New American Standard Bible

Acts 1

Introduction

1The first account I [a]composed, Theophilus, about all that Jesus began to do and teach, until the day when He was taken up to heaven, after He had [b]by the Holy Spirit given orders to the apostles whom He had chosen. To [c]these He also presented Himself alive after His suffering, by many convincing proofs, appearing to them over a period of forty days and speaking of the things concerning the kingdom of God. [d]Gathering them together, He commanded them not to leave Jerusalem, but to wait for [e]what the Father had promised, “Which,” He said, “you heard of from Me; for John baptized with water, but you will be baptized [f]with the Holy Spirit [g]not many days from now.”

So when they had come together, they were asking Him, saying, “Lord, is it at this time You are restoring the kingdom to Israel?” He said to them, “It is not for you to know times or epochs which the Father has fixed by His own authority; but you will receive power when the Holy Spirit has come upon you; and you shall be My witnesses both in Jerusalem, and in all Judea and Samaria, and even to the remotest part of the earth.”

The Ascension

And after He had said these things, He was lifted up while they were looking on, and a cloud received Him out of their sight. 10 And as they were gazing intently into [h]the sky while He was going, behold, two men in white clothing stood beside them. 11 They also said, “Men of Galilee, why do you stand looking into [i]the sky? This Jesus, who has been taken up from you into heaven, will come in just the same way as you have watched Him go into heaven.”

The Upper Room

12 Then they returned to Jerusalem from the [j]mount called [k]Olivet, which is near Jerusalem, a [l]Sabbath day’s journey away. 13 When they had entered the city, they went up to the upper room where they were staying; that is, Peter and John and [m]James and Andrew, Philip and Thomas, Bartholomew and Matthew, [n]James the son of Alphaeus, and Simon the Zealot, and Judas the [o]son of [p]James. 14 These all with one mind were continually devoting themselves to prayer, along with the women, and Mary the mother of Jesus, and with His brothers.

15 [q]At this time Peter stood up in the midst of the brethren (a gathering of about one hundred and twenty [r]persons was there together), and said, 16 “Brethren, the Scripture had to be fulfilled, which the Holy Spirit foretold by the mouth of David concerning Judas, who became a guide to those who arrested Jesus. 17 For he was counted among us and received his share in this ministry.” 18 (Now this man acquired a field with the price of his wickedness, and falling headlong, he burst open in the middle and all his intestines gushed out. 19 And it became known to all who were living in Jerusalem; so that in their own language that field was called Hakeldama, that is, Field of Blood.) 20 “For it is written in the book of Psalms,

Let his homestead be made desolate,
And let no one dwell in it’;

and,

Let another man take his [s]office.’

21 Therefore it is necessary that of the men who have accompanied us all the time that the Lord Jesus went in and out [t]among us— 22 beginning [u]with the baptism of John until the day that He was taken up from us—one of these must become a witness with us of His resurrection.” 23 So they put forward two men, Joseph called Barsabbas (who was also called Justus), and Matthias. 24 And they prayed and said, “You, Lord, who know the hearts of all men, show which one of these two You have chosen 25 to [v]occupy this ministry and apostleship from which Judas turned aside to go to his own place.” 26 And they [w]drew lots for them, and the lot fell [x]to Matthias; and he was [y]added to the eleven apostles.

Notas al pie

 1. Acts 1:1 Lit made
 2. Acts 1:2 Or through
 3. Acts 1:3 Lit whom
 4. Acts 1:4 Or eating with; or lodging with
 5. Acts 1:4 Lit the promise of the Father
 6. Acts 1:5 Or in
 7. Acts 1:5 Lit not long after these many days
 8. Acts 1:10 Or heaven
 9. Acts 1:11 Or heaven
 10. Acts 1:12 Or hill
 11. Acts 1:12 Or Olive Grove
 12. Acts 1:12 I.e. 2K cubits, or approx 3/5 mile
 13. Acts 1:13 Or Jacob
 14. Acts 1:13 Or Jacob
 15. Acts 1:13 Or brother
 16. Acts 1:13 Or Jacob
 17. Acts 1:15 Lit In these days
 18. Acts 1:15 Lit names
 19. Acts 1:20 Lit position as overseer
 20. Acts 1:21 Lit to us
 21. Acts 1:22 Lit from
 22. Acts 1:25 Lit take the place of
 23. Acts 1:26 Lit gave
 24. Acts 1:26 Or upon
 25. Acts 1:26 Lit voted together with

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìṣe àwọn Aposteli 1

A mú Jesu lọ sí ọ̀run

1Nínú ìwé mi ìṣáájú, Teofilu, ni mo ti kọ ní ti ohun gbogbo tí Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àti kọ́ títí ó fi di ọjọ́ tí a gbà á lọ sókè ọ̀run, lẹ́yìn tí ó ti ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ pàṣẹ fún àwọn aposteli tí ó yàn Lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀, ó fi ara rẹ̀ hàn fún wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí tí ó dájú pé òun wà láààyè. Ó fi ara hàn wọ́n fún ogójì ọjọ́, ó sì sọ̀rọ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Ní àkókò kan bí ó sì ti ń jẹun pẹ̀lú wọn, ó pàṣẹ yìí fún wọn: “Ẹ má ṣe kúrò ní Jerusalẹmu, ṣùgbọ́n ẹ dúró de ìlérí tí Baba mi ṣe ìlérí, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ lẹ́nu mi. Nítorí Johanu fi omi bamitiisi yín, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ díẹ̀ sí i, a o fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.”

Nítorí náà, nígbà tí wọ́n sì péjọpọ̀, wọn bi í léèrè pé, “Olúwa, láti ìgbà yí lọ ìwọ yóò ha mú ìjọba padà fún Israẹli bí?”

Ó sì wí fún wọn pé, “Kì í ṣe tiyín ni láti mọ àkókò tàbí ìgbà tí Baba ti yàn nípa àṣẹ òun tìkára rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé e yín: ẹ̀yin yóò sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerusalẹmu, àti ní gbogbo Judea, àti ní Samaria, àti títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”

Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, a gbà á sókè lójú wọn; ìkùùkuu àwọsánmọ̀ sì gbà á kúrò lójú wọn.

10 Bí wọ́n sì ti tẹjúmọ́ ojú ọ̀run bí ó ti ń lọ sókè, lójijì, àwọn ọkùnrin méjì tí ó wọ aṣọ funfun dúró létí ọ̀dọ̀ wọn. 11 Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀yin ara Galili, èéṣe tí ẹ̀yin fi dúró tí ẹ̀ ń wo ojú ọ̀run? Jesu yìí, tí a gbà sókè ọ̀run kúrò lọ́wọ́ yín, yóò padà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí tí ó ń lọ sì ọ̀run.”

A yan Mattia Rọ́pò Judasi

12 Lẹ́yìn náà ni wọ́n padà sí Jerusalẹmu láti orí òkè ti a ń pè ni olifi, tí ó tó ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ ìsinmi kan. 13 Nígbà tí wọn sì wọlé, wọn lọ sí iyàrá òkè, níbi tí wọ́n ń gbé. Àwọn tó wà níbẹ̀ ni:

Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu;

Filipi àti Tomasi;

Bartolomeu àti Matiu;

Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni Sealoti, àti Judasi arákùnrin Jakọbu.

14 Gbogbo àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn obìnrin àti Maria ìyá Jesu àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ọkàn kan dúró láti máa gbàdúrà.

15 Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni Peteru sí dìde dúró láàrín àwọn ọmọ-ẹ̀yìn (iye àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́ ọgọ́fà) 16 ó wí pé, “Ẹ̀yin ará, ìwé mímọ́ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ, èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu Dafidi nípa Judasi, tí ó ṣe atọ́nà fún àwọn tí ó mú Jesu: 17 Nítorí ọ̀kan nínú wa ni òun ń ṣe tẹ́lẹ̀, òun sì ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí.”

18 (Judasi fi èrè àìṣòótọ́ rẹ̀ ra ilẹ̀ kan; nígbà tí ó sì ṣubú ni ògèdèǹgbé, ó bẹ́ ní agbede-méjì, gbogbo ìfun rẹ̀ sì tú jáde. 19 Ó si di mí mọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń gbé Jerusalẹmu; nítorí náà ni wọ́n fi ń pè ilẹ̀ náà ni Alkedama ní èdè wọn, èyí sì ni, Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.)

20 Peteru sì wí pé, “Nítorí a ti kọ ọ́ nípa rẹ̀ nínú Ìwé Saamu pé,

“ ‘Jẹ́ ki ibùgbé rẹ̀ di ahoro,
    kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé inú rẹ̀,’

àti,

“ ‘Ipò rẹ̀ ni kí ẹlòmíràn kí ó gbà.’

21 Nítorí náà, ó di dandan láti yan ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti ń bá wa rìn ni gbogbo àkókò tí Jesu Olúwa ń wọlé, tí ó sì jáde láàrín wa. 22 Bẹ́ẹ̀ láti ìgbà bamitiisi Johanu títí ó fi di ọjọ́ náà ti a gbe é lọ sókè kúrò lọ́dọ̀ wa. Ó yẹ kí ọ̀kan nínú àwọn wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́rìí àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú wa.”

23 Wọn sì yan àwọn méjì, Josẹfu tí a ń pè ní Barsaba, (ẹni tí a sọ àpèlé rẹ̀ ni Justu) àti Mattia. 24 Wọn sì gbàdúrà, wọn sì wí pé, “Olúwa, ìwọ mọ ọkàn gbogbo ènìyàn, fihàn wá nínú àwọn méjì yìí, èwo ni ìwọ yàn 25 kí ó lè gba ipò nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ aposteli yìí, èyí tí Judasi kúrò nínú rẹ̀, ki òun kí ó lè lọ sí ipò ti ara rẹ̀.” 26 Wọ́n sì dìbò fún wọn; ìbò sí mú Mattia; a sì kà á mọ́ àwọn aposteli mọ́kànlá.