Job 38 – KJV & YCB

King James Version

Job 38:1-41

1Then the LORD answered Job out of the whirlwind, and said, 2Who is this that darkeneth counsel by words without knowledge? 3Gird up now thy loins like a man; for I will demand of thee, and answer thou me.38.3 answer…: Heb. make me know

4Where wast thou when I laid the foundations of the earth? declare, if thou hast understanding.38.4 hast…: Heb. knowest understanding 5Who hath laid the measures thereof, if thou knowest? or who hath stretched the line upon it? 6Whereupon are the foundations thereof fastened? or who laid the corner stone thereof;38.6 foundations: Heb. sockets38.6 fastened: Heb. made to sink? 7When the morning stars sang together, and all the sons of God shouted for joy? 8Or who shut up the sea with doors, when it brake forth, as if it had issued out of the womb? 9When I made the cloud the garment thereof, and thick darkness a swaddlingband for it, 10And brake up for it my decreed place, and set bars and doors,38.10 brake…: or, established my decree upon it 11And said, Hitherto shalt thou come, but no further: and here shall thy proud waves be stayed?38.11 thy…: Heb. the pride of thy waves

12Hast thou commanded the morning since thy days; and caused the dayspring to know his place; 13That it might take hold of the ends of the earth, that the wicked might be shaken out of it?38.13 ends: Heb. wings 14It is turned as clay to the seal; and they stand as a garment. 15And from the wicked their light is withholden, and the high arm shall be broken. 16Hast thou entered into the springs of the sea? or hast thou walked in the search of the depth? 17Have the gates of death been opened unto thee? or hast thou seen the doors of the shadow of death? 18Hast thou perceived the breadth of the earth? declare if thou knowest it all. 19Where is the way where light dwelleth? and as for darkness, where is the place thereof, 20That thou shouldest take it to the bound thereof, and that thou shouldest know the paths to the house thereof?38.20 to the bound: or, at, etc 21Knowest thou it, because thou wast then born? or because the number of thy days is great? 22Hast thou entered into the treasures of the snow? or hast thou seen the treasures of the hail, 23Which I have reserved against the time of trouble, against the day of battle and war? 24By what way is the light parted, which scattereth the east wind upon the earth?

25Who hath divided a watercourse for the overflowing of waters, or a way for the lightning of thunder; 26To cause it to rain on the earth, where no man is; on the wilderness, wherein there is no man; 27To satisfy the desolate and waste ground; and to cause the bud of the tender herb to spring forth? 28Hath the rain a father? or who hath begotten the drops of dew? 29Out of whose womb came the ice? and the hoary frost of heaven, who hath gendered it? 30The waters are hid as with a stone, and the face of the deep is frozen.38.30 is…: Heb. is taken 31Canst thou bind the sweet influences of Pleiades, or loose the bands of Orion?38.31 Pleiades: or, the seven stars: Heb. Cimah38.31 Orion: Heb. Cesil? 32Canst thou bring forth Mazzaroth in his season? or canst thou guide Arcturus with his sons?38.32 Mazzaroth: or, the twelve signs38.32 guide: Heb. guide them 33Knowest thou the ordinances of heaven? canst thou set the dominion thereof in the earth? 34Canst thou lift up thy voice to the clouds, that abundance of waters may cover thee? 35Canst thou send lightnings, that they may go, and say unto thee, Here we are?38.35 Here…: Heb. Behold us? 36Who hath put wisdom in the inward parts? or who hath given understanding to the heart? 37Who can number the clouds in wisdom? or who can stay the bottles of heaven,38.37 stay: Heb. cause to lie down 38When the dust groweth into hardness, and the clods cleave fast together?38.38 groweth…: or, is turned into mire: Heb. is poured 39Wilt thou hunt the prey for the lion? or fill the appetite of the young lions,38.39 the appetite: Heb. the life 40When they couch in their dens, and abide in the covert to lie in wait? 41Who provideth for the raven his food? when his young ones cry unto God, they wander for lack of meat.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 38:1-41

Ọlọ́run pe Jobu níjà

1Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé:

2“Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìlóye

láti fi ṣókùnkùn bo ìmọ̀ mi?

3Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí,

nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ

kí o sì dá mi lóhùn.

4“Níbo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀?

Wí bí ìwọ bá mòye.

5Ta ni ó fi ìwọ̀n rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n?

Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ?

6Lórí ibo ni a gbé kan ìpìlẹ̀ rẹ̀ mọ́,

tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀,

7Nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ kọrin pọ̀,

tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run hó ìhó ayọ̀?

8“Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi Òkun mọ́,

nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá,

9Nígbà tí mo fi àwọsánmọ̀ ṣe aṣọ rẹ̀,

tí mo sì fi òkùnkùn biribiri ṣe ọ̀já ìgbà inú rẹ̀,

10Nígbà tí mo ti pàṣẹ ìpinnu mi fún un,

tí mo sì ṣe bèbè àti ìlẹ̀kùn,

11Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé, kí o má sì rékọjá,

níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ?

12“Ìwọ pàṣẹ fún òwúrọ̀ láti ìgbà ọjọ́ rẹ̀ wá,

ìwọ sì mú ìlà-oòrùn mọ ipò rẹ̀,

13Kí ó lè di òpin ilẹ̀ ayé mú,

ki a lè gbọ́n àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú rẹ̀?

14Kí ó yí padà bí amọ̀ fún èdìdì amọ̀,

kí gbogbo rẹ̀ kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni pé nínú aṣọ ìgúnwà.

15A sì fa ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn búburú,

apá gíga ni a sì ṣẹ́.

16“Ìwọ ha wọ inú ìsun Òkun lọ rí bí?

Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá?

17A ha ṣílẹ̀kùn ikú sílẹ̀ fún ọ rí bí,

ìwọ sì rí ìlẹ̀kùn òjìji òkú?

18Ìwọ mòye ìbú ayé bí?

Sọ bí ìwọ bá mọ gbogbo èyí.

19“Ọ̀nà wo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé?

Bí ó ṣe ti òkùnkùn, níbo ni ipò rẹ̀,

20Tí ìwọ í fi mú un lọ sí ibi àlá rẹ̀,

tí ìwọ ó sì le mọ ipa ọ̀nà lọ sínú ilé rẹ̀?

21Ìwọ mọ èyí, nítorí nígbà náà ni a bí ọ?

Iye ọjọ́ rẹ sì pọ̀.

22“Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì òjò lọ rí bí,

ìwọ sì rí ilé ìṣúra yìnyín rí,

23Tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu,

dé ọjọ́ ogun àti ìjà?

24Ọ̀nà wo ni ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ń la,

tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé?

25Ta ni ó la ipadò fún ẹ̀kún omi,

àti ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,

26láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tí ènìyàn kò sí,

ní aginjù níbi tí ènìyàn kò sí;

27láti mú ilẹ̀ tútù, ijù àti aláìro

láti mú àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewéko rú jáde?

28Òjò ha ní baba bí?

Tàbí ta ni o bí ìkún ìṣe ìrì?

29Láti inú ta ni ìdì omi ti jáde wá?

Ta ni ó bí ìrì dídì ọ̀run?

30Nígbà tí omi di líle bí òkúta,

nígbà tí ojú ibú ńlá sì dìpọ̀.

31“Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀ Pleiadesi dáradára?

Tàbí ìwọ le tún di Ìràwọ̀ Orioni?

32Ìwọ le mú àwọn ààmì méjìlá ìràwọ̀ Masaroti jáde wá nígbà àkókò wọn?

Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Beari pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀?

33Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run?

Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé?

34“Ìwọ le gbé ohùn rẹ sókè dé àwọsánmọ̀

kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kí ó lè bò ọ́?

35Ìwọ le rán mọ̀nàmọ́ná kí wọn kí ó le lọ,

ní ọ̀nà wọn kí wọn kí ó sì wí fún wọn pé, ‘àwa nìyí’?

36Ta ni ó fi ọgbọ́n pamọ́ sí odò ikùn

tàbí tí ó fi òye sínú àyà?

37Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọsánmọ̀?

Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde,

38Nígbà tí erùpẹ̀ di líle,

àti ògúlùtu dìpọ̀?

39“Ìwọ ha dẹ ọdẹ fún abo kìnnìún bí?

Ìwọ ó sì tẹ ebi ẹgbọrọ kìnnìún lọ́rùn,

40Nígbà tí wọ́n bá mọ́lẹ̀ nínú ihò

tí wọ́n sì ba ní ibùba de ohun ọdẹ?

41Ta ni ó ń pèsè ohun jíjẹ fún ẹyẹ ìwò,

nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ń ké pe Ọlọ́run,

tí wọ́n sì máa ń fò kiri nítorí àìní ohun jíjẹ?