أيوب 18 – NAV & YCB

Ketab El Hayat

أيوب 18:1-21

بلدد

1فَقَالَ بِلْدَدُ الشُّوحِيُّ: 2«مَتَى تَكُفُّ عَنْ تَرْدِيدِ هَذِهِ الْكَلِمَاتِ؟ تَعَقَّلْ ثُمَّ نَتَكَلَّمُ. 3لِمَاذَا تَعْتَبِرُنَا كَالْبَهِيمَةِ وَحَمْقَى فِي عَيْنَيْكَ؟ 4يَا مَنْ تُمَزِّقُ نَفْسَكَ إِرْباً غَيْظاً، هَلْ تُهْجَرُ الأَرْضُ مِنْ أَجْلِكَ أَمْ تَتَزَحْزَحُ الصَّخْرَةُ مِنْ مَوْضِعِهَا؟

5أَجَلْ! إِنَّ نُورَ الأَشْرَارِ يَنْطَفِئُ وَلَهِيبَ نَارِهِمْ لَا يُضِيءُ. 6يَتَحَوَّلُ النُّورُ إِلَى ظُلْمَةٍ فِي خَيْمَتِهِ، وَيَنْطَفِئُ سِرَاجُهُ عَلَيْهِ. 7تَقْصُرُ خَطْوَاتُهُ الْقَوِيَّةُ وَتَصْرَعُهُ تَدْبِيرَاتُهُ، 8لأَنَّ قَدَمَيْهِ تُوْقِعَانِهِ فِي الشَّرَكِ وَتَطْرَحَانِهِ فِي حُفْرَةٍ، 9يَقْبِضُ الْفَخُّ عَلَى عَقِبَيْهِ وَالشَّرَكُ يَشُدُّ عَلَيْهِ، 10حِبَالَتُهُ مَطْمُورَةٌ فِي الطَّرِيقِ، وَالْمِصْيَدَةُ كَامِنَةٌ فِي سَبِيلِهِ، 11تُرْعِبُهُ أَهْوَالٌ مِنْ حَوْلِهِ وَتُزَاحِمُهُ عِنْدَ رِجْلَيْهِ، 12قُوَّتُهُ يَلْتَهِمُهَا الْجُوعُ النَّهِمُ، وَالْكَوَارِثُ مُتَأَهِّبَةٌ تَتَرَصَّدُ كَبْوَتَهُ. 13يَفْتَرِسُ الدَّاءُ جِلْدَهُ وَيَلْتَهِمُ الْمَرَضُ الأَكَّالُ أَعْضَاءَهُ. 14يُؤْخَذُ مِنْ خَيْمَتِهِ رُكْنِ اعْتِمَادِهِ، وَيُسَاقُ أَمَامَ مَلِكِ الأَهْوَالِ. 15يُقِيمُ فِي خَيْمَتِهِ غَرِيبٌ وَيُذَرُّ كِبْرِيتٌ عَلَى مَرْبِضِهِ. 16تَجِفُّ أُصُولُهُ تَحْتَهُ، وَتَتَبَعْثَرُ فُرُوعُهُ مِنْ فَوْقِهِ. 17يَبِيدُ ذِكْرُهُ مِنَ الأَرْضِ، وَلا يَبْقَى لَهُ اسْمٌ فِيهَا. 18يُطْرَدُ مِنَ النُّورِ إِلَى الظُّلْمَةِ، وَيُنْفَى مِنَ الْمَسْكُونَةِ. 19لَا يَكُونُ لَهُ نَسْلٌ، وَلا عَقِبٌ بَيْنَ شَعْبِهِ، وَلا حَيٌّ فِي أَمَاكِنِ سُكْنَاهُ. 20يَرْتَعِبُ مِنْ مَصِيرِهِ أَهْلُ الْغَرْبِ، وَيَسْتَوْلِي الْفَزَعُ عَلَى أَبْنَاءِ الشَّرْقِ. 21حَقّاً تِلْكَ هِيَ مَسَاكِنُ الأَشْرَارِ، وَهَذَا هُوَ مَقَامُ مَنْ لَا يَعْرِفُ اللهَ!»

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 18:1-21

Ìdáhùn Bilidadi

1Ìgbà náà ni Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn, ó sì wí pé:

2“Nígbà wo ni ẹ̀yin yóò tó fi ìdí ọ̀rọ̀ tì;

ẹ rò ó, nígbẹ̀yìn rẹ̀ ni àwa ó tó máa sọ.

3Nítorí kí ni a ṣe ń kà wá sí bí ẹranko,

tí a sì ń kà wá si bí ẹni ẹ̀gàn ní ojú yín?

4Ìwọ fa ara rẹ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú ìbínú rẹ̀;

kí a ha kọ ayé sílẹ̀ nítorí rẹ̀ bi?

Tàbí kí a sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀?

5“Nítòótọ́ ìmọ́lẹ̀ ènìyàn búburú ni a ó pa kúrò,

Ọ̀wọ́-iná rẹ̀ kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀.

6Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn nínú àgọ́ rẹ̀,

fìtílà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni a ó sì pa pẹ̀lú.

7Ìrìn ẹsẹ̀ agbára rẹ̀ yóò di fífọ;

ète òun tìkára rẹ̀ ni yóò bí i ṣubú.

8Nípa ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀ ó ti bọ́ sínú àwọ̀n,

ó sì rìn lórí okùn dídẹ.

9Tàkúté ni yóò mú un ní gìgísẹ̀,

àwọn àwọ̀n tí a dẹ yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀.

10A dẹkùn sílẹ̀ fún un lórí ilẹ̀,

a sì wà ọ̀fìn fún un lójú ọ̀nà.

11Ẹ̀rù ńlá yóò bà á ní ìhà gbogbo,

yóò sì lé e dé ẹsẹ̀ rẹ̀.

12Àìlera rẹ̀ yóò di púpọ̀ fún ebi,

ìparun yóò dìde dúró sí i nígbà tí ó bá ṣubú.

13Yóò jẹ ẹ̀yà ara rẹ̀;

ikú àkọ́bí ni yóò jẹ agbára rẹ̀ run.

14A ó fà á tu kúrò nínú àgọ́ tí ó gbẹ́kẹ̀lé,

a ó sì mú un tọ ọba ẹ̀rù ńlá nì lọ.

15Yóò sì máa jókòó nínú àgọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe tirẹ̀;

sulfuru ti o jóná ni a ó fún káàkiri ibùgbé rẹ̀.

16Gbòǹgbò rẹ̀ yóò gbẹ níṣàlẹ̀,

a ó sì ké ẹ̀ka rẹ̀ kúrò lókè.

17Ìrántí rẹ̀ yóò parun kúrò ni ayé,

kì yóò sí orúkọ rẹ̀ ní ìgboro ìlú.

18A ó sì lé e láti inú ìmọ́lẹ̀ sí inú òkùnkùn,

a ó sì lé e kúrò ní ayé.

19Kì yóò ní ọmọ tàbí ọmọ ọmọ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀,

Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò kù nínú agbo ilé rẹ̀.

20Ẹnu yóò ya àwọn ìran ti ìwọ̀-oòrùn sí ìgbà ọjọ́ rẹ̀,

gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù ìwárìrì ti í bá àwọn ìran ti ìlà-oòrùn.

21Nítòótọ́ irú bẹ́ẹ̀ ni ibùgbé àwọn

ènìyàn búburú Èyí sì ni ipò ẹni tí kò mọ̀ Ọlọ́run.”