레위기 22 – KLB & YCB

Korean Living Bible

레위기 22:1-33

1여호와께서 모세를 통하여 아론과 그의 아들들에게 말씀하셨다. “너희

2는 이스라엘 백성이 나에게 드리는 거룩한 예물을 함부로 다루어 나의 거룩한 이름을 욕되게 하지 말아라. 나는 여호와이다.

3너희 자손 중에 누구든지 그 몸이 부정하면서도 이스라엘 백성이 구별하여 나에게 바친 거룩한 예물에 가까이하는 자는 내 앞에서 다시는 제사장 직분을 수행하지 못할 것이다. 나는 여호와이다.

4“아론의 자손 중에 문둥병에 걸렸거나 유출병이 있는 자는 누구든지 정결하게 될 때까지 거룩한 제물을 먹지 못한다. 그리고 시체를 만진 자와 설정하여 부정하게 된 자와

5부정한 동물이나 사람에게 접촉한 자는

6저녁까지 부정하므로 목욕을 해야 한다. 그러나 목욕을 한 후에도 저녁까지는 거룩한 음식을 먹어서는 안 된다.

7이런 제사장은 해가 져서 깨끗해진 다음에야 자기 음식인 거룩한 제물을 먹을 수 있다.

8제사장은 저절로 죽었거나 맹수에게 찢겨 죽은 짐승의 고기를 먹어 자신을 더럽히지 말아라. 나는 여호와이다.

9“모든 제사장은 내가 지시한 규정을 잘 지켜야 한다. 그렇지 않으면 너희가 내 명령에 불순종한 죄로 죽음을 면치 못할 것이다. 나는 너희를 거룩하게 하는 여호와이다.

10“제사장의 가족 외에는 아무도 거룩한 음식을 먹을 수 없다. 그러므로 제사장을 찾아온 손님이나 그가 고용한 품꾼은 그 음식을 먹지 못한다.

11그러나 제사장이 돈으로 산 종이나 그 종이 그 집에서 낳은 자식들은 제사장이 먹는 음식을 먹을 수 있다.

12그리고 만일 제사장의 딸이 제사장이 아닌 사람에게 시집갔을 경우에는 그 음식을 먹을 수 없다.

13그러나 그 제사장의 딸이 과부가 되었거나 이혼을 하여 자식 없이 친정으로 돌아와 살 경우에는 자기 아버지가 먹는 음식을 먹을 수 있다. 이런 경우를 제외하고서 제사장의 가족이 아닌 사람은 아무도 제사장이 먹는 거룩한 음식을 먹어서는 안 된다.

14“만일 제사장의 가족이 아닌 다른 사람이 모르고 제사장의 거룩한 음식을 먹었으면 그는 그 먹은 것에 5분의 을 더하여 제사장에게 갚아야 한다.

15너희 제사장들은 이스라엘 백성이 나에게 바치는 거룩한 음식을 아무나 먹게 하여 더럽히지 말아라.

16이 규정을 어기는 자는 누구든지 그 죄의 대가로 형벌을 받게 될 것이다. 나는 그 음식을 거룩하게 하는 여호와이다.”

제물로 바칠 수 없는 것

17-18또 여호와께서 모세를 통하여 아론과 그의 아들들과 모든 이스라엘 백성에게 말씀하셨다. “이스라엘 자손이나 너희 가운데 사는 외국인이 서약을 지키기 위해서나 아니면 자원하는 마음으로 나에게 번제를 드리고자 하면

19그 제물은 내가 기쁘게 받을 수 있도록 소나 양이나 염소 중에서 흠이 없는 수컷을 바쳐야 한다.

20만일 너희가 흠이 있는 것을 바치면 내가 그 제물을 받지 않을 것이다.

21누구든지 서약을 지키기 위해서나 아니면 자원하는 마음으로 나에게 소나 양을 화목제물로 드리려고 하면 그 제물은 내가 기쁘게 받을 수 있도록 흠이 없는 완전한 것이어야 한다.

22그러므로 눈먼 것, 절름발이, 다리가 잘라진 것, 종기 난 것, 그리고 가려움증이나 각종 피부병에 걸린 것을 나 여호와의 단에 바치지 말아라.

23지체가 너무 크게 자랐거나 너무 작게 자란 소나 양은 자원하여 드리는 예물로는 바칠 수 있다. 그러나 서약한 것을 갚기 위해 그것을 드리면 내가 받지 않을 것이다.

24너희는 불알이 상했거나 으스러졌거나 터졌거나 잘라진 짐승을 나에게 바치지 말아라. 이런 일을 너희 땅에서 해서는 안 된다.

25또 너희는 너희 가운데 사는 외국인에게서 이런 것을 받아 너희 하나님에게 제물로 바쳐서도 안 된다. 이런 것은 흠이 있거나 결점이 있기 때문에 내가 기쁘게 받지 않을 것이다.

26-27“수소나 양이나 염소가 태어나면 7일 동안 그 어미와 같이 있게 하라. 그러나 8일 이후부터 그것을 나 여호와에게 불로 태워 바치면 내가 기쁘게 받겠다.

28너희는 잡을 짐승이 암소이건 암양이건 그 어미와 새끼를 한날에 잡지 말아라.

29너희는 나 여호와에게 감사제물을 드릴 때 내가 기쁘게 받을 수 있도록 드려라.

30그리고 그 제물은 짐승을 잡는 그 날에 먹고 다음날까지 조금도 남겨 두지 말아라. 나는 여호와이다.

31“너희는 내가 명령한 것을 준수하라. 나는 여호와이다.

32너희는 나의 거룩한 이름을 욕되게 하지 말아라. 이스라엘의 모든 백성은 나를 거룩한 자로 알아야 한다. 나는 너희를 거룩하게 하는 여호와, 곧

33너희 하나님이 되려고 너희를 이집트에서 인도해 낸 여호와이다.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Lefitiku 22:1-33

1Olúwa sọ fún Mose pé, 2“Sọ fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ kí wọ́n fi ọ̀wọ̀ fún ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli yà sọ́tọ̀ fún mi, kí wọ́n má ba à ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Èmi ni Olúwa.

3“Sọ fún wọn pé: ‘Fún àwọn ìran tí ń bọ̀. Bí ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ yín tí kò mọ́ bá wá sí ibi ọrẹ mímọ́ tí àwọn ara Israẹli ti yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, kí ẹ yọ ẹni náà kúrò nínú iṣẹ́ àlùfáà ní iwájú mi. Èmi ni Olúwa.

4“ ‘Bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Aaroni bá ní ààrùn ara tí ń ran ni, tàbí ìtújáde nínú ara. Ó lè má jẹ ọrẹ mímọ́ náà títí di ìgbà tí a ó fi wẹ̀ ẹ́ mọ́. Òun tún lè di aláìmọ́ bí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí òkú nǹkan bá sọ di àìmọ́ tàbí bí ó bá farakan ẹnikẹ́ni tí ó ní ìtújáde. 5Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan èyíkéyìí nínú ohun tí ń rákò, tí ó sọ ọ́ di aláìmọ́, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó sọ ọ́ di àìmọ́, ohunkóhun yówù kí àìmọ́ náà jẹ́. 6Ẹni náà tí ó fọwọ́ kan irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú ọrẹ mímọ́ àyàfi bí ó bá wẹ ara rẹ̀. 7Bí oòrùn bá wọ̀, ẹni náà di mímọ́, lẹ́yìn náà ni ó tó le jẹ ọrẹ mímọ́, torí pé wọ́n jẹ́ oúnjẹ rẹ̀. 8Kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí ó bá ti kú sílẹ̀, tàbí tí ẹranko fàya, kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di aláìmọ́. Èmi ni Olúwa.

9“ ‘Kí àwọn àlùfáà pa ìlànà mi mọ́, kí wọn má ba à jẹ̀bi, kí wọn sì kú nítorí pé wọ́n ṣe ọrẹ wọ̀nyí pẹ̀lú fífojútẹ́ńbẹ́lú wọn. Èmi ni Olúwa tí ó sọ wọ́n di mímọ́.

10“ ‘Kò sí ẹnikẹ́ni lẹ́yìn ìdílé àlùfáà tí ó le jẹ ọrẹ mímọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni, àlejò àlùfáà tàbí alágbàṣe rẹ̀ kò le jẹ ẹ́. 11Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá ra ẹrú, pẹ̀lú owó, tàbí tí a bí ẹrú kan nínú ìdílé rẹ̀, ẹrú náà lè jẹ oúnjẹ rẹ̀. 1222.12: Le 7.31-36.Bí ọmọbìnrin àlùfáà bá fẹ́ ẹni tí kì í ṣe àlùfáà, kò gbọdọ̀ jẹ nínú èyíkéyìí nínú ohun ọrẹ mímọ́. 13Ṣùgbọ́n bí ọmọbìnrin àlùfáà bá jẹ́ opó tàbí tí a ti kọ ọ́ sílẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò lọ́mọ tí ó sì padà sínú ilé baba rẹ̀ láti máa gbé bẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀, ó le jẹ oúnjẹ baba rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, àlejò tí kò lẹ́tọ̀ọ́ (láṣẹ) kò gbọdọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú oúnjẹ náà.

14“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣèèṣì jẹ ọrẹ mímọ́ kan, ó gbọdọ̀ ṣe àtúnṣe lórí ẹbọ náà fún àlùfáà, kí ó sì fi ìdámárùn-ún ohun tí ọrẹ náà jẹ́ kún un. 15Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ sọ ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli mú wá síwájú Olúwa di àìmọ́. 16Nípa fífi ààyè fún wọn láti jẹ ọrẹ mímọ́ náà, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀bi tí wọn yóò san nǹkan fún wá sórí wọn. Èmi ni Olúwa, tí ó sọ wọ́n di mímọ́.’ ”

Àwọn ọrẹ ẹbọ tí kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà

17Olúwa sọ fún Mose pé, 18“Sọ fún Aaroni, àwọn ọmọ rẹ̀ àti fún gbogbo Israẹli kí o sì wí fún wọn pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín yálà ọmọ Israẹli ni tàbí àlejò tí ń gbé ní Israẹli bá mú ẹ̀bùn wá fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, yálà láti san ẹ̀jẹ́ tàbí ọrẹ àtinúwá. 19Ẹ gbọdọ̀ mú akọ láìní àbùkù láti ara màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́, kí ó ba à lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín. 20Ẹ má ṣe mú ohunkóhun tí ó ní àbùkù wá, torí pé kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín. 21Bí ẹnikẹ́ni bá mú ọrẹ àlàáfíà wá láti inú agbo màlúù tàbí ti àgùntàn, fún Olúwa láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí fún ọrẹ àtinúwá. Ó gbọdọ̀ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láìní àbùkù. 22Ẹ má ṣe fi ẹranko tí ó fọ́jú, tí ó fi ara pa, tí ó yarọ, tí ó ní kókó, tí ó ní èkúkú, èépá àti egbò kíkẹ̀ rú ẹbọ sí Olúwa. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé èyíkéyìí nínú wọn sórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bi ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa. 23Ẹ le mú màlúù tàbí àgùntàn tí ó ní àbùkù tàbí tí ó yọ iké wá fún ọrẹ àtinúwá, ṣùgbọ́n kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ ẹ̀jẹ́. 24Ẹ má ṣe fi ẹranko tí kóró ẹpọ̀n rẹ̀ fọ́ tàbí tí a tẹ̀, tàbí tí a yà tàbí tí a là rú ẹbọ sí Olúwa. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí ní ilẹ̀ yín. 25Ẹ kò gbọdọ̀ gba irú ẹranko bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àlejò kankan láti fi rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ sí Ọlọ́run yín. A kò nígbà wọ́n fún yín nítorí pé wọ́n ní àbùkù, wọ́n sì díbàjẹ́.’ ”

26Olúwa sọ fún Mose pé, 27“Nígbà tí màlúù bá bímọ, tí àgùntàn bímọ, tí ewúrẹ́ sì bímọ, ọmọ náà gbọdọ̀ wà pẹ̀lú ìyá rẹ̀ fún ọjọ́ méje. Láti ọjọ́ kẹjọ ni ó ti di ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ àfinásun sí Olúwa. 28Ẹ má ṣe pa màlúù àti ọmọ rẹ̀ tàbí àgùntàn àti ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà.

29“Nígbà tí ẹ bá rú ẹbọ ọpẹ́ sí Olúwa, ẹ rú u ní ọ̀nà tí yóò fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín. 30Ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ náà gan an: Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀. Èmi ni Olúwa.

31“Ẹ pa òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni Olúwa. 32Ẹ má ṣe ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Àwọn ọmọ Israẹli gbọdọ̀ mọ̀ mí ní mímọ́. Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́. 33Tí ó sì mú yín jáde láti Ejibiti wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni Olúwa.”