ዮሐንስ 20 – NASV & YCB

New Amharic Standard Version

ዮሐንስ 20:1-31

ኢየሱስ ከሞት ተነሣ

20፥1-8 ተጓ ምብ – ማቴ 28፥1-8ማር 16፥1-8ሉቃ 24፥1-10

1በሳምንቱ የመጀመሪያ ቀን፣ በማለዳ ገና ጨለማ ሳለ፣ መግደላዊት ማርያም ወደ መቃብሩ ሄደች፤ ድንጋዩም ከመቃብሩ መግቢያ ተንከባልሎ አየች። 2ስለዚህም ወደ ስምዖን ጴጥሮስና ኢየሱስ ይወድደው ወደ ነበረው ሌላው ደቀ መዝሙር እየሮጠች መጥታ፣ “ጌታን ከመቃብር አውጥተው ወስደውታል፤ የት እንዳኖሩትም አናውቅም” አለቻቸው።

3ከዚያም ጴጥሮስና ሌላው ደቀ መዝሙር ወጥተው ወደ መቃብሩ ሄዱ። 4ሁለቱም ይሮጡ ነበር፤ ሌላው ደቀ መዝሙርም ጴጥሮስን ቀድሞት ከመቃብሩ ደረሰ። 5ጐንበስ ብሎ ሲመለከት፣ ከተልባ እግር የተሠራውን ከፈን በዚያው እንዳለ አየ፤ ወደ መቃብሩ ግን አልገባም። 6ይከተለው የነበረው ስምዖን ጴጥሮስ ደረሰና ወደ መቃብሩ ገባ፤ እርሱም ከተልባ እግር የተሠራውን ከፈን አየ፤ 7እንዲሁም በኢየሱስ ራስ ላይ ተጠምጥሞ የነበረውን ጨርቅ አየ፤ ይህም ጨርቅ ከከፈኑ ተለይቶ እንደ ተጠቀለለ ነበር። 8ከዚያም አስቀድሞ ከመቃብሩ የደረሰው ሌላው ደቀ መዝሙር ወደ ውስጥ ገባ፤ አይቶም አመነ፤ 9ይኸውም ኢየሱስ ከሙታን መነሣት እንዳለበት ገና ከመጽሐፍ ስላልተረዱ ነበር።

ኢየሱስ ለመግደላዊት ማርያም ታየ

10ከዚያም በኋላ ደቀ መዛሙርቱ ተመልሰው ወደየቤታቸው ሄዱ፤ 11ማርያም ግን ከመቃብሩ ውጭ ቆማ ታለቅስ ነበር፤ እያለቀሰችም መቃብሩን ለማየት ጐንበስ አለች። 12የኢየሱስ ሥጋ በነበረበት ቦታ፣ ነጫጭ ልብስ የለበሱ ሁለት መላእክት አንዱ በራስጌ ሌላው በግርጌ ተቀምጠው አየች።

13እነርሱም፣ “አንቺ ሴት፤ ለምን ታለቅሻለሽ?” ብለው ጠየቋት።

እርሷም፣ “ጌታዬን ወስደውታል፤ የት እንዳኖሩትም አላውቅም” አለች። 14ይህን ብላ ዘወር ስትል ኢየሱስ በዚያው ቆሞ አየች፤ ኢየሱስ መሆኑን ግን አላወቀችም።

15እርሱም፣ “አንቺ ሴት፤ ለምን ታለቅሻለሽ? ማንንስ ትፈልጊአለሽ?” አላት።

እርሷም የአትክልቱ ቦታ ጠባቂ መስሏት፣ “ጌታዬ፤ አንተ ወስደኸው ከሆነ፣ እባክህ እንድወስደው፣ የት እንዳኖርኸው ንገረኝ” አለችው።

16ኢየሱስም፣ “ማርያም” አላት።

እርሷም፣ ወደ እርሱ ዘወር ብላ በአራማይክ ቋንቋ፣ “ረቡኒ” አለችው፤ ትርጕሙም “መምህር ሆይ” ማለት ነው።

17ኢየሱስም፣ “ገና ወደ አብ ስላላረግሁ፣ አትንኪኝ፤ ይልቁንስ ወደ ወንድሞቼ ሄደሽ፣ ‘ወደ አባቴና ወደ አባታችሁ፣ ወደ አምላኬና ወደ አምላካችሁ ዐርጋለሁ’ ብሏል ብለሽ ንገሪአቸው” አላት።

18መግደላዊት ማርያምም፣ ወደ ደቀ መዛሙርቱ መጥታ፣ “ጌታን እኮ አየሁት!” አለች፤ እርሱ ያላትንም ነገረቻቸው።

ኢየሱስ ለደቀ መዛሙርቱ ታየ

19በዚያኑ ዕለት፣ በሳምንቱ መጀመሪያ ቀን በምሽት፣ ደቀ መዛሙርቱ አይሁድን በመፍራት በሮቹን ቈልፈው ተሰብስበው ሳለ፣ ኢየሱስ መጣና በመካከላቸው ቆሞ፣ “ሰላም ለእናንተ ይሁን” አላቸው። 20ይህንም ብሎ እጆቹንና ጐኑን አሳያቸው፤ ደቀ መዛሙርትም ጌታን ባዩት ጊዜ እጅግ ደስ አላቸው።

21ኢየሱስም እንደ ገና፣ “ሰላም ለእናንተ ይሁን፤ አብ እኔን እንደ ላከኝ፣ እኔም እናንተን እልካችኋለሁ” አላቸው። 22ይህን ካለ በኋላም፣ እፍ አለባቸውና እንዲህ አላቸው፤ “መንፈስ ቅዱስን ተቀበሉ፤ 23የሰዎችን ኀጢአት ይቅር ብትሉ፣ ኀጢአታቸው ይቅር ይባልላቸዋል፤ ኀጢአታቸውን ይቅር ባትሉ ግን፣ ይቅር አይባልላቸውም።”

ኢየሱስ ለቶማስ ታየ

24በዚህ ጊዜ ከዐሥራ ሁለቱ አንዱ የሆነው፣ ዲዲሞስ የተባለው ቶማስ፣ ኢየሱስ በመጣ ጊዜ ከደቀ መዛሙርቱ ጋር አልነበረም። 25ሌሎች ደቀ መዛሙርትም፣ “ጌታን አየነው እኮ!” አሉት።

እርሱ ግን፣ “በምስማር የተቸነከሩትን የእጆቹን ምልክቶች ካላየሁ፣ ምስማሮቹ በነበሩበት ቦታ ጣቴን ካላደረግሁ፣ በጐኑም እጄን ካላስገባሁ አላምንም” አለ።

26ከስምንት ቀን በኋላም፣ ደቀ መዛሙርቱ በቤት ውስጥ ነበሩ፤ ቶማስም ከእነርሱ ጋር ነበር፤ በሮቹ ተቈልፈው ነበር፤ ኢየሱስ ግን መጥቶ በመካከላቸው ቆመና፣ “ሰላም ለእናንተ ይሁን” አላቸው። 27ከዚያም ቶማስን፣ “ጣትህን ወደዚህ አምጣ፤ እጆቼንም ተመልከት፤ እጅህን ዘርጋና በጐኔ አስገባ፤ አትጠራጠር፤ እመን” አለው።

28ቶማስም፣ “ጌታዬ፤ አምላኬም!” አለው።

29ኢየሱስም፣ “አንተ ስላየኸኝ አምነሃል፤ ሳያዩ የሚያምኑ ግን ብፁዓን ናቸው” አለው።

30ኢየሱስ በዚህ መጽሐፍ ያልተጻፉ ሌሎች አያሌ ታምራዊ ምልክቶችን በደቀ መዛሙርቱ ፊት አድርጓል፤ 31ነገር ግን ኢየሱስ እርሱ ክርስቶስ፣ የእግዚአብሔርም ልጅ እንደ ሆነ ታምኑ20፥31 አንዳንድ ቅጆች በማመን እንድትድኑ ይላሉ። ዘንድ፣ አምናችሁም በስሙ ሕይወት እንዲኖራችሁ ይህ ተጽፏል።

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Johanu 20:1-31

Òfo ibojì

120.1-10: Mt 28.1-8; Mk 16.1-8; Lk 24.1-10.Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, nígbà tí ilẹ̀ kò tí ì mọ́, ni Maria Magdalene wá sí ibojì, ó sì rí i pé, a ti gbé òkúta kúrò lẹ́nu ibojì. 2Nítorí náà, ó sáré, ó sì tọ Simoni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn wá, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.”

320.3-10: Lk 24.11-12.Nígbà náà ni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà jáde, wọ́n sì wá sí ibojì. 4Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ sáré: èyí ọmọ-ẹ̀yìn náà sì sáré ya Peteru, ó sì kọ́kọ́ dé ibojì. 5Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti wo inú rẹ̀, ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀; ṣùgbọ́n òun kò wọ inú rẹ̀. 6Nígbà náà ni Simoni Peteru tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ dé, ó sì wọ inú ibojì, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀. 7Àti pé, gèlè tí ó wà níbi orí rẹ̀ kò sì wà pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, ṣùgbọ́n ó ká jọ ní ibìkan fúnrarẹ̀. 8Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, ẹni tí ó kọ́ dé ibojì wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì rí i, ó sì gbàgbọ́. 920.9: Lk 24.26,46.(Nítorí tí wọn kò sá à tí mọ ìwé mímọ́ pé, Jesu ní láti jíǹde kúrò nínú òkú.) 10Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sì tún padà lọ sí ilé wọn.

Jesu fi ara han Maria Magdalene

11Ṣùgbọ́n Maria dúró létí ibojì lóde, ó ń sọkún: bí ó ti ń sọkún, bẹ́ẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀, ó sì wo inú ibojì. 1220.12: Lk 24.4; Mt 28.5; Mk 16.5.Ó sì kíyèsi àwọn angẹli méjì aláṣọ funfun, wọ́n jókòó, ọ̀kan níhà orí àti ọ̀kan níhà ẹsẹ̀, níbi tí òkú Jesu gbé ti sùn sí.

1320.13: Jh 20.2.Wọ́n sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún?”

Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí tí wọ́n ti gbé Olúwa mi, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.” 1420.14: Mt 28.9; Jh 21.4.Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó yípadà, ó sì rí Jesu dúró, kò sì mọ̀ pé Jesu ni.

15Jesu wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Ta ni ìwọ ń wá?”

Òun ṣe bí olùṣọ́gbà ní í ṣe, ó wí fún un pé, “Alàgbà, bí ìwọ bá ti gbé e kúrò níhìn-ín yìí, sọ ibi tí ìwọ tẹ́ ẹ sí fún mi, èmi yóò sì gbé e kúrò.”

16Jesu wí fún un pé, “Maria!”

Ó sì yípadà, ó wí fún un ní èdè Heberu pé, “Rabboni!” (èyí tí ó túmọ̀ sí “Olùkọ́”).

1720.17: Jh 20.27; Mt 28.10; Jh 7.33.Jesu wí fún un pé, “Má ṣe fi ọwọ́ kàn mí; nítorí tí èmi kò tí ì gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi: ṣùgbọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin mi, sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ń gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi, àti Baba yín: àti sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín.’ ”

1820.18: Lk 24.10,23.Maria Magdalene wá, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, “Òun ti rí Olúwa!” Àti pé, ó sì ti fi nǹkan wọ̀nyí fún òun.

Jesu fi ara han àwọn Aposteli

1920.19-20: Lk 24.36-39.Ní ọjọ́ kan náà, lọ́jọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀ nígbà tí alẹ́ lẹ́, tí a sì ti ìlẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbé péjọ, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni Jesu dé, ó dúró láàrín, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.” 20Nígbà tí ó sì ti wí bẹ́ẹ̀ tán, ó fi ọwọ́ àti ìhà rẹ̀ hàn wọ́n. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yọ̀, nígbà tí wọ́n rí Olúwa.

2120.21: Jh 17.18; Mt 28.19.Nítorí náà, Jesu sì tún wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín: gẹ́gẹ́ bí Baba ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán yín.” 2220.22: Ap 2.4,33.Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó mí sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí mímọ́! 2320.23: Mt 16.19; 18.18.Ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá fi jì, a fi jì wọ́n; ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá dádúró, a dá wọn dúró.”

Jesu fi ara han Tomasi

2420.24: Jh 11.16.Ṣùgbọ́n Tomasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, tí a ń pè ní Didimu, kò wà pẹ̀lú wọn nígbà tí Jesu dé. 25Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù wí fún un pé, “Àwa ti rí Olúwa!”

Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé mo bá rí àpá ìṣó ni ọwọ́ rẹ̀ kí èmi sì fi ìka mi sí àpá ìṣó náà, kí èmi sì fi ọwọ́ mi sí ìhà rẹ̀, èmi kì yóò gbàgbọ́!”

26Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì tún wà nínú ilé, àti Tomasi pẹ̀lú wọn: nígbà tí a sì ti ti ìlẹ̀kùn, Jesu dé, ó sì dúró láàrín, ó wí pé, “Àlàáfíà fún yín.” 2720.27: Lk 24.40.Nígbà náà ni ó wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá níhìn-ín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi; sì mú ọwọ́ rẹ wá níhìn-ín, kí o sì fi sí ìhà mi: kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́.”

28Tomasi dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!”

2920.29: 1Pt 1.8.Jesu wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ rí mi ni ìwọ ṣe gbàgbọ́: alábùkún fún ni àwọn tí kò rí mi, tí wọ́n sì gbàgbọ́!”

3020.30: Jh 21.25.Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì mìíràn ni Jesu ṣe níwájú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, tí a kò kọ sínú ìwé yìí: 3120.31: Jh 3.15.Ṣùgbọ́n wọ̀nyí ni a kọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé Jesu ní í ṣe Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run, àti pé nípa gbígbàgbọ́, kí ẹ̀yin lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.