New American Standard Bible

Joshua 1

God’s Charge to Joshua

1Now it came about after the death of Moses the servant of the Lord, that the Lord spoke to Joshua the son of Nun, Moses’ [a]servant, saying, “Moses My servant is dead; now therefore arise, cross this Jordan, you and all this people, to the land which I am giving to them, to the sons of Israel. Every place on which the sole of your foot treads, I have given it to you, just as I spoke to Moses. From the wilderness and this Lebanon, even as far as the great river, the river Euphrates, all the land of the Hittites, and as far as the Great Sea toward the setting of the sun will be your territory. No man will be able to stand before you all the days of your life. Just as I have been with Moses, I will be with you; I will not fail you or forsake you. Be strong and courageous, for you shall give this people possession of the land which I swore to their fathers to give them. Only be strong and very courageous; [b]be careful to do according to all the law which Moses My servant commanded you; do not turn from it to the right or to the left, so that you may [c]have success wherever you go. This book of the law shall not depart from your mouth, but you shall meditate on it day and night, so that you may [d]be careful to do according to all that is written in it; for then you will make your way prosperous, and then you will [e]have success. Have I not commanded you? Be strong and courageous! Do not tremble or be dismayed, for the Lord your God is with you wherever you go.”

Joshua Assumes Command

10 Then Joshua commanded the officers of the people, saying, 11 “Pass through the midst of the camp and command the people, saying, ‘Prepare provisions for yourselves, for within three days you are to cross this Jordan, to go in to possess the land which the Lord your God is giving you, to possess it.’”

12 To the Reubenites and to the Gadites and to the half-tribe of Manasseh, Joshua [f]said, 13 “Remember the word which Moses the servant of the Lord commanded you, saying, ‘The Lord your God gives you rest and will give you this land.’ 14 Your wives, your little ones, and your cattle shall remain in the land which Moses gave you beyond the Jordan, but you shall cross before your brothers in battle array, all your valiant warriors, and shall help them, 15 until the Lord gives your brothers rest, as He gives you, and they also possess the land which the Lord your God is giving them. Then you shall return to [g]your own land, and possess [h]that which Moses the servant of the Lord gave you beyond the Jordan toward the sunrise.”

16 They answered Joshua, saying, “All that you have commanded us we will do, and wherever you send us we will go. 17 Just as we obeyed Moses in all things, so we will obey you; only may the Lord your God be with you as He was with Moses. 18 Anyone who rebels against your [i]command and does not obey your words in all that you command him, shall be put to death; only be strong and courageous.”

Notas al pie

  1. Joshua 1:1 Or minister
  2. Joshua 1:7 Lit observe
  3. Joshua 1:7 Or act wisely
  4. Joshua 1:8 Lit observe
  5. Joshua 1:8 Or act wisely
  6. Joshua 1:12 Lit said, saying
  7. Joshua 1:15 Lit the land of your possession
  8. Joshua 1:15 Lit it
  9. Joshua 1:18 Lit mouth

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Joṣua 1

Olúwa pàṣẹ fún Joṣua

1Lẹ́yìn ikú u Mose ìránṣẹ́ Olúwa, Olúwa sọ fún Joṣua ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ ọ Mose: “Mose ìránṣẹ́ mi ti kú. Nísinsin yìí, ìwọ àti gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹ múra láti kọjá odò Jordani lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ó fi fún wọn fún àwọn ará Israẹli. Èmi yóò fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ ẹ yín tẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlérí fún Mose. Ilẹ̀ ẹ yín yóò fẹ̀ láti aginjù Lebanoni, àti láti odò ńlá, ti Eufurate—gbogbo orílẹ̀-èdè Hiti títí ó fi dé Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn. Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.

“Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le, nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn. Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, Má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ. Má ṣe jẹ́ kí Ìwé Ofin yìí kúrò ní ẹnu rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí. Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

10 Báyìí ni Joṣua pàṣẹ fún olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ 11 “Ẹ la ibùdó já, kí ẹ sì sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Ẹ pèsè oúnjẹ yín sílẹ̀. Ní ìwòyí ọ̀túnla, ẹ̀yin yóò la Jordani yìí kọjá, láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín láti ní.’ ”

12 Ṣùgbọ́n Joṣua sọ fún àwọn ará a Reubeni, àwọn ará Gadi àti fún ìdajì ẹ̀yà Manase pé, 13 “Rántí àṣẹ tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa pa fún yín: ‘Olúwa Ọlọ́run yín á fún yin ní ìsinmi, òun yóò sì fún un yín ní ilẹ̀ yìí.’ 14 Àwọn ìyàwó yín, àwọn ọmọ yín àti àwọn ẹran ọ̀sìn yín lè dúró ní ilẹ̀ tí Mose fún un yin ní ìlà-oòrùn Jordani; ṣùgbọ́n gbogbo àwọn jagunjagun un yín, pẹ̀lú ìhámọ́ra ogun gbọdọ̀ kọjá síwájú àwọn arákùnrin yín. Ẹ̀yin yóò sì rán àwọn arákùnrin yín lọ́wọ́ 15 títí Olúwa yóò fi fún wọn ní ìsinmi, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún un yín, àti títí tí àwọn pẹ̀lú yóò fi gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún wọn. Lẹ́yìn náà, ẹ̀yin lè padà sí ilẹ̀ ìní in yín, tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa fi fún un yin ní agbègbè ìlà-oòrùn ti Jordani.”

16 Nígbà náà ni wọ́n dá Joṣua lóhùn pé, “Ohunkóhun tí ìwọ pàṣẹ fún wa ni àwa yóò ṣe, ibikíbi tí ìwọ bá rán wa ni àwa yóò lọ. 17 Gẹ́gẹ́ bí àwa ti gbọ́rọ̀ sí Mose nínú ohun gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò máa gbọ́ tìrẹ. Kí Olúwa Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà pẹ̀lú u Mose. 18 Ẹnikẹ́ni tí ó bá tàpá sí ọ̀rọ̀ rẹ, tí kò sì ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ nínú ohun gbogbo tí ìwọ yóò pàṣẹ fún wọn, pípa ni a ó pa á. Kí ìwọ sá à ṣe gírí, kí ó sì mú àyà le!”