Jesaja 23 – HTB & YCB

Het Boek

Jesaja 23:1-18

Gods profetie over Tyrus

1Dit is Gods profetie over Tyrus.

Huil, schepen van Tyrus, die vanuit verre landen op de thuisreis zijn! Huil om uw haven, want hij is verdwenen! De geruchten die u op Cyprus hoorde, zijn waar. 2-3 Overal heerst een doodse stilte. De geluiden van de rumoerige haven, vol schepen uit Sidon die koopwaar van over de zee uit Egypte en het gebied langs de Nijl aanvoeren, zijn verstomd. U was de grootste handelsmarkt ter wereld.

4Schaam u, Sidon, bolwerk van de zee. Want nu bent u kinderloos! 5Als dit nieuws Egypte bereikt, zal het veel angst veroorzaken. 6Vlucht naar Tarsis, mannen van Tyrus, en huil onderweg. 7Deze verlaten ruïne is alles wat overbleef van uw eens zo luisterrijke stad. Het einde van een roemruchte geschiedenis. Denk eens aan alle kolonisten die u naar verre landen stuurde!

8Wie heeft deze ramp over Tyrus gebracht? Over dit land dat koninkrijken schiep en wiens inwoners de belangrijkste kooplieden ter wereld waren? 9De Here van de hemelse legers heeft dit gedaan, om uw trots te vernietigen en zijn verachting te tonen over de hooggeplaatsten onder de mensen. 10Zeil maar verder, schepen van Tarsis, want uw haven is er niet meer. 11De Here strekt zijn hand uit over de zee, Hij doet de koninkrijken van deze aarde beven, Hij geeft bevel de vestingen in Kanaän te verwoesten. 12Hij zegt: ‘U, onteerde maagd, dochter van Sidon, zult nooit meer blij of sterk zijn. Zelfs als u naar Cyprus vlucht, zult u geen rust vinden.’ 13Want het zullen de Babyloniërs en niet de Assyriërs zijn die Tyrus aanvallen. Zij zullen het belegeren, de paleizen met de grond gelijk maken en het herscheppen in een ruïne. 14Huil maar, schepen van Tarsis, want uw thuishaven is verdwenen!

15-16 Zeventig jaar lang zal Tyrus worden vergeten. Dan, onder een andere koning, zal de stad weer tot leven komen, zij zal mooie liederen spelen als een prostituee die lange tijd vergeten was. Nu loopt zij weer door de straten op zoek naar minnaars en wordt weer herkend. 17Ja, na zeventig jaar zal de Here Tyrus weer laten opleven, maar zij zal niet anders zijn dan vroeger, zij zal weer terugkeren op haar slechte wegen en hoererij bedrijven met de koninkrijken van de wereld. 18Maar de winst van haar handelstransacties zal aan de Here gewijd worden. Zij zal geen voorraad kunnen opslaan, maar het zal tot voedsel en kleding dienen voor hen die bij de Here wonen.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 23:1-18

Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Tire

123.1-18: El 26.1–28.19; Jl 3.4-8; Am 1.9-10; Sk 9.3-4.Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Tire:

Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi!

Nítorí a ti pa Tire run

láìsí ilé tàbí èbúté.

Láti ilẹ̀ Saipurọsi ni

ọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn.

2Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù

àti ẹ̀yin oníṣòwò ti Sidoni,

ẹ̀yin tí àwọn a wẹ Òkun ti sọ dọlọ́rọ̀.

3Láti orí àwọn omi ńlá

ni irúgbìn ìyẹ̀fun ti ilẹ̀ Ṣihori ti wá

ìkórè ti odò Naili ni owóòná Tire,

òun sì ti di ibùjókòó ọjà fún

àwọn orílẹ̀-èdè.

4Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Sidoni àti ìwọ

àní ìwọ ilé ààbò ti Òkun,

nítorí Òkun ti sọ̀rọ̀:

“Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí

Èmi kò tí ì wo àwọn ọmọkùnrin

tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.”

5Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Ejibiti,

wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa

ìròyìn láti Tire.

6Kọjá wá sí Tarṣiṣi;

pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù.

7Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyá yín,

ògbólógbòó ìlú náà,

èyí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọ

láti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré.

8Ta ló gbèrò èyí sí Tire,

ìlú aládé,

àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-aládé

tí àwọn oníṣòwò wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká

ní orílẹ̀ ayé?

9Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀,

láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ ba

àti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́lá

ilé ayé sílẹ̀.

10Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò odò Ejibiti,

Ìwọ ọmọbìnrin Tarṣiṣi,

nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́.

11Olúwa ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí Òkun

ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.

Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Kenaani

pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run.

12Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́”

ìwọ wúńdíá ti Sidoni, tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀ báyìí!

“Gbéra, rékọjá lọ sí Saipurọsi,

níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.”

13Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli,

àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí

Àwọn Asiria ti sọ ọ́ di

ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù;

wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè,

wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò

wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.

14Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;

wọ́n ti pa odi rẹ̀ run!

15Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tire fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tire gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè:

16“Mú dùùrù kan, rìn kọjá láàrín ìlú,

Ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé;

lu dùùrù dáradára, kọ ọ̀pọ̀ orin,

kí a lè ba à rántí rẹ.”

1723.17: If 17.2.Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, Olúwa yóò bá Tire jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí panṣágà, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé. 18Síbẹ̀síbẹ̀ èrè rẹ̀ àti owó iṣẹ́ rẹ̀ ni a ó yà sọ́tọ̀ fún Olúwa; a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́. Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú Olúwa, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ.