أخبار الأيام الأول 8 – NAV & YCB

Ketab El Hayat

أخبار الأيام الأول 8:1-40

نسب شاول البنياميني

1وَأَنْجَبَ بَنْيَامِينُ خَمْسَةَ أَبْنَاءٍ هُمْ عَلَى التَّوَالِي: بِكْرُهُ بَالَعُ، وَأَشْبِيلُ وَأَخْرَخُ، 2وَنُوحَةُ وَرَافَا. 3وَأَبْنَاءُ بَالَعَ: أَدَّارُ وَجَيْرَا وَأَبِيهُودُ، 4وَأَبِيشُوعُ وَنُعْمَانُ وَأَخُوخُ، 5وَحَيْرَا وَشَفُوفَانُ، وَحُورَامُ. 6وَهَذِهِ هِيَ أَسْمَاءُ أَبْنَاءِ آحُودَ الَّذِينَ كَانُوا رُؤَسَاءَ عَائِلاتٍ مِنْ أَهْلِ جَبْعَ الَّذِينَ طُرِدُوا فِي مَا بَعْدُ إِلَى مَنَاحَةَ، 7وَهُمْ: نُعْمَانُ وَأَخِيَّا وَجَيْرَا الَّذِي قَادَهُمْ إِلَى مَنَاحَةَ، وَقَدْ أَنْجَبَ عُزَّا وَأَخِيحُودَ. 8وَأَنْجَبَ شَحْرَايِمُ فِي بِلادِ مُوآبَ، بَعْدَ أَنْ طَلَّقَ زَوْجَتَيْهِ حُوشِيمَ وَبَعْرَا، 9أَبْنَاءً مِنْ زَوْجَتِهِ الْجَدِيدَةِ خُودَشَ، هُمْ: يُوبَابُ وَظِبْيَا وَمَيْشَا وَمَلْكَامُ، 10وَيَعُوصُ وَشَبْيَا وَمِرْمَةُ. وَقَدْ أَصْبَحَ هَؤُلاءِ رُؤَسَاءَ بُيُوتَاتٍ. 11وَكَانَ قَدْ أَنْجَبَ مِنْ زَوْجَتِهِ حُوشِيمَ ابْنَيْنِ هُمَا: أَبِيطُوبُ وَأَلْفَعَلُ. 12أَمَّا أَبْنَاءُ أَلْفَعَلَ فَهُمْ: عَابِرُ وَمِشْعَامُ وَشَامِرُ الَّذِي بَنَى مَدِينَتَيْ أُونُوَ وَلُودَ وَضِيَاعَهُمَا، 13وَبَرِيعَةُ وَشَمَعُ وَهُمَا رَأْسَا عَائِلاتِ أَهْلِ أَيَّلُونَ، وَقَدْ قَامَا بِطَرْدِ سُكَّانِ جَتَّ مِنْهَا. 14أَمَّا أَخِيُو وَشَاشَقُ وَيَرِيمُوتُ، 15وَزَبَدْيَا وَعَدَادُ وَعَادَرُ، 16وَمِيخَائِيلُ وَيِشْفَةُ وَيُوخَا فَهُمْ أَبْنَاءُ بَرِيعَةَ. 17أَمَّا زَبَدْيَا وَمَشُلّامُ وَحَزْقِي وَحَابِرُ، 18وَيِشْمَرَايُ وَيَزَلْيَاهُ وَيُوبَابُ، فَهُمْ أَبْنَاءُ أَلْفَعَلَ. 19أَمَّا يَاقِيمُ وَزِكْرِي وَزَبْدِي، 20وَأَلِيعِينَايُ وَصِلَّتَايُ وَإِيلِيئِيلُ، 21وَعَدَايَا وَبَرَايَا وَشِمْرَةُ فَهُمْ أَبْنَاءُ شِمْعِي. 22وَأَمَّا يِشْفَانُ وَعَابِرُ وَإِيلِيئِيلُ، 23وَعَبْدُونُ وَزِكْرِي وَحَانَانُ، 24وَحَنَنْيَا وَعِيلامُ وَعَنَثُوثِيَا، 25وَيَفَدْيَا وَفَنُوئِيلُ فَهُمْ أَبْنَاءُ شَاشَقَ. 26أَمَّا شِمْشَرَايُ وَشَحَرْيَا وَعَثَلْيَا، 27وَيَعْرَشْيَا وَإِيلِيَّا وَزِكْرِي فَهُمْ أَبْنَاءُ يَرُوحَامَ. 28هَؤُلاءِ هُمْ رُؤَسَاءُ آبَاءِ بُيُوتَاتِهِمْ حَسَبَ سِجِلّاتِ مَوَالِيدِهِمْ، مِمَّنِ اسْتَوْطَنُوا فِي أُورُشَلِيمَ. 29وَأَسَّسَ يَعُوئِيلُ مَدِينَةَ جِبْعُونَ وَأَقَامَ فِيهَا. وَأَنْجَبَتْ لَهُ زَوْجَتُهُ مَعْكَةُ 30عَبْدُونَ الابْنَ الْبِكْرَ، ثُمَّ صُوراً وَقَيْساً وَبَعَلَ وَنَادَابَ، 31وَجَدُورَ وَأَخِيُو وَزَاكِرَ. 32وَمِقْلُوثَ الَّذِي أَنْجَبَ شَمَاةَ. وَهُمْ أَيْضاً أَقَامُوا فِي أُورُشَلِيمَ إِلَى جُوَارِ بَقِيَّةِ أَقَارِبِهِمْ.

33وَأَنْجَبَ نِيرُ قَيْساً، وَقَيْسٌ وَلَدَ شَاوُلَ الَّذِي أَنْجَبَ يَهُونَاثَانَ وَمَلْكِيشُوعَ وَأَبِينَادَابَ وَإِشْبَعَلَ. 34وَأَنْجَبَ يَهُونَاثَانُ مَرِيبْبَعَلَ، وَمَرِيبْبَعَلُ مِيخَا. 35أَمَّا أَبْنَاءُ مِيخَا فَهُمْ: فِيثُونُ وَمَالِكُ وَتَارِيعُ وآحَازُ. 36وَأَنْجَبَ آحَازُ يَهُوعَدَّةَ، وَيَهُوعَدَّةُ عَلْمَثَ وَعَزْمُوتَ وَزِمْرِي، وَزِمْرِي مُوصَا. 37وَمُوصَا وَلَدَ بِنْعَةَ، وَبِنْعَةُ رَافَةَ، وَرَافَةُ أَلِعَاسَةَ، وَأَلِعَاسَةُ آصِيلَ. 38وَكَانَ لِآصِيلَ سِتَّةُ أَبْنَاءٍ هُمْ: عَزْرِيقَامُ وَبُكْرُو وَإِسْمعِيلُ وَشَعَرْيَا وَعُوبَدْيَا وَحَانَانُ. وَجَمِيعُ هَؤُلاءِ هُمْ أَبْنَاءُ آصِيلَ. 39أَمَّا أَخُوهُ عَاشِقُ فَقَدْ أَنْجَبَ بِكْرَهُ أُولامَ ثُمَّ يَعُوشَ، فَأَلِيفَلَطَ. 40وَكَانَ أَبْنَاءُ أُولامَ مُحَارِبِينَ أَشِدَّاءَ بَارِعِينَ فِي الرِّمَايَةِ، أَكْثَرُوا مِنْ إِنْجَابِ الْبَنِينَ وَالأَحْفَادِ حَتَّى بَلَغَ عَدَدُهُمْ مِئَةً وَخَمْسِينَ. وَجَمِيعُ هَؤُلاءِ مِنْ سِبْطِ بِنْيَامِينَ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kronika 8:1-40

Ìtàn Ìdílé láti Ọ̀dọ̀ Baba Ńlá ti Saulu ará Benjamini

1Benjamini jẹ́ baba:

Bela àkọ́bí rẹ̀,

Aṣbeli ọmọkùnrin ni ẹ̀ẹ̀kejì, Ahara ẹ̀ẹ̀kẹ́ta,

2Noha ẹ̀ẹ̀kẹrin àti Rafa ẹ̀ẹ̀karùnún.

3Àwọn ọmọ Bela jẹ́:

Adari, Gera, Abihudi, 4Abiṣua, Naamani, Ahoa, 5Gera, Ṣefufani àti Huramu.

6Wọ̀nyí ni àwọn ìran ọmọ Ehudu, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé tí ó ń gbé ní Geba tí a sì lé kúrò lọ sí Manahati:

7Naamani Ahijah àti Gera, tí ó lé wọn kúrò ní ìlú, àti tí ó sì jẹ́ baba Ussa àti Ahihudu.

8A bí àwọn ọmọkùnrin fún Ṣaharaimu ní Moabu lẹ́yìn tí ó ti kọ àwọn ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, Huṣimu àti Baara. 9Nípasẹ̀ ìyàwó rẹ̀ Hodeṣi ó ní Jobabu Ṣibia, Meṣa, Malkamu, 10Jeusi, Sakia àti Mirma. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, olórí àwọn ìdílé. 11Nípasẹ̀ Huṣimu ó ní Abitubu àti Elipali.

12Àwọn ọmọ Elipali:

Eberi, Miṣamu, Ṣemedu (ẹni tí ó kọ́ Ono àti Lodi pẹ̀lú àwọn ìletò àyíká rẹ̀.) 13Pẹ̀lú Beriah àti Ṣema, tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé ti àwọn tí ó ń gbé ní Aijaloni àti àwọn tí ó lé àwọn olùgbé Gati kúrò.

14Ahio, Ṣasaki, Jeremoti, 15Sebadiah, Aradi, Ederi 16Mikaeli, Iṣifa àti Joha jẹ́ àwọn ọmọ Beriah.

17Sebadiah, Meṣullamu, Hiski, Heberi 18Iṣimerai, Isiliahi àti Jobabu jẹ́ àwọn ọmọ Elipali.

19Jakimu, Sikri, Sabdi, 20Elienai, Siletai, Elieli, 21Adaiah, Beraiah àti Ṣimrati jẹ́ àwọn ọmọ, Ṣimei.

22Iṣipani Eberi, Elieli, 23Abdoni, Sikri, Hanani, 24Hananiah, Elamu, Anitotijah, 25Ifediah àti Penueli jẹ́ àwọn ọmọ Ṣasaki.

26Ṣamṣerai, Ṣeharaiah, Ataliah 27Jareṣiah, Elijah àti Sikri jẹ́ àwọn ọmọ Jerohamu.

28Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ olórí àwọn ìdílé, olóyè gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìran wọn, wọ́n sì ń gbé ní Jerusalẹmu.

29Jeieli, baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni.

Ìyàwó o rẹ̀ a má jẹ́ Maaka, 30Àkọ́bí rẹ̀ a sì máa jẹ́ Abdoni wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu, 31Gedori Ahio, Sekeri 32Pẹ̀lú Mikiloti, tí ó jẹ́ baba Ṣimea. Wọ́n ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu.

33Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba Saulu àti Saulu baba Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali.

34Ọmọ Jonatani:

Meribu-Baali tí ó jẹ́ baba Mika.

35Àwọn ọmọ Mika:

Pitoni, Meleki, Tarea, àti Ahasi.

36Ahasi jẹ́ baba a Jeheada, Jeheada jẹ́ baba a Alemeti, Asmafeti àti Simri, Simri sì jẹ́ baba Mosa. 37Mosa jẹ́ baba Binea; Rafa sì jẹ́ ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀ àti Aseli ọmọ rẹ̀.

38Aseli ní ọmọ mẹ́fà pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn:

Asrikamu, Bokeru, Iṣmaeli, Ṣeariah, Ọbadiah àti Hanani. Gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Aseli.

39Àwọn ọmọ arákùnrin rẹ̀ Eseki:

Ulamu àkọ́bí rẹ̀, Jeuṣi ọmọkùnrin ẹ̀ẹ̀kejì àti Elifeleti ẹ̀ẹ̀kẹ́ta. 40Àwọn ọmọ Ulamu jẹ́ ògboyà jagunjagun tí ó lè gbá orin mú. Wọ́n ní ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin àti ọmọ ọmọkùnrin márùn-dínlọ́gọ́jọ ní gbogbo rẹ̀.

Gbogbo wọ̀nyí ni àwọn ìdílé ìran ọmọ Benjamini.