Jeremia 41 – HTB & YCB

Het Boek

Jeremia 41:1-18

De dood van Gedalja

1Maar in de zevende maand kwam Ismaël naar Mispa. Hij was de zoon van Nethanja en kleinzoon van Elisama, lid van de koninklijke familie en een van de hoogste functionarissen van de koning. Hij had tien mannen bij zich. 2Tijdens de maaltijd sprongen Ismaël en zijn tien mannen plotseling op, trokken hun zwaarden en vermoordden Gedalja. 3Daarna gingen zij naar buiten en richtten een slachting aan onder de andere Judeeërs en de Babylonische soldaten die daar waren.

4De volgende dag, nog voordat iemand buiten Mispa wist wat daar was gebeurd, 5kwamen tachtig mannen uit Sichem, Silo en Samaria in Jeruzalem aan. Zij kwamen om de Here in zijn tempel te aanbidden. Zij hadden hun baard afgeschoren, hun kleren gescheurd en zichzelf gesneden en hadden offers en reukwerk bij zich. 6Ismaël ging hen vanuit Mispa tegemoet en huilde. Toen hij vlakbij was, zei hij: ‘Kom toch mee en kijk wat er met Gedalja is gebeurd!’ 7Toen de mannen echter in de stad aankwamen, doodden Ismaël en zijn mannen zeventig van hen en gooiden de lijken in een put. 8De tien overige mannen wisten hun leven te redden door Ismaël te beloven dat hij hun rijke voorraden tarwe, gerst, olie en honing, die zij ergens in het open veld hadden verstopt, zou krijgen. 9De put waarin Ismaël de lijken van de vermoorde mannen gooide, was de grote put die koning Asa gemaakt had toen hij Mispa versterkte om zich te beschermen tegen koning Baësa van Israël. 10Ismaël nam de dochters van de koning gevangen, evenals al de mensen die Nebuzaradan onder de hoede van Gedalja in Mispa had achtergelaten. Korte tijd later vertrok hij met hen allen naar het land van de Ammonieten.

11Maar toen Johanan, de zoon van Karéah, en de andere verzetsmensen hoorden wat Ismaël had gedaan, 12gingen zij hem met al hun manschappen achterna om tegen hem te vechten. De twee groepen ontmoetten elkaar bij het meer van Gibeon. 13-14 Toen de gevangenen van Ismaël Johanan en zijn mannen zagen aankomen, schreeuwden zij van vreugde en sloten zich direct bij hen aan. 15Ismaël ontsnapte ondertussen met acht van zijn mannen naar het land van de Ammonieten.

16-17 Daarop gingen Johanan en zijn mannen naar het dorp Geruth-Kimham, dichtbij Bethlehem. Zij namen alle bevrijde mensen met zich mee, soldaten, vrouwen, kinderen en regeringsfunctionarissen. Ze gingen met hen naar Egypte, 18want zij waren bang voor wat de Babyloniërs zouden doen als die hoorden dat Ismaël gouverneur Gedalja had vermoord. Deze was tenslotte persoonlijk benoemd door de koning van Babel.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Jeremiah 41:1-18

1Ní oṣù keje Iṣmaeli, ọmọ Netaniah ọmọ Eliṣama, nínú irú-ọmọ ọba, àti àwọn ìjòyè ọba, àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n tọ Gedaliah ọmọ Ahikamu wá ní Mispa; níbẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ jẹun ní Mispa. 2Iṣmaeli ọmọ Netaniah àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀, sì dìde wọ́n kọlu Gedaliah ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani pẹ̀lú idà. Wọ́n sì pa á, ẹni tí ọba Babeli ti fi jẹ baálẹ̀ lórí ilẹ̀ náà. 3Iṣmaeli sì tún pa gbogbo àwọn Júù tí wọ́n wà pẹ̀lú Gedaliah ní Mispa, àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun Babeli tí wọ́n wà níbẹ̀ bákan náà.

4Ní ọjọ́ kejì tí wọ́n pa Gedaliah kí ó tó di wí pé ẹnikẹ́ni mọ̀ 5Àwọn ọgọ́rin ọkùnrin wá láti Ṣekemu, Ṣilo àti Samaria, wọ́n fa irùngbọ̀n wọn, wọ́n ya aṣọ wọn, wọ́n ṣá ara wọn lọ́gbẹ́, wọ́n mú ẹbọ ọpẹ́ àti tùràrí wá sí ilé Olúwa. 6Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah jáde kúrò láti Mispa láti lọ pàdé wọn. Ó sì ń sọkún bí ó ti ṣe ń lọ, nígbà tí ó pàdé wọn, ó wí pé, “Ẹ wá sọ́dọ̀ Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu.” 7Nígbà tí wọ́n dé ìlú náà; Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa wọ́n, wọ́n sì sọ òkú wọn sínú ihò kan. 8Ṣùgbọ́n mẹ́wàá nínú wọn sọ fún Iṣmaeli pé, “Má ṣe pa wá! Àwa ní ọkà àti barle, òróró àti oyin ní ìpamọ́ nínú oko.” Nítorí náà, ó fi wọ́n sílẹ̀: kò sì pa wọ́n pẹ̀lú àwọn yòókù. 9Nísinsin yìí, ihò náà tí ó kó gbogbo ara àwọn ọkùnrin tí ó ti pa pẹ̀lú Gedaliah sí ni ọba Asa ń lò gẹ́gẹ́ bí i ààbò nítorí ọba Baaṣa ti Israẹli. Iṣmaeli ọmọ Netaniah sì ti kó òkú kún inú rẹ̀.

10Iṣmaeli sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní Mispa nígbèkùn, ọmọbìnrin ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn tókù síbẹ̀ lórí àwọn tí Nebusaradani balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti fi yan Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu ṣe olórí. Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah kó wọn ní ìgbèkùn, ó sì jáde rékọjá sí ọ̀dọ̀ àwọn Ammoni.

11Nígbà tí Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́ nípa gbogbo ìpànìyàn náà tí Iṣmaeli ọmọ Netaniah ti ṣe. 12Wọ́n kó gbogbo àwọn ọkùnrin wọn, wọ́n sì, lọ bá Iṣmaeli ọmọ Netaniah jà. Wọ́n pàdé rẹ̀ ní odò kan lẹ́bàá Gibeoni. 13Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn Iṣmaeli tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ rí Johanani ọmọkùnrin Karea àti àwọn olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì yọ̀. 14Gbogbo àwọn ènìyàn tí Iṣmaeli ti kó ní ìgbèkùn ní Mispa yípadà, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ Johanani ọmọ Karea. 15Ṣùgbọ́n Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah àti àwọn mẹ́jọ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ Johanani, wọ́n sì sálọ sí Ammoni.

Sísá lọ sí Ejibiti

16Lẹ́yìn náà Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí wọn wà pẹ̀lú rẹ̀ sì kó gbogbo àwọn tí ó kù ní Mispa; àwọn tí ó ti rí gbà lọ́wọ́ Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah; lẹ́yìn ìgbà tí ó ti pa Gedaliah ọmọ Ahikamu. Àwọn ọmọ-ogun, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn olórí ilé ẹjọ́ tí ó ti kó wa láti Gibeoni. 17Wọ́n sì kúrò níbẹ̀, wọ́n dúró ní Geruti Kimhamu ní ẹ̀bá Bẹtilẹhẹmu ní ọ́nà ìrìnàjò wọn sí Ejibiti. 18Láti gba àwọn Babeli sílẹ̀. Wọ́n bẹ̀rù wọn nítorí wí pé, “Iṣmaeli ọmọ Netaniah ti pa Gedaliah ọmọ Ahikamu èyí tí ọba Babeli ti yàn gẹ́gẹ́ bí i gómìnà lórí ilẹ̀ náà.”