Job 15 – NIV & YCB

New International Version

Job 15:1-35

Eliphaz

1Then Eliphaz the Temanite replied:

2“Would a wise person answer with empty notions

or fill their belly with the hot east wind?

3Would they argue with useless words,

with speeches that have no value?

4But you even undermine piety

and hinder devotion to God.

5Your sin prompts your mouth;

you adopt the tongue of the crafty.

6Your own mouth condemns you, not mine;

your own lips testify against you.

7“Are you the first man ever born?

Were you brought forth before the hills?

8Do you listen in on God’s council?

Do you have a monopoly on wisdom?

9What do you know that we do not know?

What insights do you have that we do not have?

10The gray-haired and the aged are on our side,

men even older than your father.

11Are God’s consolations not enough for you,

words spoken gently to you?

12Why has your heart carried you away,

and why do your eyes flash,

13so that you vent your rage against God

and pour out such words from your mouth?

14“What are mortals, that they could be pure,

or those born of woman, that they could be righteous?

15If God places no trust in his holy ones,

if even the heavens are not pure in his eyes,

16how much less mortals, who are vile and corrupt,

who drink up evil like water!

17“Listen to me and I will explain to you;

let me tell you what I have seen,

18what the wise have declared,

hiding nothing received from their ancestors

19(to whom alone the land was given

when no foreigners moved among them):

20All his days the wicked man suffers torment,

the ruthless man through all the years stored up for him.

21Terrifying sounds fill his ears;

when all seems well, marauders attack him.

22He despairs of escaping the realm of darkness;

he is marked for the sword.

23He wanders about for food like a vulture;

he knows the day of darkness is at hand.

24Distress and anguish fill him with terror;

troubles overwhelm him, like a king poised to attack,

25because he shakes his fist at God

and vaunts himself against the Almighty,

26defiantly charging against him

with a thick, strong shield.

27“Though his face is covered with fat

and his waist bulges with flesh,

28he will inhabit ruined towns

and houses where no one lives,

houses crumbling to rubble.

29He will no longer be rich and his wealth will not endure,

nor will his possessions spread over the land.

30He will not escape the darkness;

a flame will wither his shoots,

and the breath of God’s mouth will carry him away.

31Let him not deceive himself by trusting what is worthless,

for he will get nothing in return.

32Before his time he will wither,

and his branches will not flourish.

33He will be like a vine stripped of its unripe grapes,

like an olive tree shedding its blossoms.

34For the company of the godless will be barren,

and fire will consume the tents of those who love bribes.

35They conceive trouble and give birth to evil;

their womb fashions deceit.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 15:1-35

Elifasi tako ọrọ̀ Jobu

1Ìgbà náà ní Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé:

2“Ọlọ́gbọ́n a máa sọ̀rọ̀ ìmọ̀ asán, kí

ó sì máa fi afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn kún ara rẹ̀ nínú?

3Òun lè máa fi àròyé sọ̀rọ̀ tí kò ní

èrè, tàbí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nínú èyí tí kò lè fi ṣe rere?

4Ṣùgbọ́n ìwọ ṣá ìbẹ̀rù tì,

ìwọ sì dí iṣẹ́ ìsìn lọ́nà níwájú Ọlọ́run.

5Nítorí pé ẹnu ara rẹ̀ ni ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀

rẹ̀, ìwọ sì yàn ahọ́n alárékérekè ni ààyò.

6Ẹnu ara rẹ̀ ni ó dá lẹ́bi, kì í ṣe èmi;

àní ètè ara rẹ̀ ni ó jẹ́rìí gbè ọ́.

7“Ìwọ ha í ṣe ọkùnrin tí a kọ́ bí?

Tàbí a ha dá ọ ṣáájú àwọn òkè?

8Ìwọ gbúròó àṣírí Ọlọ́run rí, tàbí

ìwọ ha dá ọgbọ́n dúró sọ́dọ̀ ara rẹ?

9Kí ni ìwọ mọ̀ tí àwa kò mọ̀?

Òye kí ní ó yé ọ tí kò sí nínú wa?

10Àwọn arúgbó àti ògbólógbòó ènìyàn wà pẹ̀lú wa,

tí wọ́n dàgbà ju baba rẹ lọ.

11Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ?

Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ?

12Èéṣe ti ọkàn rẹ fi ń ti ọ kiri,

kí ni ìwọ tẹjúmọ́ tóbẹ́ẹ̀.

13Tí ìwọ fi yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì sí Ọlọ́run,

tí ó fi ń jẹ́ ki ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ kí ó máa bọ́ ní ẹnu rẹ̀ bẹ́ẹ̀?

14“Kí ni ènìyàn tí ó fi jẹ mímọ́,

àti ẹni tí a tinú obìnrin bí tí yóò fi ṣe olódodo?

15Kíyèsi i, bi Ọlọ́run ko ba gbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,

àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ojú rẹ̀,

16mélòó mélòó ni ènìyàn, ẹni ìríra àti eléèérí,

tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bi ẹní mu omi.

17“Èmi ó fihàn ọ́, gbọ́ ti èmi;

Èyí tí èmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ,

18ohun tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn láti

ọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́,

19Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan,

ti àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá.

20Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá,

pẹ̀lú ìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo,

àti iye ọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára.

21Ìró ìbẹ̀rù ń bẹ ní etí rẹ̀;

nínú ìrora ni apanirun yóò dìde sí i.

22Kò gbàgbọ́ pé òun ó jáde kúrò nínú òkùnkùn;

a sì ṣà á sápá kan fún idà.

23Ó ń wò káàkiri fún oúnjẹ wí pé, níbo ní ó wà?

Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn súnmọ́ tòsí.

24Ìpọ́njú pẹ̀lú ìrora ọkàn yóò mú un

bẹ̀rù, wọ́n ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ bi ọba ti ìmúra ogun.

25Nítorí pé ó ti nawọ́ rẹ̀ jáde lòdì

sí Ọlọ́run, ó sì múra rẹ̀ le lòdì sí Olódùmarè,

26Ó súre, ó sì fi ẹ̀yìn gíga,

àní fi ike-kókó àpáta rẹ̀ tí ó nípọn kọlù ú.

27“Nítorí tí òun fi ọ̀rá rẹ̀ bo ara rẹ̀

lójú, o sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.

28Òun sì gbé inú ahoro ìlú,

àti nínú ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé

mọ́, tí ó múra tán láti di àlàpà.

29Òun kò lé di ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ ohun ìní rẹ̀ kò

lè dúró pẹ́; Bẹ́ẹ̀ kò lè mú pípé rẹ̀ dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.

30Òun kì yóò jáde kúrò nínú òkùnkùn;

ọ̀wọ́-iná ni yóò jó ẹ̀ka rẹ̀,

àti nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹnu Ọlọ́run ní a ó gba kúrò.

31Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀lé asán, kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ.

Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀.

32A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípé ọjọ́ rẹ̀,

ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù.

33Yóò dàbí àjàrà tí a gbọn èso àìpọ́n rẹ̀ dànù,

yóò sì rẹ̀ ìtànná rẹ̀ dànù bí i ti igi Olifi.

34Nítorí pé ayọ̀ àwọn àgàbàgebè

yóò túká, iná ní yóò sì jó àgọ́ àwọn tí ó fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀.

35Wọ́n lóyún ìwà ìkà, wọ́n sì bí ẹ̀ṣẹ̀,

ikùn wọn sì pèsè ẹ̀tàn.”