1 Corinthians 12 – KJV & YCB

King James Version

1 Corinthians 12:1-31

1Now concerning spiritual gifts, brethren, I would not have you ignorant. 2Ye know that ye were Gentiles, carried away unto these dumb idols, even as ye were led. 3Wherefore I give you to understand, that no man speaking by the Spirit of God calleth Jesus accursed: and that no man can say that Jesus is the Lord, but by the Holy Ghost. 4Now there are diversities of gifts, but the same Spirit. 5And there are differences of administrations, but the same Lord. 6And there are diversities of operations, but it is the same God which worketh all in all. 7But the manifestation of the Spirit is given to every man to profit withal. 8For to one is given by the Spirit the word of wisdom; to another the word of knowledge by the same Spirit; 9To another faith by the same Spirit; to another the gifts of healing by the same Spirit; 10To another the working of miracles; to another prophecy; to another discerning of spirits; to another divers kinds of tongues; to another the interpretation of tongues: 11But all these worketh that one and the selfsame Spirit, dividing to every man severally as he will. 12For as the body is one, and hath many members, and all the members of that one body, being many, are one body: so also is Christ. 13For by one Spirit are we all baptized into one body, whether we be Jews or Gentiles, whether we be bond or free; and have been all made to drink into one Spirit. 14For the body is not one member, but many. 15If the foot shall say, Because I am not the hand, I am not of the body; is it therefore not of the body? 16And if the ear shall say, Because I am not the eye, I am not of the body; is it therefore not of the body? 17If the whole body were an eye, where were the hearing? If the whole were hearing, where were the smelling? 18But now hath God set the members every one of them in the body, as it hath pleased him. 19And if they were all one member, where were the body? 20But now are they many members, yet but one body. 21And the eye cannot say unto the hand, I have no need of thee: nor again the head to the feet, I have no need of you. 22Nay, much more those members of the body, which seem to be more feeble, are necessary: 23And those members of the body, which we think to be less honourable, upon these we bestow more abundant honour; and our uncomely parts have more abundant comeliness. 24For our comely parts have no need: but God hath tempered the body together, having given more abundant honour to that part which lacked: 25That there should be no schism in the body; but that the members should have the same care one for another. 26And whether one member suffer, all the members suffer with it; or one member be honoured, all the members rejoice with it. 27Now ye are the body of Christ, and members in particular. 28And God hath set some in the church, first apostles, secondarily prophets, thirdly teachers, after that miracles, then gifts of healings, helps, governments, diversities of tongues. 29Are all apostles? are all prophets? are all teachers? are all workers of miracles? 30Have all the gifts of healing? do all speak with tongues? do all interpret? 31But covet earnestly the best gifts: and yet shew I unto you a more excellent way.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Kọrinti 12:1-31

Ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́

1Ní ti Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin ará, kò yẹ́ kí ẹ jẹ́ òpè. 212.2: Ef 2.11-12.Ẹ̀yin kò mọ̀ pé nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ kèfèrí, a fà yín lọ sọ́dọ̀ àwọn odi òrìṣà. 312.3: Ro 10.9.Nítorí náà, èmí ń sọ fún un yín pé kò sí ẹni ti ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run tí ó lè wí pé, “Ẹni ìfibú ni Jesu,” àti pé kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, “Olúwa ni Jesu,” bí kò ṣe nípasẹ̀ Ẹ̀mí mímọ́.

4Ǹjẹ́ onírúurú ẹ̀bùn ni ó wà, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí kan náà ni o ń pín wọn. 5Onírúurú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà sì ni. 6Onírúurú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ó sì wà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà ni ẹni tí ń ṣiṣẹ́ gbogbo wọn nínú gbogbo wọn.

7Ṣùgbọ́n à ń fi ẹ̀bùn Ẹ̀mí fún olúkúlùkù ènìyàn láti fi jèrè. 8Ẹ̀mí Mímọ́ lè fún ẹnìkan ní ọgbọ́n láti lè fún ènìyàn nímọ̀ràn, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ ńlá. Láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà ni èyí ti wá. 9Ó fi ẹ̀bùn ìgbàgbọ́ fún ẹlòmíràn, ẹlòmíràn ló sì fi agbára ìwòsàn fún nípa Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà. 1012.10: 1Kọ 14.26.Ó fi agbára fún àwọn mìíràn láti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu. Ó fún àwọn mìíràn lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àti láti wàásù pẹ̀lú ìmísí. Bákan náà ló fún àwọn kan lẹ́bùn láti mọ ìyàtọ̀ láàrín àwọn ẹ̀mí. Ó fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn àti agbára láti lè sọ èdè tí wọn kò mọ̀. Bákan náà ó fún àwọn ẹlòmíràn lágbára láti mọ̀ àti láti túmọ̀ èdè tí wọn kò gbọ́ rí. 11Àní, Ẹ̀mí kan ṣoṣo ní ń fún ni ní gbogbo ẹ̀bùn àti agbára wọ̀nyí. Òun ni ẹni tí ń ṣe ìpinnu ẹ̀bùn tí ó yẹ láti fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.

1212.12: Ro 12.4.Ara jẹ́ ọ̀kan tí ó ní àwọn ẹ̀yà púpọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹ̀yà ara tí ó pọ̀ wọ̀nyí ni ó papọ̀ láti jẹ́ ara kan ṣoṣo. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú ara Kristi tí í ṣe ìjọ. 1312.13: Ga 3.28; Kl 3.11; Ef 2.13-18; Jh 7.37-39.Nítorí pé nínú Ẹ̀mí kan ní a ti bamitiisi gbogbo wa sínú ara kan, ìbá à ṣe Júù, ìbá à ṣe Giriki, ìbá à ṣe ẹrú, ìbá à ṣe òmìnira, gbogbo wa ni a mu nínú Ẹ̀mí Mímọ́ kan náà. 14Bẹ́ẹ̀ ni, ara, kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo bí kò ṣe púpọ̀.

15Tí ẹsẹ̀ bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ọwọ́, èmi kì í ṣe ti ara,” èyí kò wí pé kì í ṣe ọ̀kan lára nínú ẹ̀yà ara. 16Bí etí bá wí pé, “Nítorí èmi kì í ṣe ojú, èmi kì í ṣe apá kan ara,” èyí kò le mú kí ó má jẹ́ apá kan ara mọ́ 17Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, níbo ni ìgbọ́ran ìbá gbé wà? Bí gbogbo ara bá jẹ́ etí, níbo ni ìgbóórùn ìbá gbé wà? 18Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi àwọn ẹ̀yà ara si ara wa, ó sí fi ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan sí ibi tí ó fẹ́ kí ó wà. 19Bí gbogbo wọn bá sì jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo nínú ẹ̀yà ara, níbo ni ara yóò gbé wà. 20Ọlọ́run dá ẹ̀yà ara púpọ̀, ṣùgbọ́n ara kan ṣoṣo ni.

21Bí ó tí rí yìí, ojú kò lè sọ fún ọwọ́ pé, “Èmi kò nílò rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni orí kò le sọ fún ẹsẹ̀ pé, “Èmi kò nílò rẹ.” 22Àwọn ẹ̀yà ara tí ó dàbí ẹni pé wọ́n ṣe aláìlágbára jùlọ, tí ó dàbí ẹni pé kò ṣe pàtàkì rárá, àwọn gan an ni a kò le ṣe aláìnílò. 23Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yà ara tí a rò pé kò lọ́lá rárá ni àwa ń fi ọlá fún jùlọ. Àwọn ẹ̀yà ara tí a rò pé ko yẹ rárá ni àwa ń fi si ipò ọlá ẹ̀yẹ tí ó ga jùlọ. 24Nítorí pé àwọn ibi tí ó ní ẹ̀yẹ ní ara wa kò nílò ìtọ́jú ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti pa gbogbo ẹ̀yà ara pọ̀ ṣọ̀kan lọ́nà kan, ó sì ti fi ẹ̀yẹ tó ga jùlọ fún ibi tí ó ṣe aláìní. 25Kí ó má ṣe sí ìyàtọ̀ nínú ara, ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara le máa jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ara wọn. 26Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jìyà, gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a pín nínú ìyà náà. Tí a bá sì bu ọlá fún ẹ̀yà ara kan, gbogbo ẹ̀yà ara ìyókù a máa bá a yọ̀.

2712.27: Ef 1.23; 4.12; Kl 1.18,24; Ef 5.30; Ro 12.5.Gbogbo yín jẹ́ ara Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì jẹ́ ẹ̀yà ara ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ara Kristi. 2812.28: Ef 4.11; 2.20; 3.5.Ọlọ́run sì gbé àwọn mìíràn kalẹ̀ nínú ìjọ, èkínní àwọn aposteli, èkejì àwọn wòlíì, ẹ̀kẹta àwọn olùkọ́ni, lẹ́yìn náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìyanu, lẹ́yìn náà àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìmúláradá, àwọn olùrànlọ́wọ́ àti àwọn agbani nímọ̀ràn, àwọn tí ń sọ onírúurú èdè. 29Ǹjẹ́ gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ aposteli bi? Tàbí gbogbo ènìyàn ni wòlíì bí? Ṣe gbogbo ènìyàn ní olùkọ́ni? Ṣé gbogbo ènìyàn ló ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu bí? 30Ṣé gbogbo ènìyàn ló lè wonisàn bí? Rárá. Ǹjẹ́ gbogbo wa ni Ọlọ́run fún ní ẹ̀bùn láti le sọ̀rọ̀ ní èdè tí a kò ì tí ì gbọ́ rí bí? Ṣé ẹnikẹ́ni ló lè túmọ̀ èdè tí wọ́n sọ tí kò sì yé àwọn ènìyàn bí? 31Ṣùgbọ́n, ẹ máa fi ìtara ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn ti ó tóbi jù.

Síbẹ̀ èmi o fi ọ̀nà kan tí ó tayọ rékọjá hàn yín.