Jesaja 20 – HTB & YCB

Het Boek

Jesaja 20:1-6

Jesaja, symbool van vreselijke rampen

1In het jaar waarin koning Sargon van Assur zijn veldmaarschalk naar de Filistijnse stad Asdod stuurde en deze de stad innam, 2gaf de Here Jesaja, de zoon van Amoz, de opdracht: ‘Trek uw profetenmantel en uw sandalen uit en blijf zo rondlopen.’ Jesaja deed wat de Here hem opdroeg en liep op blote voeten ongekleed rond.

3Toen zei de Here: ‘Mijn dienaar Jesaja, die nu drie jaar lang naakt en op blote voeten heeft rondgelopen, is het symbool van de vreselijke rampen, die Ik over Egypte en Ethiopië zal brengen. 4Want de koning van Assur zal de Egyptenaren en Ethiopiërs gevankelijk wegvoeren, naakt en op blote voeten. Jong en oud zullen met blote billen lopen, tot schande van Egypte. 5Hoe ontmoedigd zullen de Filistijnen dan zijn, want zij rekenden op de “kracht van Ethiopië” en op hun “machtige bondgenoot” Egypte! 6En zij zullen zeggen: “Als Egypte zoiets kan overkomen, welke kans hebben wij dan nog”?’

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Isaiah 20:1-6

Àsọtẹ́lẹ̀ tó lòdì sí Ejibiti àti Kuṣi

1Ní ọdún tí olórí ogun, tí Sagoni ọba Asiria rán an, wá sí Aṣdodu, ó kọlù ú ó sì kó o— 2ní àkókò náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa ti ẹnu Isaiah ọmọ Amosi jáde. Ó sọ fún un pé, “Mú aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò ní ara rẹ kí o sì bọ́ sálúbàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà.

3Lẹ́yìn náà ni Olúwa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ mi Isaiah ti lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí ààmì àti àpẹẹrẹ sí Ejibiti àti Kuṣi, 4bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọba Asiria yóò kó àwọn ìgbèkùn Ejibiti lọ ní ìhòhò àti láì wọ bàtà pẹ̀lú àwọn àtìpó Kuṣi, ọ̀dọ́ àti àgbà, pẹ̀lú ìbàdí ìhòhò—bí àbùkù Ejibiti. 5Gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Kuṣi tí wọ́n sì ń fi Ejibiti yangàn ni ẹ̀rù yóò dé bá tí a ó sì dójútì wọ́n. 6Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ní etí Òkun yóò wí pé, ‘Wo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a ti gbẹ́kẹ̀lé, àwọn tí a sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ láti ọwọ́ ọba Asiria! Báwo ni a ó ṣe sálà?’ ”