출애굽기 30 – KLB & YCB

Korean Living Bible

출애굽기 30:1-38

향단

1“너는 아카시아나무로 분향할 단을 만들어라.

2그것은 가로 세로를 각각 45센티미터로 하여 네모 반듯하게 하고 높이는 90센티미터로 하며 단 네 모퉁이에는 뿔이 나오도록 만들어야 한다.

3그리고 너는 그 단의 윗면과 전후 좌우 면과 뿔을 순금으로 싸고 30:3 또는 ‘주위에’윗 가장자리에 금테를 둘러라.

4금테 아래 양쪽에는 운반채를 꿸 금고리 두 개씩을 만들어 달고

5아카시아나무로 운반채를 만들어 금으로 싸라.

6그러고서 너는 십계명을 넣어 둔 30:6 또는 ‘언약궤’법궤 위, 곧 내가 너를 만날 속죄소를 가리는 바로 그 휘장 밖에 이 향단을 갖다 놓아라.

7아론은 매일 아침 등을 손질할 때 이 단에 향기로운 향을 피워야 하며

8또 저녁에 등불을 켤 때도 이 향을 피워야 한다. 이와 같이 너희는 나 여호와 앞에서 향을 피우는 일을 대대로 계속하라.

9그리고 이 향단에는 내가 지정하지 않은 다른 향을 피워서는 안 되며 그 위에 동물이나 곡식이나 포도주를 제물로 바쳐서도 안 된다.

10아론은 일 년에 한 번씩 속죄제물의 피를 향단 네 뿔에 발라 이 단을 정결하게 해야 한다. 이 향단은 나 여호와에게 아주 거룩한 것이다. 향단을 정결하게 하는 일을 대대로 계속하여라.”

생명의 값

11여호와께서 모세에게 말씀하셨다.

12“너는 이스라엘 백성의 인구를 조사할 때 각자 자기 생명의 값을 나 여호와에게 바치게 하라. 그러면 네가 인구 조사를 할 때 그들에게 재앙이 미치지 않을 것이다.

13인구 조사를 받는 사람은 은 30:13 히 ‘성소의 세겔대로 반 세겔’약 6그램을 나 여호와에게 바치게 하라.

1420세 이상 인구 조사를 받는 사람은 모두 이 돈을 바쳐야 한다.

15너희가 이 생명의 값을 나 여호와에게 바칠 때에는 부자라고 해서 더 많이 내거나 가난한 사람이라고 해서 덜 내는 일이 없도록 하라.

16너는 이스라엘 백성에게서 이 돈을 받아 성막 비용으로 사용하여라. 나 여호와가 이것을 너희 생명의 값으로 여기고 너희를 기억하여 지켜 주겠다.”

놋으로 만든 물통

17여호와께서 모세에게 말씀하셨다.

18“너는 놋으로 넓적한 물통과 그 받침을 만들어 성막과 단 사이에 두고 거기에 물을 채워라.

19-20아론과 그의 아들들은 성막에 들어갈 때나 단에 가까이 가서 나 여호와에게 불로 제물을 태워 바치기 전에 이 물로 반드시 손발을 씻어야 한다.

21이와 같이 그들이 손발을 씻어야 죽지 않을 것이다. 이것은 그들과 그 후손들이 대대로 지켜야 할 규정이다.”

거룩한 기름

22여호와께서 다시 이렇게 말씀하셨다.

23“너는 제일 좋은 향품, 곧 순수한 몰약 30:23 히 ‘500세겔’ 약 6킬로그램, 향기로운 육계 30:23 히 ‘250세겔’약 3킬로그램, 향기로운 창포 약 3킬로그램,

24계피 약 6킬로그램, 그리고 감람기름 30:24 히 ‘한 힌’약 4리터를 구하여

25향을 만드는 방법으로 이 모든 것을 섞어 향기로운 거룩한 기름을 만들어라.

26그런 다음 너는 이 기름을 성막, 법궤,

27상과 그 모든 기구, 등대와 그 모든 기구, 향단,

28번제단과 그 모든 기구, 그리고 넓적한 물통과 그 받침에 발라

29그 모든 것을 아주 거룩한 것으로 구별하여라. 이것에 접촉하는 사람이나 물건이 다 거룩해질 것이다.

30그리고 아론과 그의 아들들에게 이 기름을 발라 그들을 거룩하게 하여 제사장으로서 나를 섬기게 하라.

31너는 또 이스라엘 백성에게 나 여호와의 말을 이렇게 전하여라. ‘이것은 너희가 나를 섬기는 데 대대로 사용해야 할 거룩한 기름이다.

32너희는 이것을 제사장이 아닌 다른 사람의 몸에 부어서는 안 되며 또 이 기름의 제조법대로 이와 같은 것을 만들어서도 안 된다. 이것은 거룩한 것이니 너희가 거룩하게 여겨라.

33이와 같은 것을 만들거나 이 기름을 제사장이 아닌 다른 사람에게 붓는 자는 누구든지 자기 백성 가운데서 제거될 것이다.’ ”

34그런 다음 여호와께서 모세에게 또 말씀하셨다. “너는 30:34 또는 ‘소합향과 나감향과 풍자향’몰약과 섭조개 가루와 페르시아 수지와 순수한 유향을 똑같은 중량으로 섞어

35향수를 만드는 방법으로 향을 만들고 거기에 소금을 쳐서 깨끗하고 거룩하게 하여라.

36그리고 너는 그 향 얼마를 빻아 곱게 가루를 만들어 내가 너와 만날 성막 안 법궤 앞에 두어라. 이것은 너희에게 아주 거룩한 것이다.

37너희는 이런 제조법으로 너희를 위해 향을 만들지 말고 그것을 나에게 바쳐진 거룩한 것으로 여겨라.

38이 향의 냄새를 맡으려고 이와 같은 것을 만드는 자는 누구든지 자기 백성 가운데서 제거될 것이다.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 30:1-38

Pẹpẹ tùràrí

130.1-5: Ek 37.25-29.“Ìwọ yóò sì ṣe pẹpẹ igi kasia kan; máa jó tùràrí lórí rẹ̀. 2Kí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé, kí ó jẹ́ ìdajì mítà ní gígùn, ìdajì mítà ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ méjì ni gíga rẹ̀—kí ìwo rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. 3Ìwọ yóò sì bo òkè rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀ pẹ̀lú u kìkì wúrà, ìwọ yóò sì ṣe wúrà gbà á yíká. 4Ìwọ yóò sì ṣe òrùka wúrà méjì fún pẹpẹ náà níṣàlẹ̀ ìgbátí méjèèjì ní òdìkejì ìhà rẹ̀—láti gbá àwọn òpó rẹ̀ mú, láti lè máa fi gbé e. 5Ìwọ yóò sì ṣe òpó igi kasia, ìwọ yóò sì bọ́ wọ́n pẹ̀lú wúrà. 6Ìwọ yóò gbé pẹpẹ náà sí iwájú aṣọ ìkélé, èyí tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí níwájú ìtẹ́ àánú èyí tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí níbi ti èmi yóò ti máa bá ọ pàdé.

7“Aaroni yóò sì máa jó tùràrí dídùn lórí pẹpẹ náà ní àràárọ̀, nígbà tí ó tún àwọn fìtílà náà ṣe. 8Aaroni yóò sì tún jó tùràrí nígbà tí ó bá tan fìtílà ní àṣálẹ́, bẹ́ẹ̀ ní tùràrí yóò máa jó títí láé níwájú Olúwa fún àwọn ìran tó ń bọ̀. 9Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mú àjèjì tùràrí wá sórí pẹpẹ yìí tàbí ẹbọ sísun kankan tàbí ọrẹ oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ da ẹbọ ohun mímu sórí i rẹ̀. 10Aaroni yóò sì máa ṣe ètùtù sórí àwọn ìwo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún. Òun yóò sì máa ṣe ètùtù ọdọọdún yìí pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ètùtù fún ìran tó ń bọ̀. Mímọ́ jùlọ ni sí Olúwa.”

Ètùtù owó

1130.11-16: Ek 38.25,26.Nígbà náà ni Olúwa wí fún Mose pé, 12“Nígbà tí ìwọ bá ka iye àwọn ọmọ Israẹli láti mọ iye wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gbọdọ̀ mú ìràpadà ọkàn rẹ̀ wá fún Olúwa ní ìgbà tí o bá ka iye wọn. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-ààrùn kì yóò súnmọ́ wọn, nígbà tí o bá ń ka iye wọn. 13Olúkúlùkù ẹrù tí ó bá kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn tí a ti kà yóò san ìdajì ṣékélì, gẹ́gẹ́ bí ṣékélì ibi mímọ́, èyí tí ó wọn ogún gera. Ìdajì ṣékélì yìí ní ọrẹ fún Olúwa. 14Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá sínú àwọn tí a kà láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni yóò fi ọrẹ fún Olúwa. 15Àwọn olówó kì yóò san ju ìdajì ṣékélì lọ, àwọn tálákà kò sì gbọdọ̀ dín ní ìdajì ṣékélì nígbà tí ẹ̀yin bá mú ọrẹ wá fún Olúwa láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín. 16Ìwọ yóò sì gba owó ètùtù náà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, ìwọ yóò sì fi lélẹ̀ fún ìsìn àgọ́ àjọ. Yóò jẹ́ ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli níwájú Olúwa, láti ṣe ètùtù fún ọkàn yín.”

Agbada fún wíwẹ̀

17Nígbà náà ni Olúwa wí fún Mose pé, 1830.18: Ek 38.8.“Ìwọ yóò sì ṣe agbada idẹ kan, àti ẹsẹ̀ rẹ̀ idẹ, fún wíwẹ̀. Ìwọ yóò sì gbé e sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì pọn omi sínú rẹ̀. 19Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn pẹ̀lú omi tí ó wà nínú rẹ̀. 20Nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ inú àgọ́ àjọ, wọ́n yóò wẹ̀ pẹ̀lú omi nítorí kí wọ́n má ba à kú. Bákan náà, nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi pẹpẹ láti ṣe ìsìn, láti mú ẹbọ ti a fi iná sun wá fún Olúwa, 21wọn yóò sì wẹ ọwọ́ wọn àti ẹsẹ̀ wọn, nítorí kí wọn máa ba à kú. Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún Aaroni àti irú àwọn ọmọ rẹ̀ fún ìrandíran wọn.”

Òróró ìyàsímímọ́

2230.22-33: Ek 37.29.Olúwa sọ fún Mose pé, 23Ìwọ yóò mú ààyò tùràrí olóòórùn sí ọ̀dọ̀ rẹ; ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ṣékélì (kílógírámù mẹ́fà) tí òjìá ṣíṣàn, ìdajì bí ó bá yẹ àádọ́tà-lé-nígba (250) ṣékélì tí kinamoni dídùn, àti kénì dídùn àádọ́tà-lé-nígba (250) ṣékélì, 24kasia ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) ṣékélì—gbogbo rẹ̀ ní ìlànà ṣékélì ibi mímọ́ àti hínì òróró olifi kan (lítà mẹ́rin). 25Ṣe ìwọ̀nyí ní òróró mímọ́ ìkunra, tí a pò gẹ́gẹ́ bí olùṣe òórùn dídùn tì í ṣe, Yóò jẹ òróró mímọ́ ìtasórí. 26Ìwọ yóò sì lò ó láti ya àgọ́ sí mímọ́ àti àpótí ẹ̀rí náà, 27tábìlì àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà àti ohun èlò rẹ̀, àti pẹpẹ tùràrí, 28pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀. 29Ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohunkóhun tí ó bá fi ọwọ́ kàn wọn yóò di mímọ́.

30“Ìwọ yóò sì ta òróró sí orí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè sìn mí bí àlùfáà. 31Ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Èyí ni yóò ṣe òróró mímọ́ ìtasórí mi fún ìrandíran tó ń bọ̀. 32Má ṣe dà á sí ara ènìyàn kí o má sì ṣe ṣe òróró kankan ni irú rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ̀yin sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́. 33Ẹnikẹ́ni tí ó bá po irú rẹ̀, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá fi sára àlejò yàtọ̀ sí àlùfáà, a ó gé e kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ”

Tùràrí

34Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú tùràrí olóòórùn dídùn sọ́dọ̀ rẹ, onika, àti galibanumu àti kìkì tùràrí dáradára, òṣùwọ̀n kan fún gbogbo rẹ, 35ṣe tùràrí olóòórùn dídùn tí a pò, iṣẹ́ àwọn olóòórùn, tí ó ní iyọ̀, ó dára, ó sì jẹ́ mímọ́. 36Ìwọ yóò sì lọ díẹ̀ nínú rẹ̀ kúnná, ìwọ yóò sì gbé e síwájú ẹ̀rí ní àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti pàdé yín. Yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ fún yín. 37Ẹ má ṣe ṣe tùràrí kankan ní irú èyí fúnrayín; ẹ kà á ní mímọ́ sí Olúwa. 38Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe irú rẹ̀ láti máa gbádùn òórùn rẹ̀, òun ni a ó gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”