New American Standard Bible

Philippians 1

Thanksgiving

1Paul and Timothy, bond-servants of Christ Jesus,

To all the [a]saints in Christ Jesus who are in Philippi, [b]including the overseers and deacons: Grace to you and peace from God our Father and the Lord Jesus Christ.

I thank my God in all my remembrance of you, always offering prayer with joy in my every prayer for you all, in view of your [c]participation in the gospel from the first day until now. For I am confident of this very thing, that He who began a good work in you will perfect it until the day of Christ Jesus. [d]For it is only right for me to feel this way about you all, because I have you in my heart, since both in my [e]imprisonment and in the defense and confirmation of the gospel, you all are partakers of grace with me. For God is my witness, how I long for you all with the [f]affection of Christ Jesus. And this I pray, that your love may abound still more and more in real knowledge and all discernment, 10 so that you may [g]approve the things that are excellent, in order to be sincere and blameless [h]until the day of Christ; 11 having been filled with the fruit of righteousness which comes through Jesus Christ, to the glory and praise of God.

The Gospel Is Preached

12 Now I want you to know, brethren, that my circumstances have turned out for the greater progress of the gospel, 13 so that my [i]imprisonment in the cause of Christ has become well known throughout the whole [j]praetorian guard and to everyone else, 14 and that most of the [k]brethren, trusting in the Lord because of my [l]imprisonment, have far more courage to speak the word of God without fear. 15 Some, to be sure, are preaching Christ even [m]from envy and strife, but some also [n]from good will; 16 the latter do it out of love, knowing that I am appointed for the defense of the gospel; 17 the former proclaim Christ out of selfish ambition [o]rather than from pure motives, thinking to cause me distress in my [p]imprisonment. 18 What then? Only that in every way, whether in pretense or in truth, Christ is proclaimed; and in this I rejoice.

Yes, and I will rejoice, 19 for I know that this will turn out for my [q]deliverance through your [r]prayers and the provision of the Spirit of Jesus Christ, 20 according to my earnest expectation and hope, that I will not be put to shame in anything, but that with all boldness, Christ will even now, as always, be exalted in my body, whether by life or by death.

To Live Is Christ

21 For to me, to live is Christ and to die is gain. 22 [s]But if I am to live on in the flesh, this will mean fruitful labor for me; and I do not know [t]which to choose. 23 But I am hard-pressed from both directions, having the desire to depart and be with Christ, for that is very much better; 24 yet to remain on in the flesh is more necessary for your sake. 25 Convinced of this, I know that I will remain and continue with you all for your progress and joy [u]in the faith, 26 so that your proud confidence in me may abound in Christ Jesus through my coming to you again.

27 Only conduct yourselves in a manner worthy of the gospel of Christ, so that whether I come and see you or remain absent, I will hear of you that you are standing firm in one spirit, with one [v]mind striving together for the faith of the gospel; 28 in no way alarmed by your opponents—which is a sign of destruction for them, but of salvation for you, and that too, from God. 29 For to you it has been granted for Christ’s sake, not only to believe in Him, but also to suffer for His sake, 30 experiencing the same conflict which you saw in me, and now hear to be in me.

Notas al pie

 1. Philippians 1:1 Or holy ones
 2. Philippians 1:1 Lit with
 3. Philippians 1:5 Or sharing in the preaching of the gospel
 4. Philippians 1:7 Lit Just as it is right
 5. Philippians 1:7 Lit bonds
 6. Philippians 1:8 Lit inward parts
 7. Philippians 1:10 Or discover; or distinguish between the things which differ
 8. Philippians 1:10 Or for
 9. Philippians 1:13 Lit bonds
 10. Philippians 1:13 Or governor’s palace
 11. Philippians 1:14 Or brethren in the Lord, trusting because of my bonds
 12. Philippians 1:14 Lit bonds
 13. Philippians 1:15 Lit because of
 14. Philippians 1:15 Lit because of
 15. Philippians 1:17 Lit not sincerely
 16. Philippians 1:17 Lit bonds
 17. Philippians 1:19 Or salvation
 18. Philippians 1:19 Lit supplication
 19. Philippians 1:22 Or But if to live in the flesh, this will be fruitful labor for me, then I
 20. Philippians 1:22 Lit what I shall choose
 21. Philippians 1:25 Lit of
 22. Philippians 1:27 Lit soul

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Filipi 1

1Paulu àti Timotiu, àwọn ìránṣẹ́ Jesu Kristi.

Sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu tí ó wà ní Filipi, pẹ̀lú àwọn alábojútó àti àwọn díákónì.

Oore-ọ̀fẹ́ sí yín, àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Olúwa wa Jesu Kristi.

Àdúrà àti Ọpẹ́

Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín: Nínú gbogbo àdúrà mi fún un yín, èmi ń fi ayọ̀ gbàdúrà, nítorí ìdàpọ̀ yín nínú ìhìnrere láti ọjọ́ kìn-ín-ní wá títí di ìsinsin yìí. Ohun kan yìí sá à dá mi lójú pé, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín, yóò ṣe àṣepé rẹ̀ títí di ọjọ́ náà tí Jesu Kristi yóò dé:

Gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi láti ro èyí nípa gbogbo yín, nítorí tí mo fi yín sọ́kàn, bí mo tilẹ̀ wà nínú ìdè tàbí ìdáhùn ẹjọ́, àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìhìnrere, gbogbo yín jẹ́ alábápín oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú mi. Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi, bí mo ti ń ṣàfẹ́rí yín gidigidi nínú ìfẹ́ Jesu Kristi.

Èyí sì ni àdúrà mi: pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti síwájú sí i nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, 10 kí ẹ̀yin kí ó lè ní òye ohun tí ó dára jùlọ; kí ó sì jásí òdodo àti aláìjẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ títí di ọjọ́ dídé Jesu Kristi: 11 Lẹ́yìn ìgbà ti ẹ ti kún fún àwọn ìwà òdodo láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.

Ìrírí Paulu nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́

12 Ǹjẹ́ èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó mọ̀, ará, pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi jásí àtẹ̀gùn sí ìlọsíwájú ìhìnrere. 13 Nítorí ìdí èyí, ó ti hàn gbangba sí gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin àti sí àwọn ẹlòmíràn wí pé mo wà nínú ìdè fún Kristi. 14 Nítorí ìdè mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará nínú Olúwa ni a ti mú lọ́kàn le láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i pẹ̀lú ìgboyà àti láìbẹ̀rù.

15 Òtítọ́ ni pé àwọn ẹlòmíràn tilẹ̀ ń fi ìjà àti ìlara wàásù Kristi, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn sì ń fi inú rere ṣe é. 16 Àwọn kan ń fi ìjà wàásù Kristi, kì í ṣe pẹ̀lú òtítọ́ inú, wọ́n ń gbèrò láti fi ìpọ́njú kún ìdè mi: 17 Àwọn kan ẹ̀wẹ̀ si ń fi ìfẹ́ ṣe é, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé a gbé mi dìde láti dá ààbò bo iṣẹ́ ìhìnrere. 18 Kí ló tún kù? Kìkì í pé níbi gbogbo, ìbá à ní ìfẹ̀tànṣe tàbí ni ti òtítọ́ a sá à n wàásù Kristi, èmi sì ń yọ̀ nítorí èyí.

Nítòótọ́, èmi ó sì máa yọ̀, 19 nítorí tí mo mọ̀ pé èyí ni yóò yọrí sí ìgbàlà fún mi láti inú àdúrà yín wá, àti ìfikún ẹ̀mí Jesu Kristi, 20  Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn àti ìrètí mi pé kí ojú kí ó má ṣe ti mi ní ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí èmi kí ó le máa ni ìgboyà ní ìgbà gbogbo àti nísinsin yìí, kí a lè ti ipasẹ̀ mi gbé Kristi ga lára mi, ìbá à ṣe pé mo wà láààyè, tàbí mo kú. 21 Nítorí, ní ti èmi, láti wa láààyè jẹ́ Kristi, láti kú pẹ̀lú sì jẹ́ èrè fún mi. 22 Ṣùgbọ́n bí èmi bá le è ṣe iṣẹ́ ti ó ni àpẹẹrẹ nípa wíwà láààyè nínú ara, ṣùgbọ́n ohun ti èmi ó yàn, èmi kò mọ̀. 23 Ṣùgbọ́n èmi n ṣiyèméjì, nítorí ti èmi fẹ́ láti lọ kúrò nínú ayé yìí, láti wà lọ́dọ̀ Kristi; nítorí ó dára púpọ̀ jù: 24 Síbẹ̀ láti wà láààyè jẹ́ àǹfààní nítorí tiyín. 25 Bí èyí sì ti dá mi lójú, mo mọ̀ pé èmi ó dúró, èmi ó sì máa wà pẹ̀lú yín fún ìtẹ̀síwájú àti ayọ̀ yín nínú ìgbàgbọ́, 26 kí ìṣògo yín kí ó lè di púpọ̀ gidigidi nínú Jesu Kristi, àti nínú mi nípa ìpadà wá mi sọ́dọ̀ yín.

27 Ohun yówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìgbé ayé yín ri gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere Kristi: pé yálà bi mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi kí ó lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin jùmọ̀ jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìhìnrere, pẹ̀lú ọkàn kan; 28 Kí ẹ má sì jẹ́ ki àwọn ọ̀tá dẹ́rùbà yin ni ohunkóhun: èyí tí í ṣe ààmì tí ó dájú pé a ó pa wọ́n run, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ni yóò gbà yin là. 29 Nítorí tí a ti fún yin ni àǹfààní, kì í ṣe láti gba Kristi gbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú: 30 Ẹ sì máa ja ìjà kan náà, èyí ti ẹ̀yin ti ri, ti ẹ sì ti gbọ́ pé èmi n jà pẹ̀lú.