신명기 25 – KLB & YCB

Korean Living Bible

신명기 25:1-19

1“만일 사람들이 시비 문제로 법정에 나오면 재판관은 옳고 그른 것을 판 결하여 죄가 없는 사람은 놓아 주고 죄가 있는 사람은 형벌을 받게 해야 합니다.

2만일 그 죄가 매질에 해당하면 재판관이 직접 보는 앞에서 그를 엎드리게 하고 죄의 정도에 따라 그를 때리게 해야 합니다.

3그러나 40대 이상 때려서는 안 됩니다. 그 이상 때리게 되면 여러분의 동족이 대중 앞에서 모욕을 당하게 될 것입니다.

4“곡식을 밟아 떠는 소의 입에 망을 씌우지 마십시오.

5“만일 형제들이 함께 살다가 그 중 하나가 아들 없이 죽으면 그 미망인은 집을 나가 다른 사람과 재혼해서는 안 됩니다. 죽은 그 남편의 형제가 그 여자와 결혼하여 형제로서의 의무를 다해야 합니다.

6그 여자가 낳은 첫아들이 죽은 형제의 대를 잇게 하여 그 이름이 이스라엘에서 끊어지지 않게 하십시오.

7그러나 죽은 사람의 형제가 그 미망인과 결혼하기를 싫어하면 그 여자는 성의 지도자들에게 가서 ‘내 남편의 형제가 나와 결혼하기를 거절하며 자기 형제의 대를 잇게 하는 의무를 이행하지 않으려고 합니다’ 하고 말해야 합니다.

8그러면 그 성의 지도자들이 그를 불러다가 설득해 보고 그래도 거절하면

9그 미망인은 지도자들이 보는 앞에서 그 사람의 신 한 짝을 벗기고 그 얼굴에 침을 뱉으며 ‘이것은 자기 형제의 대를 잇게 하는 의무를 거절하는 자가 받는 수치이다’ 하고 말해야 합니다.

10그러면 그 후부터 그의 집안이 ‘신발을 벗긴 자의 집’ 으로 알려지게 될 것입니다.

11“만일 두 사람이 싸우고 있는데 한 사람의 아내가 자기 남편을 돕기 위해 다른 남자의 불알을 잡아당기면

12여러분은 그 여자의 손을 사정없이 잘라 버리십시오.

13-15“여러분은 저울과 되를 속이지 말고 정확한 되와 저울을 사용하십시오. 그러면 여러분의 하나님 여호와께서 주시는 땅에서 여러분이 오랫동안 살게 될 것입니다.

16여호와께서는 되와 저울을 속이는 사람을 미워하십니다.

17“여러분이 이집트에서 나올 때 아말렉 사람들이 여러분에게 행한 일을 기억하십시오.

18그들이 하나님을 두려워하지 않고 길에서 여러분을 만났을 때 지치고 피곤하여 뒤에 처진 사람들을 모조리 쳐죽였습니다.

19그러므로 여러분은 여호와 하나님이 주시는 약속의 땅에서 주변의 모든 원수들을 정복하고 평안을 누리게 될 때 아말렉 사람을 모조리 죽여 온 세상에서 그들의 이름을 기억하는 자가 없게 하십시오. 여러분은 이것을 절대로 잊지 말아야 합니다.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 25:1-19

1Nígbà tí àwọn ènìyàn méjì bá ń jà, kí wọn kó ẹjọ́ lọ sí ilé ìdájọ́, kí àwọn onídàájọ́ dá ẹjọ́ náà, kí wọn dá àre fún aláre àti ẹ̀bi fún ẹlẹ́bi. 2Bí ó bá tọ́ láti na ẹlẹ́bi, kí onídàájọ́ dá a dọ̀bálẹ̀ kí a sì nà án ní ojú u rẹ̀ ní iye pàṣán tí ó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. 3Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ fún un ju ogójì pàṣán lọ. Bí ó bá nà án ju bẹ́ẹ̀ lọ, arákùnrin rẹ̀ yóò di ẹni ìrẹ̀sílẹ̀ ní ojú rẹ̀.

425.4: 1Kọ 9.9; 1Tm 5.18.Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu.

525.5,6: Mt 22.24; Mk 12.19; Lk 20.28.Bí àwọn arákùnrin bá ń gbé pọ̀, tí ọ̀kan nínú wọn bá sì kú, tí kò sí ní ọmọkùnrin, kí aya òkú má ṣe ní àlejò ará òde ní ọkọ rẹ̀. Arákùnrin ọkọ rẹ̀ ni kí ó wọlé tọ̀ ọ́, kí ó fi ṣe aya, kí ó sì ṣe iṣẹ́ arákùnrin ọkọ fún un. 6Ọmọkùnrin tí ó bá kọ́ bí ni yóò máa jẹ́ orúkọ arákùnrin rẹ̀ tí ó kú náà, kí orúkọ rẹ̀ má ba á parẹ́ ní Israẹli.

7Ṣùgbọ́n bí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ fi aya arákùnrin rẹ̀ ṣe aya rẹ̀, obìnrin náà yóò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà ní ẹnu-bodè ìlú láti sọ pé, “Arákùnrin ọkọ ọ̀ mi kọ̀ láti gbé orúkọ arákùnrin rẹ̀ ró ní Israẹli. Kò ní ṣe ojúṣe rẹ̀ bí arákùnrin ọkọ mi sí mi.” 8Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà ìlú rẹ̀ yóò pè é, wọn yóò sì bá sọ̀rọ̀. Bí ó bá sì kọ̀ jálẹ̀ tí ó bá sọ pé, “Èmi kò fẹ́ láti fẹ́ ẹ,” 9opó arákùnrin rẹ̀ yìí yóò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ojú àwọn àgbàgbà ìlú rẹ̀, yóò yọ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ kan, yóò sì tu itọ́ sí ọkùnrin náà lójú, yóò sì wí pé, “Èyí ni ohun tí a ṣe sí ọkùnrin tí kò jẹ́ kí ìdílé arákùnrin rẹ̀ wà títí ayé.” 10A ó sì mọ ìdílé arákùnrin yìí ní Israẹli gẹ́gẹ́ bí “Ìdílé tí a yọ bàtà rẹ̀.”

11Bí ọkùnrin méjì bá ń jà, tí ìyàwó ọ̀kan nínú wọn bá sì wá láti gbèjà ọkọ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ọkùnrin tí ń lù ú, tí ó sì nawọ́ di nǹkan ọkùnrin abẹ́ ẹ rẹ̀ mú. 12Ìwọ yóò gé ọwọ́ rẹ̀ náà kúrò. Má ṣe ṣàánú fún un.

1325.13-16: Le 19.35,36.Má ṣe ní oríṣìí ìtẹ̀wọ̀n méjì tó yàtọ̀ sí ara wọn nínú àpò rẹ: ọ̀kan wúwo àti ọ̀kan fífúyẹ́. 14Má ṣe ní oríṣìí ìwọ̀n méjì tí ó yàtọ̀ sí ara wọn ní ilé è rẹ: ọ̀kan fífẹ̀, ọ̀kan kékeré. 15O gbọdọ̀ ní ìtẹ̀wọ̀n àti òṣùwọ̀n pípé àti ti òtítọ́ nítorí náà kí ìwọ kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún ọ. 16Nítorí Olúwa Ọlọ́run kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí, àní ẹnikẹ́ni tí ń ṣe àìṣòdodo.

1725.17-19: Ek 17.14; 1Sa 15.Rántí ohun tí àwọn ará Amaleki ṣe sí i yín ní ọ̀nà nígbà tí ẹ̀ ń jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá. 18Nígbà tí àárẹ̀ mú un yín tí agara sì dá a yín, wọ́n pàdé e yín ní ọ̀nà àjò o yín, wọ́n gé àwọn tí ó rẹ̀yìn kúrò, wọn kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run. 19Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá fún un yín ní ìsinmi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá yín tí ó yí i yín ká ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run ń fi fún yín láti ni ní ìní, ẹ̀yin yóò sì pa ìrántí Amaleki rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Má ṣe gbàgbé.