1 Samuel 22 – NIRV & YCB

New International Reader’s Version

1 Samuel 22:1-23

David at Adullam and Mizpah

1David left Gath and escaped to the cave of Adullam. His brothers and the other members of his family heard about it. So they went down to join him there. 2Everyone who was in trouble or owed money or was unhappy gathered around him. He became their commander. About 400 men were with him.

3From there David went to Mizpah in Moab. He spoke to the king of Moab. He said, “Please let my father and mother come and stay with you. Let them stay until I learn what God will do for me.” 4So David left his parents with the king of Moab. They stayed with him as long as David was in his usual place of safety.

5But the prophet Gad spoke to David. He said, “Don’t stay in your usual place of safety. Go into the land of Judah.” So David left and went to the forest of Hereth.

Saul Kills the Priests at Nob

6Saul heard that the place where David and his men were hiding had been discovered. Saul was sitting under a tamarisk tree on the hill at Gibeah. He was holding his spear. All his officials were standing at his side. 7Saul said to them, “Men of Benjamin, listen to me! Do you think Jesse’s son will give all of you fields and vineyards? Do you think he’ll make some of you commanders of thousands of men? Do you think he’ll make the rest of you commanders of hundreds? 8Is that why all of you have joined together against me? No one tells me when my son makes a covenant with Jesse’s son. None of you is concerned about me. No one tells me that my son has stirred up Jesse’s son to hide and wait to attack me. But that’s exactly what’s happening now.”

9Doeg was standing with Saul’s officials. He was from Edom. He said, “I saw Jesse’s son David come to Ahimelek at Nob. Ahimelek is the son of Ahitub. 10Ahimelek asked the Lord a question for David. He also gave him food and the sword of Goliath, the Philistine.”

11Then the king sent for the priest Ahimelek, the son of Ahitub. The king also sent for all the men in his family. They were the priests at Nob. All of them came to the king. 12Saul said, “Son of Ahitub, listen to me.”

“Yes, master,” he answered.

13Saul said to him, “Why have you and Jesse’s son joined together against me? Why did you give him bread and a sword? Why did you ask God a question for him? Now he has turned against me. He is hiding and waiting to attack me right now.”

14Ahimelek answered the king, “David is faithful to you. In fact, he’s more faithful to you than anyone else who serves you. He’s your own son-in-law. He’s the captain of your own personal guards. He’s highly respected by everyone in your palace. 15Was that day the first time I asked God a question for him? Of course not! Please don’t bring charges against me. Please don’t bring charges against anyone in my family. I don’t know anything at all about this whole matter.”

16But the king said, “Ahimelek, you will certainly be put to death. You and your whole family will be put to death.”

17Then the king gave an order to the guards at his side. He said, “Go and kill the priests of the Lord. They are on David’s side too. They knew he was running away from me. And they didn’t even tell me.”

But the king’s officials wouldn’t raise a hand to strike down the priests of the Lord.

18Then the king ordered Doeg, “You go and strike down the priests.” So Doeg, the Edomite, went and struck them down. That day he killed 85 priests who wore linen aprons. 19He also killed the people of Nob with his sword. Nob was a town where priests lived. Doeg killed its men and women. He killed its children and babies. He also destroyed its cattle, donkeys and sheep.

20But Abiathar, a son of Ahimelek, escaped. Ahimelek was the son of Ahitub. Abiathar ran away and joined David. 21He told David that Saul had killed the priests of the Lord. 22Then David said to Abiathar, “One day I was at Nob. I saw Doeg, the Edomite, there. I knew he would be sure to tell Saul. Your whole family has been killed. And I’m responsible for it. 23So stay with me. Don’t be afraid. The man who wants to kill you wants to kill me too. You will be safe with me.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Samuẹli 22:1-23

Dafidi ní Adullamu àti Mispa

1Dafidi sì kúrò níbẹ̀, ó sì sá sí ihò Adullamu; nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ìdílé baba rẹ̀ sì gbọ́, wọ́n sì sọ̀kalẹ̀ tọ̀ ọ́ wá níbẹ̀. 2Olúkúlùkù ẹni tí ó tí wà nínú ìpọ́njú, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ti jẹ gbèsè, àti olúkúlùkù ẹni tí ó wà nínú ìbànújẹ́, sì kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, òun sì jẹ́ olórí wọn; àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ sì tó ìwọ̀n irínwó ọmọkùnrin.

3Dafidi sì ti ibẹ̀ náà lọ sí Mispa tí Moabu: ó sì wí fún ọba Moabu pé, “Jẹ́ kí baba àti ìyá mi, èmi bẹ̀ ọ́ wá bá ọ gbé, títí èmi yóò fi mọ ohun ti Ọlọ́run yóò ṣe fún mi.” 4Ó sì mú wọn wá síwájú ọba Moabu; wọ́n sì bá á gbé ní gbogbo ọjọ́ tí Dafidi fi wà nínú ihò náà.

5Gadi wòlíì sí wí fún Dafidi pé, “Ma ṣe gbé inú ihò náà, yẹra, kí o sí lọ sí ilẹ̀ Juda.” Nígbà náà ni Dafidi sì yẹra, ó sì lọ sínú igbó Hereti.

Saulu pa àwọn àlùfáà Nobu

6Saulu si gbọ́ pé a rí Dafidi àti àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀; Saulu sì ń bẹ ní Gibeah lábẹ́ igi tamariski ní Rama; ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró tì í. 7Nígbà náà ni Saulu wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó dúró tì í, pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará Benjamini, ọmọ Jese yóò ha fún olúkúlùkù yín ni oko ọgbà àjàrà bí? Kí ó sì sọ gbogbo yin dì olórí ẹgbẹgbẹ̀rún àti olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún bí? 8Tí gbogbo yín di ìmọ̀lù sí mi, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó sọ létí mi pé, ọmọ mi ti bá ọmọ Jese mulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kó sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó ṣàánú mi, tí ó sì sọ ọ́ létí mi pé, ọmọ mi mú kí ìránṣẹ́ mi dìde sí mi láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.”

9Doegi ará Edomu tí a fi jẹ olórí àwọn ìránṣẹ́ Saulu, sì dáhùn wí pé, “Èmi rí ọmọ Jese, ó wá sí Nobu, sọ́dọ̀ Ahimeleki ọmọ Ahitubu. 10Òun sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa fún un, ó sì fún un ní oúnjẹ, ó sí fún un ni idà Goliati ará Filistini.”

11Ọba sì ránṣẹ́ pe Ahimeleki àlùfáà, ọmọ Ahitubu àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀, àwọn àlùfáà tí ó wà ni Nobu: gbogbo wọn ni ó sì wá sọ́dọ̀ ọba. 12Saulu sì wí pé, “Ǹjẹ́ gbọ́, ìwọ ọmọ Ahitubu.”

Òun sì wí pé, “Èmi nìyìí olúwa mi.”

13Saulu sì wí fún un pé, “Kí ni ó dé tí ẹ̀yin fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi, ìwọ àti ọmọ Jese, tí ìwọ fi fún un ní àkàrà, àti idà, àti ti ìwọ fi béèrè fún un lọ́dọ̀ Ọlọ́run kí òun lè dìde sí mi, láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.”

14Ahimeleki sì dá ọba lóhùn, ó sì wí pé, “Ta ni ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ bí Dafidi, ẹni tí ó jẹ́ àna ọba, ẹni tí ó ń gbọ́ tìrẹ, tí ó sì ni ọlá ní ilé rẹ. 15Òní lèmi ó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un bí? Kí èyí jìnnà sí mi: kí ọba má ṣe ka nǹkan kan sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́rùn, tàbí sí gbogbo ìdílé baba mi: nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ̀ kò mọ̀kan nínú gbogbo nǹkan yìí, díẹ̀ tàbí púpọ̀.”

16Ọba sì wí pé, “Ahimeleki, kíkú ni ìwọ yóò kú, ìwọ àti gbogbo ìdílé baba rẹ̀.”

17Ọba sì wí fún àwọn aṣáájú ti máa ń sáré níwájú ọba, tí ó dúró tì í pé, “Yípadà kí ẹ sì pa àwọn àlùfáà Olúwa; nítorí pé ọwọ́ wọn wà pẹ̀lú Dafidi, àti nítorí pé wọ́n mọ ìgbà tí òun sá, wọn kò sì sọ ọ́ létí mi.”

Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ ọba kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn lé àwọn àlùfáà Olúwa láti pa wọ́n.

18Ọba sì wí fún Doegi pé, “Ìwọ yípadà, kí o sì pa àwọn àlùfáà!” Doegi ará Edomu sì yípadà, ó sì kọlu àwọn àlùfáà, ó sì pa wọ́n ní ọjọ́ náà, àrùnlélọ́gọ́rin (85) ènìyàn ti ń wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ efodu. 19Ó sì fi ojú idà pa ara Nobu, ìlú àwọn àlùfáà náà àti ọkùnrin àti obìnrin, ọmọ wẹ́wẹ́, àti àwọn tí ó wà lẹ́nu ọmú, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti àgùntàn.

20Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ahimeleki ọmọ Ahitubu tí a ń pè ní Abiatari sì bọ́; ó sì sá àsálà tọ Dafidi lọ. 21Abiatari sì fihan Dafidi pé Saulu pa àwọn àlùfáà Olúwa tán. 22Dafidi sì wí fún Abiatari pé, “Èmi ti mọ̀ ní ọjọ́ náà, nígbà tí Doegi ará Edomu ti wà níbẹ̀ pé, nítòótọ́ yóò sọ fún Saulu: nítorí mi ni a ṣe pa gbogbo ìdílé baba rẹ. 23Ìwọ jókòó níhìn-ín lọ́dọ̀ mi, má ṣe bẹ̀rù, nítorí pé ẹni ti ń wá ẹ̀mí mi, ó ń wá ẹ̀mí rẹ: Ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ mi ni ìwọ ó wà ní àìléwu.”