Jeremiah 25 – NIV & YCB

New International Version

Jeremiah 25:1-38

Seventy Years of Captivity

1The word came to Jeremiah concerning all the people of Judah in the fourth year of Jehoiakim son of Josiah king of Judah, which was the first year of Nebuchadnezzar king of Babylon. 2So Jeremiah the prophet said to all the people of Judah and to all those living in Jerusalem: 3For twenty-three years—from the thirteenth year of Josiah son of Amon king of Judah until this very day—the word of the Lord has come to me and I have spoken to you again and again, but you have not listened.

4And though the Lord has sent all his servants the prophets to you again and again, you have not listened or paid any attention. 5They said, “Turn now, each of you, from your evil ways and your evil practices, and you can stay in the land the Lord gave to you and your ancestors for ever and ever. 6Do not follow other gods to serve and worship them; do not arouse my anger with what your hands have made. Then I will not harm you.”

7“But you did not listen to me,” declares the Lord, “and you have aroused my anger with what your hands have made, and you have brought harm to yourselves.”

8Therefore the Lord Almighty says this: “Because you have not listened to my words, 9I will summon all the peoples of the north and my servant Nebuchadnezzar king of Babylon,” declares the Lord, “and I will bring them against this land and its inhabitants and against all the surrounding nations. I will completely destroy25:9 The Hebrew term refers to the irrevocable giving over of things or persons to the Lord, often by totally destroying them. them and make them an object of horror and scorn, and an everlasting ruin. 10I will banish from them the sounds of joy and gladness, the voices of bride and bridegroom, the sound of millstones and the light of the lamp. 11This whole country will become a desolate wasteland, and these nations will serve the king of Babylon seventy years.

12“But when the seventy years are fulfilled, I will punish the king of Babylon and his nation, the land of the Babylonians,25:12 Or Chaldeans for their guilt,” declares the Lord, “and will make it desolate forever. 13I will bring on that land all the things I have spoken against it, all that are written in this book and prophesied by Jeremiah against all the nations. 14They themselves will be enslaved by many nations and great kings; I will repay them according to their deeds and the work of their hands.”

The Cup of God’s Wrath

15This is what the Lord, the God of Israel, said to me: “Take from my hand this cup filled with the wine of my wrath and make all the nations to whom I send you drink it. 16When they drink it, they will stagger and go mad because of the sword I will send among them.”

17So I took the cup from the Lord’s hand and made all the nations to whom he sent me drink it: 18Jerusalem and the towns of Judah, its kings and officials, to make them a ruin and an object of horror and scorn, a curse25:18 That is, their names to be used in cursing (see 29:22); or, to be seen by others as cursed—as they are today; 19Pharaoh king of Egypt, his attendants, his officials and all his people, 20and all the foreign people there; all the kings of Uz; all the kings of the Philistines (those of Ashkelon, Gaza, Ekron, and the people left at Ashdod); 21Edom, Moab and Ammon; 22all the kings of Tyre and Sidon; the kings of the coastlands across the sea; 23Dedan, Tema, Buz and all who are in distant places25:23 Or who clip the hair by their foreheads; 24all the kings of Arabia and all the kings of the foreign people who live in the wilderness; 25all the kings of Zimri, Elam and Media; 26and all the kings of the north, near and far, one after the other—all the kingdoms on the face of the earth. And after all of them, the king of Sheshak25:26 Sheshak is a cryptogram for Babylon. will drink it too.

27“Then tell them, ‘This is what the Lord Almighty, the God of Israel, says: Drink, get drunk and vomit, and fall to rise no more because of the sword I will send among you.’ 28But if they refuse to take the cup from your hand and drink, tell them, ‘This is what the Lord Almighty says: You must drink it! 29See, I am beginning to bring disaster on the city that bears my Name, and will you indeed go unpunished? You will not go unpunished, for I am calling down a sword on all who live on the earth, declares the Lord Almighty.’

30“Now prophesy all these words against them and say to them:

“ ‘The Lord will roar from on high;

he will thunder from his holy dwelling

and roar mightily against his land.

He will shout like those who tread the grapes,

shout against all who live on the earth.

31The tumult will resound to the ends of the earth,

for the Lord will bring charges against the nations;

he will bring judgment on all mankind

and put the wicked to the sword,’ ”

declares the Lord.

32This is what the Lord Almighty says:

“Look! Disaster is spreading

from nation to nation;

a mighty storm is rising

from the ends of the earth.”

33At that time those slain by the Lord will be everywhere—from one end of the earth to the other. They will not be mourned or gathered up or buried, but will be like dung lying on the ground.

34Weep and wail, you shepherds;

roll in the dust, you leaders of the flock.

For your time to be slaughtered has come;

you will fall like the best of the rams.25:34 Septuagint; Hebrew fall and be shattered like fine pottery

35The shepherds will have nowhere to flee,

the leaders of the flock no place to escape.

36Hear the cry of the shepherds,

the wailing of the leaders of the flock,

for the Lord is destroying their pasture.

37The peaceful meadows will be laid waste

because of the fierce anger of the Lord.

38Like a lion he will leave his lair,

and their land will become desolate

because of the sword25:38 Some Hebrew manuscripts and Septuagint (see also 46:16 and 50:16); most Hebrew manuscripts anger of the oppressor

and because of the Lord’s fierce anger.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jeremiah 25:1-38

Àádọ́rin ọdún nínú oko ẹrú

1Ọ̀rọ̀ sì tọ Jeremiah wá nípa àwọn ènìyàn Juda ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, èyí tí ó jẹ́ ọdún kìn-ín-ní Nebukadnessari ọba Babeli. 2Nítorí náà, Jeremiah wòlíì sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn Juda àti sí àwọn olùgbé Jerusalẹmu. 3Fún odidi ọdún mẹ́tàlélógún, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún kẹtàlá Josiah, ọmọ Amoni ọba Juda, títí di ọjọ́ yìí, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, mo sì ti sọ ọ́ fún un yín láti ìgbà dé ìgbà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetísílẹ̀.

4Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn wòlíì sí i yín láti ìgbà dé ìgbà, ẹ̀yin kò fetísílẹ̀. 5Wọ́n sì wí pé, “Ẹ yípadà olúkúlùkù yín kúrò ní inú ibi rẹ̀ àti ní ọ̀nà ibi rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì lè dúró ní ilẹ̀ tí Ọlọ́run fún un yín àti àwọn baba yín títí láéláé. 6Má ṣe tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n tàbí bọ wọ́n; ẹ má ṣe mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ ti fi ọwọ́ yín ṣe. Nígbà náà ni Èmi kò ní ṣe yín ní ibi.”

7“Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi,” ni Olúwa wí; “bẹ́ẹ̀ ni ẹ sì ti mú inú bí mi pẹ̀lú ohun tí ẹ fi ọwọ́ yín ṣe, ẹ sì ti mú ibi wá sórí ara yín.”

8Nítorí náà, Ọlọ́run alágbára sọ èyí: “Nítorí wí pé ẹ̀yin kò fetí sí ọ̀rọ̀ mi, 9Èmi yóò pe gbogbo àwọn ènìyàn àríwá, àti ìránṣẹ́ mi Nebukadnessari ọba Babeli,” ni Olúwa wí. “Èmi yóò sì mú wọn dìde lòdì sí ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé rẹ̀ àti sí gbogbo orílẹ̀-èdè àyíká rẹ̀. Èmi yóò pa wọ́n run pátápátá, Èmi yóò sọ wọ́n di nǹkan ẹ̀rù àti yẹ̀yẹ́ àti ìparun ayérayé. 1025.10: Jr 7.34; 16.9; If 18.23.Èmi yóò sì mú ìró ayọ̀ àti inú dídùn kúrò lọ́dọ̀ wọn; ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó, ìró ọlọ òkúta àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà. 11Gbogbo orílẹ̀-èdè yìí yóò sì di ahoro, orílẹ̀-èdè yìí yóò sì sìn ọba Babeli ní àádọ́rin ọdún.

12“Ṣùgbọ́n, nígbà tí àádọ́rin ọdún náà bá pé; Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Babeli àti orílẹ̀-èdè rẹ, ilẹ̀ àwọn ará Babeli nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí; “bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò sọ ọ́ di ahoro títí láé. 13Èmi yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ wọ̀nyí wá sórí ilẹ̀ náà, gbogbo ohun tí a ti sọ àní gbogbo èyí tí a ti kọ sínú ìwé yìí, èyí tí Jeremiah ti sọtẹ́lẹ̀ sí gbogbo orílẹ̀-èdè. 14Àwọn fúnrawọn yóò sì sin orílẹ̀-èdè púpọ̀ àti àwọn ọba ńlá. Èmi yóò sì sán fún oníkálùkù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”

Ago ìbínú Ọlọ́run

1525.15: Jr 51.7; If 14.8,10; 16.19; 17.4; 18.3.Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí fún mi: “Gba ago yìí ní ọwọ́ mí tí ó kún fún ọtí wáìnì ìbínú mi, kí o sì mú gbogbo orílẹ̀-èdè ti mo rán ọ sí mu ún. 16Nígbà tí wọ́n bá mu ún, wọn yóò ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n: bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n di aṣiwèrè nítorí idà tí yóò ránṣẹ́ sí àárín wọn.” 17Mo sì gba ago náà lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó rán mi sí mu ún.

18Jerusalẹmu àti àwọn ìlú Juda, àwọn ọba wọn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ wọn, láti sọ wọ́n di ohun ìparun, ohun ẹ̀rù, ẹ̀sìn àti ègún, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti rí lónìí yìí.

19Farao ọba Ejibiti, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn aláṣẹ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀. 20Àti gbogbo àwọn ènìyàn àjèjì tí ó wà níbẹ̀;

gbogbo àwọn ọba Usi,

gbogbo àwọn ọba Filistini, gbogbo àwọn ti Aṣkeloni, Gasa, Ekroni àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó kù sí Aṣdodu.

21Edomu, Moabu àti Ammoni;

22gbogbo àwọn ọba Tire àti Sidoni;

gbogbo àwọn ọba erékùṣù wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ ní ìkọjá Òkun.

23Dedani, Tema, Busi àti gbogbo àwọn tí ń gbé lọ́nà jíjìn réré.

24Gbogbo àwọn ọba Arabia àti àwọn ọba àwọn àjèjì ènìyàn tí ń gbé inú aginjù.

25Gbogbo àwọn ọba Simri, Elamu àti Media.

26Àti gbogbo àwọn ọba àríwá ní tòsí àti lọ́nà jíjìn, ẹnìkínní lẹ́yìn ẹnìkejì; gbogbo àwọn ìjọba lórí orílẹ̀ ayé.

Àti gbogbo wọn, ọba Ṣeṣaki náà yóò sì mu.

27“Nígbà náà, sọ fún wọn: Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli wí: Mu, kí o sì mú àmuyó kí o sì bì, bẹ́ẹ̀ ni kí o sì ṣubú láì dìde mọ́ nítorí idà tí n ó rán sí àárín yín. 28Ṣùgbọ́n bí wọ́n ba kọ̀ láti gba ago náà ní ọwọ́ rẹ kí wọ́n sì mu ún, sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run alágbára sọ: Ẹyin gbọdọ̀ mu ún! 29Wò ó, èmi ń mú ibi bọ̀ sí orí orílẹ̀-èdè tí ó ń jẹ́ orúkọ mi; ǹjẹ́ yóò ha a lè lọ láìjìyà? Ẹ̀yin ń pe idà sọ̀kalẹ̀ sórí gbogbo àwọn olùgbé ayé, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ.’

30“Nísinsin yìí, sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí nípa wọn:

“ ‘Kí o sì sọ pé, Olúwa yóò bú láti òkè wá,

yóò sì bú kíkankíkan sí ilẹ̀ náà.

Yóò parí gbogbo olùgbé ayé, bí àwọn tí ń tẹ ìfúntí

31Ìrọ́kẹ̀kẹ̀ yóò wà títí dé òpin ilẹ̀ ayé,

nítorí pé Olúwa yóò mú ìdààmú wá sí orí

àwọn orílẹ̀-èdè náà,

yóò mú ìdájọ́ wá sórí gbogbo ènìyàn,

yóò sì fi àwọn olùṣe búburú fún idà,’ ”

ni Olúwa wí.

32Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

“Wò ó! Ibi ń tànkálẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn;

Ìjì ńlá yóò sì ru sókè láti òpin ayé.”

33Nígbà náà, àwọn tí Olúwa ti pa yóò wà ní ibi gbogbo, láti ìpẹ̀kun kan sí òmíràn. A kì yóò ṣọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọ tàbí sin wọ́n; ṣùgbọ́n wọn yóò dàbí ààtàn lórí ilẹ̀.

34Ké, kí ẹ sì pohùnréré ẹkún

ẹ̀yin olùṣọ́-àgùntàn, ẹ yí nínú eruku,

ẹ̀yin olùdarí agbo ẹran,

nítorí pé ọjọ́ àti pa yín ti dé,

ẹ̀yin ó sì ṣubú bí ohun èlò iyebíye.

35Àwọn olùṣọ́-àgùntàn kì yóò rí ibi sálọ

kì yóò sì ṣí àsálà fún olórí agbo ẹran.

36Gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn,

àti ìpohùnréré ẹkún àwọn olórí

agbo ẹran; nítorí pé Olúwa ń pa pápá oko tútù wọn run.

37Ibùgbé àlàáfíà yóò di ahoro,

nítorí ìbínú ńlá Olúwa.

38Gẹ́gẹ́ bí kìnnìún yóò fi ibùba rẹ̀ sílẹ̀,

ilẹ̀ wọn yóò sì di ahoro, nítorí idà àwọn aninilára,

àti nítorí ìbínú ńlá Olúwa.