열왕기하 2 – KLB & YCB

Korean Living Bible

열왕기하 2:1-25

엘리야의 승천

1여호와께서 회오리바람으로 엘리야를 하늘로 끌어올리실 때가 되었을 때 엘 리야와 엘리사는 길갈에서 나와 길을 가고 있었다.

2그때 엘리야가 엘리사에게 “너는 여기 머물러 있거라. 여호와께서 나에게 벧엘로 가라고 명령하셨다” 하자 엘리사는 “내가 여호와의 이름으로 맹세하지만 선생님이 살아 계시는 한 나는 선생님을 떠나지 않겠습니다” 하고 대답하였다. 그래서 그들은 벧엘로 함께 내려갔다.

3그 곳에 있는 예언자의 생도들이 엘리사에게 와서 물었다. “당신은 여호와께서 오늘 당신의 선생님을 당신에게서 데려가실 줄을 아십니까?” 그러자 엘리사는 “나도 알고 있네. 조용히 하게” 하였다.

4그때 엘리야가 엘리사에게 “이제 너는 여기 머물러 있거라. 여호와께서 나에게 여리고로 가라고 명령하셨다” 하자 엘리사는 “내가 여호와의 이름으로 맹세하지만 선생님이 살아 계시는 한 나는 선생님을 떠나지 않겠습니다” 하고 대답하였다. 그래서 그들은 여리고로 함께 내려갔다.

5그 곳에 있는 예언자의 생도들도 엘리사에게 와서 물었다. “당신은 여호와께서 오늘 당신의 선생님을 당신에게서 데려가실 줄을 아십니까?” 그러자 엘리사는 “나도 알고 있네. 조용히 하게” 하였다.

6그때 엘리야가 엘리사에게 “여호와께서 나에게 요단강으로 가라고 명령하셨다. 제발 너는 여기 머물러 있거라” 하였으나 엘리사는 전과 마찬가지로 “내가 여호와의 이름으로 맹세하지만 선생님이 살아 계시는 한 나는 선생님을 떠나지 않겠습니다” 하고 대답하였다. 그래서 그들은 요단강으로 함께 갔다.

7예언자의 생도 50명이 멀리서 지켜 보는 가운데 그들 두 사람은 요단 강가에 멈춰 섰다.

8그때 엘리야가 자기 겉옷을 벗어 말아 가지고 그것으로 물을 치자 물이 좌우로 갈라졌다. 그래서 두 사람은 마른 땅을 밟고 건너갔다.

9그들이 강 저편에 이르렀을 때 엘리야가 엘리사에게 물었다. “내가 네 곁을 떠나기 전에 너에게 무엇을 해 주었으면 좋겠는지 말해 보아라.” “선생님의 2:9 또는 ‘영감’영적 능력을 내가 두 배로 받게 해 주십시오.”

10“네가 정말 어려운 것을 요구하는구나. 그러나 내가 네 곁에서 사라지는 것을 네가 보면 네 소원이 이루어질 것이다. 하지만 네가 그것을 보지 못하면 네 소원은 이루어지지 않을 것이다.”

11이렇게 그들이 말을 주고받으며 걸어가고 있었는데 갑자기 불말들이 끄는 불수레 하나가 나타나 그들 사이를 지나가며 두 사람을 갈라 놓았다. 그러자 2:11 암시됨.순식간에 엘리야가 회오리바람을 타고 하늘로 올라가 버렸다.

12엘리사는 이 광경을 보고 “나의 아버지여! 나의 아버지여! 이스라엘의 전차와 마병이여!” 하고 외쳤다. 엘리야가 사라지고 다시 보이지 않자 엘리사는 슬퍼서 자기 옷을 잡아 둘로 찢고

13엘리야의 몸에서 떨어진 겉옷을 주워 가지고 요단강으로 돌아왔다. 그는 강둑에 서서

14그 겉옷으로 강물을 내리치며 “엘리야의 하나님 여호와는 어디 계십니까?” 하고 외쳤다. 그러자 강물이 좌우로 갈라져 엘리사는 강을 건넜다.

15이때 여리고에서 온 예언자의 생도들이 엘리사가 행한 일을 보고 “엘리야의 영이 엘리사에게 내렸다!” 하고 외쳤다. 그러고서 그들은 엘리사에게 가서 그를 영접하며 그 앞에 엎드려

16이렇게 말하였다. “여기 건장한 사람 50명이 있습니다. 말씀만 하십시오. 우리가 가서 당신의 선생님을 찾아보도록 하겠습니다. 여호와의 성령께서 그를 들어다가 어느 산이나 계곡에 던지셨을지도 모릅니다.” 그때 엘리사가 “아니다. 그럴 필요가 없다” 하였으나

17그들이 끝까지 고집하므로 하는 수 없이 그들을 보내 주었다. 50명의 그 예언자 생도들은 3일 동안 엘리야를 찾아다녔으나 그를 발견하지 못하고

18여리고에 머물러 있는 엘리사에게 돌아왔다. 그래서 엘리사는 그들에게 “내가 가지 말라고 하지 않았느냐?” 하고 꾸짖었다.

엘리사의 기적

19몇몇 여리고 사람들이 엘리사에게 와서 이렇게 말하였다. “선생님도 보셔서 아시겠지만 이 성은 아름다운 곳에 위치해 있으나 물이 좋지 못하므로 농작물이 제대로 열매를 맺지 못합니다.”

20그래서 엘리사는 새 그릇에 소금을 가득 담아 오게 한 다음

21그것을 가지고 샘으로 가서 물에 소금을 뿌리며 외쳤다. “이것은 여호와의 말씀이다. ‘내가 이 물을 고쳤으니 다시는 이 물을 먹고 사람이 죽거나 농산물이 열매를 맺지 못하는 일이 없을 것이다!’ ”

22그러자 그 물은 엘리사의 말대로 좋은 물이 되어 오늘날까지도 맑고 깨끗하다.

23그 후에 엘리사는 여리고를 떠나 벧엘로 올라갔는데 가는 도중에 성에서 아이들이 나와 그를 조롱하며 “대머리야, 꺼져라! 대머리야, 꺼져라!” 하고 소리를 질러댔다.

24이때 엘리사가 돌아서서 그들을 보고 여호와의 이름으로 저주하자 숲속에서 암곰 두 마리가 나와 아이들 42명을 찢어 죽였다.

25그런 다음 엘리사는 갈멜산으로 갔다가 후에 사마리아로 돌아갔다.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 2:1-25

Elijah gun kẹ̀kẹ́ iná lọ sí ọ̀run

1Nígbà tí Ọlọ́run ń fẹ́ gbé Elijah lọ sí òkè ọ̀run nínú àjà, Elijah àti Eliṣa wà ní ọ̀nà láti Gilgali. 2Elijah wí fún Eliṣa pé, “Dúró níbí; Olúwa rán mi lọ sí Beteli.”

Ṣùgbọ́n Eliṣa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé Olúwa wà láyé àti gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, Èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Beteli.

3Àwọn ọmọ wòlíì ní Beteli jáde wá sí ọ̀dọ̀ Eliṣa wọ́n sì béèrè pé, “Ṣé ìwọ mọ̀ pé Olúwa yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí?”

“Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi mọ̀,” Eliṣa dáhùn “Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”

4Nígbà náà Elijah sì wí fún un pé, “Dúró níbí, Eliṣa: Olúwa ti rán mi lọ sí Jeriko.”

Ó sì dá a lóhùn pé, “Bí ó ti dájú pé Olúwa yè àti tí ìwọ náà yè, Èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Wọ́n sì jọ lọ sí Jeriko.

5Àwọn ọmọ wòlíì tí ó wà ní Jeriko sì gòkè tọ Eliṣa wá wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé ìwọ mọ̀ wí pé Olúwa yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí?”

“Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi mọ̀,” Ó dá wọn lóhùn, “Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ nípa rẹ̀.”

6Nígbà náà Elijah wí fún un pé, “Dúró níbí; Olúwa rán mi lọ sí Jordani.”

Ó sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ wí pé, Olúwa yè àti gẹ́gẹ́ bí o ti yè, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì sì jọ ń lọ.

7Àádọ́ta àwọn ọkùnrin ọmọ wòlíì sì lọ láti lọ dúró ní ọ̀nà jíjìn, wọ́n sì kọ ojú da ibi tí Elijah àti Eliṣa ti dúró ní Jordani. 8Elijah sì mú agbádá ó sì ká a sókè ó sì lu omi náà pẹ̀lú rẹ̀. Omi náà sì pín sí ọ̀tún àti sí òsì, àwọn méjèèjì sì rékọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ.

9Nígbà tí wọ́n rékọjá, Elijah sì wí fún Eliṣa pé, “Sọ fún mi, kí ni èmi lè ṣe fún ọ kí ó tó di wí pé wọ́n gbà mí kúrò lọ́dọ̀ rẹ?”

“Jẹ́ kí èmi kí ó jogún ìlọ́po méjì ẹ̀mí rẹ.” Ó dá a lóhùn.

10“Ìwọ ti béèrè ohun tí ó ṣòro,” Elijah wí pé, “Síbẹ̀ tí ìwọ bá rí mi nígbà tí a bá gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ, yóò jẹ́ tìrẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kò ní rí bẹ́ẹ̀.”

112.11: If 11.12.Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń rìn lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ pọ̀, lọ́gán kẹ̀kẹ́ iná àti ẹṣin iná yọ sí wọn ó sì ya àwọn méjèèjì nípa, Elijah sì gòkè lọ sí ọ̀run pẹ̀lú àjà. 12Eliṣa rí èyí ó sì kígbe sókè, “Baba mi! Baba mi! Kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin Israẹli!” Eliṣa kò sì rí i mọ́. Ó sì mú aṣọ ara rẹ̀ ó sì fà wọ́n ya sọ́tọ̀.

13Ó sì mú agbádá tí ó ti jábọ́ láti ọ̀dọ̀ Elijah ó sì padà lọ, ó sì dúró lórí bèbè Jordani. 14Ó sì mú agbádá náà tí ó jábọ́ láti ọwọ́ rẹ̀, ó sì lu omi pẹ̀lú rẹ̀. “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run Elijah wà?” Ó béèrè. Nígbà tí ó lu omi náà, ó sì pín sí apá ọ̀tún àti sí òsì, Eliṣa sì rékọjá.

15Àwọn ọmọ wòlíì láti Jeriko, tí wọ́n ń wò, wí pé, “Ẹ̀mí Elijah sinmi lé Eliṣa.” Wọ́n sì lọ láti lọ bá a, wọ́n sì dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀. 16“Wò ó,” wọ́n wí pé, “Àwa ìránṣẹ́ ni àádọ́ta ọkùnrin alágbára. Jẹ́ kí wọ́n lọ láti lọ wá ọ̀gá rẹ wá. Bóyá ẹ̀mí Olúwa ti gbé e sókè, ó sì gbé e kalẹ̀ lórí òkè ńlá tàbí lórí ilẹ̀.”

“Rárá,” Eliṣa dá a lóhùn pé, “Má ṣe rán wọn.”

17Ṣùgbọ́n wọ́n rọ̀ ọ́ títí ojú fi tì í láti gbà. Ó wí pé, “Rán wọn.” Wọ́n sì rán àádọ́ta ènìyàn tí ó wá a fún ọjọ́ mẹ́ta ṣùgbọ́n wọn kò rí i. 18Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Eliṣa, tí ó dúró ní Jeriko, ó wí fún wọn pé, “Ṣé èmi kò sọ fún un yín kí ẹ má lọ?”

Ìwòsàn omi

19Àwọn ọkùnrin ìlú wí fún Eliṣa, pé “Wò ó, olúwa wa, ìtẹ̀dó ìlú yìí dára, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí i, ṣùgbọ́n omi náà burú, ilẹ̀ náà sì sá.”

20Ó sì wí pé, “Mú àwokòtò tuntun fún mi wá, kí o sì mú iyọ̀ sí inú rẹ̀.” Wọ́n sì gbé e wá fún un.

21Nígbà náà ó sì jáde lọ sí ibi orísun omi, ó sì da iyọ̀ sí inú rẹ̀, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi ti wo omi yìí sàn. Kò ní mú ikú wá mọ́ tàbí mú ilẹ̀ náà sá.’ ” 22Omi náà sì ti dára ni mímu títí di òní, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Eliṣa ti sọ.

Wọ́n fi Eliṣa ṣe yẹ̀yẹ́

23Láti ibẹ̀ Eliṣa lọ sókè ní Beteli gẹ́gẹ́ bí ó ti ń rìn lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọ̀dọ́ kan jáde wá láti ìlú náà wọ́n sì fi ṣe ẹlẹ́yà. “Máa lọ sókè ìwọ apárí!” Wọ́n wí pé. “Máa lọ sókè ìwọ apárí!” 24Ó sì yípadà, ó sì wò wọ́n ó sì fi wọ́n bú ní orúkọ Olúwa. Nígbà náà beari méjì sì jáde wá láti inú igbó ó sì lu méjìlélógójì (42) lára àwọn ọ̀dọ́ náà. 25Ó sì lọ sí orí òkè Karmeli láti ibẹ̀ ó sì padà sí Samaria.