Job 10 – KJV & YCB

King James Version

Job 10:1-22

1My soul is weary of my life; I will leave my complaint upon myself; I will speak in the bitterness of my soul.10.1 weary…: or, cut off while I live 2I will say unto God, Do not condemn me; shew me wherefore thou contendest with me. 3Is it good unto thee that thou shouldest oppress, that thou shouldest despise the work of thine hands, and shine upon the counsel of the wicked?10.3 work: Heb. labour 4Hast thou eyes of flesh? or seest thou as man seeth? 5Are thy days as the days of man? are thy years as man’s days, 6That thou enquirest after mine iniquity, and searchest after my sin? 7Thou knowest that I am not wicked; and there is none that can deliver out of thine hand.10.7 Thou…: Heb. It is upon thy knowledge

8Thine hands have made me and fashioned me together round about; yet thou dost destroy me.10.8 have…: Heb. took pains about me 9Remember, I beseech thee, that thou hast made me as the clay; and wilt thou bring me into dust again? 10Hast thou not poured me out as milk, and curdled me like cheese? 11Thou hast clothed me with skin and flesh, and hast fenced me with bones and sinews.10.11 fenced: Heb. hedged 12Thou hast granted me life and favour, and thy visitation hath preserved my spirit. 13And these things hast thou hid in thine heart: I know that this is with thee.

14If I sin, then thou markest me, and thou wilt not acquit me from mine iniquity. 15If I be wicked, woe unto me; and if I be righteous, yet will I not lift up my head. I am full of confusion; therefore see thou mine affliction; 16For it increaseth. Thou huntest me as a fierce lion: and again thou shewest thyself marvellous upon me. 17Thou renewest thy witnesses against me, and increasest thine indignation upon me; changes and war are against me.10.17 witnesses: that is, plagues 18Wherefore then hast thou brought me forth out of the womb? Oh that I had given up the ghost, and no eye had seen me! 19I should have been as though I had not been; I should have been carried from the womb to the grave. 20Are not my days few? cease then, and let me alone, that I may take comfort a little, 21Before I go whence I shall not return, even to the land of darkness and the shadow of death; 22A land of darkness, as darkness itself; and of the shadow of death, without any order, and where the light is as darkness.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jobu 10:1-22

Àròyé Jobu tẹ̀síwájú

1“Agara ìwà ayé mi dá mi tán,

èmi yóò tú àròyé mi sókè lọ́dọ̀ mi,

èmi yóò máa sọ̀rọ̀ nínú kíkorò ìbìnújẹ́ ọkàn mi.

2Èmi yóò wí fún Ọlọ́run pé: má ṣe dá mi lẹ́bi;

fihàn mí nítorí ìdí ohun tí ìwọ fi ń bá mi jà.

3Ó ha tọ́ tí ìwọ ìbá fi máa ni mí lára,

tí ìwọ ìbá fi máa gan iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,

tí ìwọ yóò fi máa tàn ìmọ́lẹ̀ sí ìmọ̀ ènìyàn búburú.

4Ojú rẹ kì ha ṣe ojú ènìyàn bí?

Tàbí ìwọ a máa ríran bí ènìyàn ti í ríran?

5Ọjọ́ rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn,

ọdún rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn?

6Tí ìwọ fi ń béèrè àìṣedéédéé mi,

tí ìwọ sì fi wá ẹ̀ṣẹ̀ mi rí?

7Ìwọ mọ̀ pé èmi kì í ṣe oníwà búburú,

kò sì sí ẹni tí ó le gbà mí kúrò ní ọwọ́ rẹ?

8“Ọwọ́ rẹ ni ó mọ mi, tí ó sì da mi.

Síbẹ̀ ìwọ tún yípadà láti jẹ mí run.

9Èmi bẹ̀ ọ́ rántí pé ìwọ ti mọ mí bí amọ̀;

ìwọ yóò ha sì tún mú mi padà lọ sínú erùpẹ̀?

10Ìwọ kò ha ti tú mí dà jáde bí i wàrà,

ìwọ kò sì mú mí dìpọ̀ bí i wàràǹkàṣì?

11Ìwọ sá ti fi àwọ̀ ẹran-ara wọ̀ mí,

ìwọ sì fi egungun àti iṣan ṣọgbà yí mi ká.

12Ìwọ ti fún mi ní ẹ̀mí àti ojúrere,

ìbẹ̀wò rẹ sì pa ọkàn mi mọ́.

13“Nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ sì ti fi pamọ́ nínú rẹ;

èmi mọ̀ pé, èyí ń bẹ ní ọkàn rẹ.

14Bí mo bá ṣẹ̀, nígbà náà ni ìwọ yóò máa ṣọ́ mi

ìwọ kì yóò sì dárí àìṣedéédéé mi jì.

15Bí mo bá ṣe ẹni búburú, ègbé ni fún mi!

Bí mo bá sì ṣe ẹni rere,

bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì le gbe orí mi sókè.

Èmi dààmú, mo si wo ìpọ́njú mi.

16Bí mo bá gbé orí mi ga. Ìwọ ń dẹ mí kiri bi i kìnnìún;

àti pẹ̀lú, ìwọ a sì fi ara rẹ hàn fún mi ní ìyànjú.

17Ìwọ sì tún mun àwọn ẹlẹ́rìí rẹ dìde sí mi

di ọ̀tún, Ìwọ sì sọ ìrunú rẹ di púpọ̀ sí mi;

Àwọn ogun rẹ si dìde sinmi bi igbe omi Òkun.

18“Nítorí kí ni ìwọ ṣe mú mi jáde láti inú wá?

Háà! Èmi ìbá kúkú ti kú, ojúkójú kì bá tí rí mi.

19Tí kò bá le jẹ́ pé èmi wà láààyè,

À bá ti gbé mi láti inú lọ isà òkú.

20Ọjọ́ mi kò ha kúrú bí? Rárá!

Dáwọ́ dúró, kí ó sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ mi.

Nítorí kí èmi lè ni ayọ̀ ní ìṣẹ́jú kan.

21Kí èmi kí ó tó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà sẹ́yìn mọ́,

Àní si ilẹ̀ òkùnkùn àti òjìji ikú.

22Ilẹ̀ òkùnkùn bí òkùnkùn tìkára rẹ̀,

Àti ti òjìji ikú àti rúdurùdu,

Níbi tí ìmọ́lẹ̀ dàbí òkùnkùn.”