이사야 63 – KLB & YCB

Korean Living Bible

이사야 63:1-19

심판하시고 구원하시는 하나님

1에돔의 보스라성에서 오는 자가 누구냐? 화려하게 붉은 옷을 입고 63:1 또는 ‘큰 능력으로’위 풍 당당하게 걸어오는 자가 누구냐? “그는 의를 말하며 구원할 능력을 가진 나 여호와이다.”

2어째서 네 옷이 포도즙틀을 밟는 사람처럼 붉은가?

3“내가 분노하여 포도즙틀을 밟듯이 내 원수들을 혼자서 짓밟았는데 그들의 피가 튀어 내 옷을 더럽혔다.

4내가 내 백성의 원수를 갚아 그들을 구할 때가 되었으나

5내가 보니 나를 도와주는 자가 아무도 없어 놀라지 않을 수 없었다. 그래서 내가 분노하여 혼자 심판을 단행하였으니

6내가 분노로 이방 나라들을 마구 짓밟아 부수고 그들의 피를 땅에 쏟아 버렸다.”

찬양과 기도

7내가 여호와의 한결같은 사랑을 말하고 우리를 위해 행하신 모든 일에 대하여 그를 찬양할 것이니 여호와께서는 그의 자비와 한결같은 사랑으로 이스라엘 백성에게 풍성한 은혜를 베푸셨다.

8여호와께서 “그들은 내 백성이며 거짓말을 하지 않는 자녀” 라 하시고 그들의 구원자가 되셨으며

9그들의 모든 환난에 동참하셔서 그들을 직접 구원하셨다. 그가 사랑과 자비로 그들을 구출해 내시고 그들을 항상 돌보셨으나

10그들이 여호와를 거역하고 그의 성령을 근심하게 하였다. 그래서 그가 그들의 대적이 되어 그들과 싸우셨다.

11그때 백성들이 옛날 모세 때의 일을 기억하며 이렇게 말하였다. “바다에서 자기 백성의 지도자들을 구원하신 분이 어디 계시는가? 그들 가운데 성령을 보내신 분이 지금 어디 계시는가?

12-13모세를 통하여 그의 크신 능력으로 위 대한 일을 행하시며 바닷물을 갈라 자기 백성을 깊은 물 가운데로 인도해 내셔서 영구한 명성을 얻으신 분이 어디 계시는가?” 그들은 여호와의 인도를 받아 광야를 누비는 말처럼 넘어지지 않고 안전하게 깊은 물을 건넜다.

14여호와의 성령께서 비옥한 골짜기로 내려가는 가축처럼 그들을 편히 쉬게 하셨다. 이와 같이 여호와께서는 자기 백성을 인도하여 자기 이름을 영화롭게 하셨다.

15여호와여, 하늘에서 굽어살피시며 거룩하고 영광스러운 주의 처소에서 우리를 보소서. 전에 우리에게 보여 주신 주의 크신 관심은 어디 있습니까? 이제 주의 능력은 어디 있으며 주의 사랑과 자비는 어디 있습니까? 제발 우리를 외면하지 마소서.

16주는 우리의 아버지이십니다. 우리의 조상 아브라함과 야곱은 우리를 인정하지 않을지라도 주는 항상 우리를 구원하시는 우리의 아버지가 아니십니까?

17여호와여, 어째서 우리가 주의 길에서 떠나 우리 마음을 굳게 하여 주를 두려운 마음으로 섬길 수 없게 하십니까? 항상 주를 섬기는 주의 종들을 위해 돌아오소서.

18주의 백성들이 주의 성소를 차지한 지 얼마 되지 않아 우리 원수들이 그 곳을 짓밟아 버렸습니다.

19주는 마치 우리를 다스리시는 분이 아닌 것처럼, 또 우리가 주의 백성이 아닌 것처럼 우리를 취급하십니다.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 63:1-19

Ọjọ́ ẹ̀san àti ìràpadà Ọlọ́run

163.1-6: Isa 34; Jr 49.7-22; El 25.12-14; 35; Am 1.11-12; Ọd; Ml 1.2-5.Ta nì eléyìí tí ó Edomu wá,

ti òun ti aṣọ àrẹpọ́n láti Bosra wá?

Ta nì eléyìí, tí ó ní ògo nínú aṣọ rẹ̀,

tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀?

“Èmi ni ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodo

tí ó ní ipa láti gbàlà.”

2Èéṣe tí aṣọ yín fi pupa

gẹ́gẹ́ bí i tàwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfúntí?

363.3: If 19.15.“Èmi nìkan ti dá tẹ ìfúntí wáìnì;

láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹnikẹ́ni kò sì wà pẹ̀lú mi.

Mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìbínú mi

mo sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ìrunú mi

ẹ̀jẹ̀ wọn sì fọ́n sí aṣọ mi,

mo sì da àbàwọ́n sí gbogbo aṣọ mi.

4Nítorí ọjọ́ ẹ̀san wà ní ọkàn mi

àti pé ọdún ìràpadà mi ti dé

5Mo wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti ṣe ìrànwọ́.

Àyà fò mí pé ẹnikẹ́ni kò ṣèrànwọ́;

nítorí náà apá mi ni ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún mi

àti ìrunú mi ni ó gbé mi ró.

6Mo tẹ orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi;

nínú ìrunú mi mo jẹ́ kí wọ́n mu

mo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ lórí erùpẹ̀.”

Ìyìn àti àdúrà

7Èmi yóò sọ nípa àánú Olúwa

ìṣe rẹ gbogbo tí ó yẹ kí a yìn ín fún,

gẹ́gẹ́ bí ohun tí Olúwa ti ṣe fún wa

bẹ́ẹ̀ ni, ohun rere gbogbo tí ó ti ṣe

fún ilé Israẹli

gẹ́gẹ́ bí àánú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore rẹ̀.

8Ó wí pé, “Lóòtítọ́ ènìyàn mi ni wọ́n,

àwọn ọmọ tí kì yóò jẹ́ òpùrọ́ fún mi”;

bẹ́ẹ̀ ni, ó sì di Olùgbàlà wọn.

9Nínú gbogbo ìpọ́njú wọn, inú òun pẹ̀lú bàjẹ́

àti angẹli tí ó wà níwájú rẹ̀ gbà wọ́n là.

Nínú ìfẹ́ àti àánú rẹ̀, ó rà wọ́n padà;

ó gbé wọn sókè ó sì pọ̀n wọ́n

ní gbogbo ọjọ́ ìgbà n nì.

10Síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ṣọ̀tẹ̀

wọ́n sì ba Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ nínú jẹ́.

Bẹ́ẹ̀ ni ó yípadà ó sì di ọ̀tá wọn

òun tìkára rẹ̀ sì bá wọn jà.

1163.11: Hb 13.20.Lẹ́yìn náà ni àwọn ènìyàn rẹ̀ rántí ọjọ́ ìgbà n nì,

àwọn ọjọ́ Mose àti àwọn ènìyàn rẹ̀

níbo ni ẹni náà wà tí ó mú wọn la Òkun já,

pẹ̀lú olùṣọ́-àgùntàn agbo ẹran rẹ̀?

Níbo ni ẹni náà wà tí ó rán

Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrín wọn,

12ta ni ó rán apá ògo ti agbára rẹ̀

láti wà ní apá ọ̀tún Mose,

ta ni ó pín omi ní yà níwájú wọn,

láti gba òkìkí ayérayé fún ara rẹ̀,

13ta ni ó síwájú wọn la àwọn ọ̀gbun nì já?

Gẹ́gẹ́ bí ẹṣin ni gbangba ìlú wọn tí kò sì kọsẹ̀;

14gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ ẹran tí ó lọ sí pápá oko,

a fún wọn ní ìsinmi láti ọwọ́ Ẹ̀mí Olúwa.

Báyìí ni ẹ ṣe tọ́ àwọn ènìyàn yín

láti fún ara yín ní orúkọ kan tí ó lógo.

15Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì rí i

láti ìtẹ́ ògo rẹ, mímọ́ àti ológo.

Níbo ni ìtara àti agbára rẹ wà?

Ìwà jẹ́ẹ́jẹ́ rẹ àti àánú rẹ ni a

ti mú kúrò níwájú wa.

16Ṣùgbọ́n ìwọ ni baba wa,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Abrahamu kò mọ̀ wá

tàbí Israẹli mọ ẹni tí à á ṣe;

ìwọ, Olúwa ni Baba wa,

Olùràpadà wa láti ìgbà n nì ni orúkọ rẹ.

17Èéṣe Olúwa tí o fi jẹ́ kí a ṣáko kúrò ní ojú ọ̀nà rẹ

tí o sì ṣé àyà wa le tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi bọ̀wọ̀ fún ọ?

Padà nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ,

àwọn ẹ̀yà tí ṣe ogún ìní rẹ.

18Fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ fi gba ibi mímọ́ rẹ,

ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwọn ọ̀tá wa ti tẹ ibi mímọ́ rẹ mọ́lẹ̀.

19Àwa jẹ́ tìrẹ láti ìgbà n nì;

ṣùgbọ́n ìwọ kò tí ì jẹ ọba lé wọn lórí,

a kò sì tí ì pè wọ́n mọ́ orúkọ rẹ.