ኢሳይያስ 40 – NASV & YCB

New Amharic Standard Version

ኢሳይያስ 40:1-31

የእግዚአብሔርን ሕዝብ የሚያጽናና ቃል

1አጽናኑ፤ ሕዝቤን አጽናኑ፤

ይላል አምላካችሁ።

2ለኢየሩሳሌም አለዝባችሁ ንገሯት፤

ዐውጁላትም፤

በባርነት ያገለገለችበት ዘመን አብቅቷል፤

የኀጢአቷም ዋጋ ተከፍሏል፤

ስለ ኀጢአቷ ሁሉ ከእግዚአብሔር እጅ

ሁለት ዕጥፍ ተቀብላለች።

3የዐዋጅ ነጋሪ ድምፅ እንዲህ ይላል፤

የእግዚአብሔርን መንገድ፣

በምድረ በዳ አዘጋጁ፤

ለአምላካችን አውራ ጐዳና፣

በበረሓ አስተካክሉ።

4ሸለቆው ሁሉ ከፍ ይላል፤

ተራራውና ኰረብታው ሁሉ ዝቅ ይላል፤

ወጣ ገባው ምድር ይስተካከላል፤

ሰርጓጕጡም ሜዳ ይሆናል።

5የእግዚአብሔርም ክብር ይገለጣል፤

ሰው ሁሉ በአንድነት ያየዋል፤

የእግዚአብሔር አፍ ይህን ተናግሯልና።”

6ድምፅም፣ “ጩኽ” አለኝ፤

እኔም፣ “ምን ብዬ ልጩኽ?” አልሁ።

“ሰው ሁሉ እንደ ሣር ነው፤

ክብሩም ሁሉ እንደ ሜዳ አበባ ነው።

7ሣሩ ይደርቃል፤ አበባውም ይረግፋል፤

የእግዚአብሔር እስትንፋስ ነፍሶበታልና፤

ሕዝቡ በርግጥ ሣር ነው።

8ሣሩ ይደርቃል፤ አበባውም ይረግፋል፤

የአምላካችን ቃል ግን ለዘላለም ጸንቶ ይኖራል።”

9አንተ ለጽዮን የምሥራችን የምትነግር፤

ከፍ ወዳለው ተራራ ውጣ፤

አንተ ለኢየሩሳሌም ብሥራት የምትነግር፣40፥9 ወይም፣ ጽዮን ሆይ፤ የምሥራቹን የምታበሥሪ፣ ወደ ረዥም ተራራ ላይ ውጪ ወይም የምሥራቹን የምታበሥሪ ኢየሩሳሌም ሆይ

ድምፅህን ከፍ አድርገህ ጩኽ።

ከፍ አድርገው፤ አትፍራ፤

ለይሁዳም ከተሞች፣

“እነሆ፤ አምላካችሁ!” በል።

10እነሆ፤ጌታ እግዚአብሔር በኀይል

ይመጣል፤

ክንዱ ስለ እርሱ ይገዛል።

እነሆ፤ ዋጋው ከእርሱ ጋር ነው፤

የሚከፍለውም ብድራት አብሮት አለ።

11መንጋውን እንደ እረኛ ያሰማራል፤

ጠቦቶቹን በክንዱ ይሰበስባል፤

በዕቅፉም ይይዛቸዋል፤

የሚያጠቡትንም በጥንቃቄ ይመራል።

12ውሆችን በዕፍኙ የሰፈረ፣

ሰማያትን በስንዝሩ የለካ፣

የምድርን ዐፈር በመስፈሪያ ሰብስቦ የያዘ፣

ተራሮችን በሚዛን፣

ኰረብቶችንም በመድሎት የመዘነ ማነው?

13የእግዚአብሔርን መንፈስ የተረዳ፣

አማካሪውስ ሆኖ ያስተማረው ማነው?

14ዕውቀት ለማግኘት እግዚአብሔር ማንን አማከረ?

ትክክለኛውንስ መንገድ ማን አስተማረው?

ዕውቀትን ያስተማረው፣

የማስተዋልንም መንገድ ያሳየው ማን ነበር?

15እነሆ፤ አሕዛብ በገንቦ ውስጥ እንዳለች ጠብታ ናቸው፤

በሚዛን ላይ እንዳለ ትቢያ ይቈጠራሉ፤

ደሴቶችንም እንደ ደቃቅ ዐፈር ይመዝናቸዋል።

16ሊባኖስ ለመሠዊያ እሳት አትበቃም፤

የእንስሶቿም ቍጥር ለሚቃጠል መሥዋዕት ያንሳል።

17አሕዛብ ሁሉ በፊቱ እንደ ኢምንት ናቸው፤

ከምንም የማይቈጠሩ መና ናቸው።

18እንግዲህ፣ እግዚአብሔርን ከማን ጋር ታወዳድሩታላችሁ?

ከየትኛውስ ምስል ጋር ታነጻጽሩታላችሁ?

19የተቀረጸውንማ ምስል ባለ እጅ ይቀርጸዋል፤

ወርቅ አንጥረኛም በወርቅ ይለብጠዋል፤

የብር ሰንሰለትም ያበጅለታል።

20እንዲህ ያለውን መባ ማቅረብ የማይችል ምስኪን ድኻ፣

የማይነቅዝ ዕንጨት ይመርጣል፤

የማይወድቅ ምስልን ለማቆምም፣

ታዋቂ ባለሙያ ይፈልጋል።

21አላወቃችሁምን?

አልሰማችሁምን?

ከጥንት አልተነገራችሁምን?

ምድር ከተመሠረተች ጀምሮ አላስተዋላችሁምን?

22እርሱ ከምድር ክበብ በላይ በዙፋን ላይ ይቀመጣል፤

ሕዝቦቿም እንደ አንበጣ ናቸው።

ሰማያትን እንደ ድባብ ይዘረጋቸዋል፤

እንደ መኖሪያ ድንኳንም ይተክላቸዋል።

23አለቆችን ኢምንት፣

የዚህን ዓለም ገዦች እንዳልነበሩ ያደርጋቸዋል።

24ተተክለው ምንም ያህል ሳይቈዩ፣

ተዘርተው ምንም ያህል ሳይሰነብቱ፣

ገና ሥር መስደድ ሳይጀምሩ

አነፈሰባቸው፤ እነርሱም ደረቁ፤

ዐውሎ ነፋስም እንደ ገለባ ጠራርጎ ወሰዳቸው።

25ቅዱሱ፣ “ከማን ጋር ታወዳድሩኛላችሁ?

የሚስተካከለኝስ ማን አለ?” ይላል።

26ዐይናችሁን አንሡ፤ ወደ ሰማይ ተመልከቱ፤

እነዚህን ሁሉ የፈጠረ ማን ነው?

የከዋክብትን ሰራዊት አንድ በአንድ የሚያወጣቸው፣

በየስማቸው የሚጠራቸው እርሱ ነው።

ከኀይሉ ታላቅነትና ከችሎታው ብርታት የተነሣ፣

አንዳቸውም አይጠፉም።

27ያዕቆብ ሆይ፤ ለምን እንዲህ ትላለህ?

እስራኤል ሆይ፤ ለምን እንዲህ ትናገራለህ?

“መንገዴ ከእግዚአብሔር ተሰውራለች፤

ፍርዴም በአምላኬ ቸል ተብላለች” ለምን ትላለህ?

28አታውቅምን?

አልሰማህምን?

እግዚአብሔር የዘላለም አምላክ፣

የምድር ዳርቻ ፈጣሪ ነው።

አይደክምም፤ አይታክትም፤

ማስተዋሉም በማንም አይመረመርም።

29ለደከመው ብርታት ይሰጣል፤

ለዛለው ጕልበት ይጨምራል።

30ወጣቶች እንኳ ይደክማሉ፤ ይታክታሉም፤

ጐበዛዝትም ተሰናክለው ይወድቃሉ።

31እግዚአብሔርን ተስፋ የሚያደርጉ ግን፣

ኀይላቸውን ያድሳሉ፤

እንደ ንስር በክንፍ ይወጣሉ፤

ይሮጣሉ፤ አይታክቱም፤

ይሄዳሉ፤ አይደክሙም።

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 40:1-31

Ìtùnú fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run

1Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú,

ni Ọlọ́run yín wí.

2Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu

kí o sì kéde fún un

pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí,

pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,

pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ Olúwa

ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

340.3: Mt 3.3; Mk 1.3; Lk 3.4; Jh 1.23.Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù:

“Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe,

ṣe òpópó tí ó tọ́ ní aginjù fún Ọlọ́run wa.

440.4-5: Lk 3.5-6.Gbogbo Àfonífojì ni a ó gbé sókè,

gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀;

wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àti

ọ̀nà pálapàla ni a óò sọ di títẹ́jú pẹrẹsẹ,

5Ògo Olúwa yóò sì di mí mọ̀

gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rí i.

Nítorí ẹnu Olúwa ni ó ti sọ ọ́.”

640.6-8: 1Pt 1.24-25.Ohùn kan wí pé, “Kígbe sókè.”

Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?”

“Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko,

àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná igbó.

7Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,

nítorí èémí Olúwa ń fẹ́ lù wọ́n.

Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn.

8Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,

ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”

940.9: Isa 52.7; Nh 1.15; Ap 10.36; Ro 10.15.Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni,

lọ sí orí òkè gíga.

Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu,

gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo,

gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù;

sọ fún àwọn ìlú u Juda,

“Ọlọ́run rẹ nìyìí!”

1040.10: If 22.7,12.Wò ó, Olúwa Olódùmarè náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára,

apá rẹ̀ sì ń jẹ ọba fún un.

Wò ó, èrè rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀,

àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá.

11Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn:

Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀.

Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan àyà rẹ̀;

ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí àwọn tí ó ní.

12Ta ni ó tiwọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀,

tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀

tí ó wọn àwọn ọ̀run?

Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀,

tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀n

àti òkè kéékèèkéé nínú òṣùwọ̀n?

1340.13: Ro 11.34; 1Kọ 2.16.Ta ni ó ti mọ ọkàn Olúwa,

tàbí tí ó ti tọ́ ọ ṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀?

14Ta ni Olúwa ké sí kí ó là á lọ́yẹ

àti ta ni ó kọ́ òun ní ọ̀nà tí ó tọ́?

Ta ni ẹni náà tí ó kọ́ ọ ní ọgbọ́n

tàbí tí ó fi ipa ọ̀nà òye hàn án?

15Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀-èdè dàbí i ẹ̀kún omi

nínú garawa;

a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n;

ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n.

16Lebanoni kò tó fún pẹpẹ iná,

tàbí kí àwọn ẹranko rẹ̀ kí ó tó fún ẹbọ sísun.

17Níwájú rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè dàbí ohun tí kò sí;

gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlò

tí kò tó ohun tí kò sí.

18Ta ni nígbà náà tí ìwọ yóò fi Ọlọ́run wé?

Ère wo ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé rẹ̀?

19Ní ti ère, oníṣọ̀nà ni ó dà á,

ti alágbẹ̀dẹ wúrà sì fi wúrà bò ó

tí a sì ṣe ẹ̀wọ̀n ọ̀nà sílífà fún un.

20Ọkùnrin kan tí ó tálákà jù kí ó lè mú

irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ wá,

wá igi tí kò le è rà.

Ó wá oníṣọ̀nà tí ó

láti ṣe àgbékalẹ̀ ère tí kì yóò le è ṣubú.

21Ǹjẹ́ o kò tí ì mọ̀

ìwọ kò tí ì gbọ́?

A kò tí ì sọ fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá?

Ìwọ kò tí ì mọ láti ìgbà ìpìlẹ̀ ayé?

22Òun jókòó lórí ìtẹ́ ní òkè òbírí ilẹ̀ ayé,

àwọn ènìyàn rẹ̀ sì dàbí i láńtata.

Ó ta àwọn ọ̀run bí ìbòrí ìgúnwà,

ó sì nà wọ́n jáde gẹ́gẹ́ bí àgọ́ láti gbé.

23Ó sọ àwọn ọmọ ọba di asán

àti àwọn aláṣẹ ayé yìí ni ó ti sọ dòfo.

24Gẹ́rẹ́ tí a ti gbìn wọ́n,

kété tí a gbìn wọ́n,

kété tí wọ́n fi gbòǹgbò múlẹ̀,

bẹ́ẹ̀ ni ó fẹ́ atẹ́gùn lù wọ́n gbogbo wọn sì gbẹ,

bẹ́ ni ìjì líle sì gbá wọn lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò.

25“Ta ni ẹ ó fi mi wé?

Tàbí ta ni ó bá mi dọ́gba?” ni Ẹni Mímọ́ wí.

26Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wo àwọn ọ̀run:

Ta ni ó dá àwọn wọ̀nyí?

Ẹni tí ó mú àkójọpọ̀ àwọn ìràwọ̀ jáde wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan

tí ó sì pè wọ́n ní orúkọ lọ́kọ̀ọ̀kan.

Nítorí agbára ńlá àti ipá rẹ̀,

ọ̀kan ṣoṣo nínú wọn kò sọnù.

27Èéṣe tí o fi sọ, ìwọ Jakọbu

àti tí o ṣàròyé, ìwọ Israẹli;

“Ọ̀nà mi pamọ́ níwájú Olúwa;

ìṣe mi ni a kò kọbi ara sí

láti ọwọ́ Ọlọ́run mi”?

28Ìwọ kò tí ì mọ̀?

Ìwọ kò tí ì gbọ́?

Olúwa òun ni Ọlọ́run ayérayé,

Ẹlẹ́dàá gbogbo ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé.

Agara kì yóò da bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣàárẹ̀,

àti òye rẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò le ṣe òdínwọ̀n rẹ̀.

29Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀

ó sì fi kún agbára àwọn tí agara dá.

30Àní, ó ń rẹ̀ wọ́n àwọn ọ̀dọ́, wọ́n ń rẹ̀wẹ̀sì,

àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì ń kọsẹ̀ wọ́n ṣubú;

31ṣùgbọ́n àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa

yóò sọ agbára wọn di ọ̀tun.

Wọn yóò fìyẹ́ fò lókè bí idì;

wọn yóò sáré àárẹ̀ kò ní mú wọn,

wọn yóò rìn òòyì kò ní kọ́ wọn.