New American Standard Bible

Ephesians 1

The Blessings of Redemption

1Paul, an apostle of Christ Jesus [a]by the will of God,

To the [b]saints who are [c]at Ephesus and who are faithful in Christ Jesus: Grace to you and peace from God our Father and the Lord Jesus Christ.

Blessed be the God and Father of our Lord Jesus Christ, who has blessed us with every spiritual blessing in the heavenly places in Christ, just as He chose us in Him before the foundation of the world, that we would be holy and blameless before [d]Him. In love [e]He predestined us to adoption as sons through Jesus Christ to Himself, according to the [f]kind intention of His will, to the praise of the glory of His grace, which He freely bestowed on us in the Beloved. In [g]Him we have redemption through His blood, the forgiveness of our trespasses, according to the riches of His grace which He [h]lavished on [i]us. In all wisdom and insight He [j]made known to us the mystery of His will, according to His [k]kind intention which He purposed in Him 10 with a view to an administration [l]suitable to the fullness of the times, that is, the summing up of all things in Christ, things [m]in the heavens and things on the earth. In Him 11 [n]also we [o]have obtained an inheritance, having been predestined according to His purpose who works all things after the counsel of His will, 12 to the end that we who were the first to hope in [p]Christ would be to the praise of His glory. 13 In [q]Him, you also, after listening to the message of truth, the gospel of your salvation—having also [r]believed, you were sealed in [s]Him with the Holy Spirit of promise, 14 who is [t]given as a pledge of our inheritance, with a view to the redemption of God’s own possession, to the praise of His glory.

15 For this reason I too, having heard of the faith in the Lord Jesus which exists among you and [u]your love for all the [v]saints, 16 do not cease giving thanks for you, while making mention of you in my prayers; 17 that the God of our Lord Jesus Christ, the Father of glory, may give to you a spirit of wisdom and of revelation in the [w]knowledge of Him. 18 I pray that the eyes of your heart [x]may be enlightened, so that you will know what is the hope of His calling, what are the riches of the glory of His inheritance in the [y]saints, 19 and what is the surpassing greatness of His power toward us who believe. These are in accordance with the working of the strength of His might 20 which He brought about in Christ, when He raised Him from the dead and seated Him at His right hand in the heavenly places, 21 far above all rule and authority and power and dominion, and every name that is named, not only in this age but also in the one to come. 22 And He put all things in subjection under His feet, and gave Him as head over all things to the church, 23 which is His body, the fullness of Him who fills all in all.

Notas al pie

 1. Ephesians 1:1 Lit through
 2. Ephesians 1:1 Or holy ones
 3. Ephesians 1:1 Three early mss do not contain at Ephesus
 4. Ephesians 1:4 Or Him, in love
 5. Ephesians 1:5 Lit having predestined
 6. Ephesians 1:5 Lit good pleasure
 7. Ephesians 1:7 Lit whom
 8. Ephesians 1:8 Lit made abundant toward
 9. Ephesians 1:8 Or us, in all wisdom and insight
 10. Ephesians 1:9 Lit making known
 11. Ephesians 1:9 Lit good pleasure
 12. Ephesians 1:10 Lit of
 13. Ephesians 1:10 Lit upon
 14. Ephesians 1:11 Lit in whom also
 15. Ephesians 1:11 Or were made a heritage
 16. Ephesians 1:12 I.e. the Messiah
 17. Ephesians 1:13 Lit whom
 18. Ephesians 1:13 Or believed in Him, you were sealed
 19. Ephesians 1:13 Lit whom
 20. Ephesians 1:14 Or a down payment
 21. Ephesians 1:15 Three early mss do not contain your love
 22. Ephesians 1:15 V 1, note 2
 23. Ephesians 1:17 Or true knowledge
 24. Ephesians 1:18 Lit being
 25. Ephesians 1:18 Or holy ones

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Efesu 1

1Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run,

Sí àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní Efesu, àti sí àwọn olóòtítọ́ nínú Kristi Jesu:

Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa.

Ìbùkún ti Ẹ̀mí Mímọ́ nínú Kristi

Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kristi. Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́ Ẹni tí Ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jesu Kristi fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀ fún ìyìn ògo oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí Ó ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀: Nínú rẹ̀ ni àwa rí ìràpadà gba nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run èyí tí ó fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye, Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mí mọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bí ìdùnnú rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kristi, 10 èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ Kristi.

11 Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́yìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀, 12 kí àwa kí ó le wà fún ìyìn ògo rẹ̀, àwa tí a ti ni ìrètí ṣáájú nínú Kristi. 13 Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kristi nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìhìnrere ìgbàlà yin. Nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe èdìdì ayé yin nínú rẹ, èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀, 14 èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àṣansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ti Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀.

Ìdúpẹ́ àti àdúrà

15 Nítorí ìdí èyí, nígbà tí mo ti gbúròó ìgbàgbọ́ ti ń bẹ láàrín yín nínú Jesu Olúwa, àti ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. 16 Èmi kò sì sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, àti láti máa rántí yín nínú àdúrà mi; 17 Mo sì ń béèrè nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọgbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ ọ́n sí i. 18 Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkàn yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìrètí ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́, 19 àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀, 20 èyí tí ó fi sínú Kristi, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run. 21 Ó gbéga ju gbogbo ìjọba, àti àṣẹ, àti agbára, àti òye àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kì í ṣe ni ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́n ni èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú. 22 Ọlọ́run sì ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ, 23 èyí tí i ṣe ara rẹ̀, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹni tí ó kún ohun gbogbo ní gbogbo ọ̀nà.