1 Corinthians 16 – KJV & YCB

King James Version

1 Corinthians 16:1-24

1Now concerning the collection for the saints, as I have given order to the churches of Galatia, even so do ye. 2Upon the first day of the week let every one of you lay by him in store, as God hath prospered him, that there be no gatherings when I come. 3And when I come, whomsoever ye shall approve by your letters, them will I send to bring your liberality unto Jerusalem. 4And if it be meet that I go also, they shall go with me. 5Now I will come unto you, when I shall pass through Macedonia: for I do pass through Macedonia. 6And it may be that I will abide, yea, and winter with you, that ye may bring me on my journey whithersoever I go. 7For I will not see you now by the way; but I trust to tarry a while with you, if the Lord permit. 8But I will tarry at Ephesus until Pentecost. 9For a great door and effectual is opened unto me, and there are many adversaries. 10Now if Timotheus come, see that he may be with you without fear: for he worketh the work of the Lord, as I also do. 11Let no man therefore despise him: but conduct him forth in peace, that he may come unto me: for I look for him with the brethren. 12As touching our brother Apollos, I greatly desired him to come unto you with the brethren: but his will was not at all to come at this time; but he will come when he shall have convenient time. 13Watch ye, stand fast in the faith, quit you like men, be strong. 14Let all your things be done with charity. 15I beseech you, brethren, (ye know the house of Stephanas, that it is the firstfruits of Achaia, and that they have addicted themselves to the ministry of the saints,) 16That ye submit yourselves unto such, and to every one that helpeth with us, and laboureth. 17I am glad of the coming of Stephanas and Fortunatus and Achaicus: for that which was lacking on your part they have supplied. 18For they have refreshed my spirit and yours: therefore acknowledge ye them that are such.

19The churches of Asia salute you. Aquila and Priscilla salute you much in the Lord, with the church that is in their house. 20All the brethren greet you. Greet ye one another with an holy kiss. 21The salutation of me Paul with mine own hand. 22If any man love not the Lord Jesus Christ, let him be Anathema Maranatha. 23The grace of our Lord Jesus Christ be with you. 24My love be with you all in Christ Jesus. Amen.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kọrinti 16:1-24

Ìkójọpọ̀ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run

116.1: Ap 24.17.Ǹjẹ́ ní ti ìdáwó fún àwọn ènìyàn mímọ́, bí mo tí wí fún àwọn ìjọ Galatia, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní kí ẹ ṣe. 216.2: Ap 20.7; 2Kọ 9.4-5.Ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, kí olúkúlùkù yín fi sínú ìṣúra lọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni apá kan, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe rere fún ún, ki ó má ṣe si ìkójọ nígbà tí mo bá dé. 316.3: 2Kọ 8.18-19.Àti nígbà ti mo bá dé, àwọn ẹni tí ẹ bá yàn, àwọn ni èmi ó rán láti mú ẹ̀bùn yín gòkè lọ si Jerusalẹmu. 4Bí ó bá sì yẹ kí èmí lọ pẹ̀lú, wọn ó sì bá mi lọ.

Ìbéèrè ti ara ẹni

516.5: Ro 15.26; Ap 19.21.Ṣùgbọ́n èmi yóò tọ̀ yin wá, nígbà tí èmí bá ti kọjá láàrín Makedonia: nítorí èmi yóò kọjá láàrín Makedonia. 6Bóyá èmi ó sì dúró pẹ̀lú yín, tàbí kí n tilẹ̀ lo àkókò òtútù, ki ẹ̀yin lé sìn mí ni ọ̀nà àjò mí, níbikíbi tí mo bá ń lọ. 716.7: Ap 18.21.Nítorí èmi kò fẹ́ kan ri yín kí èmi sì ṣe bẹ́ẹ̀ kọjá lọ; nítorí èmi ń retí àti dúró lọ́dọ̀ yín díẹ̀, bí Olúwa bá fẹ́ 816.8: Ap 18.19.Ṣùgbọ́n èmi yóò dúró ni Efesu títí dí Pentikosti. 916.9: Ap 19.9.Nítorí pé ìlẹ̀kùn ńlá láti ṣe iṣẹ́ gidi ṣí sílẹ̀ fún mí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn ọ̀tá tí ń bẹ.

1016.10: Ap 16.1.Ǹjẹ́ bí Timotiu bá dé, ẹ jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ yín láìbẹ̀rù: nítorí òun ń ṣé iṣẹ́ Olúwa, bí èmi pẹ̀lú ti ń ṣe. 11Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá; nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin.

1216.12: Ap 18.24.Ṣùgbọ́n ní ti Apollo arákùnrin wa, mo bẹ̀ ẹ́ púpọ̀ láti tọ̀ yín wá pẹ̀lú àwọn arákùnrin: Ṣùgbọ́n kì í ṣe ìfẹ́ rẹ̀ rárá láti wà nísinsin yìí, ṣùgbọ́n òun yóò wá nígbà tí ààyè bá ṣí sílẹ̀ fún un.

1316.13: Sm 31.24; Ef 6.10.Ẹ máa ṣọ́ra, ẹ dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, ẹ ṣe bi ọkùnrin tí ó ní ìgboyà, ẹ jẹ́ alágbára. 14Ẹ máa ṣe ohun gbogbo nínú ìfẹ́.

15Ǹjẹ́ mo bẹ̀ yín ará, ẹ ṣá mọ ilé Stefana pé, àwọn ni ẹni àkọ́kọ́ tó gba Jesu ní Akaia, àti pé, wọn sì tí fi ará wọn fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ènìyàn mímọ́. 16Kí ẹ̀yin tẹríba fún irú àwọn báwọ̀nyí, àti fún olúkúlùkù olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú wa tí ó sì ń ṣe làálàá. 17Mo láyọ̀ fún wíwá Stefana àti Fortunatu àti Akaiku: nítorí èyí tí ó kù nípá tí yín wọ́n ti fi kún un. 18Nítorí tí wọ́n tu ẹ̀mí mí lára àti tiyín: nítorí náà, ẹ máa gba irú àwọn ti ó rí bẹ́ẹ̀.

Ìkíni ìkẹyìn

1916.19: Ap 18.2; Ro 16.5.Àwọn ìjọ ni Asia kí í yín.

Akuila àti Priskilla kí í yín púpọ̀ nínú Olúwa, pẹ̀lú ìjọ tí ó wà ni ilé wọn.

2016.20: Ro 16.16.Gbogbo àwọn arákùnrin kí í yín.

Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí ara yín.

2116.21: Kl 4.18; Ga 6.11; 2Tẹ 3.17.Ìkíni ti èmi Paulu, láti ọwọ́ èmi tìkára mi wá.

2216.22: Ro 9.3.Bí ẹnikẹ́ni kò bá ní ìfẹ́ Jesu Kristi Olúwa, jẹ́ kí ó dì ẹni ìfibú. Máa bọ Olúwa wa!

2316.23: Ro 16.20.Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa kí ó wà pẹ̀lú yín!

24Ìfẹ́ mi wá pẹ̀lú gbogbo yín nínú Kristi Jesu. Àmín.