Hesabu 12 – NEN & YCB

Kiswahili Contemporary Version (Neno: Bibilia Takatifu)

Hesabu 12:1-16

Miriamu Na Aroni Wampinga Mose

112:1 Kut 15:20; 2:21Miriamu na Aroni walianza kuzungumza dhidi ya Mose kwa sababu ya mke wake Mkushi, kwa kuwa alikuwa ameoa Mkushi. 212:2 Hes 16:3; 11:1; Mwa 29:33; Mik 6:4; 2Fal 19:4; Za 94:9; Eze 35:12Waliuliza, “Je, Bwana amesema kupitia Mose peke yake? Je, hajasema kutupitia sisi pia?” Naye Bwana akasikia hili.

312:3 Mt 11:29; 1Tim 6:11; 2Tim 2:25; Za 149:4; 1Pet 3:4(Basi Mose alikuwa mtu mnyenyekevu sana, mnyenyekevu kuliko mtu mwingine yeyote katika uso wa dunia.)

4Ghafula Bwana akawaambia Mose, Aroni na Miriamu, “Njooni katika Hema la Kukutania, ninyi nyote watatu.” Kwa hiyo wote watatu wakaenda. 512:5 Kut 13:21; Hes 11:25; Kut 34:5Kisha Bwana akashuka katika nguzo ya wingu, akasimama kwenye ingilio la Hema, akawaita Aroni na Miriamu. Wakati wote wawili waliposogea mbele, 612:6 1Sam 3:7, 21; Mwa 15:1; 20:3; 46:2; Mt 27:19; Ebr 1:1; 1Fal 3:5; Mwa 46:2; Ay 33:15; Lk 1:11; 1:22; Mt 1:20Bwana akasema, “Sikilizeni maneno yangu:

“Akiwapo nabii wa Bwana miongoni mwenu,

nitajifunua kwake kwa maono,

nitanena naye katika ndoto.

712:7 Kum 34:5; Yos 1:1-2; Za 105:26; Ebr 3:2, 5Lakini sivyo kwa mtumishi wangu Mose;

yeye ni mwaminifu katika nyumba yangu yote.

812:8 Amu 14:12; 1Fal 10:1; Za 17:15; 49:4; 140:13; Mit 1:6; Dan 5:12; Kut 20:4; 24:2; Ay 19:26; Isa 6:1Kwake nitanena naye uso kwa uso,

waziwazi wala si kwa mafumbo;

yeye ataona umbo la Bwana.

Kwa nini basi ninyi hamkuogopa

kuzungumza kinyume cha mtumishi wangu Mose?”

912:9 Kut 4:14; Mwa 17:22Hasira ya Bwana ikawaka dhidi yao, akawaacha.

1012:10 Kut 4:6; 40:2; Kum 24:9; Law 13:11; 2Fal 5:1, 27; 2Nya 16:12; 21:12Wakati hilo wingu liliinuka kutoka juu ya Hema, Miriamu akawa tayari ana ukoma, mweupe kama theluji. Aroni akamgeukia, akaona ana ukoma. 1112:11 2Sam 19:19; 24:10Kisha Aroni akamwambia Mose, “Tafadhali, bwana wangu, usituhesabie dhambi hii ambayo tumeifanya kwa upumbavu. 1212:12 Za 88:4; Efe 2:1-5; Kol 2:13; 1Tim 5:6Usimwache awe kama mtoto mchanga aliyezaliwa akiwa mfu, ambaye nusu ya mwili wake imeharibika hapo atokapo katika tumbo la mama yake.”

1312:13 Kut 15:26; Za 6:2; 147:3; Isa 1:6; 30:26; 53:5; Yer 17:14; Hos 6:1Hivyo Mose akamlilia Bwana akisema, “Ee Mungu, nakuomba umponye!”

1412:14 Kum 25:9; Ay 17:6; 30:9-10; Isa 50:6; Law 13:46; Hes 5:2-3; Ebr 12:9; 2Nya 26:20, 21Bwana akamjibu Mose, “Je, kama baba yake angemtemea usoni, asingeona aibu kwa siku saba? Mfungie nje ya kambi kwa siku saba; baada ya hapo anaweza kurudishwa kambini.” 1512:15 Law 14:8; 13; Kum 24:9Kwa hiyo Miriamu akafungiwa nje ya kambi kwa siku saba, nao watu hawakuendelea na safari mpaka aliporudishwa kambini.

1612:16 Hes 10:12; 11:35; 15:32; Mwa 21:21Baada ya hayo, watu waliondoka Haserothi, wakapiga kambi katika Jangwa la Parani.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 12:1-16

Miriamu Àti Aaroni tako Mose

1Miriamu àti Aaroni sọ̀rọ̀-òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ obìnrin ará Etiopia. 2Wọ́n sì wí pé, “Nípa Mose nìkan ni Olúwa ti sọ̀rọ̀ bí, kò ha ti ipa wa sọ̀rọ̀ bí?” Olúwa sì gbọ́ èyí.

3(Mose sì jẹ́ ọlọ́kàn tútù ju gbogbo ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé lọ).

4Lẹ́ẹ̀kan náà ni Olúwa sọ fún Mose, Aaroni àti Miriamu pé, “Ẹ̀yin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, jáde wá sínú àgọ́ ìpàdé.” Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì jáde síta. 5Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú ọ̀wọ́n ìkùùkuu, ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó ké sí Aaroni àti Miriamu. Àwọn méjèèjì sì bọ́ síwájú, 6Ó wí pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi:

“Bí wòlíì Olúwa bá wà láàrín yín

Èmi Olúwa a máa fi ara à mi hàn án ní ojúran,

Èmi a máa bá a sọ̀rọ̀ nínú àlá.

712.7: Hb 3.2,5,6.Ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Mose ìránṣẹ́ mi:

ó jẹ́ olóòtítọ́ nínú gbogbo ilé mi.

812.8: El 33.11; De 34.10.Mo sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní ojúkojú,

ọ̀rọ̀ yékéyéké tí kì í ṣe òwe,

ó rí àwòrán Olúwa

Kí ló wá dé tí ẹ̀yin kò ṣe bẹ̀rù

láti sọ̀rọ̀-òdì sí Mose ìránṣẹ́ mi?”

9Ìbínú Olúwa sì ru sókè sí wọn Olúwa sì fi wọ́n sílẹ̀.

10Nígbà tí ìkùùkuu kúrò lórí àgọ́ lójijì ni Miriamu di adẹ́tẹ̀, ó funfun bí i yìnyín. Aaroni sì padà wo Miriamu ó sì rí i pé ó ti di adẹ́tẹ̀, 11Aaroni sì wí fún Mose pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀, èyí tí a fi ìwà òmùgọ̀ dá sí wa lọ́rùn. 12Má ṣe jẹ́ kí ó dàbí òkú ọmọ tí a bí, tí ìdajì ara rẹ̀ ti rà dànù.”

13Torí èyí Mose sì kígbe sí Olúwa, “Ọlọ́run, jọ̀wọ́, mú un láradá!”

1412.14: Nu 5.2,3.Olúwa sì dá Mose lóhùn, “Bí baba rẹ̀ bá tutọ́ sí i lójú, ojú kò wa ní í tì í fún ọjọ́ méje? Dá a dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, lẹ́yìn èyí ki a tó ó le mú wọlé.” 15Miriamu sì dúró sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ méje, àwọn ènìyàn kò sì tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn títí tí Miriamu fi wọ inú ibùdó padà.

16Lẹ́yìn èyí, àwọn ènìyàn kúrò ní Haserotu, wọ́n sì pa ibùdó sí Aginjù Parani.