Matthew 9 – NIRV & YCB

New International Reader’s Version

Matthew 9:1-38

Jesus Forgives and Heals a Man Who Could Not Walk

1Jesus stepped into a boat. He went over to the other side of the lake and came to his own town. 2Some men brought to him a man who could not walk. He was lying on a mat. Jesus saw that they had faith. So he said to the man, “Don’t lose hope, son. Your sins are forgiven.”

3Then some teachers of the law said to themselves, “This fellow is saying a very evil thing!”

4Jesus knew what they were thinking. So he said, “Why do you have evil thoughts in your hearts? 5Is it easier to say, ‘Your sins are forgiven’? Or to say, ‘Get up and walk’? 6But I want you to know that the Son of Man has authority on earth to forgive sins.” So he spoke to the man who could not walk. “Get up,” he said. “Take your mat and go home.” 7The man got up and went home. 8When the crowd saw this, they were filled with wonder. They praised God for giving that kind of authority to a human being.

Jesus Chooses Matthew and Eats With Sinners

9As Jesus went on from there, he saw a man named Matthew. He was sitting at the tax collector’s booth. “Follow me,” Jesus told him. Matthew got up and followed him.

10Later Jesus was having dinner at Matthew’s house. Many tax collectors and sinners came. They ate with Jesus and his disciples. 11The Pharisees saw this. So they asked the disciples, “Why does your teacher eat with tax collectors and sinners?”

12Jesus heard this. So he said, “Those who are healthy don’t need a doctor. Sick people do. 13Go and learn what this means, ‘I want mercy and not sacrifice.’ (Hosea 6:6) I have not come to get those who think they are right with God to follow me. I have come to get sinners to follow me.”

Jesus Is Asked About Fasting

14One day John’s disciples came. They said to Jesus, “We and the Pharisees often go without eating. Why don’t your disciples go without eating?”

15Jesus answered, “How can the guests of the groom be sad while he is with them? The time will come when the groom will be taken away from them. Then they will fast.

16“People don’t sew a patch of new cloth on old clothes. The new piece will pull away from the old. That will make the tear worse. 17People don’t pour new wine into old wineskins. If they do, the skins will burst. The wine will run out, and the wineskins will be destroyed. No, people pour new wine into new wineskins. Then both are saved.”

Jesus Heals a Dead Girl and a Suffering Woman

18While Jesus was saying this, a synagogue leader came. He got down on his knees in front of Jesus. He said, “My daughter has just died. But come and place your hand on her. Then she will live again.” 19Jesus got up and went with him. So did his disciples.

20Just then a woman came up behind Jesus. She had a sickness that made her bleed. It had lasted for 12 years. She touched the edge of his clothes. 21She thought, “I only need to touch his clothes. Then I will be healed.”

22Jesus turned and saw her. “Dear woman, don’t give up hope,” he said. “Your faith has healed you.” The woman was healed at that moment.

23When Jesus entered the synagogue leader’s house, he saw the noisy crowd and people playing flutes. 24He said, “Go away. The girl is not dead. She is sleeping.” But they laughed at him. 25After the crowd had been sent outside, Jesus went in. He took the girl by the hand, and she got up. 26News about what Jesus had done spread all over that area.

Jesus Heals Two Blind Men

27As Jesus went on from there, two blind men followed him. They called out, “Have mercy on us, Son of David!”

28When Jesus went indoors, the blind men came to him. He asked them, “Do you believe that I can do this?”

“Yes, Lord,” they replied.

29Then he touched their eyes. He said, “It will happen to you just as you believed.” 30They could now see again. Jesus strongly warned them, “Be sure that no one knows about this.” 31But they went out and spread the news. They talked about him all over that area.

32While they were going out, another man was brought to Jesus. A demon controlled him, and he could not speak. 33When the demon was driven out, the man spoke. The crowd was amazed. They said, “Nothing like this has ever been seen in Israel.”

34But the Pharisees said, “He drives out demons by the power of the prince of demons.”

There Are Only a Few Workers

35Jesus went through all the towns and villages. He taught in their synagogues. He preached the good news of the kingdom. And he healed every illness and sickness. 36When he saw the crowds, he felt deep concern for them. They were treated badly and were helpless, like sheep without a shepherd. 37Then Jesus said to his disciples, “The harvest is huge. But there are only a few workers. 38So ask the Lord of the harvest to send workers out into his harvest field.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Matiu 9:1-38

Jesu mú arọ láradá

19.1-8: Mk 2.1-12; Lk 5.17-26.Jesu bọ́ sínú ọkọ̀, ó sì rékọjá odò lọ sí ìlú abínibí rẹ̀ 29.2: Mt 9.22; Mk 6.50; 10.49; Jh 16.33; Ap 23.11; Lk 7.48.Àwọn ọkùnrin kan gbé arọ kan tọ̀ ọ́ wá lórí àkéte rẹ̀. Nígbà tí Jesu rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ tújúká, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

3Nígbà yìí ni àwọn olùkọ́ òfin wí fún ara wọn pé, “Ọkùnrin yìí ń sọ̀rọ̀-òdì!”

4Jesu sì mọ̀ èrò inú wọn, ó wí pé, “Nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe ń ro búburú nínú yín? 5Èwo ni ó rọrùn jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ;’ tàbí wí pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn?’ 6Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì ni.” Ó sì wí fún arọ náà pé, “Dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ ilé rẹ.” 7Ọkùnrin náà sì dìde, ó sì lọ ilé rẹ̀. 8Nígbà tí ìjọ ènìyàn rí í ẹnu sì yà wọ́n, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, ti ó fi irú agbára báyìí fún ènìyàn.

Ìpè Matiu

99.9-13: Mk 2.13-17; Lk 5.27-32; 15.1-2; 7.34.Bí Jesu sì ti ń rékọjá láti ibẹ̀ lọ, o rí ọkùnrin kan ti à ń pè ní Matiu, ó jókòó ní ibùdó àwọn agbowó òde, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn,” Matiu sì dìde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

10Ó sì ṣe, bí Jesu tí jókòó ti ó ń jẹun nínú ilé Matiu, sì kíyèsi i, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti “ẹlẹ́ṣẹ̀” wá, wọ́n sì bá a jẹun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 11Nígbà tí àwọn Farisi sì rí i, wọ́n wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “ ‘Èéṣe’ tí olùkọ́ yín fi ń bá àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun pọ̀?”

12Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu gbọ́ èyí, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọ́n le kò wá oníṣègùn bí kò ṣe àwọn tí ara wọn kò dá. 13Ṣùgbọ́n ẹ lọ kọ́ ohun ti èyí túmọ̀ sí: ‘Àánú ni èmi ń fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;’ nítorí èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

Ìbéèrè nípa àwẹ̀ lọ́wọ́ Jesu

149.14-17: Mk 2.18-22; Lk 5.33-39; 18.12.Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu tọ̀ ọ́ wá láti béèrè wí pé, “Èéṣe tí àwa àti àwọn Farisi fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò gbààwẹ̀?”

15Jesu sì dáhùn pé, “Àwọn ọmọ ilé ìyàwó ha le máa ṣọ̀fọ̀, nígbà tí ọkọ ìyàwó ń bẹ lọ́dọ̀ wọn? Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó lọ́wọ́ wọn; nígbà náà ni wọn yóò gbààwẹ̀.

16“Kò sí ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ tuntun lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù; nítorí èyí tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò ya ní ojú lílẹ̀, aṣọ náà yóò sì ya púpọ̀ sì i ju ti ìṣáájú lọ. 17Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí fi ọtí tuntun sínú ògbólógbòó ìgò-awọ; bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgò-awọ yóò bẹ́, ọtí á sì tú jáde, ìgò-awọ á sì ṣègbé. Ṣùgbọ́n ọtí tuntun ni wọn í fi sínú ìgò-awọ tuntun àwọn méjèèjì a sì ṣe déédé.”

Ọmọbìnrin tó kú àti obìnrin onísun-ẹ̀jẹ̀

18Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, kíyèsi i, ìjòyè kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ wí pé, “Ọmọbìnrin mi kú nísinsin yìí, ṣùgbọ́n wá fi ọwọ́ rẹ̀ lé e, òun yóò sì yè.” 19Jesu dìde ó sì bá a lọ àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

20Sì kíyèsi i, obìnrin kan ti ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ ní ọdún méjìlá, ó wá lẹ́yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀. 21Nítorí ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à le fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.”

229.22: Mk 10.52; Lk 7.50; 17.19; Mt 15.28; 9.29.Nígbà tí Jesu sì yí ara rẹ̀ padà tí ó rí i, ó wí pé, “Ọmọbìnrin, tújúká, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradà.” A sì mú obìnrin náà láradá ni wákàtí kan náà.

23Nígbà tí Jesu sí i dé ilé ìjòyè náà, ó bá àwọn afunfèrè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń pariwo. 24Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ; nítorí ọmọbìnrin náà kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi i rín ẹ̀rín ẹlẹ́yà. 25Ṣùgbọ́n nígbà tí a ti àwọn ènìyàn jáde, ó wọ ilé, ó sì fà ọmọbìnrin náà ní ọwọ́ sókè; bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin náà sì dìde. 26Òkìkí èyí sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.

Jesu wo afọ́jú àti odi sàn

279.27-31: Mt 20.29-34.Nígbà tí Jesu sì jáde níbẹ̀, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n ń kígbe sókè wí pé, “Ṣàánú fún wa, ìwọ ọmọ Dafidi.”

28Nígbà tí ó sì wọ̀ ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ wá, Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ pé mo le ṣe èyí?”

Wọn sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ìwọ lè ṣe é.”

29Ó sì fi ọwọ́ bà wọ́n ní ojú, ó wí pé, “Kí ó rí fún yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín.” 30Ojú wọn sì là; Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi, wí pé, “Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan kí ó mọ̀ nípa èyí.” 31Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n lọ, wọ́n ròyìn rẹ̀ yí gbogbo ìlú náà ká.

329.32-34: Lk 11.14-15; Mt 12.22-24; Mk 3.22; Jh 7.20.Bí wọ́n tí ń jáde lọ, wò ó wọ́n mú ọkùnrin odi kan tí ó ní ẹ̀mí èṣù tọ Jesu wá. 33Nígbà tí a lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, ọkùnrin tí ó ya odi sì fọhùn. Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn, wọ́n wí pé, “A kò rí irú èyí rí ní Israẹli.”

34Ṣùgbọ́n àwọn Farisi wí pé, “Agbára olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”

Àwọn Alágbàṣe Kéré

359.35: Mt 4.23; Mk 6.6.Jesu sì rìn yí gbogbo ìlú ńlá àti ìletò ká, ó ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn, ó sì ń wàásù ìhìnrere ìjọba ọrun, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn àti gbogbo àìsàn ní ara àwọn ènìyàn. 369.36: Mk 6.34; Mt 14.14; 15.32; Nu 27.17; Sk 10.2.Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àánú wọn ṣe é, nítorí àárẹ̀ mú wọn, wọn kò sì rí ìrànlọ́wọ́, bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́. 379.37-38: Lk 10.2; Jh 4.35.Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni ìkórè pọ̀ ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan 38Nítorí náà, ẹ gbàdúrà sí Olúwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.”