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wà?”

Ojú mi yóò rí ìṣubú rẹ̀;

nísinsin yìí ni yóò di ìtẹ̀mọ́lẹ̀

bí ẹrẹ̀ òpópó.

11Ọjọ́ tí a ó mọ odi rẹ yóò dé,

ọjọ́ náà ni àṣẹ yóò jìnnà réré.

12Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ

láti Asiria àti ìlú ńlá Ejibiti

àní láti Ejibiti dé Eufurate

láti Òkun dé Òkun

àti láti òkè ńlá dé òkè ńlá.

13Ilẹ̀ náà yóò di ahoro fún àwọn olùgbé inú rẹ̀,

nítorí èso ìwà wọn.

Àdúrà àti ìyìn

14Fi ọ̀pá rẹ bọ́ àwọn ènìyàn, agbo ẹran ìní rẹ,

èyí tí ó ń dágbé nínú igbó

ní àárín Karmeli;

Jẹ́ kí wọn jẹun ní Baṣani àti Gileadi

bí ọjọ́ ìgbàanì.

15“Bí i ọjọ́ tí ó jáde kúrò ní Ejibiti wá,

ni èmi yóò fi ohun ìyanu hàn án.”

16Orílẹ̀-èdè yóò rí i, ojú yóò sì tì wọ́n,

nínú gbogbo agbára wọn.

Wọn yóò fi ọwọ́ lé ẹnu wọn,

etí wọn yóò sì di.

17Wọn yóò lá erùpẹ̀ bí ejò,

wọn yóò sì jáde kúrò nínú ihò wọn bí ekòló.

Wọn yóò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,

wọn yóò sì bẹ̀rù nítorí rẹ̀.

18Ta ni Ọlọ́run bí rẹ̀,

ẹni tí ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì,

tí ó sì fojú fo ìrékọjá èyí tókù ìní rẹ̀?

Kì í dúró nínú ìbínú rẹ̀ láéláé

nítorí òun ní inú dídùn sí àánú.

19Òun yóò tún padà yọ́nú sí wa;

òun yóò tẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀,

yóò sì fa gbogbo àìṣedéédéé wa sínú ibú Òkun.

207.20: Lk 1.55.Ìwọ yóò fi òtítọ́ hàn sí Jakọbu

ìwọ yóò sì fi àánú hàn sí Abrahamu,

bí ìwọ ṣe búra fún àwọn baba wa

láti ọjọ́ ìgbàanì.