Acts 23 – KJV & YCB

King James Version

Acts 23:1-35

1And Paul, earnestly beholding the council, said, Men and brethren, I have lived in all good conscience before God until this day. 2And the high priest Ananias commanded them that stood by him to smite him on the mouth. 3Then said Paul unto him, God shall smite thee, thou whited wall: for sittest thou to judge me after the law, and commandest me to be smitten contrary to the law? 4And they that stood by said, Revilest thou God’s high priest? 5Then said Paul, I wist not, brethren, that he was the high priest: for it is written, Thou shalt not speak evil of the ruler of thy people. 6But when Paul perceived that the one part were Sadducees, and the other Pharisees, he cried out in the council, Men and brethren, I am a Pharisee, the son of a Pharisee: of the hope and resurrection of the dead I am called in question. 7And when he had so said, there arose a dissension between the Pharisees and the Sadducees: and the multitude was divided. 8For the Sadducees say that there is no resurrection, neither angel, nor spirit: but the Pharisees confess both. 9And there arose a great cry: and the scribes that were of the Pharisees’ part arose, and strove, saying, We find no evil in this man: but if a spirit or an angel hath spoken to him, let us not fight against God. 10And when there arose a great dissension, the chief captain, fearing lest Paul should have been pulled in pieces of them, commanded the soldiers to go down, and to take him by force from among them, and to bring him into the castle. 11And the night following the Lord stood by him, and said, Be of good cheer, Paul: for as thou hast testified of me in Jerusalem, so must thou bear witness also at Rome. 12And when it was day, certain of the Jews banded together, and bound themselves under a curse, saying that they would neither eat nor drink till they had killed Paul. 13And they were more than forty which had made this conspiracy. 14And they came to the chief priests and elders, and said, We have bound ourselves under a great curse, that we will eat nothing until we have slain Paul. 15Now therefore ye with the council signify to the chief captain that he bring him down unto you to morrow, as though ye would enquire something more perfectly concerning him: and we, or ever he come near, are ready to kill him. 16And when Paul’s sister’s son heard of their lying in wait, he went and entered into the castle, and told Paul. 17Then Paul called one of the centurions unto him, and said, Bring this young man unto the chief captain: for he hath a certain thing to tell him. 18So he took him, and brought him to the chief captain, and said, Paul the prisoner called me unto him, and prayed me to bring this young man unto thee, who hath something to say unto thee. 19Then the chief captain took him by the hand, and went with him aside privately, and asked him, What is that thou hast to tell me? 20And he said, The Jews have agreed to desire thee that thou wouldest bring down Paul to morrow into the council, as though they would enquire somewhat of him more perfectly. 21But do not thou yield unto them: for there lie in wait for him of them more than forty men, which have bound themselves with an oath, that they will neither eat nor drink till they have killed him: and now are they ready, looking for a promise from thee. 22So the chief captain then let the young man depart, and charged him, See thou tell no man that thou hast shewed these things to me. 23And he called unto him two centurions, saying, Make ready two hundred soldiers to go to Cæsarea, and horsemen threescore and ten, and spearmen two hundred, at the third hour of the night; 24And provide them beasts, that they may set Paul on, and bring him safe unto Felix the governor. 25And he wrote a letter after this manner: 26Claudius Lysias unto the most excellent governor Felix sendeth greeting. 27This man was taken of the Jews, and should have been killed of them: then came I with an army, and rescued him, having understood that he was a Roman. 28And when I would have known the cause wherefore they accused him, I brought him forth into their council: 29Whom I perceived to be accused of questions of their law, but to have nothing laid to his charge worthy of death or of bonds. 30And when it was told me how that the Jews laid wait for the man, I sent straightway to thee, and gave commandment to his accusers also to say before thee what they had against him. Farewell. 31Then the soldiers, as it was commanded them, took Paul, and brought him by night to Antipatris. 32On the morrow they left the horsemen to go with him, and returned to the castle: 33Who, when they came to Cæsarea, and delivered the epistle to the governor, presented Paul also before him. 34And when the governor had read the letter, he asked of what province he was. And when he understood that he was of Cilicia; 35I will hear thee, said he, when thine accusers are also come. And he commanded him to be kept in Herod’s judgment hall.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Ìṣe àwọn Aposteli 23:1-35

1Paulu tẹjúmọ́ ìgbìmọ̀, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi tí ń fi gbogbo ẹ̀rí ọkàn rere lo ayé mi níwájú Ọlọ́run títí fi di òní yìí.” 2Nígbà yìí ni Anania olórí àlùfáà pàṣẹ fún àwọn tí ó dúró tí Paulu pé, kí wọn ó gbá a lẹ́nu. 3Nígbà náà ni Paulu wí fún un pé, “Ọlọ́run yóò lù ọ́, ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun: ìwọ jókòó láti dá mi lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, ṣùgbọ́n ìwọ gan an rú òfin nípa pípàṣẹ pé kí a lù mí!”

4Àwọn tí ó dúró tì Paulu sì wí pé, “Ìwọ́ ń gan olórí àlùfáà Ọlọ́run?”

523.5: El 22.28.Paulu sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi kò mọ̀ pé olórí àlùfáà ni: nítorí a tí kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní búburú.’ ”

6Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu ṣàkíyèsí pé, apá kan wọn jẹ́ Sadusi, apá kan sì jẹ́ Farisi, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, Èmi jẹ́ Farisi, ọmọ Farisi sì ni èmi. Mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.” 7Nígbà tí ó sì tí wí èyí, ìyapa dé láàrín àwọn Farisi àti àwọn Sadusi: àjọ sì pín sì méjì. 8Nítorí tí àwọn Sadusi wí pé, kò sì àjíǹde, tàbí angẹli, tàbí ẹ̀mí: ṣùgbọ́n àwọn Farisi jẹ́wọ́ méjèèjì:

9Ó sì di ariwo ńlá, nínú àwọn olùkọ́ òfin tí ó wà ni apá tí àwọn Farisi dìde, wọ́n ń jà, wí pé, “Àwa kò rí ohun búburú kan lára ọkùnrin yìí,” wọ́n wí “àwa kò sì mọ̀ nítòótọ́ bí angẹli kan tàbí ẹ̀mí kan ń ba à sọ̀rọ̀?” 10Nígbà tí ìyapa sì di ńlá, tí olórí ogun bẹ̀rù kí Paulu má ba à di fífàya lọ́wọ́ wọn, ó pàṣẹ pé ki àwọn ọmọ-ogun sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ipá mú un kúrò láàrín wọn, kí wọn sì mú un wá sínú àgọ́ àwọn ológun.

11Ní òru ọjọ́ náà Olúwa dúró tì Paulu, ó wí pé, “Mú ọkàn le! Bí ìwọ ti jẹ́rìí fún mi ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò lè ṣàìjẹ́rìí ni Romu pẹ̀lú.”

Ìdìtẹ̀ láti pa Paulu

12Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn Júù kan dìtẹ̀, wọ́n fi ara wọn bú pé, àwọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ní àwọn kì yóò mú títí àwọn ó fi pa Paulu: 13Àwọn tí ó dìtẹ̀ yìí sì ju ogójì ènìyàn lọ. 14Wọ́n sì tọ olórí àwọn àlùfáà àti àwọn alàgbà lọ, wọn sì wí pé, “Àwa tí fi ara wa sínú ìdè ìbúra pé, a kì yóò tọ́ oúnjẹ kan wò títí àwa ó fi pa Paulu. 15Ǹjẹ́ nísinsin yìí kí ẹ̀yin pẹ̀lú àjọ ìgbìmọ̀ wí fún olórí ogun, kí ó mú un sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá, bí ẹni pé ẹ̀yin ń fẹ́ wádìí ọ̀ràn rẹ̀ dájúdájú. Kí ó tó súnmọ́ tòsí, àwa ó ti múra láti pa á.”

16Nígbà tí ọmọ arábìnrin Paulu sí gbúròó ìdìtẹ̀ wọn, ó lọ, ó sì wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó sì sọ fún Paulu.

17Paulu sì pé ọ̀kan nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Mú ọmọkùnrin yìí tọ olórí ogun lọ: nítorí ó ní nǹkan láti sọ fún un.” 18Ó mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ olórí ogun.

Balógun ọ̀rún náà wí pé, “Paulu òǹdè pè mi sọ́dọ̀ rẹ̀, ó síbẹ̀ mí pé ki èmi mú ọmọkùnrin yìí tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ó ní nǹkan láti sọ fún ọ.”

19Alábojútó-ogun fà á lọ́wọ́, ó sì lọ si apá kan, ó sì bi í léèrè níkọ̀kọ̀ pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ní sọ fún mi?”

20Ó sì wí pé, “Àwọn Júù fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti wá bẹ̀ ọ́, kí o mú Paulu sọ̀kalẹ̀ wá sí àjọ ìgbìmọ̀ ní ọ̀la, bí ẹni pé àwọn ń fẹ́ béèrè nǹkan dájúdájú nípa rẹ̀. 21Nítorí náà má ṣe gbọ́ tiwọn: nítorí àwọn tí ó dènà dè é nínú wọn ju ogójì ọkùnrin lọ, tí wọ́n fi ara wọn bú pé, àwọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kì yóò mu títí àwọn o fi pa á. Wọ́n sì ti múra tan nísinsin yìí, wọ́n ń retí ìdáhùn lọ́dọ̀ rẹ.”

22Nígbà náà ni olórí ogun fi ọmọ náà sílẹ̀ láti lọ, ó sí kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe wí fún ẹnìkan pé, ìwọ fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi.”

A gbé Paulu lọ Kesarea

23Ó sì pe méjì nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ múra igba ọmọ-ogun sílẹ̀, láti lọ sí Kesarea, àti àádọ́rin ẹlẹ́ṣin, àti igba ọlọ́kọ̀, ní wákàtí kẹta òru. 24Ó sì wí pé, kí wọn pèsè ẹṣin, kí wọ́n gbé Paulu gùn ún; kí wọ́n sì lè mú un dé ọ̀dọ̀ Feliksi baálẹ̀ ní àlàáfíà.”

25Ó sì kọ ìwé kan báyìí pé:

26Kilaudiu Lisia,

Sí Feliksi baálẹ̀ ọlọ́lá jùlọ:

Àlàáfíà.

27Àwọn Júù mú ọkùnrin yìí, wọ́n sì ń pète láti pa á: nígbà náà ni mo dé pẹ̀lú ogun, mo sì gbà á lọ́wọ́ wọn nígbà tí mo gbọ́ pé ará Romu ni í ṣe. 28Nígbà tí mo sì ń fẹ́ mọ ìdí ọ̀ràn tí wọn fi ẹ̀sùn kàn án sí, mo mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí àjọ ìgbìmọ̀ wọn. 29Ẹni tí mo rí pé, wọ́n fi sùn nítorí ọ̀ràn òfin wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò dá ọ̀ràn ohun kan tí ó tọ́ sí ikú àti sí ẹ̀wọ̀n. 30Nígbà tí a sì tí jí i sọ fún mi pé, wọn yóò dènà de ọkùnrin náà, mo rán an sí ọ lọ́gán, mo sì pàṣẹ fún àwọn olùfisùn rẹ̀ pẹ̀lú, láti sọ ohun tí wọ́n bá rí wí sí i níwájú rẹ̀.

31Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gbe Paulu, wọ́n sì mú un lóru lọ si Antipatrisi, gẹ́gẹ́ bí a tí pàṣẹ fún wọn. 32Ní ọjọ́ kejì wọ́n sì fi àwọn ẹlẹ́ṣin sílẹ̀ láti máa bá a lọ, àwọn sì padà wá sínú àgọ́ àwọn ológun. 33Nígbà tí wọ́n dé Kesarea, tí wọ́n sí fi ìwé fún baálẹ̀, wọ́n mú Paulu pẹ̀lú wá síwájú rẹ̀. 34Nígbà tí ó sì ti ka ìwé náà, ó béèrè pé agbègbè ìlú wo ni tirẹ̀. Nígbà tí ó sì gbọ́ pé ará Kilikia ni; 35Ó wí pé, “Èmi yóò gbọ́ ẹjọ́ rẹ, nígbà tí àwọn olùfisùn rẹ pẹ̀lú bá dé.” Ó sì pàṣẹ pé kí wọn pa Paulu mọ́ ní abẹ́ àbojútó àwọn olùṣọ́ ní gbọ̀ngàn ìdájọ́ ààfin Herodu.