عزرا 7 – NAV & YCB

Ketab El Hayat

عزرا 7:1-28

عزرا يأتي إلى أورشليم

1وَبَعْدَ هَذِهِ الأُمُورِ فِي أَثْنَاءِ حُكْمِ أَرْتَحْشَشْتَا مَلِكِ فَارِسَ، رَجَعَ مِنْ بَابِلَ رَجُلٌ اسْمُهُ عِزْرَا بْنُ سَرَايَا بْنِ عَزَرْيَا بْنِ حِلْقِيَّا 2بْنِ شَلُّومَ بْنِ صَادُوقَ بْنِ أَخِيطُوبَ، 3بْنِ أَمَرْيَا بْنِ عَزَرْيَا بْنِ مَرَايُوثَ، 4بْنِ زَرَحْيَا بْنِ عُزِّي بْنِ بُقِّي، 5بْنِ أَبِيشُوعَ بْنِ فِينْحَاسَ بْنِ أَلْعَازَارَ بْنِ هرُونَ رَئِيسِ الْكَهَنَةِ، 6وَكَانَ عِزْرَا كَاتِباً مَاهِراً فِي شَرِيعَةِ مُوسَى الَّتِي أَعْلَنَهَا الرَّبُّ إِلَهُ إِسْرَائِيلَ؛ وَقَدْ مَنَحَهُ الْمَلِكُ كُلَّ سُؤْلِهِ بِفَضْلِ الرَّبِّ إِلَهِهِ. 7وَرَجَعَ مَعَهُ بَعْضُ بَنِي إِسْرَائِيلَ، وَبَعْضُ الْكَهَنَةِ وَاللّاوِيِّينَ وَالْمُغَنِّينَ وَحُرَّاسِ الْهَيْكَلِ وَخُدَّامِهِ إِلَى أُورُشَلِيمَ، فِي السَّنَةِ السَّابِعَةِ مِنْ وِلايَةِ الْمَلِكِ أَرْتَحْشَشْتَا، 8فَوَصَلَ إِلَى أُورُشَلِيمَ فِي الشَّهْرِ الْخَامِسِ (آب – أُغُسْطُسَ) مِنَ السَّنَةِ السَّابِعَةِ لِحُكْمِ الْمَلِكِ. 9إِذْ بَدَأَ رِحْلَتَهُ مِنْ بَابِلَ فِي الشَّهْرِ الأَوَّلِ (آذَارَ – مَارِسَ)، وَوَصَلَ إِلَى أُورُشَلِيمَ فِي الشَّهْرِ الْخَامِسِ، بِفَضْلِ يَدِ اللهِ الصَّالِحَةِ الَّتِي رَعَتْهُ، 10لأَنَّ عِزْرَا أَخْلَصَ نِيَّتَهُ لِطَلَبِ شَرِيعَةِ الرَّبِّ وَمُمَارَسَتِهَا، وَتَعْلِيمِ الشَّعْبِ فَرَائِضَهَا وَأَحْكَامَهَا.

رسالة أرتحششتا لعزرا

11وَهَذَا نَصُّ الرِّسَالَةِ الَّتِي سَلَّمَهَا الْمَلِكُ أَرْتَحْشَشْتَا لِعِزْرَا الْكَاهِنِ الْكَاتِبِ، الْعَالِمِ بِكَلامِ وَصَايَا الرَّبِّ وَفَرَائِضِهِ الَّتِي أَبْلَغَهَا لإِسْرَائِيلَ:

12«مِنْ أَرْتَحْشَشْتَا مَلِكِ الْمُلُوكِ إِلَى عِزْرَا الْكَاهِنِ كَاتِبِ شَرِيعَةِ إِلَهِ السَّمَاءِ، سَلامٌ، وَبَعْدُ.

13لَقَدْ صَدَرَ مِنِّي أَمْرٌ بِالسَّمَاحِ لِكُلِّ مَنْ أَرَادَ فِي مَمْلَكَتِي مِنْ شَعْبِ إِسْرَائِيلَ وَكَهَنَتِهِ وَاللّاوِيِّينَ أَنْ يَرْجِعَ مَعَكَ إِلَى أُورُشَلِيمَ، 14فَأَنْتَ مُرْسَلٌ مِنْ قِبَلِ الْمَلِكِ وَمُسْتَشَارِيهِ السَّبْعَةِ لِلاطِّلاعِ عَلَى مَدَى تَطْبِيقِ أَبْنَاءِ يَهُوذَا وَأُورُشَلِيمَ لِشَرِيعَةِ إِلَهِكَ الَّتِي بَيْنَ يَدَيْكَ، 15وَلِحَمْلِ مَا يَتَبَرَّعُ بِهِ الْمَلِكُ وَمُسْتَشَارُوهُ مِنْ فِضَّةٍ وَذَهَبٍ لإِلَهِ إِسْرَائِيلَ الَّذِي مَسْكَنُهُ فِي أُورُشَلِيمَ. 16فَضْلاً عَمَّا تَحْصُلُ عَلَيْهِ مِنْ فِضَّةٍ وَذَهَبٍ مِنْ إِقْلِيمِ بَابِلَ، وَمَا تَجْمَعُهُ مِنْ تَبَرُّعَاتِ الشَّعْبِ وَالْكَهَنَةِ لِهَيْكَلِ إِلَهِهِمْ فِي أُورُشَلِيمَ، 17لِتَجِدَّ فِي شِرَاءِ ثِيرَانٍ وَكِبَاشٍ وَخِرَافٍ مَعَ تَقْدِمَاتِهَا وَسَكَائِبِ خَمْرِهَا بِهَذِهِ الْفِضَّةِ، لِتُقَرِّبَهَا عَلَى مَذْبَحِ هَيْكَلِ إِلَهِكُمْ فِي أُورُشَلِيمَ. 18أَمَّا مَا يَتَبَقَّى مِنَ الْفِضَّةِ وَالذَّهَبِ، فَتَتَصَرَّفُ فِيهِ أَنْتَ وَسَائِرُ الْكَهَنَةِ حَسَبَ مَا تَرَاهُ بِمُقْتَضَى إِرَادَةِ إِلَهِكُمْ. 19كَذَلِكَ سَلِّمْ أَمَامَ إِلَهِ أُورُشَلِيمَ مَا أُعْطِيتَ مِنْ آنِيَةٍ لِتُسْتَخْدَمَ فِي هَيْكَلِ إِلَهِكَ، 20ثُمَّ خُذْ مِنْ بَيْتِ مَالِ الْمَلِكِ مَا تَرَى الْهَيْكَلَ فِي حَاجَةٍ إِلَيْهِ. 21وَقَدْ أَصْدَرْتُ أَمْراً، أَنَا أَرْتَحْشَشْتَا الْمَلِكُ، إِلَى جَمِيعِ أُمَنَاءِ أَمْوَالِ الْمَلِكِ فِي عَبْرِ نَهْرِ الْفُرَاتِ أَنْ يُلَبُّوا عَلَى وَجْهِ السُّرْعَةِ كُلَّ مَطَالِبِ عِزْرَا الْكَاهِنِ كَاتِبِ شَرِيعَةِ إِلَهِ السَّمَاءِ، 22إِلَى مِئَةِ وَزْنَةٍ (نَحْوَ ثَلاثَةِ آلافٍ وَسِتِّ مِئَةِ كِيلُو جِرَامٍ) مِنَ الْفِضَّةِ وَمِئَةِ كُرٍّ مِنَ الْقَمْحِ (نَحْوَ أَرْبَعَةٍ وَعِشْرِينَ أَلْفَ لِتْرٍ) وَمِئَةِ بَثٍّ مِنَ النَّبِيذِ (نَحْوَ أَلْفَيْنِ وَأَرْبَعِ مِئَةِ لِتْرٍ) وَمِئَةِ بَثٍّ مِنَ الزَّيْتِ، وَمِنَ الْمِلْحِ مَا يَحْتَاجُ إِلَيْهِ مِنْ غَيْرِ حَدٍّ. 23وَلْيُنَفَّذْ بِأَسْرَعِ وَقْتٍ كُلُّ مَا يَأْمُرُ بِهِ إِلَهُ السَّمَاءِ بِشَأْنِ هَيْكَلِهِ، لأَنَّهُ لِمَاذَا يَحُلُّ غَضَبُهُ عَلَى دِيَارِ الْمَلِكِ وَأَبْنَائِهِ؟ 24نُفِيدُكُمْ أَنَّ جَمِيعَ الْكَهَنَةِ وَاللّاوِيِّينَ وَالْمُغَنِّينَ وَحُرَّاسِ الْهَيْكَلِ وَخُدَّامِهِ وَالْعَامِلِينَ فِيهِ، مُعْفَوْنَ مِنْ أَيَّةِ جِزْيَةٍ أَوْ خَرَاجٍ أَو خَفَارَةٍ. 25أَمَّا أَنْتَ يَا عِزْرَا فَبِمُقْتَضَى مَا تَتَمَتَّعُ بِهِ مِنْ حِكْمَةِ إِلَهِكَ، عَيِّنْ حُكَّاماً وَقُضَاةً مِنَ الْعَارِفِينَ بِشَرَائِعِ إِلَهِكَ، يَقْضُونَ بَيْنَ الشَّعْبِ الْمُقِيمِ فِي عَبْرِ نَهْرِ الْفُرَاتِ، وَلْيُعَلِّمُوا الْجَاهِلِينَ بِها. 26وَلْيُحْكَمْ عَلَى كُلِّ مَنْ لَا يُطَبِّقُ شَرِيعَةَ إِلَهِكَ وَشَرِيعَةَ الْمَلِكِ بِالْمَوْتِ أَوِ النَّفْيِ أَوْ بِغَرَامَةٍ مَالِيَّةٍ أَوْ بَالسَّجْنِ».

27فَقَالَ عِزْرَا: «مُبَارَكٌ الرَّبُّ إِلَهُ آبَائِنَا الَّذِي وَضَعَ مِثْلَ هَذَا فِي قَلْبِ الْمَلِكِ لِتَكْرِيمِ هَيْكَلِ الرَّبِّ فِي أُورُشَلِيمَ، 28وَقَدْ ظَلَّلَنِي بِالرَّحْمَةِ أَمَامَ الْمَلِكِ وَمُسْتَشَارِيهِ، وَأَمَامَ جَمِيعِ قَادَتِهِ الْمُقْتَدِرِينَ؛ وَبِفَضْلِ يَدِ الرَّبِّ الَّتِي رَعَتْنِي تَشَدَّدْتُ وَجَمَعْتُ بَعْضَ رُؤَسَاءِ إِسْرَائِيلَ لِيَرْجِعُوا مَعِي».

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esra 7:1-28

Esra wá sí Jerusalẹmu

1Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ní àkókò ìjọba ọba Artasasta ní Persia, Esra ọmọ Seraiah, ọmọ Asariah, ọmọ Hilkiah, 2Ọmọ Ṣallumu, ọmọ Sadoku, ọmọ Ahitubu, 3ọmọ Amariah, ọmọ Asariah, ọmọ Meraioti, 4ọmọ Serahiah, ọmọ Ussi, ọmọ Bukki, 5ọmọ Abiṣua, ọmọ Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni olórí àlùfáà— 6Esra yìí sì gòkè wá láti Babeli. Olùkọ́ tí ó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa òfin Mose, èyí tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ti fi fún wọn. Ọba sì fi gbogbo ohun tí ó béèrè fún un, nítorí ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run wà lára rẹ̀. 7Ní ọdún keje ọba Artasasta díẹ̀ lára àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà àti àwọn tí ń ṣiṣẹ́ nínú tẹmpili náà gòkè wá sí Jerusalẹmu.

8Ní oṣù karùn-ún ọdún keje ọba yìí ni Esra dé sí Jerusalẹmu. 9Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ̀ láti Babeli ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, ó sì dé Jerusalẹmu ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù karùn-ún nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run rẹ̀ wà ní ara rẹ̀. 10Esra ti fi ara rẹ̀ jì fún kíkọ́ àti pípa òfin Olúwa mọ́, ó sì ń kọ́ òfin àti ìlànà Mose ní Israẹli.

Ọba Artasasta kọ lẹ́tà sí Esra

11Èyí ni ẹ̀dà lẹ́tà ti ọba Artasasta fún àlùfáà Esra olùkọ́ni, ẹni tó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú àkọsílẹ̀ òfin àti ìlànà Olúwa fún Israẹli:

12Artasasta, ọba àwọn ọba,

Sí àlùfáà Esra, olùkọ́ òfin Ọlọ́run ọ̀run:

Àlàáfíà.

13Mo pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi, ti ó wà ní abẹ́ ìṣàkóso ìjọba mi, tí ó bá fẹ́ láti bá ọ lọ sí Jerusalẹmu lè tẹ̀lé ọ lọ. 14Ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ méjèèje rán ọ lọ láti wádìí nípa òfin Ọlọ́run rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nípa Juda àti Jerusalẹmu. 15Síwájú sí i, kí ìwọ kí ó kó fàdákà àti wúrà lọ pẹ̀lú rẹ èyí tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ fi tọkàntọkàn fún Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ibùjókòó rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu, 16pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ìwọ lè rí ní agbègbè ìjọba Babeli àti àwọn ọrẹ àtinúwá àwọn ènìyàn àti ti àwọn àlùfáà fún tẹmpili Ọlọ́run wọn ní Jerusalẹmu. 17Pẹ̀lú owó yìí, rí i dájú pé ó ra àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti akọ ọ̀dọ́-àgùntàn, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, àti ọrẹ ohun mímu, kí ìwọ kí ó fi wọ́n rú ẹbọ lórí pẹpẹ tẹmpili Ọlọ́run rẹ ní Jerusalẹmu.

18Ìwọ àti àwọn Júù arákùnrin rẹ lè fi èyí tókù fàdákà àti wúrà ṣe ohunkóhun tí ó bá dára lójú yín, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run yín. 19Kó gbogbo ohun èlò tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ fún Ọlọ́run Jerusalẹmu fún ìsìn nínú tẹmpili Ọlọ́run rẹ. 20Ohunkóhun mìíràn tí o bá nílò fún tẹmpili Ọlọ́run rẹ tí ó sì ní láti pèsè, o lè mú u láti inú ìṣúra ọba.

21Èmi, ọba Artasasta, pàṣẹ fún gbogbo olùtọ́jú ilé ìṣúra agbègbè Eufurate láìrójú láti pèsè ohunkóhun tí àlùfáà Esra, olùkọ́ni ní òfin Ọlọ́run ọ̀run bá béèrè lọ́wọ́ yín 22tó ọgọ́ọ̀rún kan tálẹ́ǹtì fàdákà, ọgọ́rùn-ún kan òṣùwọ̀n àlìkámà, àti dé ọgọ́rùn-ún bati ọtí wáìnì, àti dé ọgọ́rùn-ún bati òróró olifi, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyọ̀. 23Ohunkóhun tí Ọlọ́run ọ̀run bá fẹ́, jẹ́ kí ó di ṣíṣe ní pípé fún tẹmpili Ọlọ́run ọ̀run. Èéṣe tí ìbínú yóò ṣe wá sí agbègbè ọba àti sí orí àwọn ọmọ rẹ̀? 24Ìwọ sì ní láti mọ̀ pé ìwọ kò ní àṣẹ láti sọ sísan owó orí, owó òde tàbí owó bodè di dandan fún àwọn àlùfáà, àwọn Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà, àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili tàbí àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn nínú ilé Ọlọ́run yìí.

25Ìwọ Esra, ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n Ọlọ́run rẹ̀, èyí tí ó ní, yan àwọn adájọ́ àgbà àti àwọn onídàájọ́ láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn agbègbè Eufurate, gbogbo àwọn tí ó mọ òfin Ọlọ́run rẹ. Ìwọ yóò sì kọ́ ẹnikẹ́ni tí kò mọ̀ àwọn òfin náà. 26Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe ìgbọ́ràn sí òfin Ọlọ́run rẹ àti sí òfin ọba ní ó gbọdọ̀ kú tàbí kí a lé e jáde tàbí kí a gbẹ́sẹ̀ lé ẹrù rẹ̀ tàbí kí a sọ ọ́ sínú ẹ̀wọ̀n.

27Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wa, ẹni tí ó fi sí ọkàn ọba láti mú ọlá wá sí ilé Olúwa ní Jerusalẹmu ní ọ̀nà yìí. 28Ẹni tí ó jẹ́ kí ojúrere rẹ̀ tàn kàn mí níwájú ọba àti àwọn olùbádámọ̀ràn àti ní iwájú àwọn alágbára ìjòyè ọba. Nítorí ọwọ́ Olúwa Ọlọ́run wà lára mi, mo mú ọkàn le, mo sì kó àwọn olórí jọ láàrín àwọn ènìyàn Israẹli láti gòkè lọ pẹ̀lú mi.