1 Samuel 13 – NIRV & YCB

New International Reader’s Version

1 Samuel 13:1-23

Samuel Judges Saul’s Sin

1Saul was 30 years old when he became king. He ruled over Israel for 42 years.

2Saul chose 3,000 of Israel’s men. Two thousand of them were with him at Mikmash and in the hill country of Bethel. One thousand were with Jonathan at Gibeah in the land of Benjamin. Saul sent the rest back to their homes.

3Some Philistine soldiers were stationed at Geba. Jonathan attacked them. The other Philistines heard about it. Saul announced, “Let the Hebrew people hear about what has happened!” He had trumpets blown all through the land. 4So all the Israelites heard the news. They were told, “Saul has attacked the Philistine army camp at Geba. Now the Philistines can’t stand the Israelites.” The Israelites were called out to join Saul at Gilgal.

5The Philistines gathered together to fight against Israel. They had 3,000 chariots and 6,000 chariot drivers. Their soldiers were as many as the grains of sand on the seashore. They went up and camped at Mikmash. It was east of Beth Aven. 6The Israelites saw that their army was in deep trouble. So they hid in caves. They hid among bushes and rocks. They also hid in pits and empty wells. 7Some of them even went across the Jordan River. They went to the lands of Gad and Gilead.

Saul remained at Gilgal. All the troops with him were shaking with fear. 8He waited seven days, just as Samuel had told him to. But Samuel didn’t come to Gilgal. And Saul’s men began to scatter. 9So he said, “Bring me the burnt offering and the friendship offerings.” Then he offered up the burnt offering. 10Just as Saul finished offering the sacrifice, Samuel arrived. Saul went out to greet him.

11“What have you done?” asked Samuel.

Saul replied, “I saw that the men were scattering. I saw that the Philistines were gathering together at Mikmash. You didn’t come when you said you would. 12So I thought, ‘Now the Philistines will come down to attack me at Gilgal. And I haven’t asked the Lord for his blessing.’ So I felt I had to sacrifice the burnt offering.”

13“You have done a foolish thing,” Samuel said. “You haven’t obeyed the command the Lord your God gave you. If you had, he would have made your kingdom secure over Israel for all time to come. 14But now your kingdom won’t last. The Lord has already looked for a man who is dear to his heart. He has appointed him king of his people. That’s because you haven’t obeyed the Lord’s command.”

15Then Samuel left Gilgal and went up to Gibeah in the land of Benjamin. Saul counted the men who were with him. The total number was about 600.

Israel Doesn’t Have Weapons

16Saul and his son Jonathan were staying in Gibeah in the land of Benjamin. The men who remained in the army were there with them. At the same time, the Philistines camped at Mikmash. 17Three groups of soldiers went out from the Philistine camp to attack Israel. One group turned and went toward Ophrah in the area of Shual. 18Another went toward Beth Horon. The third went toward the border that looked out over the Valley of Zeboim. That valley faces the desert.

19There weren’t any blacksmiths in the whole land of Israel. That’s because the Philistines had said, “The Hebrews might hire them to make swords or spears!” 20So all the Israelites had to go down to the Philistines. They had to go to them to get their plows, hoes, axes and sickles sharpened. 21It cost a fourth of an ounce of silver to sharpen a plow or a hoe. It cost an eighth of an ounce to sharpen a pitchfork or an axe. That’s also what it cost to put new tips on the large sticks used to drive oxen.

22So the Israelite soldiers went out to battle without swords or spears in their hands. That was true for all of Saul’s and Jonathan’s soldiers. Only Saul and his son Jonathan had those weapons.

Jonathan Attacks the Philistines

23A group of Philistine soldiers had gone out to the pass at Mikmash.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Samuẹli 13:1-23

Samuẹli fi Saulu bú

1Saulu sì jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba lórí Israẹli ní ọdún méjìlélógójì.

2Saulu yan ẹgbẹ̀ẹ́dógún (3,000) ọkùnrin ní Israẹli, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ní Mikmasi àti ní ìlú òkè Beteli ẹgbẹ̀rún kan (1,000) sì wà lọ́dọ̀ Jonatani ní Gibeah ti Benjamini. Àwọn ọkùnrin tókù ni ó rán padà sí ilé e wọn.

3Jonatani sì kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini ní Gibeah, Filistini sì gbọ́ èyí. Nígbà náà ni Saulu fọn ìpè yí gbogbo ilẹ̀ náà ká, ó sì wí pé, “Jẹ́ kí àwọn Heberu gbọ́!” 4Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli sì gbọ́ ìròyìn pé, “Saulu ti kọlu ẹgbẹ́ ogun àwọn Filistini, Israẹli sì di òórùn búburú fún àwọn Filistini.” Àwọn ènìyàn náà sì péjọ láti darapọ̀ mọ́ Saulu ní Gilgali.

5Àwọn Filistini kó ara wọn jọ pọ̀ láti bá Israẹli jà, pẹ̀lú ẹgbàá-mẹ́dógún kẹ̀kẹ́, (3,000) ẹgbẹ̀ta (6,000) ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, àwọn ológun sì pọ̀ bí yanrìn etí Òkun. Wọ́n sì gòkè lọ, wọ́n dó ní Mikmasi ní ìhà ilẹ̀ oòrùn Beti-Afeni. 6Nígbà tí àwọn ọkùnrin Israẹli sì rí i pé àwọn wà nínú ìpọ́njú àti pé àwọn ológun wọn wà nínú ìhámọ́, wọ́n fi ara pamọ́ nínú ihò àti nínú igbó láàrín àpáta, nínú ọ̀fìn, àti nínú kànga gbígbẹ. 7Àwọn Heberu mìíràn tilẹ̀ kọjá a Jordani sí ilẹ̀ Gadi àti Gileadi.

Saulu wà ní Gilgali síbẹ̀, gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì ń wárìrì fún ìbẹ̀rù. 8Ó sì dúró di ọjọ́ méje, àkókò tí Samuẹli dá; ṣùgbọ́n Samuẹli kò wá sí Gilgali, àwọn ènìyàn Saulu sì bẹ̀rẹ̀ sí ní túká. 9Saulu sì wí pé, “Ẹ mú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ wá fún mi.” Saulu sì rú ẹbọ sísun náà. 10Bí ó sì ti ń parí rírú ẹbọ sísun náà, Samuẹli sì dé, Saulu sì jáde láti lọ kí i.

11Samuẹli sì wí pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí.”

Saulu sì dáhùn pé, “Nígbà tí mo rí pé àwọn ènìyàn náà ń túká, àti tí ìwọ kò sì wá ní àkókò ọjọ́ tí ìwọ dá, tí àwọn Filistini sì kó ara wọ́n jọ ní Mikmasi, 12mo rò pé, ‘Àwọn Filistini yóò sọ̀kalẹ̀ tọ̀ mí wá ní Gilgali nísinsin yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ì tí ì wá ojúrere Olúwa.’ Báyìí ni mo mú ara mi ní ipá láti rú ẹbọ sísun náà.”

13Samuẹli sì wí fún un pé, “Ìwọ hu ìwà aṣiwèrè, ìwọ kò sì pa òfin tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ mọ́; bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, òun ìbá fi ìdí ìjọba rẹ kalẹ̀ lórí Israẹli láéláé. 14Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìjọba rẹ kì yóò dúró pẹ́, Olúwa ti wá ọkùnrin tí ó wù ú ní ọkàn rẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì ti yàn án láti ṣe olórí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ìwọ kò pa òfin Olúwa mọ́.”

15Nígbà náà ni Samuẹli kúrò ní Gilgali, ó sì gòkè lọ sí Gibeah ti Benjamini, Saulu sì ka àwọn ènìyàn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta.

Israẹli láìní ohun ìjà

16Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani àti àwọn ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú wọn dúró ní Gibeah ti Benjamini, nígbà tí àwọn Filistini dó ní Mikmasi. 17Ẹgbẹ́ àwọn onísùmọ̀mí mẹ́ta jáde lọ ní àgọ́ àwọn Filistini ní ọnà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ẹgbẹ́ kan gba ọ̀nà ti Ofira ní agbègbè ìlú Ṣuali, 18òmíràn gba ọ̀nà Beti-Horoni, ẹ̀kẹta sí ìhà ibodè tí ó kọjú sí Àfonífojì Ṣeboimu tí ó kọjú sí ijù.

19A kò sì rí alágbẹ̀dẹ kan ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli, nítorí tí àwọn Filistini wí pé, “Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ àwọn Heberu yóò rọ idà tàbí ọ̀kọ̀!” 20Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo Israẹli tọ àwọn Filistini lọ láti pọ́n dòjé wọn, ọ̀kọ̀, àáké àti ọ̀ṣọ́ wọn. 21Iye tí wọ́n fi pọ́n dòjé àti ọ̀kọ̀ jẹ́ ọwọ́ méjì nínú ìdámẹ́ta ṣékélì, àti ìdámẹ́ta ṣékélì fún pípọ́n òòyà-irin tí ilẹ̀, àáké àti irin ọ̀pá olùṣọ́ màlúù.

Jonatani kọlu àwọn ará Filistini

22Bẹ́ẹ̀ ni ọjọ́ ìjà ẹnìkankan nínú àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú Saulu àti Jonatani kò sì ní idà, tàbí ọ̀kọ̀ ní ọwọ́; àfi Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani ni wọ́n ni wọ́n.

23Àwọn ẹgbẹ́ ogun Filistini sì ti jáde lọ sí ìkọjá Mikmasi.