Exodus 20 – NIRV & YCB

New International Reader’s Version

Exodus 20:1-26

God Gives His People the Ten Commandments

1Here are all the words God spoke. He said,

2“I am the Lord your God. I brought you out of Egypt. That is the land where you were slaves.

3“Do not put any other gods in place of me.

4“Do not make for yourself statues of gods that look like anything in the sky. They may not look like anything on the earth or in the waters either. 5Do not bow down to them or worship them. I, the Lord your God, am a jealous God. I cause the sins of the parents to affect their children. I will cause the sins of those who hate me to affect even their grandchildren and great-grandchildren. 6But for all time to come I show love to all those who love me and keep my commandments.

7“Do not misuse the name of the Lord your God. The Lord will find guilty anyone who misuses his name.

8“Remember to keep the Sabbath day holy. 9Do all your work in six days. 10But the seventh day is a sabbath to honor the Lord your God. Do not do any work on that day. The same command applies to your sons and daughters, your male and female servants, and your animals. It also applies to any outsiders who live in your towns. 11In six days the Lord made the heavens, the earth, the sea and everything in them. But he rested on the seventh day. So the Lord blessed the Sabbath day and made it holy.

12“Honor your father and mother. Then you will live a long time in the land the Lord your God is giving you.

13“Do not murder.

14“Do not commit adultery.

15“Do not steal.

16“Do not be a false witness against your neighbor.

17“Do not want to have anything your neighbor owns. Do not want to have your neighbor’s house, wife, male or female servant, ox or donkey.”

18The people saw the thunder and lightning. They heard the trumpet. They saw the mountain covered with smoke. They trembled with fear and stayed a long way off. 19They said to Moses, “Speak to us yourself. Then we’ll listen. But don’t let God speak to us. If he does, we’ll die.”

20Moses said to the people, “Don’t be afraid. God has come to test you. He wants you to have respect for him. That will keep you from sinning.”

21Moses approached the thick darkness where God was. But the people remained a long way off.

Worship the Lord

22Then the Lord said to Moses, “Here is what you must tell the people of Israel. Say to them, ‘You have seen for yourselves what I said to you from heaven. 23Do not put any other gods in place of me. Do not make silver or gold statues of them for yourselves.

24“ ‘Make an altar out of dirt for me. Sacrifice your burnt offerings and friendship offerings on it. Sacrifice your sheep, goats and cattle on it. I will come to you and bless you everywhere I cause my name to be honored. 25If you make an altar out of stones to honor me, do not build it with blocks of stone. You will make it “unclean” if you use a tool on it. 26Do not walk up steps to my altar. If you do, someone might see your naked body under your robes.’

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 20:1-26

Òfin mẹ́wàá

1Ọlọ́run sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé:

220.2-17: De 5.6-21.“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti, láti oko ẹrú jáde wá.

320.3: Ek 20.23; De 5.7.“Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.

420.4: Ek 20.23; 34.17; Le 19.4; 26.1; De 4.15-19; 5.8; 27.15.Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. 520.5,6: Ek 23.24; 34.6,7,14; De 4.24; 5.9,10; 7.9.Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi. 6Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.

720.7: Le 19.12; De 5.11.Ẹ má ṣe ṣi orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín lò, torí pé ẹnikẹ́ni tí o bá ṣi orúkọ rẹ̀ lò kì yóò lọ láìjẹ̀bi.

820.8: Ek 23.12; 31.12-17; 34.21; 35.2,3; Le 19.3; De 5.12-15.Rántí ọjọ́ ìsinmi láti yà á sí mímọ́. 9Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ, 10Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ: nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, àti ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ, tí ń bẹ nínú ibodè rẹ. 11Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ó sì sinmi ní ọjọ́ keje: nítorí náà ni Olúwa ṣe bùkún ọjọ́ ìsinmi tí ó sì yà á sí mímọ́.

1220.12-16: Mt 19.18,19; Mk 10.19; Lk 18.20.20.12: Le 19.3; De 5.16; Mt 15.4; Mk 7.10; Ef 6.2.Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.

1320.13: Gẹ 9.6; Ek 21.12; Le 24.17; De 5.17; Mt 5.21; Jk 2.11.20.13-17: Ro 13.9.Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.

1420.14: Le 20.10; De 5.18; Mt 5.27; Ro 7.7.Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.

1520.15: Le 19.11; De 5.19.Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.

1620.16: Ek 23.1; De 5.20.Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.

1720.17: De 5.21; Ro 7.7.Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéjì rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéjì rẹ.”

18Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n ṣìgàṣìgà fún ìbẹ̀rù. 19Wọ́n wí fún Mose pé, “Ìwọ fúnrarẹ̀ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú.”

20Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣẹ̀.”

21Àwọn ènìyàn sì dúró ní òkèèrè nígbà tí Mose súnmọ́ ibi òkùnkùn biribiri níbi tí Ọlọ́run wà.

22Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ará Israẹli: ‘Ẹ̀yin ti rí i fúnrayín bí èmi ti bá a yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá. 2320.23: Ek 20.3,4; 34.17; De 27.15.Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sin ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi: ẹ̀yin kò gbọdọ̀ rọ ọlọ́run fàdákà tàbí ọlọ́run wúrà fún ara yín.

2420.24: Ek 27.1-8; De 12.5; 26.2.“ ‘Pẹpẹ erùpẹ̀ ni kí ìwọ mọ fún mi. Ní orí pẹpẹ yìí ni kí ìwọ ti máa rú ẹbọ sísun rẹ sí mi àti ẹbọ àlàáfíà rẹ, àgùntàn rẹ, ewúrẹ́ àti akọ màlúù rẹ. Ní ibi gbogbo tí mo gbé fi ìrántí orúkọ mi sí, èmi yóò sì máa tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bùkún ọ níbẹ̀. 2520.25: De 27.5-7; Jo 8.31.Bí ìwọ bá ṣe pẹpẹ òkúta fún mi, má ṣe fi òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ kọ́ ọ, nítorí bí ìwọ bá lo ohun ọnà rẹ lórí rẹ̀, ìwọ sọ ọ di àìmọ́. 26Ìwọ kò gbọdọ̀ gun àkàsọ̀ lọ sí ibi pẹpẹ mi, kí àwọn ènìyàn má ba à máa wo ìhòhò rẹ láti abẹ́ aṣọ tí ìwọ wọ̀ nígbà tí ìwọ bá ń gòkè lọ sí ibi pẹpẹ.’