민수기 4 – KLB & YCB

Korean Living Bible

민수기 4:1-49

고핫 자손들의 임무

1여호와께서 4:1 원문에는 ‘모세와 아론에게’모세에게 말씀하셨다.

2-3“너는 레위 지파의 고핫 집안 가운 데 30세부터 50세까지 성막에서 일할 수 있는 남자가 몇 명이나 되는지 가족별로 조사하여라.

4고핫 자손이 할 일은 성막의 가장 거룩한 비품을 관리하는 것이다.

5“진영을 이동할 때에는 아론과 그의 아들들이 먼저 성막 안으로 들어가 휘장을 거둬서 법궤를 덮게 하라.

6그리고 그 위에 바닷소의 가죽을 덮고 그 가죽 위를 순청색 천으로 덮은 다음 운반채를 법궤 고리에 꿰게 하라.

7“상에는 푸른 천을 깔고 그 위에다 대접과 국자와 잔과 주전자와 항상 차려 놓는 빵을 놓아라.

8그리고 그것을 붉은 천으로 덮고 다시 바닷소의 가죽으로 덮은 다음 운반채를 상 고리에 꿰어라.

9“다음에는 청색 천으로 등대와 등잔과 심지 자르는 가위와 불똥 그릇과 모든 기름 그릇을 싸야 한다.

10이 모든 것을 싼 다음에는 다시 바닷소의 가죽으로 싸서 들것 위에 놓아라.

11“그리고 청색 천을 향단 위에 깔고 다시 바닷소의 가죽으로 그 위를 덮은 다음 운반채를 그 고리에 꿰어라.

12성막의 나머지 기구들도 청색 천으로 싼 다음 바닷소의 가죽으로 덮어 들것에 놓아라.

13“번제단은 먼저 거기 있는 재를 다 퍼낸 후에 자색 천을 그 위에 펴고

14제단에서 사용되는 모든 기구, 곧 불 옮기는 그릇과 고기 갈고리와 부삽과 피를 담는 그릇을 놓은 다음 바닷소의 가죽을 덮고 운반채를 번제단 고리에 꿰어라.

15“아론과 그의 아들들이 이 거룩한 물건들과 기구들을 다 꾸려 놓은 후에 진영이 이동할 준비가 완료되면 고핫 자손들이 그것을 운반하게 하라. 그러나 고핫 자손들은 이 거룩한 기구들을 만져서는 안 된다. 만일 그들이 그것을 만지면 죽을 것이다. 성막 물건 중에서 이것들은 고핫 자손들이 운반해야 한다.

16“아론의 아들인 제사장 엘르아살은 불이 꺼지지 않도록 기름을 붓고 분향할 향품과 날마다 드리는 소제물과 거룩한 기름과 성막 전체와 그 안에 있는 모든 거룩한 기구들을 맡아 관리해야 한다.”

17여호와께서 다시 4:17 원문에는 ‘모세와 아론에게’모세에게 말씀하셨다.

18“너는 레위인 중에서 고핫 자손이 끊어지지 않도록 하라.

19그들이 가장 거룩한 물건에 접근할 때 죽지 않도록 아론과 그의 아들들이 그들과 함께 성소에 들어가서 그들이 각자 해야 할 일과 운반할 물건을 지시하도록 하라.

20그러나 고핫 자손들은 성소에 들어가서 잠시라도 거룩한 물건을 보아서는 안 된다. 그렇지 않으면 죽을 것이다.”

게르손 자손들의 임무

21여호와께서 모세에게 이렇게 말씀하셨다.

22-23“너는 게르손 집안 가운데서도 30세 부터 50세까지 성막에서 일할 수 있는 남자가 몇 명이나 되는지 가족별로 조사하여라.

24“게르손 자손이 해야 할 일은

25성막 휘장, 성막과 그 덮개들, 바닷소의 가죽으로 된 제일 윗덮개, 성막 출입구 휘장,

26성막과 제단을 둘러 친 포장, 뜰의 출입구 막, 밧줄, 그리고 이 모든 것에 사용되는 기구를 운반하는 것이다.

27게르손 자손이 하는 모든 일은 아론과 그의 아들들의 지시를 받아야 한다. 그리고 너는 그들이 운반할 물건을 하나하나 지정해 주어라.

28이상은 게르손 자손들이 성막에서 해야 할 일이다. 그들은 아론의 아들인 제사장 이다말의 지시를 직접 받도록 하라.”

므라리 자손들의 임무

29-30“너는 므라리 집안 가운데서 30세부터 50세까지 성막에서 일할 수 있는 남자가 몇 명이나 되는지 가족별로 조사하여라.

31므라리 자손이 해야 할 일은 성막 널빤지, 가로대, 기둥과 그 받침들,

32성막 뜰 기둥과 그 받침, 말뚝과 줄, 그리고 이 모든 것에 사용되는 기구를 운반하는 일이다. 너는 그들에게 각자 운반할 물건을 지정해 주어라.

33이상은 아론의 아들인 제사장 이다말의 지시를 받아 므라리 자손이 성막에서 해야 할 일이다.”

레위인들의 인구 조사

34-48모세와 아론과 다른 지도자들은 여호 와의 명령에 따라 고핫 자손과 게르손 자손과 므라리 자손 가운데 30세부터 50세까지 성막에서 일할 수 있는 남자들을 각 집안과 가족 단위로 조사했는데 그들이 조사한 것을 보면

고핫 자손 가운데 2,750명게르손 자손 가운데 2,630명므라리 자손 가운데 3,200명

모두 8,580명이었다.

49이와 같이 모세는 여호와의 명령에 따라 그들을 조사하여 각자 해야 할 일과 운반할 물건을 정해 주었다.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Numeri 4:1-49

Àwọn ọmọ Kohati

14.1-33: Nu 1.50-53; 3.5-8,21-37; 8.19; 18.3,4,23.Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé: 2“Ka iye àwọn ọmọ Kohati láàrín àwọn ọmọ Lefi nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn. 3Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé.

4“Wọ̀nyí ni iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Kohati nínú àgọ́ àjọ, láti tọ́jú àwọn ohun èlò mímọ́ jùlọ. 5Nígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀síwájú, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sí aṣọ ìbòrí rẹ̀, wọn yóò sì fi bo àpótí ẹ̀rí. 6Wọn yóò sì fi awọ ewúrẹ́ bò ó, lórí awọ ewúrẹ́ yìí ni wọn ó tẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

7“Lórí tábìlì àkàrà ìfihàn ni kí wọn ó na aṣọ aláró kan sí, kí wọn kí ó sì fi àwopọ̀kọ́ sórí rẹ̀, àti ṣíbí àti àwokòtò àti ìgò fún ọrẹ ohun mímu; àti àkàrà ìgbà gbogbo ní kí ó wà lórí rẹ̀. 8Lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọn yóò da, wọn ó tún fi awọ ewúrẹ́ bò ó, wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

9“Kí wọn kí ó sì mú aṣọ aláwọ̀ aláró kan, kí wọn kí ó sì fi bo ọ̀pá fìtílà àti fìtílà rẹ̀, àti alumagaji rẹ̀, àti àwo alumagaji rẹ̀, àti gbogbo ohun èlò òróró rẹ̀, èyí tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀. 10Kí wọn ó fi awọ ẹran yí fìtílà àti gbogbo ohun èlò rẹ, kí wọn kí ó sì gbé e lé orí férémù tí wọn yóò fi gbé e.

11“Ní orí pẹpẹ wúrà ni kí wọn ó tẹ́ aṣọ aláró kan sí, wọn yóò sì fi awọ seali bò ó, kí wọ́n sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

12“Kí wọn kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, kí wọn ó fi aṣọ aláwọ̀ búlúù yìí, kí wọn ó sì fi awọ seali bò ó, kí wọn ó sì fi gbé wọn ka orí férémù.

13“Kí wọn ó kó eérú kúrò lórí pẹpẹ idẹ, kí wọn ó sì tẹ́ aṣọ aláwọ̀ àlùkò lé e lórí. 14Nígbà náà ni kí wọn ó kó gbogbo ohun èlò fún iṣẹ́ ìsìn níbi pẹpẹ, títí dórí àwo iná, fọ́ọ̀kì ẹran, ọkọ́ eérú àti àwokòtò. Kí wọn ó fi awọ ewúrẹ́ bo gbogbo rẹ̀, kí wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

15“Lẹ́yìn tí Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti parí bíbo ibi mímọ́ àti gbogbo ohun èlò ibi mímọ́, nígbà tí àgọ́ bá sì ṣetán láti tẹ̀síwájú, kí àwọn ọmọ Kohati bọ́ síwájú láti gbé e, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ohun mímọ́ kankan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn ó kú. Àwọn ọmọ Kohati ni yóò gbé gbogbo ohun tó wà nínú àgọ́ ìpàdé.

16“Iṣẹ́ Eleasari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àbojútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí: Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò ibi mímọ́.”

17Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, 18“Rí i pé a kò gé ẹ̀yà Kohati kúrò lára àwọn ọmọ Lefi: 19Nítorí kí wọ́n lè yè, kí wọ́n má ba à kú nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ tòsí àwọn ohun mímọ́ jùlọ: Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó wọ ibi mímọ́ láti pín iṣẹ́ oníkálùkù àti àwọn ohun tí wọn yóò gbé. 20Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Kohati kò gbọdọ̀ wọlé láti wo àwọn ohun mímọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ ìṣẹ́jú kan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kú.”

Àwọn ọmọ Gerṣoni

21Olúwa sọ fún Mose pé: 22“Tún ka iye àwọn ọmọ Gerṣoni nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn. 23Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé.

24“Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni, bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àti ní ẹrù rírù: 25Àwọn ni yóò máa ru àwọn aṣọ títa ti àgọ́, ti àgọ́ ìpàdé àti ìbòrí rẹ̀, àti awọ ewúrẹ́ tí a fi bò ó, aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, 26Aṣọ títa ti àgbàlá tó yí àgọ́ àti pẹpẹ ká, aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé sí àgbàlá, okùn àti àwọn ohun èlò iṣẹ́ ìsìn, àti ohun gbogbo tí à ń lò fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn ó máa sìn. Àwọn ọmọ Gerṣoni ni yóò ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ pẹ̀lú àwọn nǹkan wọ̀nyí. 27Gbogbo iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Gerṣoni yálà ni iṣẹ́ ṣíṣe tàbí ní ẹrù rírù ni, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò máa darí wọn; ìwọ ni kí o sì yàn ẹrù tí oníkálùkù yóò rù fún un. 28Èyí ni iṣẹ́ ìdílé àwọn Gerṣoni ni àgọ́ ìpàdé Itamari, ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà ni yóò sì jẹ alábojútó iṣẹ́ wọn.

Àwọn ọmọ Merari

29“Ka iye àwọn ọmọ Merari nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn. 30Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. 31Iṣẹ́ tí wọn yóò sì máa ṣe nínú àgọ́ ìpàdé nìyìí: gbígbẹ́ àwọn férémù àgọ́, pákó ìdábùú rẹ̀, òpó àti ihò òpó rẹ̀, 32Pẹ̀lú gbogbo òpó tó yí àgbàlá ká àti ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn kí o sì yan ohun tí oníkálùkù yóò rù fún un; 33Èyí ni iṣẹ́ ìsìn ìdílé àwọn ọmọ Merari, bí wọn yóò ti máa ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé lábẹ́ àkóso Itamari ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà.”

Àbájáde kíka àwọn ọmọ Lefi

34Mose àti Aaroni pẹ̀lú àwọn olórí ìjọ ènìyàn ka àwọn ọmọ Kohati nípa ìdílé àti ilé baba wọn.

35Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń wá ṣiṣẹ́ ní Àgọ́ ìpàdé. 36Iye wọn nípa ìdílé jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlá ó-dínàádọ́ta (2,750). 37Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Kohati tó ń ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé; tí Mose àti Aaroni kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.

38Wọ́n ka àwọn ọmọ Gerṣoni nípa ìdílé àti ilé baba wọn.

39Gbogbo ọmọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, gbogbo àwọn tó lè ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. 40Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá ó-lé-ọgbọ̀n (2,630). 41Èyí jẹ́ àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Gerṣoni, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. Mose àti Aaroni ṣe bí àṣẹ Olúwa.

42Wọ́n ka àwọn ọmọ Merari nípa ìdílé àti ilé baba wọn.

43Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún, àwọn tó ṣiṣẹ́ ní àgọ́ ìpàdé. 44Iye wọn nípa ìdílé àti ilé baba wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún (3,200). 45Èyí ni àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Merari. Mose àti Aaroni kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mose.

46Gbogbo àwọn tí a kà nínú àwọn ọmọ Lefi, ti Mose àti Aaroni àti àwọn olórí Israẹli kà, nípa ìdílé wọn àti gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn. 47Gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn tó sì ń ru àwọn ẹrù inú Àgọ́ Ìpàdé. 48Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá lé lẹ́gbàarin ó dín ogún (8,580). 49Wọ́n yan iṣẹ́ àti àwọn ohun tí ẹni kọ̀ọ̀kan yóò máa gbé fún un gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ láti ẹnu Mose.

Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe kà wọ́n gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.