Job 22 – NIV & YCB

New International Version

Job 22:1-30

Eliphaz

1Then Eliphaz the Temanite replied:

2“Can a man be of benefit to God?

Can even a wise person benefit him?

3What pleasure would it give the Almighty if you were righteous?

What would he gain if your ways were blameless?

4“Is it for your piety that he rebukes you

and brings charges against you?

5Is not your wickedness great?

Are not your sins endless?

6You demanded security from your relatives for no reason;

you stripped people of their clothing, leaving them naked.

7You gave no water to the weary

and you withheld food from the hungry,

8though you were a powerful man, owning land—

an honored man, living on it.

9And you sent widows away empty-handed

and broke the strength of the fatherless.

10That is why snares are all around you,

why sudden peril terrifies you,

11why it is so dark you cannot see,

and why a flood of water covers you.

12“Is not God in the heights of heaven?

And see how lofty are the highest stars!

13Yet you say, ‘What does God know?

Does he judge through such darkness?

14Thick clouds veil him, so he does not see us

as he goes about in the vaulted heavens.’

15Will you keep to the old path

that the wicked have trod?

16They were carried off before their time,

their foundations washed away by a flood.

17They said to God, ‘Leave us alone!

What can the Almighty do to us?’

18Yet it was he who filled their houses with good things,

so I stand aloof from the plans of the wicked.

19The righteous see their ruin and rejoice;

the innocent mock them, saying,

20‘Surely our foes are destroyed,

and fire devours their wealth.’

21“Submit to God and be at peace with him;

in this way prosperity will come to you.

22Accept instruction from his mouth

and lay up his words in your heart.

23If you return to the Almighty, you will be restored:

If you remove wickedness far from your tent

24and assign your nuggets to the dust,

your gold of Ophir to the rocks in the ravines,

25then the Almighty will be your gold,

the choicest silver for you.

26Surely then you will find delight in the Almighty

and will lift up your face to God.

27You will pray to him, and he will hear you,

and you will fulfill your vows.

28What you decide on will be done,

and light will shine on your ways.

29When people are brought low and you say, ‘Lift them up!’

then he will save the downcast.

30He will deliver even one who is not innocent,

who will be delivered through the cleanness of your hands.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 22:1-30

Èsì Elifasi

1Ìgbà náà ni Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé:

222.2,3: Jb 35.6-8.“Ènìyàn lè è ṣe rere fún Ọlọ́run?

Bí ọlọ́gbọ́n ti í ṣe rere fún ara rẹ̀?

3Ohun ayọ̀ ha ni fún Olódùmarè pé olódodo ni ìwọ?

Tàbí èrè kí ni fún un ti ìwọ mú ọ̀nà rẹ̀ pé?

4“Yóò ha bá ọ wí bí, nítorí ìbẹ̀rù

Ọlọ́run rẹ? Yóò ha bá ọ lọ sínú ìdájọ́ bí?

5Ìwà búburú rẹ kò ha tóbi,

àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ láìníye?

6Nítòótọ́ ìwọ béèrè fún ààbò ni ọwọ́ arákùnrin rẹ láìnídìí,

ìwọ sì tú oníhòhò ní aṣọ wọn.

7Ìwọ kò fi omi fún aláàárẹ̀ mu,

ìwọ sì háwọ́ oúnjẹ fún ẹni tí ebi ń pa.

8Bí ó ṣe ti alágbára nì, òun ni ó ní ilẹ̀,

ọlọ́lá sì tẹ̀dó sínú rẹ̀.

9Ìwọ ti rán àwọn opó padà lọ ní ọwọ́ òfo;

Apá àwọn ọmọ aláìní baba ti di ṣiṣẹ́.

10Nítorí náà ni ìdẹ̀kùn ṣe yí ọ káàkiri,

àti ìbẹ̀rù òjijì ń yọ ọ́ lẹ́nu,

11Èéṣe tí òkùnkùn fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè ríran;

Èéṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.

12“Ọlọ́run kò ha jẹ́ ẹni gíga ọ̀run?

Sá wo orí àwọn ìràwọ̀ bí wọ́n ti ga tó!

13Ìwọ sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe mọ̀?

Òun ha lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn wá bí?

14Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ tí ó nípọn jẹ ìbora fún un,

tí kò fi lè ríran; ó sì ń rìn nínú àyíká ọ̀run.

15Ǹjẹ́ ìwọ fẹ́ rin ipa ọ̀nà ìgbàanì tí àwọn

ènìyàn búburú tí rìn?

16A ké wọn lulẹ̀ kúrò nínú ayé láìpé ọjọ́ wọn;

ìpìlẹ̀ wọn ti da bí odò ṣíṣàn;

17Àwọn ẹni tí ó wí fún Ọlọ́run pé, ‘Lọ kúrò lọ́dọ̀ wa!

Kí ni Olódùmarè yóò ṣe fún wọn?’

18Síbẹ̀ ó fi ohun rere kún ilé wọn!

Ṣùgbọ́n ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi!

19Àwọn olódodo rí ìparun wọn, wọ́n sì yọ̀,

àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀ sì fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà pé,

20‘Lóòtítọ́ àwọn ọ̀tá wa ni a ké kúrò,

iná yóò sì jó oró wọn run.’

21“Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà;

nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ.

22Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀ wá,

kí o sì to ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àyà rẹ.

23Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmarè, a sì gbé ọ ró:

Bí ìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ,

24Tí ìwọ bá tẹ́ wúrà dáradára sílẹ̀

lórí erùpẹ̀ àti wúrà ofiri lábẹ́ òkúta odò,

25Nígbà náà ní Olódùmarè yóò jẹ́ wúrà rẹ,

àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

26Lóòtítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inú dídùn nínú Olódùmarè,

ìwọ ó sì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run.

27Bí ìwọ bá gbàdúrà rẹ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóò sì gbọ́ tìrẹ,

ìwọ ó sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.

28Ìwọ ó sì gbìmọ̀ ohun kan pẹ̀lú, yóò sì fi ìdí múlẹ̀ fún ọ;

ìmọ́lẹ̀ yóò sì mọ́ sípa ọ̀nà rẹ.

29Nígbà tí ipa ọ̀nà rẹ bá lọ sísàlẹ̀,

nígbà náà ni ìwọ o wí pé, ‘Ìgbésókè ń bẹ!’

Ọlọ́run yóò sì gba onírẹ̀lẹ̀ là!

30Yóò gba ẹni tí kì í ṣe aláìjẹ̀bi là,

a ó sì gbà á nípa mímọ́ ọwọ́ rẹ̀.”