John 15 – KJV & YCB

King James Version

John 15:1-27

1I am the true vine, and my Father is the husbandman. 2Every branch in me that beareth not fruit he taketh away: and every branch that beareth fruit, he purgeth it, that it may bring forth more fruit. 3Now ye are clean through the word which I have spoken unto you. 4Abide in me, and I in you. As the branch cannot bear fruit of itself, except it abide in the vine; no more can ye, except ye abide in me. 5I am the vine, ye are the branches: He that abideth in me, and I in him, the same bringeth forth much fruit: for without me ye can do nothing. 6If a man abide not in me, he is cast forth as a branch, and is withered; and men gather them, and cast them into the fire, and they are burned. 7If ye abide in me, and my words abide in you, ye shall ask what ye will, and it shall be done unto you. 8Herein is my Father glorified, that ye bear much fruit; so shall ye be my disciples. 9As the Father hath loved me, so have I loved you: continue ye in my love. 10If ye keep my commandments, ye shall abide in my love; even as I have kept my Father’s commandments, and abide in his love. 11These things have I spoken unto you, that my joy might remain in you, and that your joy might be full. 12This is my commandment, That ye love one another, as I have loved you. 13Greater love hath no man than this, that a man lay down his life for his friends. 14Ye are my friends, if ye do whatsoever I command you. 15Henceforth I call you not servants; for the servant knoweth not what his lord doeth: but I have called you friends; for all things that I have heard of my Father I have made known unto you. 16Ye have not chosen me, but I have chosen you, and ordained you, that ye should go and bring forth fruit, and that your fruit should remain: that whatsoever ye shall ask of the Father in my name, he may give it you. 17These things I command you, that ye love one another. 18If the world hate you, ye know that it hated me before it hated you. 19If ye were of the world, the world would love his own: but because ye are not of the world, but I have chosen you out of the world, therefore the world hateth you. 20Remember the word that I said unto you, The servant is not greater than his lord. If they have persecuted me, they will also persecute you; if they have kept my saying, they will keep yours also. 21But all these things will they do unto you for my name’s sake, because they know not him that sent me. 22If I had not come and spoken unto them, they had not had sin: but now they have no cloke for their sin. 23He that hateth me hateth my Father also. 24If I had not done among them the works which none other man did, they had not had sin: but now have they both seen and hated both me and my Father. 25But this cometh to pass, that the word might be fulfilled that is written in their law, They hated me without a cause. 26But when the Comforter is come, whom I will send unto you from the Father, even the Spirit of truth, which proceedeth from the Father, he shall testify of me: 27And ye also shall bear witness, because ye have been with me from the beginning.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Johanu 15:1-27

Àjàrà àti ẹ̀ka rẹ̀

115.1: Isa 5.1-7; El 19.10; Mk 12.1-9; Mt 15.13; Ro 11.17.“Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni olùṣọ́gbà. 2Gbogbo ẹ̀ka nínú mi tí kò bá so èso, òun a mú kúrò: gbogbo ẹ̀ka tí ó bá sì so èso, òun a wẹ̀ ẹ́ mọ́, kí ó lè so èso sí i. 315.3: Jh 13.10.Ẹ̀yin mọ́ nísinsin yìí nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín. 415.4: Jh 6.56; 1Jh 2.6.Ẹ máa gbé inú mi, èmi ó sì máa gbé inú yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fún ara rẹ̀ bí kò ṣe pé ó ba ń gbé inú àjàrà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹ bá ń gbé inú mi.

5“Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó ń gbé inú mi, àti èmi nínú rẹ̀, òun ni yóò so èso lọ́pọ̀lọpọ̀: nítorí ní yíya ara yín kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ kò lè ṣe ohun kan. 6Bí ẹnìkan kò bá gbé inú mi, a gbé e sọnù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka, a sì gbẹ; wọn a sì kó wọn jọ, wọn a sì sọ wọ́n sínú iná, wọn a sì jóná. 715.7: Jh 14.13; 16.23; Mt 7.7; Jk 1.5.Bí ẹ̀yin bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi bá sì gbé inú yín, ẹ ó béèrè ohunkóhun tí ẹ bá fẹ́, a ó sì ṣe é fún yín. 815.8: Mt 5.16.Nínú èyí ní a yìn Baba mi lógo pé, kí ẹ̀yin kí ó máa so èso púpọ̀; ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.

9“Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì fẹ́ yín: ẹ dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀. 1015.10: Jh 14.15; 1Jh 5.3.Bí ẹ̀yin bá pa òfin mi mọ́, ẹ ó dúró nínú ìfẹ́ mi; gẹ́gẹ́ bí èmi ti pa òfin Baba mi mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀. 11Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí ayọ̀ mi kí ó lè wà nínú yín, àti kí ayọ̀ yín kí ó lè kún. 12Èyí ni òfin mi, pé kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti fẹ́ràn yín. 1315.13: Ro 5.7; Jh 10.11.Kò sí ẹnìkan tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé ẹnìkan fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. 1415.14: Lk 12.4.Ọ̀rẹ́ mi ni ẹ̀yin ń ṣe, bí ẹ bá ṣe ohun tí èmi pàṣẹ fún yín. 15Èmi kò pè yín ní ọmọ ọ̀dọ̀ mọ́; nítorí ọmọ ọ̀dọ̀ kò mọ ohun tí olúwa rẹ̀ ń ṣe: ṣùgbọ́n èmi pè yín ní ọ̀rẹ́ nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá, mo ti fihàn fún yín. 1615.16: Jh 6.70; 13.18; 14.13; 16.23.Kì í ṣe ẹ̀yin ni ó yàn mí, ṣùgbọ́n èmi ni ó yàn yín, mo sì fi yín sípò, kí ẹ̀yin kí ó lè lọ, kí ẹ sì so èso, àti kí èso yín lè dúró; kí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, kí ó lè fi í fún yín. 17Nǹkan wọ̀nyí ni mo pàṣẹ fún yín pé, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín.

Ayé kórìíra àwọn ọmọ-ẹ̀yìn

1815.18: Jh 7.7; 1Jh 3.13; Mt 10.22; 24.9.“Bí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé, ó ti kórìíra mi ṣáájú yín. 19Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ń ṣe ti ayé, ayé ìbá fẹ́ yin bi àwọn tirẹ̀; gẹ́gẹ́ bi o ṣe ri tí ẹ̀yin kì ń ṣe ti ayé, ṣùgbọ́n èmi ti yàn yín kúrò nínú ayé, nítorí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín. 2015.20: Jh 13.16; Mt 10.24; 1Kọ 4.12; Ap 4.17; 1Pt 4.14; If 2.3.Ẹ rántí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín pé, ‘Ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju olúwa rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n ó ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú: bí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọ́n ó sì pa tiyín mọ́ pẹ̀lú. 21Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n yóò ṣe sí yín, nítorí orúkọ mi, nítorí tí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi. 2215.22: Jh 9.41.Ìbá ṣe pé èmi kò ti wá kí n sì ti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n di aláìríwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 23Ẹni tí ó bá kórìíra mi, ó kórìíra Baba mi pẹ̀lú. 24Ìbá ṣe pé èmi kò ti ṣe iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì láàrín wọn tí ẹlòmíràn kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n sì rí, wọ́n sì kórìíra èmi àti Baba mi. 2515.25: Sm 35.19; 69.4.Ṣùgbọ́n èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ nínú òfin wọn kí ó lè ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi ní àìnídìí.’

2615.26: Jh 14.16,26; 16.7; 1Jh 2.1; 5.7.“Ṣùgbọ́n nígbà tí Olùtùnú náà bá dé, ẹni tí èmi ó rán sí yín láti ọ̀dọ̀ Baba wá, àní Ẹ̀mí òtítọ́ nì, tí ń ti ọ̀dọ̀ Baba wá, òun náà ni yóò jẹ́rìí mi: 2715.27: Jh 19.35; 21.24; 1Jh 4.14.Ẹ̀yin pẹ̀lú yóò sì jẹ́rìí mi, nítorí tí ẹ̀yin ti wà pẹ̀lú mi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wá.