歴代誌Ⅱ 25 – JCB & YCB

Japanese Contemporary Bible

歴代誌Ⅱ 25:1-28

25

ユダの王アマツヤ

1アマツヤは二十五歳で王となり、二十九年間エルサレムで治めました。母親はエホアダンといい、エルサレム出身でした。 2アマツヤ王は正しいことを行いましたが、いつも本心からとは限りませんでした。 3王としての地位が固まると、彼は父の暗殺者を処刑しました。 4それでもモーセの律法を守り、その子どもたちまでは殺しませんでした。モーセの律法では、父親は子どものせいで殺されてはならず、子どもも父親のせいで殺されてはならないことになっていました。めいめいの罪のために裁かれるべきなのです。

5-6それから王は、軍を再編成し、ユダとベニヤミンの各氏族に指導者を立てました。人口調査をしてみると、槍と剣の使い手として訓練された二十歳以上の兵士が三十万人いることがわかりました。また王は、銀百タラント(三千四百キログラム)を払って、十万人の訓練された兵士をイスラエルから雇いました。 7しかし、預言者が主のことばを伝えました。「王よ、イスラエルの兵士を雇い入れてはなりません。主はその者たちとは共におられないからです。 8もし、彼らといっしょに戦いに出たら、どんなによく戦っても敗れます。神には助ける力もあれば、くじく力もあるのです。」

9アマツヤは泣き言を言いました。「あの兵士に払った金が惜しい。金のことはどうしたらよいだろう。」

「神様は、それ以上のものをあなたに与えることがおできになります。」

10そこでアマツヤは、雇い入れた兵士たちを郷里のエフライムに帰しました。このことで、彼らは侮辱されたと思い、ひどく腹を立てました。

11王は勇気を出し、軍を率いて塩の谷へ行き、そこでセイルから来た一万人を打ちました。 12ほかにも一万人を生け捕りにし、がけから突き落としたので、みな谷底の岩に砕かれて死にました。 13一方、強制送還されたイスラエルの兵士は、ベテ・ホロンからサマリヤまでの地域にあるユダの幾つかの町に侵入し、三千人を殺し、多くの戦利品を奪い去りました。

14エドム人を打ち破ったアマツヤ王は、セイルの人々の偶像を持ち帰っただけでなく、偶像を神々として祭り、その前に頭を下げ、香までたいたのです。 15これを激しく怒った主は、預言者を送って、きびしく王を問いただしました。「あなたの手から自分の民を救い出せなかったような神々を、なぜ拝むのか。」

16王は、預言者のことばをさえぎりました。「いつ私があなたに助言を求めたか。殺されたくなければ、黙っていることだ。」

「これで、はっきりしました。神様はあなたを滅ぼすおつもりです。あなたが偶像を拝み、私の勧めを聞こうとされないからです。」預言者は、警告を残して立ち去りました。

17そののち、ユダの王アマツヤは相談役の意見を取り入れて、エホアハズの子でエフーの孫に当たる、イスラエルの王ヨアシュに戦いをしかけました。 18するとヨアシュ王は、次のようなたとえをもって応じたのです。「レバノン山のあざみがレバノン山の杉に、『娘さんを息子の嫁にくれないか』と頼みました。ところが、レバノン山の野獣が通りかかり、そのあざみを踏みにじりました。 19あなたは、エドムを征服したことで鼻を高くしている。しかし、悪いことは言わないから、おとなしくしていなさい。へたな手出しはおやめなさい。さもないと、ユダの民ともども痛い目に会いますよ。」

20しかし、アマツヤは聞き入れようとしませんでした。神は、エドムの神々を拝んでいた王を滅ぼそうとしていたのです。 21両軍はユダのベテ・シェメシュでぶつかりましたが、 22ユダは総くずれになって退却しました。 23イスラエルの王ヨアシュは、負けたユダの王アマツヤを捕らえ、捕虜としてエルサレムに連れて来たうえ、エルサレムの城壁をエフライムの門から隅の門まで二百メートルにわたって取り壊すよう命じました。 24また、神殿にあったすべての財宝と金の鉢、それに王宮の財宝を運び出し、オベデ・エドムを含む人質を連れてサマリヤに帰りました。

25アマツヤ王は、イスラエルの王ヨアシュの死後、なお十五年も生き延びました。 26アマツヤのくわしい伝記は、『ユダとイスラエル諸王の年代記』に記されています。 27それには、王が神から離れたいきさつ、エルサレムで謀反が起こりラキシュへ逃げたこと、追いつめられてラキシュで殺されたことなどが記録されています。 28人々は彼の遺体を馬でエルサレムに運び、王室墓地に葬りました。

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 25:1-28

Amasiah ọba Juda

125.1-4: 2Ọb 14.2-6.Amasiah jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n (29) Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jehoadani, ó wá láti Jerusalẹmu. 2Ó ṣe ohun tí ó dára lójú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe tọkàntọkàn. 3Lẹ́yìn tí ìjọba ti wà ní ìdarí rẹ̀, ó pa àwọn oníṣẹ́ tí ó pa baba rẹ̀ ọba. 4Síbẹ̀ kò pa àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n ó ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ nínú òfin nínú ìwé Mose, níbi tí Olúwa ti paláṣẹ pé: “A kò gbọdọ̀ pa àwọn baba fún àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn ọmọ fún baba wọn; Olúkúlùkù ni kí ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”

5Amasiah, pe gbogbo àwọn ènìyàn Juda pọ̀, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn sí àwọn alákòóso ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún fún gbogbo Juda àti Benjamini, ó sì gbá iye wọn láti ẹni ogún ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ jọ, ó sì rí i pé ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) àwọn ọkùnrin ni ó ti múra fún ìsìn ogun, tí ó lè gbá ọ̀kọ̀ àti àpáta mú. 6Ó sì yá (100,000) ọ̀kẹ́ márùn-ún àwọn ọkùnrin oníjà láti Israẹli fún ọgọ́rùn-ún mẹ́wàá àwọn tálẹ́ǹtì fàdákà.

7Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run kan tọ̀ ọ́ wá ó sì wí pé, “ọba, àwọn ọ̀wọ́ ogun láti Israẹli kò gbọdọ̀ yan pẹ̀lú rẹ, nítorí tí Olúwa kò wà pẹ̀lú Israẹli kì í ṣe pẹ̀lú ẹnìkankan láti Efraimu. 8Àní, tí ẹ bá lọ jà pẹ̀lú ìmúláyàle ní ojú ogun, Ọlọ́run yóò bì ọ́ ṣubú níwájú àwọn ọ̀tá, nítorí Ọlọ́run ní agbára láti ràn ọ́ lọ́wọ́ àti láti bì ọ́ ṣubú.”

9Amasiah sì bi ènìyàn Ọlọ́run pé, “Ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì tí mo ti san fún àwọn ọ̀wọ́ ogun àwọn ọmọ Israẹli ńkọ́?”

Ènìyàn Ọlọ́run dáhùn pé “Olúwa lè fún ọ ní èyí tí ó ju ìyẹn lọ.”

10Bẹ́ẹ̀ ni Amasiah, tú àwọn ọwọ́ ogun tí ó ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Efraimu ká. Ó sì rán wọn lọ ilé. Wọ́n kún fún ìbínú pẹ̀lú Juda, wọ́n sì padà lọ ilé pẹ̀lú ìbínú ńlá.

1125.11: 2Ọb 14.7.Nígbà náà, Amasiah ko ogun rẹ jọ àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ lọ sí Àfonífojì iyọ̀, níbi tí ó ti pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) àwọn ọkùnrin Seiri. 12Àwọn ọkùnrin Juda pẹ̀lú fi agbára mú àwọn ọkùnrin ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá láààyè. Wọ́n mú wọn lọ sí orí òkè bèbè òkúta, wọ́n jù wọ́n sílẹ̀, kí gbogbo wọn sì fọ́ sí wẹ́wẹ́.

13Ní báyìí àwọn ọ̀wọ́ ogun tí Amasiah ti rán lọ padà, tí wọn kò nípa nínú ogun gbógun sí àwọn ìlú Juda láti Samaria sí Beti-Horoni. Wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta nínú wọn, wọ́n sì kó ọ̀pọ̀ ìkógun ńlá.

14Nígbà tí Amasiah padà láti ibi pípa àwọn ará Edomu, ó mú àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn Seiri padà wá. Ó gbé wọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àwọn ọlọ́run tirẹ̀. Ó tẹríba fún wọn, ó sì rú ẹbọ fún wọn. 15Ìbínú Olúwa ru sí Amasiah, ó sì rán wòlíì kan sí i, tí ó wí pé, “kí ni ó dé tí ìwọ fi ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ọlọ́run àwọn ènìyàn yìí, tí wọn kò le gba àwọn ènìyàn tiwọn kúrò lọ́wọ́ rẹ?”

16Bí ó ti n sọ̀rọ̀, ọba wí fún un pé, “Ṣé a yàn ọ́ ní olùgba ọba lámọ̀ràn ni? Dúró! Èéṣe tí a ó fi lù ọ́ bolẹ̀?”

Bẹ́ẹ̀ ni, wòlíì náà dúró ṣùgbọ́n ó wí pé, “Èmi mọ̀ pé Ọlọ́run ti pinnu láti pa ọ́ run nítorí ìwọ ti ṣe èyí, ìwọ kò sì tẹ́tí sí ìmọ̀ràn mi.”

1725.17-20,21-24: 2Ọb 14.8-14.Lẹ́yìn tí Amasiah ọba Juda ti béèrè lọ́wọ́ àwọn olùdámọ̀ràn, ó rán ìpèníjà yìí sí Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọmọ Jehu, ọba Israẹli pé: “Wá bá mi lójúkojú.”

18Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Israẹli fèsì padà sí Amasiah ọba Juda pé, “koríko kékeré kan ní Lebanoni rán iṣẹ́ sí igi kedari ní Lebanoni, fi ọmọbìnrin rẹ fún ọmọkùnrin mi ní ìgbéyàwó. Nígbà náà, ẹhànnà ẹranko ènìyàn ni Lebanoni wá, ó sì tẹ òṣùṣú náà lábẹ́ ẹsẹ̀. 19Ìwọ wí fún ara à rẹ wí pé, ìwọ ti ṣẹ́gun Edomu àti nísinsin yìí ìwọ ní ìhàlẹ̀ àti ìgbéraga. Ṣùgbọ́n dúró ní ilé! Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń wá wàhálà tí o sì fi ń fa ìṣubú rẹ àti ti Juda pẹ̀lú?”

20Amasiah, bí ó tì wù kí ó rí kò tẹ́tí nítorí Ọlọ́run ṣe é kí ó lè gbé wọn lé Jehoaṣi lọ́wọ́: nítorí wọ́n wá àwọn ọlọ́run Edomu. 21Bẹ́ẹ̀ ni Jehoaṣi, ọba Israẹli: òun àti Amasiah ọba Juda dojúkọ ara wọn ní Beti-Ṣemeṣi ní Juda. 22Àwọn ọmọ Israẹli da Juda rú, gbogbo olúkúlùkù ènìyàn sì sálọ sí ìlú rẹ̀. 23Jehoaṣi ọba Israẹli fi agbára mú Amasiah ọba Juda, ọmọ Joaṣi ọmọ Ahasiah ní Beti-Ṣemeṣi. Nígbà náà Joaṣi mú u wá sí Jerusalẹmu. Ó sì wó ògiri Jerusalẹmu lulẹ̀ láti ẹnu-ọ̀nà Efraimu sí igun ẹnu-ọ̀nà apá kan títí ń lọ sí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ẹsẹ̀ bàtà ní gígùn. 24Ọba kó gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò tí wọ́n rí ni ilé Ọlọ́run tí ọ́ wà ní àbojútó Obedi-Edomu, lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣúra ààfin àti àwọn ògo pẹ̀lú, ó sì padà lọ sí Samaria.

2525.25-28: 2Ọb 14.17-20.Amasiah ọmọ Joaṣi ọba Juda gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn ikú Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi ọba Israẹli. 26Fún ti iṣẹ́ mìíràn ti ìjọba Amasiah láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé àwọn ọba Juda àti Israẹli? 27Láti ìgbà tí Amasiah ti yípadà kúrò láti máa tẹ̀lé Olúwa, wọ́n dìtẹ̀ sí i ní Jerusalẹmu, ó sì sálọ sí Lakiṣi ṣùgbọ́n, wọ́n rán àwọn ọkùnrin tẹ̀lé e lọ sí Lakiṣi, wọ́n sì pa á síbẹ̀. 28A gbé e padà pẹ̀lú ẹṣin. A sì sin ín pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ ní ìlú ńlá ti Juda.