كورنثوس الأولى 15 – NAV & YCB

Ketab El Hayat

كورنثوس الأولى 15:1-58

قيامة المسيح

1عَلَى أَنِّي أُذَكِّرُكُمْ، أَيُّهَا الإِخْوَةُ بِالإِنْجِيلِ الَّذِي بَشَّرْتُكُمْ بِهِ، وَقَبِلْتُمُوهُ وَمَازِلْتُمْ قَائِمِينَ فِيهِ، 2وَبِهِ أَيْضاً أَنْتُمْ مُخَلَّصُونَ، إِنْ كُنْتُمْ تَتَمَسَّكُونَ بِالْكَلِمَةِ الَّتِي بَشَّرْتُكُمْ بِها، إِلّا إِذَا كُنْتُمْ قَدْ آمَنْتُمْ عَبَثاً. 3فَالْوَاقِعُ أَنِّي سَلَّمْتُكُمْ، فِي أَوَّلِ الأَمْرِ، مَا كُنْتُ قَدْ تَسَلَّمْتُهُ، وَهُوَ أَنَّ الْمَسِيحَ مَاتَ مِنْ أَجْلِ خَطَايَانَا وَفْقاً لِمَا فِي الْكُتُبِ، 4وَأَنَّهُ دُفِنَ، وَأَنَّهُ قَامَ فِي الْيَوْمِ الثَّالِثِ وَفْقاً لِمَا فِي الْكُتُبِ، 5وَأَنَّهُ ظَهَرَ لِبُطْرُسَ، ثُمَّ لِلاثْنَيْ عَشَرَ. 6وَبَعْدَ ذلِكَ ظَهَرَ لأَكْثَرَ مِنْ خَمْسِ مِئَةِ أَخٍ مَعاً مَازَالَ مُعْظَمُهُمْ حَيًّا، فِي حِينِ رَقَدَ الآخَرُونَ. 7ثُمَّ ظَهَرَ لِيَعْقُوبَ، وَبَعْدَ ذلِكَ لِلرُّسُلِ جَمِيعاً. 8وَآخِرَ الْجَمِيعِ، ظَهَرَ لِي أَنَا أَيْضاً، وَكَأَنِّي طِفْلٌ وُلِدَ فِي غَيْرِ أَوَانِهِ! 9فَإِنِّي أَنَا أَصْغَرُ الرُّسُلِ شَأْناً، وَلَسْتُ أَهْلاً لأَنْ أُدْعَى رَسُولاً لأَنِّي اضْطَهَدْتُ كَنِيسَةَ اللهِ. 10وَلكِنْ، بِنِعْمَةِ اللهِ صِرْتُ عَلَى مَا أَنَا عَلَيْهِ الآنَ، وَنِعْمَتُهُ الْمَوْهُوبَةُ لِي لَمْ تَكُنْ عَبَثاً، إِذْ عَمِلْتُ جَاهِداً أَكْثَرَ مِنَ الرُّسُلِ الآخَرِينَ جَمِيعاً. إِلّا أَنِّي لَمْ أَكُنْ أَنَا الْعَامِلَ، بَلْ نِعْمَةُ اللهِ الَّتِي كَانَتْ مَعِي. 11وَسَوَاءٌ أَكُنْتُ أَنَا أَمْ كَانُوا هُمْ، فَهكَذَا نُبَشِّرُ، وَهكَذَا آمَنْتُمْ.

قيامة الأموات

12وَالآنَ، مَادَامَ يُبَشَّرُ بِأَنَّ الْمَسِيحَ قَامَ مِنْ بَيْنِ الأَمْوَاتِ، فَكَيْفَ يَقُولُ بَعْضُكُمْ إِنَّهُ لَا قِيَامَةَ لِلأَمْوَاتِ؟ 13فَإِنْ كَانَتْ قِيَامَةُ الأَمْوَاتِ غَيْرَ مَوْجُودَةٍ، فَمَعْنَى ذَلِكَ أَنَّ الْمَسِيحَ لَمْ يَقُمْ أَيْضاً! 14وَلَوْ لَمْ يَكُنِ الْمَسِيحُ قَدْ قَامَ، لَكَانَ تَبْشِيرُنَا عَبَثاً وَإِيمَانُكُمْ عَبَثاً، 15وَلَكَانَ تَبَيَّنَ عِنْدَئِذٍ أَنَّنَا شُهُودُ زُورٍ عَلَى اللهِ، إِذْ إِنَّنَا شَهِدْنَا عَلَى اللهِ أَنَّهُ أَقَامَ الْمَسِيحَ، وَهُوَ لَمْ يُقِمْهُ لَوْ صَحَّ أَنَّ الأَمْوَاتَ لَا يُقَامُونَ. 16إِذَنْ، لَوْ كَانَ الأَمْوَاتُ لَا يُقَامُونَ، لَكَانَ الْمَسِيحُ لَمْ يَقُمْ أَيْضاً. 17وَلَوْ لَمْ يَكُنِ الْمَسِيحُ قَدْ قَامَ، لَكَانَ إِيمَانُكُمْ عَبَثاً، وَلَكُنْتُمْ بَعْدُ فِي خَطَايَاكُمْ، 18وَلَكَانَ الَّذِينَ رَقَدُوا فِي الْمَسِيحِ قَدْ هَلَكُوا! 19وَلَوْ كَانَ رَجَاؤُنَا فِي الْمَسِيحِ يَقْتَصِرُ عَلَى هَذِهِ الْحَيَاةِ، لَكُنَّا أَشْقَى النَّاسِ جَمِيعاً! 20أَمَّا الآنَ فَالْمَسِيحُ قَدْ قَامَ مِنْ بَيْنِ الأَمْوَاتِ بِكْراً لِلرَّاقِدِينَ. 21فَبِمَا أَنَّ الْمَوْتَ كَانَ بِإِنْسَانٍ، فَإِنَّ قِيَامَةَ الأَمْوَاتِ أَيْضاً تَكُونُ بِإِنْسَانٍ. 22فَإِنَّهُ، كَمَا يَمُوتُ الْجَمِيعُ فِي آدَمَ، فَكَذَلِكَ سَيَحْيَى الْجَمِيعُ فِي الْمَسِيحِ، 23عَلَى أَنَّ لِكُلِّ وَاحِدٍ رُتْبَتَهُ: فَأَوَّلاً الْمَسِيحُ بِصِفَتِهِ الْبِكْرَ؛ وَبَعْدَهُ خَاصَّتُهُ لَدَى رُجُوعِهِ، 24وَبَعْدَ ذَلِكَ الآخِرَةُ حِينَ يُسَلِّمُ الْمَسِيحُ الْمُلْكَ لِلهِ الآبِ بَعْدَ أَنْ يَكُونَ قَدْ أَبَادَ كُلَّ رَئَاسَةٍ وَكُلَّ سُلْطَةٍ وَكُلَّ قُوَّةٍ. 25فَإِنَّهُ لابُدَّ أَنْ يَمْلِكَ «إِلَى أَنْ يَضَعَ جَمِيعَ الأَعْدَاءِ تَحْتَ قَدَمَيْهِ». 26وَآخِرُ عَدُوٍّ يُبَادُ هُوَ الْمَوْتُ، 27ذَلِكَ بِأَنَّهُ قَدْ «أَخْضَعَ كُلَّ شَيْءٍ تَحْتَ قَدَمَيْهِ». وَلَكِنْ، فِي قَوْلِهِ إِنَّ كُلَّ شَيْءٍ قَدْ أُخْضِعَ، فَمِنَ الْوَاضِحِ أَنَّهُ يَسْتَثْنِي اللهَ الَّذِي جَعَلَ كُلَّ شَيْءٍ خَاضِعاً لِلابْنِ. 28وَعِنْدَمَا يَتِمُّ إِخْضَاعُ كُلُّ شَيْءٍ لِلابْنِ، فَإِنَّ الابْنَ نَفْسَهُ سَيَخْضَعُ لِلَّذِي أَخْضَعَ لَهُ كُلَّ شَيْءٍ، لِكَيْ يَكُونَ اللهُ هُوَ كُلُّ شَيْءٍ فِي كُلِّ شَيْءٍ!

29وَالآنَ، إِنْ صَحَّ أَنَّ الأَمْوَاتَ لَا يَقُومُونَ أَبَداً، فَمَا مَعْنَى مَا يَفْعَلُهُ الَّذِينَ يَعْتَمِدُونَ بَدَلَ الَّذِينَ يَمُوتُونَ؟ لِمَاذَا إِذَنْ يَعْتَمِدُونَ بَدَلاً مِنْهُمْ؟ 30وَلِمَاذَا نُعَرِّضُ نَحْنُ أَنْفُسَنَا لِلْخَطَرِ كُلَّ سَاعَةٍ؟ 31فَبِحَسَبِ افْتِخَارِي بِكُمْ فِي الْمَسِيحِ يَسُوعَ رَبِّنَا، أَشْهَدُ أَيُّهَا الإِخْوَةُ أَنِّي أَمُوتُ كُلَّ يَوْمٍ! 32وَلَوْ كُنْتُ بِمَنْطِقِ الْبَشَرِ قَدْ تَعَرَّضْتُ لِلْمَوْتِ فِي أَفَسُسَ بَيْنَ مَخَالِبِ الْوُحُوشِ، فَأَيُّ نَفْعٍ يَعُودُ عَلَيَّ إِنْ كَانَ الَّذِينَ يَمُوتُونَ لَا يَقُومُونَ؟ وَلِمَ لَا «نَأْكُلُ وَنَشْرَبُ، لأَنَّنَا غَداً نَمُوتُ؟» 33لَا تَنْقَادُوا إِلَى الضَّلالِ: إِنَّ الْمُعَاشَرَاتِ الرَّدِيئَةَ تُفْسِدُ الأَخْلاقَ الْجَيِّدَةَ! 34عُودُوا إِلَى الصَّوَابِ كَمَا يَجِبُ وَلا تُخْطِئُوا، فَإِنَّ بَعْضاً مِنْكُمْ يَجْهَلُونَ اللهَ تَمَاماً أَقُولُ هَذَا لِكَيْ تَخْجَلُوا!

جسد القيامة

35وَلَكِنَّ أَحَداً قَدْ يَقُولُ: «كَيْفَ يُقَامُ الأَمْوَاتُ؟ وَبِأَيِّ جِسْمٍ يَعُودُونَ؟» 36يَا غَافِلُ! إِنَّ مَا تَزْرَعُهُ لَا يَحْيَا إِلّا بَعْدَ أَنْ يَمُوتَ. 37وَمَا تَزْرَعُهُ لَيْسَ هُوَ الْجِسْمَ الَّذِي سَيَطْلُعُ بَلْ مُجَرَّدُ حَبَّةٍ مِنَ الْحِنْطَةِ مَثَلاً أَوْ غَيْرِهَا مِنَ البُزُورِ. 38ثُمَّ يُعْطِيهَا اللهُ الْجِسْمَ الَّذِي يُرِيدُ، كَمَا يُعْطِي كُلَّ نَوْعٍ مِنَ الْبُزُورِ جِسْمَهُ الْخَاصَّ. 39وَلَيْسَ لِلأَجْسَادِ كُلِّهَا شَكْلٌ وَاحِدٌ بَلْ لِلنَّاسِ جَسَدٌ وَلِلْحَيَوَانَاتِ جَسَدٌ آخَرُ وَلِلسَّمَكِ آخَرُ وَلِلطَّيْرِ آخَرُ. 40ثُمَّ إِنَّ هُنَاكَ أَجْسَاماً سَمَاوِيَّةً وَأَجْسَاماً أَرْضِيَّةً. وَلَكِنَّ الأَجْسَامَ السَّمَاوِيَّةَ لَهَا بَهَاءٌ، وَالأَرْضِيَّةَ لَهَا بَهَاءٌ مُخْتَلِفٌ. 41فَالشَّمْسُ لَهَا بَهَاءٌ، وَالْقَمَرُ لَهُ بَهَاءٌ آخَرُ، وَالنُّجُومُ لَهَا بَهَاءٌ مُخْتَلِفٌ، لأَنَّ كُلَّ نَجْمٍ يَخْتَلِفُ عَنِ الآخَرِ بِبَهَائِهِ. 42وَهَكَذَا الْحَالُ فِي قِيَامَةِ الأَمْوَاتِ: يُزْرَعُ الْجَسَدُ مُنْحَلًّا، وَيُقَامُ غَيْرَ مُنْحَلٍّ، 43يُزْرَعُ مُهَاناً، وَيُقَامُ مَجِيداً، يُزْرَعُ ضَعِيفاً، وَيُقَامُ قَوِيًّا، 44يُزْرَعُ جِسْماً مَادِّيًّا، وَيُقَامُ جِسْماً رُوحِيًّا. فَبِمَا أَنَّ هُنَاكَ جِسْماً مَادِّيًّا، فَهُنَاكَ أَيْضاً جِسْمٌ رُوحِيٌّ. 45فَهكَذَا أَيْضاً قَدْ كُتِبَ: «صَارَ الإِنْسَانُ الأَوَّلُ، آدَمُ، نَفْساً حَيَّةً» وَأَمَّا آدَمُ الأَخِيرُ فَهُوَ روحٌ بَاعِثٌ لِلْحَيَاةِ. 46عَلَى أَنَّ الرُّوحِيَّ لَمْ يَكُنْ أَوَّلاً، بَلْ جَاءَ الْمَادِّيُّ أَوَّلاً ثُمَّ الرُّوحِيُّ: 47الإِنْسَانُ الأَوَّلُ مِنَ الأَرْضِ وَقَدْ صُنِعَ مِنَ التُّرَابِ؛ أَمَّا الإِنْسَانُ الثَّانِي فَهُوَ مِنَ السَّمَاءِ. 48فَعَلَى مِثَالِ الْمَصْنُوعِ مِنَ التُّرَابِ، سَيَكُونُ الْمَصْنُوعُونَ مِنَ التُّرَابِ، وَعَلَى مِثَالِ السَّمَاوِيِّ سَيَكُونُ السَّمَاوِيُّونَ. 49وَمِثْلَمَا حَمَلْنَا صُورَةَ الْمَصْنُوعِ مِنَ التُّرَابِ، سَنَحْمِلُ أَيْضاً صُورَةَ السَّمَاوِيِّ.

50ثُمَّ إِنِّي، أَيُّهَا الإِخْوَةُ، أُؤَكِّدُ لَكُمْ أَنَّ الأَجْسَامَ ذَاتَ اللَّحْمِ وَالدَّمِ لَا يُمْكِنُهَا أَنْ تَرِثَ مَلَكُوتَ اللهِ، كَمَا لَا يُمْكِنُ لِلْمُنْحَلِّ أَنْ يَرِثَ غَيْرَ الْمُنْحَلِّ.

51وَهَا أَنَا أَكْشِفُ لَكُمْ سِرّاً: إِنَّنَا لَنْ نَرْقُدَ جَمِيعاً، وَلَكِنَّنَا سَنَتَغَيَّرُ جَمِيعاً، 52فِي لَحْظَةٍ، بَلْ فِي طَرْفَةِ عَيْنٍ عِنْدَمَا يُنْفَخُ فِي الْبُوقِ الأَخِيرِ. فَإِنَّهُ سَوْفَ يُنْفَخُ فِي الْبُوقِ، فَيَقُومُ الأَمْوَاتُ بِلا انْحِلالٍ. وَأَمَّا نَحْنُ، فَسَنَتَغَيَّرُ. 53فَلابُدَّ لِهَذَا الْجِسْمِ الْقَابِلِ لِلانْحِلالِ أَنْ يَلْبَسَ عَدَمَ انْحِلالٍ، وَلِهَذَا الْفَانِي أَنْ يَلْبَسَ خُلُوداً. 54وَبَعْدَ أَنْ يَلْبَسَ هَذَا الْمُنْحَلُّ عَدَمَ انْحِلالٍ، وَهَذَا الْفَانِي خُلُوداً، تَتِمُّ الْكَلِمَةُ الَّتِي قَدْ كُتِبَتْ: «ابْتُلِعَ الْمَوْتُ فِي النَّصْرِ!» 55فَأَيْنَ، يَا مَوْتُ، شَوْكَتُكَ؟ وَأَيْنَ، يَا مَوْتُ نَصْرُكَ؟ 56وَشَوْكَةُ الْمَوْتِ إِنَّمَا هِيَ الْخَطِيئَةُ، وَقُوَّةُ الْخَطِيئَةِ إِنَّمَا هِيَ الشَّرِيعَةُ. 57وَلَكِنِ الشُّكْرُ لِلهِ الَّذِي يَمْنَحُنَا النَّصْرَ بِرَبِّنَا يَسُوعَ الْمَسِيحِ! 58إِذَنْ، يَا إِخْوَتِي الأَحِبَّاءَ، كُونُوا رَاسِخِينَ غَيْرَ مُتَزَحْزِحِينَ، كَثِيرِي الاجْتِهَادِ فِي عَمَلِ الرَّبِّ دَائِماً، عَالِمِينَ أَنَّ جَهْدَكُمْ فِي الرَّبِّ لَيْسَ عَبَثاً!

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kọrinti 15:1-58

Àjíǹde Kristi

1Ǹjẹ́ ará, èmi ń sọ ìhìnrere náà dí mí mọ̀ fún un yín, tí mo ti wàásù fún un yín, èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ti gbá, nínú èyí tí ẹ̀yin sì dúró. 2Nípasẹ̀ ìhìnrere yìí ni a fi ń gbà yín là pẹ̀lú, bí ẹ̀yin bá di ọ̀rọ̀ ti mo ti wàásù fún yín mú ṣinṣin. Bí bẹ́ẹ̀ kọ̀, ẹ̀yin kàn gbàgbọ́ lásán.

315.3: 1Kọ 11.23; 1Pt 2.24; Isa 53.5-12.Nítorí èyí tí mo rí gbà ṣáájú ohun gbogbo ní èmi pẹ̀lú ti fi lé e yín lọ́wọ́, bí Kristi ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ tí wí. 415.4: Mt 16.21; Sm 16.8-9.Àti pé a sìnkú rẹ̀, àti pé ó jíǹde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ tí wí; 515.5: Lk 24.34; Mt 28.17.Àti pé ó farahàn Peteru, lẹ́yìn èyí, àwọn méjìlá 6Lẹ́yìn èyí, ó farahàn àwọn ará tí o jú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lọ lẹ́ẹ̀kan náà; ọ̀pọ̀ nínú wọn wà títí fi di ìsinsin yìí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn. 7Lẹ́yìn èyí ni ó farahan Jakọbu; lẹ́yìn náà fún gbogbo àwọn aposteli. 815.8: 1Kọ 9.1; Ga 1.16; Ap 9.3-6.Àti níkẹyìn gbogbo wọn ó farahàn mí pẹ̀lú, bí ẹni tí a bí ṣáájú àkókò rẹ̀.

915.9: Ap 8.3.Nítorí èmi ni ẹni tí ó kéré jùlọ nínú àwọn aposteli, èmi ẹni tí kò yẹ láti pè ní aposteli, nítorí tí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run. 10Ṣùgbọ́n nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run mo rí bí mo ti rí: oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí a fi fún mi kò sì jẹ́ asán; ṣùgbọ́n mó ṣiṣẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ jú gbogbo wọn lọ: ṣùgbọ́n kì í ṣe èmi, bí kò ṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ó wà pẹ̀lú mi. 11Nítorí náà ìbá à ṣe èmí tàbí àwọn ni, èyí ní àwa wàásù, èyí ní ẹ̀yin sì gbàgbọ́.

Àjíǹde òkú

12Ǹjẹ́ bí a bá wàásù Kristi pé ó tí jíǹde kúrò nínú òkú, èéha tí ṣe tí àwọn mìíràn nínú yín fi wí pé, àjíǹde òkú kò sí. 13Ṣùgbọ́n bí àjíǹde òkú kò sí, ǹjẹ́ Kristi kò jíǹde. 1415.14: 1Tẹ 4.14.Bí Kristi kò bá sì jíǹde, ǹjẹ́ asán ni ìwàásù wà, asán sì ni ìgbàgbọ́ yín pẹ̀lú. 15Ṣùgbọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ, a mú wa ni ẹlẹ́rìí èké fún Ọlọ́run; nítorí ti àwa jẹ́rìí Ọlọ́run pé ó jí Kristi dìde kúrò nínú òkú: ẹni tí òun kò jí dìde bí ó bá ṣe pé àwọn òkú kò jíǹde? 16Nítorí pé bi á kò bá jí àwọn òkú dìde, ǹjẹ́ a kò jí Kristi dìde, 17bí a kò bá sì jí Kristi dìde, asán ní ìgbàgbọ́ yín; ẹ̀yin wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín síbẹ̀. 1815.18: 1Tẹ 4.16.Ǹjẹ́ àwọn pẹ̀lú tí ó sùn nínú Kristi ṣègbé. 19Bí ó bá ṣe pé kìkì ayé yìí nìkan ní àwa ní ìrètí nínú Kristi, àwa jásí òtòṣì jùlọ nínú gbogbo ènìyàn.

20Ǹjẹ́ nísinsin yìí Kristi tí jíǹde kúrò nínú òkú, ó sì dí àkọ́bí nínú àwọn tí ó sùn. 2115.21: Ro 5.12.Nítorí ìgbà tí ó jẹ́ pé nípa ènìyàn ní ikú ti wá, nípa ènìyàn ní àjíǹde òkú sì ti wá pẹ̀lú. 2215.22: Ro 5.14-18.Nítorí bí gbogbo ènìyàn ti kú nínú Adamu, bẹ́ẹ̀ ní a ó sì sọ gbogbo ènìyàn dí alààyè nínú Kristi. 2315.23: 1Tẹ 2.19.Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ènìyàn ní ipá tirẹ̀: Kristi àkọ́bí; lẹ́yìn èyí àwọn tí ó jẹ́ tí Kristi ni wíwá rẹ̀. 24Nígbà náà ni òpin yóò dé, nígbà tí ó bá ti fi ìjọba fún Ọlọ́run Baba, nígbà tí ó bá pa gbogbo àṣẹ àti gbogbo ọlá àti agbára run. 2515.25: Sm 110.1.Nítorí ti òun gbọdọ̀ ti jẹ ọba kí òun to fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. 26Ikú ní ọ̀tá ìkẹyìn tí a ó parun 2715.27: Sm 8.6; Ef 1.22.“Nítorí ó ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wí pé, “Ohun gbogbo ni á fi sí abẹ́ rẹ̀,” o dájú pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ní kò sí ní abẹ́ rẹ̀, Òun ní ó fi ohun gbogbo sí abẹ́ àkóso Kristi. 2815.28: Fp 3.21.Nígbà tí a bá sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀ tán, nígbà náà ni á ó fi ọmọ tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sábẹ́ Ẹni tí ó fi ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jásí ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.

29Ní báyìí, bí kò bá sí àjíǹde, kín ní ète àwọn ènìyàn tí wọn ń tẹ bọ omi nítorí òkú? Bí àwọn òkú kò bá jíǹde rárá, nítorí kín ni a ṣe ń bamitiisi wọn nítorí wọn? 30Nítorí kín ní àwa sì ṣe ń bẹ nínú ewu ni wákàtí gbogbo? 31Mo sọ nípa ayọ̀ tí mo ní lórí yín nínú Kristi Jesu Olúwa wá pé, èmi ń kú lójoojúmọ́. 3215.32: 2Kọ 8–9; Isa 22.13.Kí a wí bí ènìyàn, bí mo bá ẹranko jà ní Efesu, àǹfààní kín ni ó jẹ́ fún mi? Bí àwọn òkú kò bá jíǹde,

“Ẹ jẹ́ kí a máa jẹ, kí á máa mú;

nítorí ní ọlá ni àwa ó kú.”

33Kí a má tàn yín jẹ́, “Ẹgbẹ́ búburú bá ìwà rere jẹ́.” 3415.34: Ro 13.11.Ẹ jí ìjí òdodo, kí ẹ má sì dẹ́ṣẹ̀; nítorí àwọn ẹlòmíràn kò ni imọ̀ Ọlọ́run, mo sọ èyí kí ojú ba à lè tiyín.

Àjíǹde ara

35Ṣùgbọ́n ẹnìkan yóò wí pé, “Báwo ni àwọn òkú yóò ṣe jíǹde? Irú ara wó ni wọn ó padà sí?” 3615.36: Jh 12.24.Ìwọ aláìmòye, ohun tí ìwọ fúnrúgbìn kì í yè bí kò ṣe pé ó ba kú: 37Àti èyí tí ìwọ fúnrúgbìn, kì í ṣe ara tí ń bọ̀ ni ìwọ fúnrúgbìn, ṣùgbọ́n èso lásán ni, ìbá à ṣe alikama, tàbí irú mìíràn. 3815.38: Gẹ 1.11.Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún ún ni ara bí o tí wù ú, àti fún olúkúlùkù irúgbìn ara tirẹ̀. 39Gbogbo ẹran-ara kì í ṣe ẹran-ara kan náà: ṣùgbọ́n ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ènìyàn, ọ̀tọ̀ ni ẹran-ara ti ẹranko, ọ̀tọ̀ ní ti ẹja, ọ̀tọ̀ sì ní tí ẹyẹ. 40Ará ti òkè ọ̀run ń bẹ, ara ti ayé pẹ̀lú sì ń bẹ: ṣùgbọ́n ògo ti òkè ọ̀run ọ̀tọ̀, àti ògo ti ayé ọ̀tọ̀. 41Ọ̀tọ̀ ni ògo ti oòrùn, ọ̀tọ̀ ni ògo ti òṣùpá, ọ̀tọ̀ sì ni ògo ti ìràwọ̀; ìràwọ̀ ṣá yàtọ̀ sí ìràwọ̀ ni ògo.

4215.42: Da 12.3.Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sí ni àjíǹde òkú. A gbìn ín ní ìdíbàjẹ́; a sí jì í dìde ni àìdíbàjẹ́: 43A gbìn ín ni àìní ọlá, a sí jí i dìde ni ògo; a gbìn ín ni àìlera, a sì jí í dìde ní agbára. 44A gbìn ín ni, ara ẹran a sì jí i dìde ni ara ti ẹ̀mí.

Bí ara ẹran bá ń bẹ, ara ẹ̀mí náà sì ń bẹ. 4515.45: Gẹ 2.7.Bẹ́ẹ̀ ní a si kọ ọ́ pé, “Adamu ọkùnrin ìṣáájú, alààyè ọkàn ni a dá a;” Adamu ìkẹyìn ẹ̀mí ìsọnidààyè. 46Ṣùgbọ́n èyí tí í ṣe tí ẹ̀mí kọ ní ó kọ́kọ́ ṣáájú, bí kò ṣe èyí tí í ṣe tí ara ọkàn, lẹ́yìn náà èyí ti í ṣe ti ẹ̀mí. 47Ọkùnrin ìṣáájú ti inú erùpẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ẹni erùpẹ̀: ọkùnrin èkejì láti ọ̀run wá ni. 48Bí ẹni erùpẹ̀ ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe erùpẹ̀: bí ẹni tí ọ̀run ti rí, irú bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn tí í ṣe tí ọ̀run. 49Bí àwa ti rú àwòrán ẹni erùpẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwa ó sì rú àwòrán ẹni ti ọ̀run.

50Ará, ǹjẹ́ èyí ní mo wí pé, ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè jogún ìjọba Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìdíbàjẹ́ kò lé jogún àìdíbàjẹ́. 51Kíyèsi í, ohun ìjìnlẹ̀ ni mo sọ fún un yín: gbogbo wá kì yóò sùn, ṣùgbọ́n gbogbo wá ní a ó paláradà, 52Lọ́gán, ni ìṣẹ́jú kan, nígbà ìpè ìkẹyìn: nítorí ìpè yóò dún, a ó sì jí àwọn òkú dìde ní àìdíbàjẹ́, a ó sì pa wá láradà. 53Nítorí pé ara ìdíbàjẹ́ yìí kò lè ṣàìgbé ìdíbàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò lè ṣàìgbé ara àìkú wọ̀. 5415.54: Isa 25.8.Ṣùgbọ́n nígbà tí ará ìdíbàjẹ́ yìí bá ti gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, ti ara kíkú yìí bá sí ti gbé àìkú wọ̀ bẹ́ẹ̀ tan, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ ti a kọ yóò ṣẹ pé, “A gbé ikú mí ní ìṣẹ́gun.”

55“Ikú, oró rẹ dà?

Ikú, ìṣẹ́gun rẹ́ dà?”

56Oró ikú ni ẹ̀ṣẹ̀; àti agbára ẹ̀ṣẹ̀ ni òfin 57Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fì ìṣẹ́gun fún wá nípa Olúwa wá Jesu Kristi!

58Nítorí náà ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ẹ máa dúró ṣinṣin, láìyẹsẹ̀, kí ẹ máa pọ̀ si í ní iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo, ní ìwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé iṣẹ́ yin kì í ṣe asán nínú Olúwa.